Jèhófà Ń kó Wa Yọ Nínú Páńpẹ́ Pẹyẹpẹyẹ
“[Jèhófà] tìkára rẹ̀ yóò dá ọ nídè kúrò nínú pańpẹ́ pẹyẹpẹyẹ.”—SÁÀMÙ 91:3.
1. Ta ni “pẹyẹpẹyẹ” náà, kí nìdí tó sì fi yẹ ká ṣọ́ra fún un?
ẸNÌ kan wà tó fẹ́ pa gbogbo àwa Kristẹni run, ọgbọ́n ẹni náà sì ga ju tèèyàn lọ fíìfíì. Bíbélì pe ẹni yìí ní “pẹyẹpẹyẹ” nínú Sáàmù 91:3. Ta ni ọ̀tá yìí? Látìgbà tí ẹ̀dà ìwé ìròyìn yìí, ti June 1, ọdún 1883 ti jáde, ló ti jẹ́ ká mọ̀ pé Sátánì Èṣù ni ọ̀tá náà. Ọ̀tá tó lágbára gan-an yìí máa ń lo ọgbọ́n àyínìke láti ṣi àwọn èèyàn Jèhófà lọ́nà àti láti dẹkùn mú wọn bí pẹyẹpẹyẹ ṣe máa ń dẹkùn mẹ́yẹ.
2. Kí nìdí tí Bíbélì ṣe fi Sátánì wé pẹyẹpẹyẹ?
2 Láyé ọjọ́un, àwọn èèyàn máa ń mú ẹyẹ nítorí orin dídùn táwọn ẹyẹ máa ń kọ, nítorí ìyẹ́ wọn tó rẹwà gan-an, àti nítorí kí wọ́n lè pa wọ́n jẹ tàbí láti fi wọ́n rúbọ. Àmọ́ ẹyẹ jẹ́ ẹ̀dá kan tó nífura gan-an, ó máa ń ṣọ́ra, ó sì máa ń ṣòroó mú. Nítorí náà, lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ẹni tó bá fẹ́ mú ẹyẹ yóò kọ́kọ́ fara balẹ̀ kíyè sí ẹyẹ tó fẹ́ mú náà dáadáa, á sì mọ àwọn ìṣesí ẹyẹ náà. Lẹ́yìn náà, yóò wá àwọn ọ̀nà ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tó máa fi mú un. Ìdí tí Bíbélì ṣe fi Sátánì wé pẹyẹpẹyẹ ni pé ká lè mọ àwọn ọ̀nà tó máa ń lò. Sátánì máa ń fara balẹ̀ kíyè sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Ó máa ń wo bá a ti ń hùwà àtàwọn ìṣesí wa, lẹ́yìn náà yóò wá dẹ páńpẹ́ tá ò ní fura sí láti fi mú wa. (2 Tímótì 2:26) Bí Sátánì bá sì rí wa mú pẹ́nrẹ́n, àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà bà jẹ́ nìyẹn, èyí sì lè yọrí sí ìparun fún wa. Nítorí náà, ká má bàa kó sọ́wọ́ rẹ̀, ó yẹ ká mọ oríṣiríṣi ọ̀nà tí “pẹyẹpẹyẹ” yìí ń lò.
3, 4. Ìgbà wo làwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ Sátánì máa ń jọ ti kìnnìún, ìgbà wo ni wọ́n sì máa ń jọ ti ejò ṣèbé?
