Ǹjẹ́ o Fara Mọ́ Ìṣàkóso Jèhófà?
“Ẹ wí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè pé: ‘Jèhófà fúnra rẹ̀ ti di ọba.’”—SÁÀMÙ 96:10.
1, 2. (a) Ohun àgbàyanu wo ló ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí oṣù October ọdún 29 Sànmánì Kristẹni? (b) Kí lohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ kí Jésù mọ̀?
OHUN àgbàyanu kan ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí oṣù October ọdún 29 Sànmánì Kristẹni. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí lórí ilẹ̀ ayé. Mátíù, ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ náà, ó ní: “Lẹ́yìn tí a batisí rẹ̀, Jésù jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti inú omi; sì wò ó! ọ̀run ṣí sílẹ̀, [Jòhánù Olùbatisí] sì rí tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń sọ̀kalẹ̀ bí àdàbà bọ̀ wá sórí [Jésù]. Wò ó! Pẹ̀lúpẹ̀lù, ohùn kan wá láti ọ̀run tí ó wí pé: ‘Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.’” Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ díẹ̀ tó jẹ́ pé gbogbo àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó kọ ìwé Ìhìn Rere ló sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.—Mátíù 3:16, 17; Máàkù 1:9-11; Lúùkù 3:21, 22; Jòhánù 1:32-34.
2 Ẹ̀mí mímọ́ tí Ọlọ́run tú dà sórí Jésù, tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà sì ṣojú àwọn èèyàn, fi hàn pé Jésù ni Ẹni Àmì Òróró náà, ìyẹn Mèsáyà tàbí Kristi. (Jòhánù 1:33) Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, “Irú-ọmọ” tí Ọlọ́run ṣèlérí náà fara hàn! Ẹni tí Sátánì yóò pa ní gìgísẹ̀ ló wà níwájú Jòhánù Olùbatisí yìí, òun ló sì máa fọ́ orí ẹni tó jẹ́ olórí ọ̀tá Jèhófà àti ìṣàkóso Rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Àtìgbà náà ni Jésù ti mọ̀ dájú pé òun gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá òun láti mú ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn nípa ìṣàkóso Rẹ̀ àti Ìjọba Rẹ̀ ṣẹ.
3. Báwo ni Jésù ṣe múra sílẹ̀ fún ipa tó máa kó nínú fífi hàn pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso?
3 Kí Jésù lè múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ tó wà níwájú rẹ̀, “bí ó ti kún fún ẹ̀mí mímọ́, ó kúrò ní Jọ́dánì, ẹ̀mí sì ṣamọ̀nà rẹ̀ káàkiri nínú aginjù.” (Lúùkù 4:1; Máàkù 1:12) Ogójì ọjọ́ ni Jésù fi wà níbẹ̀, èyí sì jẹ́ kó ní àkókò tó pọ̀ tó láti ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀ràn tí Sátánì dá sílẹ̀ nípa ẹni tó yẹ kó jẹ́ alákòóso àti irú ìgbésí ayé tóun gbọ́dọ̀ gbé láti fi hàn pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso. Gbogbo èèyàn tó wà láyé àtàwọn áńgẹ́lì lọ́run lọ̀ràn yìí kàn. Ìdí nìyí tó fi yẹ ká ronú lórí jíjẹ́ tí Jésù jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run ká lè mọ ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe láti fi hàn pé ìṣàkóso Jèhófà ló wu àwa náà láti fara mọ́.—Jóòbù 1:6-12; 2:2-6.
