Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Yè Lédè Tó Ń Kú Lọ
ǸKAN bí ìlàjì nínú èdè táwọn èèyàn ń sọ lágbàáyé ló ti dàwátì láti nǹkan bí ọgọ́rùn ọdún mélòó kan sẹ́yìn. Nígbà táwọn ọmọ ìbílẹ̀ ìlú tó ń sọ èdè kan bá pa èdè wọn tì, èdè yẹn á di òkú èdè. Ìdí nìyẹn táwọn èèyàn fi sábà máa ń pe èdè Látìn ní “òkú èdè,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀ tó sì jẹ́ pé òun lèdè tí ìjọba Vatican fọwọ́ sí nílùú Róòmù.
Èdè Látìn yìí náà lèdè tí wọ́n kọ́kọ́ fi túmọ̀ Bíbélì. Ṣáwọn Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ sáwọn òkú èdè ṣì lè “yè” tàbí kó ṣì wúlò lásìkò wa yìí? Ṣé wọ́n tiẹ̀ lè nípa kankan lórí àwọn tó ń ka Bíbélì lóde òní? A máa rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí tá a bá ṣàyẹ̀wò ìtàn nípa àwọn Bíbélì tó wà láwọn òkú èdè wọ̀nyẹn.
Àwọn Bíbélì Tí Wọ́n Kọ́kọ́ Tú sí Èdè Látìn
Èdè Látìn ni wọ́n kọ́kọ́ ń sọ nílùú Róòmù. Àmọ́ èdè Gíríìkì ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kọ lẹ́tà sáwọn Kristẹni tó wà nílùú náà.a Ohun tó sì kọ rọrùn fún wọn láti lóye torí pé èdè méjèèjì làwọn ará Róòmù ń sọ. Torí pé àwọn ìlú tí wọ́n ti ń sọ èdè Gíríìkì ní Éṣíà kékeré lọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó ń gbé nílùú Róòmù ti wá, àwọn èèyàn máa ń sọ pé ìlú náà ti di ìlú àwọn Gíríìkì. Àwọn èdè táwọn èèyàn ń sọ láwọn àgbègbè tó wà lábẹ́ àṣẹ ilẹ̀ ọba Róòmù yàtọ̀ síra láti ibì kan sí ibòmíì, àmọ́ bí ilẹ̀ ọba náà ṣe ń fẹ̀ sí i làwọn èèyàn púpọ̀ túbọ̀ ń sọ èdè Látìn. Ìyẹn ló mú kí wọ́n túmọ̀ Ìwé Mímọ́ láti èdè Gíríìkì sí èdè Látìn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀rúndún kejì Sànmánì Kristẹni ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìtúmọ̀ yẹn ní àríwá ilẹ̀ Áfíríkà.
Vetus Latina tàbí ìtúmọ̀ Èdè Látìn Àtijọ́ ni wọ́n ń pe àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n ṣe jáde lédè Látìn nígbà yẹn. Títí dòní olónìí, a ò tíì rí ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ tó ní odindi Ìwé Mímọ́ lédè Látìn nínú. Àpá tá a rí lára ìwé Vetus Latina lóde òní àtàwọn ibi táwọn òǹkọ̀wé ayé àtijọ́ ti fa ọ̀rọ̀ yọ nínú ìwé náà jẹ́ kó dà bíi pé ìwé náà pín sí oríṣiríṣi. Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn atúmọ̀ èdè tó yàtọ̀ síra ló túmọ̀ àwọn ìwé náà lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, nígbà tó yàtọ̀ síra àti níbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Torí náà, dípò kí ìwé náà jẹ́ ìwé kan ṣoṣo péré, ńṣe ló jẹ́ àkójọ àwọn ìwé tí wọ́n tú sí èdè Látìn láti èdè Gíríìkì.
Ìdàrúdàpọ̀ wáyé nígbà táwọn atúmọ̀ èdè kan gbìyànjú láti dá tú apá kan Ìwé Mímọ́ sí èdè Látìn. Nígbà tí ọ̀rúndún kẹrin ń parí lọ, Augustine gbà pé “gbogbo ẹni tó bá ti ní ìwé àfọwọ́kọ lédè Gíríìkì, tó sì gbà pé òun ní ìmọ̀ nípa èdè Látìn àti èdè Gíríìkì, láìkà bí ìmọ̀ tó ní náà ṣe kéré tó sí, ló ń túmọ̀ àwọn ìwé àfọwọ́kọ láti èdè Gíríìkì” sí èdè Látìn. Augustine àtàwọn kan ronú pé àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì tó wà nígbà yẹn ti pọ̀ jù, wọn ò sì gbà pé ìtumọ̀ tó péye làwọn èèyàn wọ̀nyẹn ṣe síbẹ̀.