3 Ẹni tó kọ Sáàmù yìí tún lo àpèjúwe kan tó fakíki, ó fi àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ Sátánì wé ti ẹgbọrọ kìnnìún tàbí ti ejò ṣèbé. (Sáàmù 91:13) Bíi ti kìnnìún, Sátánì máa ń pa kuuru mọ́ wa nígbà míì nípa lílo inúnibíni tàbí nípa mímú kí ìjọba gbógun tàwọn èèyàn Jèhófà. (Sáàmù 94:20) Irú àwọn ìgbéjàkò tó jọ ti kìnnìún yìí lè mú káwọn kan fi Jèhófà sílẹ̀. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, òdìkejì ohun tó wà lọ́kàn àwọn tó ń ṣenúnibíni ló máa ń ṣẹlẹ̀, torí pé ńṣe làwọn àtakò ojúkoojú yìí máa ń mú káwọn èèyàn Ọlọ́run túbọ̀ wà níṣọ̀kan. Àmọ́, àwọn ìgbéjàkò Sátánì tá ò fura sí, èyí tó jọ bí ejò ṣèbé ṣe ń yọ́ kẹ́lẹ́ ṣọṣẹ́ ńkọ́?
4 Èṣù máa ń lo ọgbọ́n rẹ̀ tó ga ju tèèyàn lọ láti gbéjà kò wá lọ́nà tá ò fura sí tó sì jẹ́ ọ̀nà tó lè ṣekú pani bí ejò olóró ṣe máa ń pitú láti ibi tó fara pamọ́ sí. Ó ti tipa báyìí sọ èrò àwọn Kristẹni kan dìdàkudà, débi pé ìfẹ́ rẹ̀ ni wọ́n ń ṣe dípò ìfẹ́ Jèhófà, èyí sì ti yọrí sí ìbànújẹ́. Inú wa dùn pé a kò ṣàìmọ àwọn ètekéte Sátánì. (2 Kọ́ríńtì 2:11) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká gbé mẹ́rin yẹ̀ wò lára àwọn páńpẹ́ tó lè ṣekú pani tí “pẹyẹpẹyẹ” yìí máa ń lò.
Ìbẹ̀rù Èèyàn
5. Kí nìdí tó fi rọrùn gan-an láti kó sínú ìdẹkùn “wíwárìrì nítorí ènìyàn”?
5 “Pẹyẹpẹyẹ” yìí mọ̀ pé àwa èèyàn kì í fẹ́ káwọn mìíràn ta wá nù, a máa ń fẹ́ kí wọ́n gba tiwa ni, èyí kò sì burú. Àwa Kristẹni máa ń bìkítà nípa èrò àwọn ẹlòmíràn àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wọn. Èṣù mọ èyí, ó sì máa ń fẹ́ mú wa nípa lílo àníyàn tá a máa ń ní nígbà táwọn èèyàn bá ní èrò òdì nípa wa. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń dẹkùn mú àwọn kan lára àwọn èèyàn Ọlọ́run nípa mímú kí wọ́n máa ‘wárìrì nítorí ènìyàn.’ (Òwe 29:25) Táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run bá lọ torí ìbẹ̀rù èèyàn ṣe ohun táwọn mìíràn ń ṣe tó sì jẹ́ ohun tí Jèhófà sọ pé kò dára, tàbí tí wọ́n kọ̀ láti ṣe ohun tí Ọlọ́run pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe, “pẹyẹpẹyẹ” náà ti rí wọn mú nìyẹn.—Ìsíkíẹ́lì 33:8; Jákọ́bù 4:17.
6. Àpẹẹrẹ wo ló jẹ́ ká rí ọ̀nà tí ọ̀dọ́ kan lè gbà dẹni tí “pẹyẹpẹyẹ” náà dẹkùn mú?