Sátánì Ta Ko Ìṣàkóso Jèhófà
4. Kí ni Sátánì ṣe tó túbọ̀ gbé ọ̀ràn ìṣàkóso wá sójú táyé?
4 Ó dájú pé kò sí èyí tí Sátánì kò mọ̀ nípa rẹ̀ nínú gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ tá a mẹ́nu kàn yìí. Kíá ló sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbéjà ko ẹni tó jẹ́ olórí lára “irú-ọmọ” “obìnrin” Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Ìgbà mẹ́ta ni Èṣù dán Jésù wò, tó ń rọ Jésù pé kó ṣe ohun tó dà bíi pé yóò ṣe Jésù láǹfààní dípò ohun tí Bàbá rẹ̀ fẹ́ kó ṣe. Àdánwò kẹta ló tiẹ̀ wá gbé ọ̀ràn ìṣàkóso wá sójú táyé dáadáa. Ó fi “gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn” han Jésù ó sì sọ fún un ní tààràtà pé: “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ dájúdájú bí ìwọ bá wólẹ̀, tí o sì jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.” Níwọ̀n bí Jésù ti mọ̀ pé Èṣù ló ń darí “gbogbo ìjọba ayé,” ó jẹ́ kó mọ ẹni tóun gbà pé ó jẹ́ alákòóso. Ó fún un lésì pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì! Nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.’”—Mátíù 4:8-10.
5. Iṣẹ́ tí kò rọrùn wo ni Jésù ní láti ṣe?
5 Ọ̀nà tí Jésù gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀ fi hàn kedere pé títi ìṣàkóso Jèhófà lẹ́yìn lohun tó jẹ ẹ́ lógún jù lọ. Jésù mọ̀ dájú pé òun gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú, ìyẹn ikú tí yóò ti ọwọ́ Sátánì wá, èyí tí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì pè ní pípa “irú-ọmọ” obìnrin náà ní gìgísẹ̀, láti fi hàn pé Ọlọ́run ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ alákòóso. (Mátíù 16:21; 17:12) Ó tún ní láti fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run ni irinṣẹ́ tí Jèhófà yóò lò láti pa Sátánì run àti láti mú kí gbogbo ẹ̀dá tún ní àlàáfíà padà kí ìgbésí ayé wọn sì tòrò minimini. (Mátíù 6:9, 10) Kí ni Jésù ṣe láti ṣe iṣẹ́ tó ṣòro gan-an yìí láṣeyọrí?
‘Ìjọba Ọlọ́run Ti Sún Mọ́lé’
6. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ni Ọlọ́run máa lò láti “fọ́ iṣẹ́ Èṣù túútúú”?
6 Nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó “lọ sí Gálílì, ó ń wàásù ìhìn rere Ọlọ́run, ó sì ń wí pé: ‘Àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti pé, ìjọba Ọlọ́run sì ti sún mọ́lé.’” (Máàkù 1:14, 15) Kódà, ó sọ pé: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run, . . . nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.” (Lúùkù 4:18-21, 43) Jésù lọ jákèjádò orílẹ̀-èdè náà, “ó ń wàásù, ó sì ń polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 8:1) Jésù tún ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu, ó bọ́ ogunlọ́gọ̀ èèyàn, ó dáwọ́ ìjì líle dúró, ó wo àwọn tó ń ṣàìsàn sàn, ó sì tún jí òkú dìde. Nípa ṣíṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí, Jésù fi hàn pé Ọlọ́run lè mú gbogbo ìyà àti ohun búburú tó jẹ́ àbájáde ọ̀tẹ̀ tó wáyé ní Édẹ́nì kúrò kó sì tipa bẹ́ẹ̀ “fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.”—1 Jòhánù 3:8.