Ìtumọ̀ Ti Jerome
Ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Jerome, tó máa ń ṣiṣẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé fún Damasus tó jẹ́ bíṣọ́ọ̀bù ìlú Róòmù, lọ́dún 382 Sànmánì Kristẹni, ló ṣé àwọn nǹkan kan láti yanjú ìdàrúdàpọ̀ tó wà nínú àwọn ìwé táwọn atúmọ̀ èdè kan ti tú. Bíṣọ́ọ̀bù yìí ní kí Jerome ṣàtúnṣe àwọn ìwé Ìhìn Rere tí wọ́n ti tú sí èdè Látìn, ọdún bíi mélòó kan péré sì ni Jerome fi parí iṣẹ́ yẹn. Lẹ́yìn náà ló wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàtúnṣe sáwọn ìwé Bíbélì yòókù tí wọ́n ti tú sí èdè Látìn.
Látinú oríṣiríṣi àwọn ìtúmọ̀ táwọn kan ti ṣe ni Jerome ti ṣe ìtúmọ̀ tiẹ̀ jáde, ìtúmọ̀ tí Jerome ṣe yìí ni wọ́n wá ń pè ní Vulgate nígbà tó yá. Látinú ìtumọ̀ Septuagint, ìyẹn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n tú sí èdè Gíríìkì ní ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ni Jerome ti tú ìwé Sáàmù. Ó tún wá fúnra ẹ̀ ṣàtúnṣe àwọn ìwé Ìhìn Rere tí wọ́n ti tú tẹ́lẹ̀, ó sì tú èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, tí wọ́n kọ lédè Hébérù àtijọ́, sí èdè Látìn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ẹlòmíì ló wá ṣàtúnṣe àwọn apá tó kù nínú Ìwé Mímọ́. Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, àwọn atúmọ̀ èdè wá fi àwọn apá kan lára Vetus Latina kún ìtumọ̀ Vulgate tí Jerome ṣe.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò kọ́kọ́ fara mọ́ ìtúmọ̀ Bíbélì tí Jerome ṣe. Kódà Augustine pàápàá ṣe lámèyítọ́ ẹ̀. Àmọ́ nígbà tó yá, ọ̀pọ̀ èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́wọ́ gba ìtumọ̀ Bíbélì tí Jerome ṣe bí àwòkọ́ṣe fún títúmọ̀ odindi Bíbélì. Ní ọ̀rúndún kẹjọ sí ìkẹsàn-án, àwọn ọ̀mọ̀wé kan bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàtúnṣe sáwọn àṣìkọ ọ̀rọ̀ tó ti wà nínú ìtúmọ̀ Bíbélì tí Jerome ṣe torí báwọn èèyàn ṣe ń dà á kọ. Alcuin àti Theodulf wà lára àwọn ọ̀mọ̀wé wọ̀nyẹn. Àwọn míì ló wá pín ìwé ọ̀hún sí orí-orí, kó lè rọrùn láti máa ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́. Nígbà tí ọ̀làjú dé, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀wé lórí ẹ̀rọ, ìtumọ̀ Bíbélì tí Jerome ṣe ni wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ jáde.
Ibi àpérò táwọn olórí ìjọ Kátólíìkì ṣe lọ́dún 1546 ni Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ti kọ́kọ́ pe ìtúmọ̀ Bíbélì tí Jerome ṣe ní Vulgate. Àwọn tó wà níbi àpérò náà sọ pé “ojúlówó” Bíbélì ni Bíbélì Vulgate yìí, wọ́n sì sọ pé òun ni Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì gbọ́dọ̀ máa lò. Síbẹ̀, wọ́n ṣètò pé kí wọ́n ṣàtúnṣe Bíbélì náà, wọ́n sì ṣètò àwọn ìgbìmọ̀ tó máa bójú tó iṣẹ́ ọ̀hún. Àmọ́, Póòpù Sixtus Karùn-ún fẹ́ kíṣẹ́ náà tètè parí, ó sì gbà pé òun lè dáa ṣe, ló bá pinnu láti parí iṣẹ́ náà fúnra ẹ̀. Kò pẹ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ẹ̀dà Bíbélì tí Póòpù yìí tún ṣe ni Póòpù náà kú lọ́dún 1590. Kíá làwọn kádínà ní kí wọ́n dáwọ́ títẹ Bíbélì náà dúró, torí wọ́n gbà pé àṣìṣe pọ̀ ńbẹ̀, wọn ò sì jẹ́ kí wọ́n pín in fáwọn èèyàn.