6 Bí àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́ kan lè juwọ́ sílẹ̀ táwọn ọmọléèwé rẹ̀ bá fi sìgá lọ̀ ọ́. Ó lè má wá sọ́kàn rẹ̀ rárá pé òun á mu sìgá nígbà tó kúrò nílé lọ́jọ́ yẹn. Àmọ́ kó tó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó máa ṣàkóbá fún ìlera rẹ̀ tó sì tún jẹ́ ohun tí kò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú. (2 Kọ́ríńtì 7:1) Báwo ló ṣe dẹni tó lọ́wọ́ sírú nǹkan bẹ́ẹ̀? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ló lọ bá àwọn ọmọkọ́mọ rìn tí ẹ̀rù sì ń bà á pé wọn kò ní gba tòun. Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ má ṣe jẹ́ kí “pẹyẹpẹyẹ” náà rí yín tàn jẹ kó sì dẹkùn mú yín o! Kó má bàa rí yín mú láàyè, ẹ má ṣe juwọ́ sílẹ̀, kódà nínú àwọn nǹkan kéékèèké. Ẹ fi ìkìlọ̀ Bíbélì tó sọ pé kẹ́ ẹ yẹra fún ẹgbẹ́ búburú sílò.—1 Kọ́ríńtì 15:33.
7. Báwo ni Sátánì ṣe lè mú káwọn òbí kan dẹni tí kò fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run mọ́?
7 Àwọn òbí tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ máa ń rí i dájú pé àwọn ṣe ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ pé káwọn ṣe, ìyẹn ni pé kí wọ́n pèsè ohun tí ìdílé wọn nílò fún wọn. (1 Tímótì 5:8) Àmọ́ ohun tí Sátánì fẹ́ ni pé káwọn Kristẹni dẹni tó ń gbájú mọ́ ọ̀rọ̀ àtijẹ-àtimu nìkan. Wọ́n lè máa pa ìpàdé jẹ nígbà gbogbo torí pé ọ̀gá wọn níbi iṣẹ́ sọ pé wọ́n gbọ́dọ̀ máa ṣe àfikún iṣẹ́. Ẹ̀rù lè máa bà wọ́n láti tọrọ àyè níbi iṣẹ́ láti lọ gbádùn ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àgbègbè látìbẹ̀rẹ̀ dópin kí wọ́n sì lè jọ́sìn Jèhófà pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn. Ohun tí kò ní jẹ́ kí wọ́n kó sínú ìdẹkùn yìí ni pé kí wọ́n “gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.” (Òwe 3:5, 6) Bákan náà, tá a bá ń rántí pé apá kan ìdílé Jèhófà ni gbogbo wa àti pé ó ti ṣèlérí pé òun á bójú tó wa, èyí kò ní jẹ́ ká sọ ọ̀rọ̀ àtijẹ-àtimu di ohun tó ṣe pàtàkì jù. Ẹ̀yin òbí, ǹjẹ́ ẹ nígbàgbọ́ pé lọ́nà kan tàbí òmíràn, Jèhófà yóò bójú tó ẹ̀yin àti ìdílé yín tẹ́ ẹ bá ṣe ìfẹ́ rẹ̀? Àbí ẹ máa jẹ́ kí Èṣù dẹ páńpẹ́ mú yín kó sì sọ yín dẹni tó ń ṣèfẹ́ rẹ̀ nítorí ìbẹ̀rù èèyàn? A rọ̀ yín pé kẹ́ ẹ ronú lórí àwọn ìbéèrè yìí kẹ́ ẹ sì gbàdúrà nípa wọn.
Ìfẹ́ Ọrọ̀ Lè Dẹkùn Múni
8. Ọ̀nà wo ni Sátánì ń gbà lo ìfẹ́ ọrọ̀ láti dẹkùn múni?