7. Kí ni Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n lọ ṣe, kí ló sì jẹ́ àbájáde rẹ̀?
7 Kí ìhìn rere nípa Ìjọba náà lè di èyí tá a wàásù rẹ̀ dé gbogbo ibi tó bá ṣeé ṣe, Jésù kó àwọn olóòótọ́ èèyàn kan jọ tí wọ́n jẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó wá kọ́ wọn ní ọ̀nà tí wọn yóò gbà ṣe iṣẹ́ yìí. Ó kọ́kọ́ yan iṣẹ́ yìí fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá ó sì “rán wọn jáde láti wàásù ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 9:1, 2) Lẹ́yìn náà ló wá rán àwọn àádọ́rin mìíràn pé kí wọ́n lọ máa wàásù pé: “Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́ tòsí.” (Lúùkù 10:1, 8, 9) Nígbà táwọn ọmọlẹ́yìn wọ̀nyí padà dé tí wọ́n sì ròyìn àṣeyọrí tí wọ́n ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà fún Jésù, ó fèsì pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí rí Sátánì tí ó ti já bọ́ . . . bí mànàmáná láti ọ̀run.”—Lúùkù 10:17, 18.
8. Kí ni ọ̀nà tí Jésù gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀ fi hàn kedere?
8 Jésù lo ara rẹ̀ gan-an fún iṣẹ́ yìí kò sì jẹ́ kí àǹfààní èyíkéyìí tó yọjú láti jẹ́rìí nípa Ìjọba Ọlọ́run bọ́ mọ́ òun lọ́wọ́. Ó ṣiṣẹ́ kára gan-an, tọ̀sántòru ló sì fi ń lo ara rẹ̀, kódà ó yááfì àwọn ohun téèyàn fi ń gbádùn ayé. Ó sọ pé: “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ibi wíwọ̀sí, ṣùgbọ́n Ọmọ ènìyàn kò ní ibì kankan láti gbé orí rẹ̀ lé.” (Lúùkù 9:58; Máàkù 6:31; Jòhánù 4:31-34) Nígbà tó kù díẹ̀ kí Jésù kú, ó fìgboyà sọ níwájú Pọ́ńtíù Pílátù pé: “Nítorí èyí . . . ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́.” (Jòhánù 18:37) Ọ̀nà tí Jésù gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀ látòkèdélẹ̀ fi hàn pé, ìdí tó fi wá sáyé kì í kàn ṣe láti jẹ́ àgbà olùkọ́, tàbí oníṣẹ́ ìyanu, tàbí Olùgbàlà tó kàn yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti kú. Àmọ́ ó jẹ́ láti ti ìṣàkóso Jèhófà lẹ́yìn àti láti fi hàn pé Ọlọ́run lágbára láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀.—Jòhánù 14:6.
“A Ti Ṣe É Parí!”
9. Báwo ni Sátánì ṣe wá rí “irú-ọmọ” obìnrin Ọlọ́run pa ní gìgísẹ̀?
9 Gbogbo ohun tí Jésù ṣe nítorí Ìjọba náà kò dùn mọ́ Sátánì Èṣù tó jẹ́ Ọ̀tá Ọlọ́run nínú rárá. Léraléra ni Sátánì lo apá ti orí ilẹ̀ ayé lára “irú-ọmọ” rẹ̀, ìyẹn ètò ìṣèlú àti ètò ìsìn, láti pa “irú-ọmọ” obìnrin Ọlọ́run. Látìgbà tí wọ́n ti bí Jésù títí dìgbà tí ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé fi wá sópin ni Sátánì àtàwọn ìsọ̀ǹgbè rẹ̀ ń lépa rẹ̀. Níkẹyìn, nígbà ìrúwé ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àkókó tó fún Ọmọ èèyàn láti dẹni tá a fà lé Ọ̀tá náà lọ́wọ́ kó bàa lè pà á ní gìgísẹ̀. (Mátíù 20:18, 19; Lúùkù 18:31-33) Àwọn àkọsílẹ̀ inú ìwé Ìhìn Rere jẹ́ ká rí i kedere bí Sátánì ṣe lo àwọn èèyàn láti dájọ́ ikú fún Jésù tí wọ́n sì jẹ́ kó kú ikú oró lórí òpó igi ìdálóró. Àwọn tó lò ni Júdásì Ísíkáríótù, àwọn olórí àlùfáà, àwọn akọ̀wé, àwọn Farisí, àtàwọn ará Róòmù.—Ìṣe 2:22, 23.