Wọ́n ṣe ìtúmọ̀ míì jáde lọ́dún 1592, Póòpù Clement Kẹjọ ló bójú tó o, wọ́n sì pe ìtúmọ̀ tuntun yìí ní ìtúmọ̀ Sixtine Clementine. Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì lo ìtúmọ̀ yìí fúngbà díẹ̀. Bíbélì Sixtine Clementine Vulgate yìí ni wọ́n fi túmọ̀ àwọn Bíbélì Kátólíìkì sáwọn èdè ìbílẹ̀ kan, irú bí èyí tí Ọ̀gbẹ́ni Antonio Martini tú sí èdè àwọn ará Ítálì lọ́dún 1781.
Bíbélì Òde Òní Lédè Látìn
Nígbà tí wọ́n fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ inú ìtúmọ̀ Bíbélì Vulgate ní ọ̀rúndún ogún, wọ́n wá rí i pé ó nílò àtúnṣe bíi tàwọn ìtúmọ̀ Bíbélì míì. Ìdí nìyẹn tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì fi gbé ìgbìmọ̀ kan dìde, lọ́dún 1965, láti ṣe Bíbélì Vulgate tuntun jáde, ojúṣe ìgbìmọ̀ yìí sì ni láti ṣàtúnṣe Bíbélì Vulgate lédè Látìn kí wọ́n sì rí i pé àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ bá òye táwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ ní mu. Bíbélì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe yìí ni wọ́n á máa fi ṣèsìn láwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì tí wọ́n bá ti ń sọ èdè Látìn.
Ọdún 1969 ni wọ́n ṣe apá àkọ́kọ́ lára ìtumọ̀ tuntun yìí jáde, nígbà tó sì di ọdún 1979, Póòpù John Paul Kejì fọwọ́ sí ìtumọ̀ Bíbélì tí wọ́n pè ní Nova Vulgata. Orúkọ àtọ̀runwá náà, Iahveh, wà nínú àwọn ẹsẹ bíi mélòó kan nínú ẹ̀dà tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe jáde, títí kan inú ìwé Ẹ́kísódù 3:15 àti 6:3. Ọ̀kan lára àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ yẹn sọ pé, àtúnṣe làwọn ẹ̀dà tuntun táwọn ṣe jáde lọ́dún 1986 jẹ́ séyìí tó ti jáde tẹ́lẹ̀ torí pé inú ẹ̀dà tuntun yìí làwọn ti dá “Dominus [ìyẹn ‘Olúwa’] pa dà sáwọn ibi tí Iahveh wà tẹ́lẹ̀.”
Onírúurú èèyàn, títí kan àwọn ọ̀mọ̀wé tí wọ́n jẹ́ Kátólíìkì, ló ṣe lámèyítọ́ ìtumọ̀ yìí bí wọ́n ṣe ṣe nígbà tí ìtumọ̀ Vulgate jáde ní ọgọ́rùn-ún ọdún mélòó kan ṣáájú ìgbà yẹn. Báwọn tó ṣe ìtúmọ̀ Bíbélì Nova Vulgata jáde tiẹ̀ ń ronú pé ìtumọ̀ Bíbélì yìí máa jẹ́ kí ìmọ̀ gbogbo àwọn ẹlẹ́sìn ṣọ́ọ̀ṣì ṣọ̀kan, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ronú pé ìyapa ló máa dá sílẹ̀, torí pé òun ni wọ́n fẹ́ máa fi ṣàlàyé gbogbo àwọn ẹ̀dà Bíbélì tó wà lédè míì dípò kí wọ́n lo àwọn ìwé àfọwọ́kọ tó ti wà látìgbà láéláé. Lórílẹ̀-èdè Jámánì, ìtúmọ̀ Bíbélì Nova Vulgata dá àríyànjiyàn sílẹ̀ láàárín àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì àtàwọn Kátólíìkì, torí pé wọ́n fẹ́ ṣe ẹ̀dà Bíbélì tuntun tó máa wúlò fún ṣọ́ọ̀ṣì méjèèjì. Àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì fẹ̀sùn kan àwọn Kátólíìkì pé kò yẹ kí wọ́n fi dandan lé e pé kí ìtumọ̀ tuntun yìí bá ìtumọ̀ Nova Vulgata mu.