8 Sátánì tún máa ń lo ìfẹ́ ọrọ̀ láti dẹ páńpẹ́ mú wa. Ètò ìṣòwò ayé yìí sábà máa ń mú káwọn èèyàn lọ́wọ́ sáwọn okòwò tó lè sọni dolówó òjijì, èyí sì lè tan àwọn kan lára àwọn èèyàn Ọlọ́run pàápàá jẹ. Nígbà míì, wọ́n lè fún ẹnì kan nímọ̀ràn pé: “Ṣiṣẹ́ kára o. Tí nǹkan bá ti wá rọ̀ ṣọ̀mù fún ẹ tán, ó lè wá tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́ kó o sì máa gbádùn ayé rẹ. Kódà, o tiẹ̀ lè máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà pàápàá.” Irú àwọn ọ̀rọ̀ báyìí lè jẹ́ ọ̀nà tí kò bọ́gbọ́n mu táwọn kan ń gbà ronú, ìyẹn àwọn tó máa ń fẹ́ láti jìfà lára àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn nínú ìjọ Ọlọ́run. Ṣọ́ra fún irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Ǹjẹ́ kò jọ èrò ọkùnrin ọlọ́rọ̀ inú àkàwé Jésù yẹn tó jẹ́ “aláìlọ́gbọ́n-nínú”?—Lúùkù 12:16-21.
9. Kí nìdí tí ìfẹ́ àwọn nǹkan tara fi lè sọ àwọn Kristẹni kan dẹni tí Èṣù dẹkùn mú?
9 Ọ̀nà tí Sátánì ń gbà dárí ètò àwọn nǹkan búburú rẹ̀ yìí máa ń mú káwọn èèyàn fẹ́ láti máa ní nǹkan ṣáá. Ìfẹ́ yìí lè wá ṣàkóbá fún ìgbésí ayé Kristẹni kan tó bá yá. Ó lè fún ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa nínú rẹ̀, kó sì mú kó di “aláìléso.” (Máàkù 4:19) Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé ká jẹ́ kóhun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ tẹ́ wa lọ́rùn. (1 Tímótì 6:8) Àmọ́ ohun tó ń mú kí ọ̀pọ̀ kó sínú páńpẹ́ “pẹyẹpẹyẹ” náà ni pé wọn ò gbà pé àwọn nílò ìmọ̀ràn yẹn. Àbí ó lè jẹ́ pé ìgbéraga ló mú kí wọ́n máa rò pé irú ìgbésí ayé táwọn ti ń gbé bọ̀ látẹ̀yìnwá ló yẹ káwọn máa gbé lọ? Àwa náà ńkọ́? Ǹjẹ́ fífẹ́ láti ní àwọn nǹkan ń mú ká máa wo ìjọsìn tòótọ́ bí ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì? (Hágáì 1:2-8) Ó bani nínú jẹ́ pé táwọn kan bá níṣòro owó, ńṣe ni wọ́n máa ń pa ìjọsìn wọn sí Ọlọ́run tì kí wọ́n lè máa gbé irú ìgbésí ayé tó ti mọ́ wọn lára lọ. Ńṣe ni irú ìwà tó fi hàn pé èèyàn nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ yìí máa ń múnú “pẹyẹpẹyẹ” náà dùn!
Ohun Ìnàjú Tí Kò Bójú Mu Lè Dẹkùn Múni
10. Àyẹ̀wò wo ló yẹ kí Kristẹni kọ̀ọ̀kan ṣe nípa ara rẹ̀?
10 Ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ mìíràn tí “pẹyẹpẹyẹ” yìí tún máa ń lò ni pé káwọn èèyàn má lè fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó dára àtohun tó burú. Irú èrò àwọn ara Sódómù àti Gòmórà ayé ọjọ́un ló wá ń fara hàn nínú àwọn ohun ìnàjú tí wọ́n ń ṣe jáde báyìí. Kódà, ìwà ipá àti ìṣekúṣe tó burú jáì làwọn ìròyìn orí tẹlifíṣọ̀n àtàwọn ohun tó ń jáde nínú ìwé ìròyìn ń dá lé lórí jù. Ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n sì ń gbé jáde láti dá àwọn èèyàn lára yá kò jẹ́ káwọn èèyàn lè “fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Hébérù 5:14) Àmọ́ rántí ohun tí Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì Aísáyà sọ pé: “Ègbé ni fún àwọn tí ń sọ pé ohun tí ó dára burú àti pé ohun tí ó burú dára!” (Aísáyà 5:20) Ṣé “pẹyẹpẹyẹ” yẹn ti dọ́gbọ́n fi irú àwọn ohun ìnàjú burúkú bẹ́ẹ̀ sọ ìrònú rẹ dìdàkudà? Ó yẹ kó o yẹ ara rẹ wò.—2 Kọ́ríńtì 13:5.