10. Kí lohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tí Jésù ṣe yanjú nípasẹ̀ ikú rẹ̀ lórí òpó igi oró?
10 Kí ló máa ń wá sọ́kàn rẹ nígbà tó o bá ronú nípa bí Jésù ṣe wà lórí òpó igi ìdálóró, tó wà nínú ìrora ńlá, tó sì ń kú díẹ̀díẹ̀? Ó ṣeé ṣe kó o rántí ẹbọ ìràpadà tí Jésù fi ara rẹ̀ rú nítorí ẹ̀dá èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀. (Mátíù 20:28; Jòhánù 15:13) Ìfẹ́ ńlá tó mú kí Jèhófà pèsè ẹbọ yẹn lè jọ ọ́ lójú gan-an. (Jòhánù 3:16) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára ọmọ ogun ilẹ̀ Róòmù yẹn ló ṣe rí lára ìwọ náà, ìyẹn ọmọ ogun tí orí rẹ̀ wú débi tó fi sọ pé: “Dájúdájú, Ọmọ Ọlọ́run ni èyí.” (Mátíù 27:54) Gbogbo ìwọ̀nyí jẹ́ ọ̀nà tó dára gan-an láti fi hàn pé o mọyì ẹbọ yẹn. Àmọ́, rántí pé ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ kẹ́yìn lórí òpó igi ìdálóró ni pé: “A ti ṣe é parí!” (Jòhánù 19:30) Kí lohun náà? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ṣe àwọn nǹkan kan yọrí nípasẹ̀ ọ̀nà tó gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀ àti ikú rẹ̀, ǹjẹ́ kì í ṣe olórí ìdí tó fi wá sáyé ni pé kó lè yanjú ọ̀rọ̀ bóyá Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ alákòóso tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ǹjẹ́ Bíbélì kò sì sàsọtẹ́lẹ̀ pé níwọ̀n bí Jésù ti jẹ́ “irú ọmọ” náà, Sátánì yóò fojú rẹ̀ rí màbo, ìyẹn á sì jẹ́ kí Jésù lè mú gbogbo ẹ̀gbin tó ti bá orúkọ Jèhófà kúrò? (Aísáyà 53:3-7) Àwọn nǹkan wọ̀nyí kì í ṣe ohun tó rọrùn, síbẹ̀ Jésù ṣe gbogbo rẹ̀ yanjú. Àṣeyọrí ńlá gbáà ló mà ṣe o!
11. Kí ni Jésù yóò ṣe kí àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run sọ lọ́gbà Édẹ́nì lè nímùúṣẹ ní kíkún?
11 Nítorí pé Jésù jẹ́ olóòótọ́ àti adúró ṣinṣin, Ọlọ́run jí i dìde, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn o, àmọ́ gẹ́gẹ́ bí “ẹ̀mí tí ń fúnni ní ìyè.” (1 Kọ́ríńtì 15:45; 1 Pétérù 3:18) Ìlérí tí Jèhófà sì ṣe fún Ọmọ rẹ̀ tó ṣe lógo ni pé: “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi fi àwọn ọ̀tá rẹ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ.” (Sáàmù 110:1) “Àwọn ọ̀tá” wọ̀nyí ni Sátánì, olórí ọ̀daràn náà, àti gbogbo àwọn tó para pọ̀ jẹ́ “irú ọmọ” rẹ̀. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jésù Kristi ni Ọba Ìjọba Mèsáyà ti Jèhófà, òun ni yóò ṣáájú nínú pípa gbogbo àwọn ọlọ̀tẹ̀ run, lọ́run àti láyé. (Ìṣípayá 12:7-9; 19:11-16; 20:1-3, 10) Ìgbà yẹn ni àsọtẹ́lẹ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì 3:15 àti àdúrà tí Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ yóò wá nímùúṣẹ ní kíkún. Àdúrà náà ni pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Mátíù 6:10; Fílípì 2:8-11.
