Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé
Tó Bá Jẹ́ Ẹni Pípé Ni Ádámù, Báwo Ló Ṣe Wá Dẹ́ṣẹ̀?
Ó ṣeé ṣe fún Ádámù láti dẹ́ṣẹ̀, torí pé Ọlọ́run fún un lómìnira láti yan ohun tó bá fẹ́. Ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún Ádámù yìí ò sọ ọ́ di aláìpé. Ká sòótọ́, Ọlọ́run nìkan ló pé láìkù síbì kan. (Diutarónómì 32:3, 4; Sáàmù 18:30; Máàkù 10:18) Béèyàn tàbí ohunkóhun mìíràn bá pé, ó níbi tó mọ. Bí àpẹẹrẹ, ó lè máà sóhun tó lè gé ẹran bí ọ̀bẹ, àmọ́ ṣé a wá lè tìtorí ìyẹn fọ̀bẹ jẹun? Ohun tá a bá ń lo nǹkan fún la lè fi ṣe láṣepé.
Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá Ádámù? Ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn tó fi dá Ádámù ni láti tipasẹ̀ rẹ̀ dá àwọn èèyàn olórí pípé, tí wọ́n á lè fúnra wọn yan ohun tí wọ́n bá fẹ́. Àwọn tó bá fẹ́ fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn ọ̀nà tó gbà ń ṣe nǹkan máa yàn láti ṣègbọràn sáwọn òfin rẹ̀. Nítorí náà, Ọlọ́run ò dá agbára láti máa ṣàdéédéé ṣègbọràn mọ́ wa, àmọ́ ńṣe lèèyàn máa ń fínnúfíndọ̀ ṣègbọràn. (Diutarónómì 10:12, 13; 30:19, 20) Nípa bẹ́ẹ̀, tó bá jẹ́ pé Ádámù ò lè yàn láti ṣàìgbọràn ni, á jẹ́ pé kò pé délẹ̀délẹ̀ nìyẹn, torí èèyàn tó lómìnira láti yan ohun tó bá fẹ́ ni Ọlọ́run dá a. Bíbélì jẹ́ ká mọ bí Ádámù ṣe yàn láti lo òmìnira tó ní, ó sọ pé Ádámù tẹ̀ lé aya rẹ̀ láti ṣàìgbọràn sí òfin tí Ọlọ́run fún wọn nípa “igi ìmọ̀ rere àti búburú.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:17; 3:1-6.
Àbí ṣe ni Ọlọ́run dá Ádámù lọ́nà tí kò fi lè mọ̀yàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, tó fi jẹ́ pé kò ní lè ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání, kò sì ní lè kojú ìdẹwò? Jèhófà Ọlọ́run ti ṣàyẹ̀wò gbogbo àwọn nǹkan tó dá sáyé, tó fi mọ́ tọkọtaya àkọ́kọ́, kó tó di pé Ádámù ṣàìgbọràn, ó sì rí i pé “ó dára gan-an ni.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀, Ẹlẹ́dàá rẹ̀ ò ṣẹ̀ṣẹ̀ ní láti tún ohunkóhun ṣe lára ẹ̀, àmọ́ ó jẹ́ kó yé Ádámù pé, ó jẹ̀bi ọ̀ràn náà láìkù síbì kan. (Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19) Ádámù ti kùnà láti jẹ́ kí ìfẹ́ tó ní fún Ọlọ́run àti ìfẹ́ láti ṣohun tó tọ́ mú kó ṣègbọràn sí Ọlọ́run ju ohunkóhun mìíràn lọ.
Ohun míì tún ni pé, nígbà tí Jésù wà láyé, èèyàn pípé bíi ti Ádámù lòun náà. Àmọ́ Jésù ò dà bí àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù yòókù, torí ńṣe ni Màríà lóyún rẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, ìdí sì nìyẹn tí kò fi jogún àìpé kankan tí kò ní jẹ́ kó lè kojú ìdẹwò. (Lúùkù 1:30, 31; 2:21; 3:23, 38) Ńṣe ni Jésù fínnúfíndọ̀ jẹ́ olóòótọ́ sí Bàbá rẹ̀ láìkà àdánwò lílágbára tó dojú kọ sí. Bí Ádámù ṣe lo òmìnira tó ní fi hàn pé ńṣe ló fọwọ́ ara ẹ̀ ṣera ẹ̀, torí pé ó kọ̀ láti ṣègbọràn sí òfin Jèhófà.
Kí wá nìdí tí Ádámù fi yàn láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run? Àbí ńṣe ló rò pé èyí á mú kí nǹkan túbọ̀ rọ òun lọ́rùn? Rárá o, torí pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé, “a kò tan Ádámù jẹ.” (1 Tímótì 2:14) Àmọ́, ńṣe ni Ádámù mọ̀ọ́mọ̀ fara mọ́ ìfẹ́ ọkàn ìyàwó rẹ̀ tó ti jẹ èso igi tí Ọlọ́run kà léèwọ̀ náà. Ó wù ú pé kó tẹ́ aya rẹ̀ lọ́rùn ju pé kó ṣègbọràn sí Ẹlẹ́dàá lọ. Nígbà tí Éfà fi èso yẹn lọ Ádámù, ńṣe ló yẹ kó dúró díẹ̀ kó sì ronú lórí ipa tí àìgbọràn rẹ̀ máa ní lórí àjọṣe òun àti Ọlọ́run. Nítorí pé ìfẹ́ tí Ádámù ní fún Ọlọ́run ò jinlẹ̀, ó juwọ́ sílẹ̀ fún ìdẹwò, èyí sì kan ìdẹwò látọ̀dọ̀ ìyàwó rẹ̀.
Ádámù ti dẹ́ṣẹ̀ kó tó bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ, torí náà, gbogbo àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ ló jẹ́ aláìpé. Síbẹ̀, Ọlọ́run fún àwa náà ní òmìnira láti yan ohun tó bá wù wá bíi ti Ádámù. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa ronú jinlẹ̀ lórí oore Jèhófà, ká sì nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run látọkàn wá, torí òun ló yẹ ká máa ṣègbọràn sí, òun ló sì yẹ ká máa jọ́sìn.—Sáàmù 63:6; Mátíù 22:36, 37.