11. Ìkìlọ̀ wo ni ìwé ìròyìn yìí ṣe nípa àwọn eré ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ tí wọ́n máa ń ṣe lórí tẹlifíṣọ̀n?
11 Ní ọdún mẹ́rìnlélógún sẹ́yìn, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ fi tìfẹ́tìfẹ́ kìlọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà pé kí wọ́n ṣọ́ra fún àwọn eré ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ tó máa ń wáyé lórí tẹlifíṣọ̀n.a Ohun tó sọ nípa báwọn eré wọ̀nyí ṣe ń nípa lórí àwọn èèyàn láìmọ̀ rèé, ó ní: ‘Nítorí ọ̀rọ̀ ìfẹ́, kò sí ìwà burúkú kankan tó burú lójú àwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, ọmọbìnrin kan tó gboyún láì ṣègbéyàwó sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan pé: “Àní mo nífẹ̀ẹ́ Victor. Ohunkóhun tó bá wu àwọn èèyàn ni kí wọ́n sọ. . . . Kí n ṣáà ti bímọ fún un lohun tó jẹ mi lógún jù lọ láyé yìí!” Orin tó rọra ń dún lábẹ́lẹ̀ kò jẹ́ káwọn tó ń wo eré náà rí i pé ohun tí ọmọbìnrin náà ṣe burú gan-an. Ìwọ tí ò ń wo eré yẹn náà nífẹ̀ẹ́ Victor. Àánú ọmọbìnrin náà ṣe ọ́. O fara mọ́ ohun tí kò dára tí wọ́n ṣe. Arábìnrin kan tó máa ń wo irú eré yìí tẹ́lẹ̀ àmọ́ tó wá ronú ara rẹ̀ wò nígbà tó yá sọ pé, “Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé èèyàn lè máa ronú pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò burú. A mọ̀ pé ìṣekúṣe kò dára. . . . Àmọ́ mo rí i pé nínú ọkàn mi lọ́hùn-ún, mi ò gbà pé ohun tí wọ́n ṣe burú.”’
12. Àwọn ohun wo ló fi hàn pé àwọn ìkìlọ̀ tá a ń rí gbà báyìí lórí wíwo irú àwọn eré kan lórí tẹlifíṣọ̀n bọ́ sákòókò?
12 Látìgbà táwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyẹn ti jáde, irú eré tó ń sọ ọkàn dìdàkudà yìí ti wá pọ̀ rẹpẹtẹ. Ní ọ̀pọ̀ ibi, tọ̀sán tòru ni wọ́n máa ń ṣe irú àwọn eré bẹ́ẹ̀ lórí tẹlifíṣọ̀n. Àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin, àti ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ máa ń gba irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ sọ́kàn wọn déédéé. Àmọ́ àwa ò gbọ́dọ̀ tanra wa jẹ, ká máa rò pé kò sóhun tó burú nínú irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Kò ní bọ́gbọ́n mu ká máa ronú pé àwọn ohun ìnàjú tí kò bójú mu kò kúkú burú ju àwọn ohun tá à ń rí tó ń ṣẹlẹ̀ láyìíká wa. Ǹjẹ́ Kristẹni kan lè sọ pé kò sóhun tó burú nínú jíjẹ́ kí àwọn tí kò jẹ́ gbà lálejò sínú ilé rẹ̀ láé wá máa dá òun lára yá?
13, 14. Ọ̀nà wo làwọn kan sọ pé àwọn gbà jàǹfààní látinú àwọn ìkìlọ̀ nípa tẹlifíṣọ̀n?