Àpẹẹrẹ Tó Yẹ Ká Tẹ̀ Lé
12, 13. (a) Kí ni àbájáde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tá à ń wàásù rẹ̀ lónìí? (b) Kí ló yẹ ká bi ara wa bá a bá fẹ́ máa tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Kristi?
12 Lọ́jọ́ òní, à ń wàásù ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sàsọtẹ́lẹ̀ pé yóò rí. (Mátíù 24:14) Èyí sì ti mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Inú wọn ń dùn gan-an nítorí àwọn ìbùkún tí Ìjọba yẹn yóò mú wá. Wọ́n ń retí láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé níbi tí àlàáfíà máa wà tí kò sì ní sí ewu kankan, tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n sì ń sọ nípa ohun tí wọ́n ń retí yìí fáwọn mìíràn. (Sáàmù 37:11; 2 Pétérù 3:13) Ṣé ọ̀kan lára àwọn tó ń polongo Ìjọba Ọlọ́run ni ọ́? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a yìn ọ́ gan-an. Àmọ́ ohun kan wà tí gbogbo wa gbọ́dọ̀ ronú lé lórí.
13 Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: ‘Kristi jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.’ (1 Pétérù 2:21) Kíyè sí i pé nínú ẹsẹ yìí, kì í ṣe bí Jésù ṣe gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù tó tàbí bó ṣe mọ àwọn èèyàn kọ́ tó ni Pétérù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ bí kò ṣe ìyà tó jẹ. Níwọ̀n bí Pétérù ti wà láyé lákòókò tí Jésù wà láyé, ó mọ̀ dájú pé Jésù múra tán láti jìyà kó bàa lè fi hàn pé ìṣàkóso Jèhófà lóun fara mọ́ kó sì lè fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. Àwọn ọ̀nà wo làwa náà lè gbà tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù? A gbọ́dọ̀ bi ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ mo múra tán láti fara da ìyà kí n bàa lè fi hàn pé mò ń ti ìṣàkóso Jèhófà lẹ́yìn mo sì ń bọlá fún un? Ǹjẹ́ mò ń fi hàn nípa ọ̀nà tí mò ń gbà gbé ìgbésí ayé mi àti ọwọ́ tí mo fi mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi pé títi ìṣàkóso Jèhófà lẹ́yìn lóhun tó jẹ mí lógún jù lọ?’—Kólósè 3:17.
14, 15. (a) Kí ni Jésù ṣe nígbà tí wọ́n fún un nímọ̀ràn tó kù díẹ̀ káàtó àti nígbà tí wọ́n fi ohun tí kò tọ́ lọ̀ ọ́, kí nìdí tó sì fi ṣe bẹ́ẹ̀? (b) Kí lohun tó yẹ kó máa wà lọ́kàn wa nígbà gbogbo? (Sọ̀rọ̀ lórí ohun tó wà nínú àpótí náà, “Dúró Síhà Ọ̀dọ̀ Jèhófà.”)
14 Ojoojúmọ́ là ń rí àdánwò tá a sì ń láwọn ìpinnu láti ṣe. Àwọn ìpinnu kan ṣòro láti ṣe àwọn kan ò sì fi bẹ́ẹ̀ ṣòro. Kí ló yẹ kó máa darí ìpinnu wa? Bí àpẹẹrẹ, nígbà tá a bá dojú kọ àdánwò tó fẹ́ mú ká ṣe ohun tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́, kí la máa ń ṣe? Nígbà tí Pétérù sọ fún Jésù pé kó ṣàánú ara rẹ̀, èsì wo ni Jésù fún un? Jésù sọ fún un pé: “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi, Sátánì! . . . Kì í ṣe àwọn ìrònú Ọlọ́run ni ìwọ ń rò, bí kò ṣe ti ènìyàn.” (Mátíù 16:21-23) Tàbí nígbà tí wọ́n bá fún wa láwọn àǹfààní kan tó lè sọ wá dolówó tàbí tó lè mú ká wà nípò gíga lẹ́nu iṣẹ́, tí èyí á sì ṣàkóbá fún iṣẹ́ ìsìn àti àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run, ǹjẹ́ a máa ń ṣe bíi ti Jésù? Nígbà tí Jésù ṣàkíyèsí pé àwọn tó rí iṣẹ́ ìyanu òun “máa tó wá mú òun láti fi òun jẹ ọba,” kíákíá ló kúrò nítòsí wọn.—Jòhánù 6:15.