Báwọn èèyàn tó ń sọ èdè Látìn ò tiẹ̀ pọ̀ mọ́, Bíbélì tó wà lédè Látìn ti nípa tí kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn lórí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó ń ka Bíbélì. Òun ló pinnu àwọn ọ̀rọ̀ tí ọ̀pọ̀ àwọn onísìn ń lò lónírúurú èdè. Láìka èdè tí wọ́n bá fi tẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí, ó ṣì ń bá a nìṣó láti máa sa agbára, ó sì ń yí ìgbésí ayé ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn pa dà, bí wọ́n ti ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti máa ṣègbọràn sáwọn ẹ̀kọ́ inú rẹ̀.—Hébérù 4:12.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àlàyé síwájú sí i lórí ìdí tí wọ́n fi kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni lédè Gíríìkì, wo àpilẹ̀kọ tá a pe àkọlé ẹ̀ ní “Ǹjẹ́ O Mọ̀?” lójú ìwé 13.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 23]
Póòpù John Paul Kejì fọwọ́ sí ìtúmọ̀ Bíbélì Nova Vulgata. Orúkọ àtọ̀runwá náà, “Iahveh,” wà nínú àwọn ẹ̀dà tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ jáde
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 21]
ÀWỌN Ọ̀RỌ̀ TÍ Ò LÈ PA RẸ́ NÍNÚ ÌTÀN
Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tí ò lè pa rẹ́ nínú ìtàn ló wà nínú ìtúmọ̀ Bíbélì, tí wọ́n pè ní Vetus Latina, tí wọ́n tú látinú èdè Gíríìkì. Ọ̀kan lára irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ tá a tú sí “májẹ̀mú,” ìyẹn di·a·theʹke, lédè Gíríìkì. (2 Kọ́ríńtì 3:14) Ìtúmọ̀ tí wọ́n fun ọ̀rọ̀ yìí, látinú Bíbélì Vetus Latina, ló jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì máa pe Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì ní Májẹ̀mú Láéláé àti Májẹ̀mú Tuntun títí dòní olónìí.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]
ÌLÀNÀ TÁWỌN ÈÈYÀN KỌMINÚ SÍ
Lọ́dún 2001, ìgbìmọ̀ àwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì, tó ń bójú tó ìjọsìn àtọ̀runwá àtàwọn ìlànà tó jẹ mọ́ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, tẹ ìwé òfin àti ìlànà wọn tí wọ́n pè ní Liturgiam authenticam jáde. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìjọ Kátólíìkì ló ti kọminú sáwọn ìlànà tó wà nínú ìwé ọ̀hún.
Ìwé òfin yẹn sọ pé, báwọn ọ̀rọ̀ kan nínú ìtumọ̀ Bíbélì ti Nova Vulgata ò tiẹ̀ bá àwọn ojúlówó ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ mu, òun làwọn tó bá fẹ́ túmọ̀ Bíbélì ṣì gbọ́dọ̀ máa lò, torí pé ìtumọ̀ Bíbélì yìí ni ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì fọwọ́ sí. Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì tí wọ́n bá sì fi ìtumọ̀ Nova Vulgata ṣe nìkan làwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì máa fọwọ́ sì. Ìwé òfin yẹn tún sọ pé, nínú àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì ti Kátólíìkì, “ọ̀rọ̀ tó bá bá ìtumọ̀” Dominus, tàbí “Olúwa,” mu “làwọn atúmọ̀ èdè gbọ́dọ̀ máa lò” fún “àwọn lẹ́tà Hébérù mẹ́rin (ìyẹn YHWH) tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run olódùmarè” bó ṣe wà nínú àwọn ẹ̀dà ìtúmọ̀ Bíbélì Nova Vulgata tí wọ́n ṣe jáde lẹ́ẹ̀kejì. Ìyẹn sì yàtọ̀ sí “Iahveh” tó wà nínú àwọn ẹ̀dà tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe.b
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
b Wo àpilẹ̀kọ tá a pe àkọlé ẹ̀ ní “Àwọn Aláṣẹ Ìjọ Kátólíìkì Fẹ́ Pa Orúkọ Ọlọ́run Rẹ́,” lójú ìwé 30.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Bíbélì èdè Látìn tí Alcuin túmọ̀ lọ́dún 800 sànmánì Kristẹni
[Credit Line]
Látinú Paléographìe latine, tí F. Steffens ṣe (www.archivi.beniculturali.it)
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Ìtumọ̀ Vulgate tí Sixtine-Clementine túmọ̀ lọ́dún 1592
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ẹ́kísódù 3:15, ìtumọ̀ Nova Vulgata tí wọ́n tú lọ́dún 1979
[Credit Line]
© 2008 Libreria Editrice Vaticana