13 Ọ̀pọ̀ rí ẹ̀kọ́ kọ́ nígbà tí wọ́n fi ìkìlọ̀ tó wá látọ̀dọ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” yìí sílò. (Mátíù 24:45-47) Lẹ́yìn táwọn kan ka ìmọ̀ràn tó sojú abẹ́ níkòó tó sì bá Bíbélì mu yìí, wọ́n kọ̀wé láti sọ báwọn àpilẹ̀kọ náà ṣe ran àwọn lọ́wọ́.b Ẹnì kan kọ̀wé pé: ‘Fún odindi ọdún mẹ́tàlá lo fi jẹ́ pé mi ò lè ṣe kí n má wo eré kan tí wọ́n máa ń ṣe lórí tẹlifíṣọ̀n lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Mo rò pé níwọ̀n ìgbà tí mo ti ń lọ sípàdé tí mo sì ń lọ sóde ìwàásù lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, kò séwu. Àmọ́ mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í ní irú èrò táwọn èèyàn ayé máa ń ní, èyí tó máa ń fara hàn nínú àwọn eré wọ̀nyí, pé tí ọkọ ẹni bá ń hùwàkiwà síni tàbí téèyàn rí i pé kò nífẹ̀ẹ́ òun, kò sóhun tó burú nínú kéèyàn ṣe panṣágà, ọkùnrin yẹn ló fọwọ́ ara rẹ̀ fà á. Bí mo ṣe lọ hùwà burúkú yìí nìyẹn nígbà ti mo ronú pé kò ‘sóhun tó burú’ níbẹ̀ mo sì ṣẹ̀ sí Jèhófà àti sí ọkọ mi.’ Obìnrin yìí dẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́. Nígbà tó yá, ó gbà pé ohun tí òun ṣe kò dára, ó ronú pìwà dà, wọ́n sì gbà á padà sínú ìjọ Ọlọ́run. Àwọn àpilẹ̀kọ tó kìlọ̀ nípa àwọn eré ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ lórí tẹlifíṣọ̀n fún un lókun láti má ṣe máa fi ohun tí Jèhófà kórìíra najú.—Ámósì 5:14, 15.
14 Ẹlòmíràn tí irú àwọn eré bẹ́ẹ̀ ti ṣàkóbá fún tóun náà ka àwọn àpilẹ̀kọ yẹn sọ pé: ‘Mo sunkún nígbà tí mo ka àwọn àpilẹ̀kọ yẹn, torí pé wọ́n jẹ́ kí n rí i pé mi ò fi gbogbo ọkàn mi sin Jèhófà. Mo ṣèlérí fún Ọlọ́run mi pé mi ò tún ní sọ ara mi dẹrú fún irú àwọn eré bẹ́ẹ̀ mọ́.’ Lẹ́yìn tí arábìnrin kan dúpẹ́ fún àwọn àpilẹ̀kọ yìí, ó jẹ́wọ́ pé wíwo irú àwọn eré bẹ́ẹ̀ ti di bárakú fóun, ó wá kọ̀wé pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé . . . ǹjẹ́ kò ní ṣàkóbá fún àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà. Báwo làwọn tí mò ń wò nínú àwọn eré wọ̀nyí ṣe lè jẹ́ ọ̀rẹ́ mi kí Jèhófà sì tún jẹ́ ọ̀rẹ́ mi?” Bí irú àwọn eré bẹ́ẹ̀ bá sọ ọkàn àwọn èèyàn dìdàkudà lọ́dún mẹ́rìnlélógún sẹ́yìn, ipa wo ni wọ́n á máa ní lórí àwọn èèyàn lónìí? (2 Tímótì 3:13) A gbọ́dọ̀ mọ̀ pé Sátánì ń fi eré ìnàjú dẹ páńpẹ́ ní oríṣiríṣi ọ̀nà tí wọ́n lè gbà wá, ì báà jẹ́ àwọn eré ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ lórí tẹlifíṣọ̀n, eré kọ̀ǹpútà oníwà ipá, tàbí àwọn fídíò orin oníṣekúṣe.