15 Kí nìdí tí Jésù kò fi gba gbẹ̀rẹ́ rárá láwọn àkókò yìí àti láwọn àkókò mìíràn? Nítorí ó mọ̀ dájú pé ohun kan wà tó ṣe pàtàkì ju kóun kàn bọ́ lọ́wọ́ ewu tàbí kọ́wọ́ òun tẹ ohun tó máa ṣe òun láǹfààní. Ìfẹ́ bàbá rẹ̀ ló fẹ́ ṣe, ó sì fẹ́ fi hàn pé ìṣàkóso Jèhófà lòun fara mọ́ láìfi ibikíbi tó lè já sí fóun pè. (Mátíù 26:50-54) Nítorí náà, bí ọ̀ràn ẹni tó yẹ kó jẹ́ alákòóso kò bá yé wa yékéyéké kó sì máa wà lọ́kàn wa nígbà gbogbo bó ti wà lọ́kàn Jésù, a lè juwọ́ sílẹ̀ nígbàkigbà tàbí ká kùnà. Kí nìdí? Ìdí ni pé a lè kó sínú àwọn ìdẹkùn Sátánì, ẹni tó jẹ́ ọ̀gá nínú mímú kóhun tó burú fara hàn bí ohun tó dára, gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣe nígbà tó tan Éfà jẹ.—2 Kọ́ríńtì 11:14; 1 Tímótì 2:14.
16. Kí ló yẹ kó jẹ́ olórí ìdí tá a fi lọ ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́?
16 Nígbà tá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a máa ń gbìyànjú láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro tí wọ́n ní, a sì máa ń fi ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìṣòro náà hàn wọ́n. Èyí jẹ́ ọ̀nà tó dára gan-an láti mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́, olórí ìdí tá a fi ń wàásù fáwọn èèyàn kì í kàn ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ ohun tí Bíbélì sọ nìkan tàbí kí wọ́n lè mọ àwọn ìbùkún tí Ìjọba Ọlọ́run máa mú wá. A gbọ́dọ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ̀ pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ alákòóso ayé àtọ̀run. Ǹjẹ́ wọ́n múra tán láti di Kristẹni tòótọ́, kí wọ́n gbé “òpó igi oró” wọn, kí wọ́n sì fara da ìyà nítorí Ìjọba yẹn? (Máàkù 8:34) Ṣé wọ́n ṣe tán láti dara pọ̀ mọ́ àwọn tó fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà kí wọ́n sì tipa báyìí fi hàn pé òpùrọ́ àti abanijẹ́ ni Sátánì? (Òwe 27:11) Àǹfààní ńlá la ní pé a lè ran ara wa àtàwọn mìíràn lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.—1 Tímótì 4:16.
Ìgbà Tí Ọlọ́run Yóò Di “Ohun Gbogbo fún Olúkúlùkù”
17, 18. Àkókò tó dára gan-an wo la lè máa retí bá a bá fi hàn pé ìṣàkóso Jèhófà la fara mọ́?
