Sún Mọ́ Ọlọ́run
Ẹ̀rí Tó Ta Yọ Jù Lọ Pé Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Wa
ÁBÚRÁHÁMÙ fẹ́ràn Ọlọ́run. Bàbá ńlá olóòótọ́ yìí tún fẹ́ràn Ísákì, ọmọ tó bí lọ́jọ́ ogbó rẹ̀. Àmọ́ nígbà tí Ísákì wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25], Ọlọ́run dan ìgbàgbọ́ Ábúráhámù wò, ìyẹn sì máa jẹ́ kó ṣe ohun tí bàbá kan ò ní gbàdúrà pé kó ṣẹlẹ̀ sóun, Ọlọ́run sọ fún un pé kó fi ọmọ rẹ̀ rúbọ. Àmọ́, Ísákì ò kú o. Bí Ábúráhámù ṣe gbé ọ̀bẹ sókè, tó sì fẹ́ dá a lé ọmọ ẹ̀ lọ́rùn ni Ọlọ́run bá rán áńgẹ́lì sí i. Ìtàn Bíbélì tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 22:1-18 yìí jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ ìfẹ́ tó ta yọ tí Ọlọ́run máa fi hàn sí wa.
Ẹsẹ 1 sọ pé: “Ọlọ́run . . . dán Ábúráhámù wò.” Ábúráhámù nígbàgbọ́ tó lágbára, àmọ́ ní báyìí Ọlọ́run máa dán ìgbàgbọ́ rẹ̀ wò lọ́nà tí ò rírú ẹ̀ rí. Ọlọ́run sọ pé: “Jọ̀wọ́, mú ọmọkùnrin rẹ, ọmọkùnrin rẹ kan ṣoṣo tí o nífẹ̀ẹ́ gidigidi, Ísákì, kí o sì . . . fi í rúbọ níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun lórí ọ̀kan nínú àwọn òkè ńlá tí èmi yóò tọ́ka sí fún ọ.” (Ẹsẹ 2) Má gbàgbé pé Ọlọ́run kì í gbà kí àdánwò tó kọjá agbára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí wọn. Nítorí náà, àdánwò yìí fi hàn pé Ọlọ́run gba ẹ̀rí Ábúráhámù jẹ́.—1 Kọ́ríńtì 10:13.
Ábúráhámù ṣègbọràn lójú ẹsẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ábúráhámù dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì mú méjì nínú àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ àti Ísákì ọmọkùnrin rẹ̀; ó sì la igi fún ọrẹ ẹbọ sísun náà. Lẹ́yìn náà, ó dìde, ó sì rìnnà àjò.” (Ẹsẹ 3) Ẹ̀rí fi hàn pé Ábúráhámù ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àdánwò tó dé bá a yìí fẹ́ni kẹ́ni.
Lẹ́yìn náà ni Ábúráhámù wá rìnrìn àjò ọjọ́ mẹ́ta, ìyẹn sì jẹ́ kó ráyè ronú jinlẹ̀. Síbẹ̀, Ábúráhámù ò yí ìpinnu ẹ̀ pa dà. Àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ fi bí ìgbàgbọ́ ẹ̀ ṣe lágbára tó hàn. Bó ṣe ń wo òkè ńlá tí Ọlọ́run sọ pé kó ti rú ẹbọ náà lọ́ọ̀ọ́kán, ó sọ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ẹ dúró síhìn-ín . . . , ṣùgbọ́n èmi àti ọmọdékùnrin náà fẹ́ tẹ̀ síwájú lọ sí ọ̀hún yẹn láti jọ́sìn kí a sì padà wá bá yín.” Nígbà tí Ísákì béèrè àgùntàn tí wọ́n máa fi rúbọ, Ábúráhámù sọ pé: “Ọlọ́run yóò pèsè àgùntàn . . . náà fúnra rẹ̀.” (Ẹsẹ 5, 8) Ábúráhámù nígbàgbọ́ pé òun àti ọmọ òun jọ máa pa dà sílé. Kí nìdí tó fi nírú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé, “ó ṣírò pé Ọlọ́run lè gbé [Ísákì] dìde, àní kúrò nínú òkú.”—Hébérù 11:19.
Nígbà tí wọ́n dé orí òkè náà, bí Ábúráhámù ṣe fẹ́ fi ọ̀bẹ “pa ọmọkùnrin rẹ̀” báyìí ni áńgẹ́lì kan dá a dúró. Ọlọ́run wá ní kí Ábúráhámù fi àgbò kan tó há sáàárín igbó rúbọ “dípò ọmọkùnrin rẹ̀.” (Ẹsẹ 10-13) Lójú Ọlọ́run, ńṣe ló dà bíi pé Ábúráhámù ti fi Ísákì rúbọ. (Hébérù 11:17) Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé: “Lójú Ọlọ́run, gbígbà tí Ábúráhámù gbà láti fi Ísákì ọmọ ẹ̀ rúbọ ò yàtọ̀ sí pé ó ti fi rúbọ lóòótọ́.”
Ábúráhámù ò já Jèhófà kulẹ̀. Jèhófà sì san Ábúráhámù lẹ́san rere tórí pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi rán an létí májẹ̀mú tó wà láàárín wọn tó sì tún fi kún un pé nípasẹ̀ irú ọmọ Ábúráhámù ni gbogbo aráyé máa bù kún ara wọn.—Ẹsẹ 15-18.
Níkẹyìn, Ọlọ́run ò jẹ́ kí Ábúráhámù fi ọmọ rẹ̀ rúbọ, àmọ́ Ọlọ́run ṣì máa fi ọmọ tara ẹ̀ rúbọ. Bí Ábúráhámù ṣe múra tán láti fi Ísákì rúbọ ń ṣàpẹẹrẹ bí Ọlọ́run náà ṣe máa fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, ìyẹn Jésù, rúbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa. (Jòhánù 3:16) Bí Jèhófà ṣe fi Kristi rúbọ ni ọ̀nà tó ta yọ jù lọ tó gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa. Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti lè ṣerú ohun tó tó yẹn nítorí wa, ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Àwọn nǹkan wo lèmi náà ti ṣe tán láti yááfì kí n lè múnú Ọlọ́run dùn?’