Sátánì Lè Lo Èdèkòyédè Láti Dẹkùn Mú Ọ
15. Ọ̀nà wo ni àwọn kan ti gbà kó sínú páńpẹ́ Èṣù?
15 Sátánì máa ń lo èdèkòyédè bíi páńpẹ́ láti dá ìpínyà sílẹ̀ láàárín àwọn èèyàn Jèhófà. Èṣù lè dẹkùn mú wa lọ́nà yìí, kódà bá a tiẹ̀ ní àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ètò Ọlọ́run. Àwọn kan tiẹ̀ ti kó sínú páńpẹ́ Èṣù nítorí pé wọ́n ń jẹ́ kí èdèkòyédè ṣàkóbá fún àlàáfíà, ìṣọ̀kan, àti àjọṣe rere tí Jèhófà fi jíǹkí àwọn èèyàn rẹ̀.—Sáàmù 133:1-3.
16. Báwo ni Sátánì ṣe ń gbìyànjú láti fi ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí dá ìpínyà sílẹ̀ láàárín wa?
16 Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, Sátánì gbìyànjú láti pa apá tó jẹ́ ti orí ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà run nípa gbígbèjà kò ó ní tààràtà, àmọ́ ó kùnà. (Ìṣípayá 11:7-13) Látìgbà náà ló ti ń lo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí láti fa ìpínyà láàárín wa. Tá a bá jẹ́ kí èdèkòyédè da àárín wa rú, á jẹ́ pé a ti fún “pẹyẹpẹyẹ” náà láyè láti wọlé sáàárín wa nìyẹn. A lè tipa báyìí ṣèdíwọ́ fún ẹ̀mí mímọ́ débi pé kò ní lè ṣiṣẹ́ dáadáa nínú ìgbésí ayé wa àti nínú ìjọ. Bírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, inú Sátánì á dùn gan-an nítorí pé tí kò bá sí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan nínú ìjọ, èyí máa ń ṣèdíwọ́ fún iṣẹ́ ìwàásù.—Éfésù 4:27, 30-32.
17. Kí ló lè ran àwọn tó ní èdèkòyédè lọ́wọ́ láti yanjú rẹ̀?
17 Kí lo lè ṣe bí èdèkòyédè bá ṣẹlẹ̀ láàárín ìwọ àtẹnì kan tẹ́ ẹ jọ jẹ́ Kristẹni? Lóòótọ́, ìṣòro yàtọ̀ síra. Àmọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè fàṣòro, kò sídìí kankan tí kò fi yẹ ká yanjú èdèkòyédè tó lè wà láàárín wa. (Mátíù 5:23, 24; 18:15-17) Ọlọ́run mí sí ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọn ò sì lábùkù rárá. Àwọn ìlànà Bíbélì kò kùnà rí tá a bá fi wọn sílò. Gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń yọrí sí rere!