17 Bá a ti ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe nísinsìnyí ká lè fi hàn nípa ìwà wa àti iṣẹ́ ìwàásù wa pé ìṣàkóso Jèhófà la fara mọ́, a lè máa wọ̀nà de ìgbà tí Jésù Kristi yóò “fi ìjọba lé Ọlọ́run àti Baba rẹ̀ lọ́wọ́.” Ìgbà wo nìyẹn yóò jẹ́? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé, ó ní: “Nígbà tí ó bá ti sọ gbogbo ìjọba àti gbogbo ọlá àṣẹ àti agbára di asán. Nítorí òun gbọ́dọ̀ ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí Ọlọ́run yóò fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. . . . Nígbà náà ni Ọmọ fúnra rẹ̀ pẹ̀lú yóò fi ara rẹ̀ sábẹ́ Ẹni tí ó fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, kí Ọlọ́run lè jẹ́ ohun gbogbo fún olúkúlùkù.”—1 Kọ́ríńtì 15:24, 25, 28.
18 Nígbà tí Ọlọ́run bá di “ohun gbogbo fún olúkúlùkù,” àkókò yẹn á mà ti lọ wà jù o! Ìjọba yẹn á ti ṣe ohun tí Ọlọ́run torí rẹ̀ gbé e kalẹ̀. Gbogbo àwọn tó ta ko ìṣàkóso Jèhófà á ti pa run. Àlàáfíà á ti wà ní gbogbo ayé àtọ̀run, ohun gbogbo á sì tòrò minimini. Gbogbo ìṣẹ̀dá pátá yóò wá kọrin bíi ti ọ̀kan lára àwọn tó kọ sáàmù pé: “Ẹ gbé ògo tí ó jẹ́ ti orúkọ Jèhófà fún un . . . Ẹ wí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè pé: ‘Jèhófà fúnra rẹ̀ ti di ọba.’”—Sáàmù 96:8, 10.
Ǹjẹ́ O Lè Dáhùn?
• Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé ọ̀ràn bí Ọlọ́run ṣe lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ alákòóso ló ṣe pàtàkì sóun jù lọ?
• Kí ni olórí ohun tí Jésù ṣàṣeyọrí rẹ̀ nípasẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ àti ikú rẹ̀?
• Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù láti fi hàn pé ìṣàkóso Jèhófà la fara mọ́?
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
DÚRÓ SÍHÀ Ọ̀DỌ̀ JÈHÓFÀ
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin lórílẹ̀-èdè Kòríà àti láwọn ibòmíràn ti mọ̀, nígbà táwọn Kristẹni bá wà nínú ìdánwò tó le gan-an, ó dára kí wọ́n lóye ìdí tí wọ́n fi ń dojú kọ àwọn ìṣòro yẹn.
Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n lákòókò ìjọba Soviet ayé ọjọ́un sọ pé: “Ohun tó jẹ́ ká lè ní ìfaradà ni pé, a lóye ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́gbà Édẹ́nì dáadáa, ìyẹn ọ̀ràn nípa bóyá Ọlọ́run lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. . . . A mọ̀ pé a láǹfààní láti fi hàn pé ìṣàkóso Jèhófà la fara mọ́. . . . Èyí fún wa lókun ó sì jẹ́ ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà.”
Ẹlẹ́rìí mìíràn ṣàlàyé ohun tó ran òun àtàwọn Ẹlẹ́rìí yòókù lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n tí wọ́n ti ń kó àwọn èèyàn lọ ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó. Ó sọ pé: “Jèhófà kò fi wá sílẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan nira gan-an, a ò gbàgbé àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. A máa ń gbéra wa ró nígbà gbogbo nípa rírán ara wa létí pé ìhà ọ̀dọ̀ Jèhófà la wà nínú ọ̀ràn ẹni tó yẹ kó jẹ́ alákòóso ayé àtọ̀run.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé ìṣàkóso Jèhófà lóun fara mọ́ nígbà tí Sátánì dán an wò?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Kí ni ikú Jésù mú kó ṣeé ṣe?