18. Báwo ni fífara wé Jèhófà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti yanjú èdèkòyédè?
18 Jèhófà “ṣe tán láti dárí jini” bẹ́ẹ̀ sì ni “ìdáríjì tòótọ́” wà lọ́dọ̀ rẹ̀. (Sáàmù 86:5; 130:4) Tá a bá ń fara wé Jèhófà, ńṣe là ń fi hàn pé a jẹ́ ọmọ tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ gan-an. (Éfésù 5:1) Gbogbo wa la jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tá a sì nílò ìdáríjì Jèhófà lójú méjèèjì. Ìdí èyí ló fi yẹ ká ṣọ́ra gan-an tó bá ń ṣe wá bíi pé ká má ṣe dárí ji ẹnì kan tó ṣẹ̀ wá. A lè dà bí ẹrú tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú àkàwé kan. Ó kọ̀ láti darí ji ẹrú bíi tirẹ̀ tó jẹ ẹ́ lówó tó kéré gan-an tá a bá fi wé gbèsè ńlá tóun jẹ́ ọ̀gá rẹ̀ tí ọ̀gá rẹ̀ sì darí rẹ̀ jì í. Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, ó ní kí wọ́n lọ ju ẹrú tí kò darí ji ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yẹn sẹ́wọ̀n. Jésù wá parí àkàwé náà nípa sísọ pé: “Ọ̀nà kan náà ni Baba mi ọ̀run yóò gbà bá yín lò pẹ̀lú bí olúkúlùkù yín kò bá dárí ji arákùnrin rẹ̀ láti inú ọkàn-àyà yín wá.” (Mátíù 18:21-35) Tá a bá ronú jinlẹ̀ lórí àkàwé yìí, tá a sì rántí pé àìmọye ìgbà ni Jèhófà ti darí jì wá fàlàlà, dájúdájú èyí á ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá ń gbìyànjú láti yanjú èdèkòyédè àárín àwa àti arákùnrin wa!—Sáàmù 19:14.
Kò Séwu Tá A Bá Wà Ní “Ibi Ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ”
19, 20. Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo “ibi ìkọ̀kọ̀” Jèhófà àti “òjìji” rẹ̀ lákòókò eléwu tá a wà yìí?
19 Àkókò tá a wà yìí léwu gan-an. Ká ní kì í ṣe pé Jèhófà ń dáàbò bò wá tìfẹ́tìfẹ́ ni, ó dájú pé Sátánì á ti pa gbogbo wa run. Ká má bàa kó sínú páńpẹ́ “pẹyẹpẹyẹ” náà, a ò gbọ́dọ̀ kúrò ní ibi ààbò ìṣàpẹẹrẹ, a sì ní láti máa “gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ” nípa wíwá “ibùwọ̀ fún ara [wa] lábẹ́ òjìji Olódùmarè.”—Sáàmù 91:1.
20 Ẹ jẹ́ ká máa wo àwọn ìránnilétí Jèhófà àtàwọn ìtọ́sọ́nà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun tó ń dáàbò bò wá, ká má ṣe wò wọ́n bí ohun tó ń ká wa lọ́wọ́ kò. Gbogbo wa pátá ni ọ̀tá tọ́gbọ́n rẹ̀ ju tèèyàn lọ fíìfíì yìí dojú kọ. Ká ní kì í ṣe pé Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ tìfẹ́tìfẹ́ ni, ì bá máà sẹ́nì kankan nínú wa tó máa bọ́ nínú páńpẹ́ rẹ̀. (Sáàmù 124:7, 8) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa gbàdúrà pé kí Jèhófà kó wa yọ nínú àwọn páńpẹ́ tí “pẹyẹpẹyẹ” náà ń dẹ sílẹ̀!—Mátíù 6:13.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ile-Iṣọ Naa, June 1, 1983, ojú ìwé 3 sí 7.
b Ile-Iṣọ Naa, June 1, 1984, ojú ìwé 23.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí nìdí tí “ìwárìrì nítorí èèyàn” fi jẹ́ páńpẹ́ tó lè ṣekú pani?
• Ọ̀nà wo ni Èṣù ń gbà lo ìfẹ́ ọrọ̀ láti dẹkùn múni?
• Ọ̀nà wo ni Sátánì ti gbà fi eré ìnàjú tí kò bójú mu dẹkùn mú àwọn kan?
• Páńpẹ́ wo ni Èṣù ń lò láti da àárín wa rú?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Ìbẹ̀rù èèyàn ti dẹkùn mú àwọn kan
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Ṣé àwọn ohun tí Jèhófà kórìíra lo fi ń najú?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Kí lo lè ṣe bí ìwọ àtẹnì kan tẹ́ ẹ jọ jẹ́ Kristẹni bá ní èdèkòyédè?