Ṣé Ààwẹ̀ Gbígbà Ló Máa Jẹ́ Kó O Sún Mọ́ Ọlọ́run?
‘Tó o bá ń gbààwẹ̀, wàá máa ronú jinlẹ̀ nípa àjọṣe ẹ pẹ̀lú Ọlọ́run, wàá sì máa rántí pé oúnjẹ àtàwọn nǹkan ìní kọ́ ló ṣe pàtàkì jù.’—OBÌNRIN ẸLẸ́SÌN KÁTÓLÍÌKÌ KAN.
‘Ìgbà tó o bá gbààwẹ̀ lo tó máa ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run.’—ỌKÙNRIN KAN TÓ JẸ́ RÁBÌ ÀWỌN JÚÙ.
‘Dandan lọ̀rọ̀ ààwẹ̀ gbígbà nínú ẹ̀sìn tèmi, òun ló máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé mo ti fayé mi fún Ọlọ́run, pé mo sì moore Ọlọ́run. Torí pé mo fẹ́ràn Ọlọ́run ni mo ṣe ń gbààwẹ̀.’—OBÌNRIN KAN TÓ JẸ́ ẸLẸ́SÌN BAHA’I.
ṢÀṢÀ lẹ̀sìn tó wà láyé yìí táwọn ọmọ ìjọ wọn kì í gbààwẹ̀, tàwọn ẹlẹ́sìn Búdà la fẹ́ sọ ni àbí tàwọn ẹlẹ́sìn Híńdú; tàwọn Mùsùlùmí ni àbí tàwọn ẹlẹ́sìn Jáínì ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ tàwọn tó ń ṣe Ìsìn Àwọn Júù. Ọ̀pọ̀ ló gbà pé téèyàn bá febi panú fáwọn àkókò kan, èèyàn máa túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.
Ṣóòótọ́ ni? Ṣé dandan ni kó o gbààwẹ̀? Kí ni Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tiẹ̀ sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí?
Ààwẹ̀ Táwọn Kan Gbà Lásìkò Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì
Lásìkò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, onírúurú nǹkan tínú Ọlọ́run dùn sí ló mú káwọn èèyàn gbààwẹ̀. Àwọn kan gbààwẹ̀ láti fi ẹ̀dùn ọkàn wọn hàn tàbí láti fi hàn pé àwọn ti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan tí wọ́n dá (1 Sámúẹ́lì 7:4-6), àwọn míì gbààwẹ̀ kí Ọlọ́run lè fàánú hàn sí wọn tàbí kó lè dáàbò bò wọ́n (Àwọn Onídàájọ́ 20:26-28; Lúùkù 2: 36, 37), torí káwọn kan sì lè mú kí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣàṣàrò túbọ̀ gbéṣẹ́ sí i ni wọ́n ṣe ń gbààwẹ̀.—Mátíù 4:1, 2.
Yàtọ̀ sáwọn tá a mẹ́nu kàn yìí, Bíbélì tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn kan tó gbààwẹ̀, àmọ́ tínú Ọlọ́run ò dùn sí i. Sọ́ọ̀lù Ọba gbààwẹ̀ kó tó lọ sọ́dọ̀ àwọn abẹ́mìílò. (Léfítíkù 20:6; 1 Sámúẹ́lì 28:20) Àwọn aṣebi, irú bíi Jésíbẹ́lì àtàwọn agbawèrèmẹ́sìn tó fẹ́ pa àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà ṣètò àkókò fún ààwẹ̀ gbígbà. (1 Àwọn Ọba 21:7-12; Ìṣe 23: 12-14) Ohun táwọn èèyàn sì mọ àwọn Farisí mọ́ jù lọ ni ààwẹ̀ tí wọ́n máa ń gbà ní gbogbo ìgbà. (Máàkù 2:18) Síbẹ̀, Jésù bẹnu àtẹ́ lù wọ́n, wọn ò sì rójúure Ọlọ́run. (Mátíù 6:16; Lúùkù 18:12) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà ò ka ààwẹ̀ táwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà sí nǹkan kan nítorí ìwàkiwà wọn àti pé ìdí tí wọ́n fi gbààwẹ̀ náà ò bá ìfẹ́ rẹ̀ mu.—Jeremáyà 14:12.
Àwọn àpẹẹrẹ tá a jíròrò yìí ti jẹ́ ká rí i pé kì í ṣe ààwẹ̀ yẹn gan-an ló ń múnú Ọlọ́run dùn séèyàn. Àmọ́, ọ̀pọ̀ lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó ń fi tọkàntara sìn ín, ni inú Ọlọ́run dùn sí ààwẹ̀ tí wọ́n gbà. Torí náà, ṣó yẹ káwọn Kristẹni máa gbààwẹ̀?
Ṣé Dandan Ni Káwọn Kristẹni Máa Gbààwẹ̀?
Òfin Mósè pa á láṣẹ pé káwọn Júù máa “ṣẹ́ ọkàn [ara wọn] níṣẹ̀ẹ́,” ìyẹn ni pé kí wọ́n máa gbààwẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, ní Ọjọ́ Ètùtù. (Léfítíkù 16:29-31; Sáàmù 35:13) Ààwẹ̀ yìí nìkan ni Jèhófà pàṣẹ pé káwọn èèyàn òun máa gbà.a Ó dájú pé àwọn Júù máa ṣègbọràn sí àṣẹ yẹn, torí Òfin Mósè ló ń darí wọn. Àmọ́, Òfin Mósè kọ́ ló ń darí àwa Kristẹni, torí náà òfin yẹn ò kàn wá.—Róòmù 10:4; Kólósè 2:14.
Òótọ́ ni pé Jésù gbààwẹ̀ bí Òfin ṣe sọ, àmọ́ ààwẹ̀ gbígbà kọ́ làwọn èèyàn mọ̀ ọ́n mọ́. Ó ṣàlàyé bó ṣe yẹ káwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ máa ṣe nígbà tó bá wù wọ́n láti gbààwẹ̀, àmọ́ kò sígbà tó pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n máa gbààwẹ̀. (Mátíù 6:16-18; 9:14) Tọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, kí wá nìdí tí Jésù fi sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa gbààwẹ̀ lẹ́yìn tóun bá kú? (Mátíù 9:15) Àṣẹ kọ́ ni Jésù pa nínú ẹsẹ Bíbélì yìí. Ohun tí Jésù ń sọ ni pé nígbà tóun bá kú, inú àwọn ọmọlẹ́yìn máa bà jẹ́ débi pé ẹnu wọn máa kọ oúnjẹ.
Àkọsílẹ̀ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó gbààwẹ̀ lára àwọn tó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni jẹ́ ká mọ̀ pé tó bá jẹ́ pé nǹkan tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu lèèyàn ń torí ẹ̀ febi panú, inú Ọlọ́run máa dùn sírú ààwẹ̀ bẹ́ẹ̀. (Ìṣe 13:2, 3; 14:23)b Torí náà, ààwẹ̀ gbígbà kì í ṣe dandan fáwa Kristẹni. Àmọ́, bẹ́nì kan bá wá pinnu pé òun fẹ́ gbààwẹ̀, ó máa dáa kó fara balẹ̀ ronú lórí àwọn ohun tí kì í jẹ́ kínú Ọlọ́run dùn sáwọn ààwẹ̀ kan.
Àwọn Ewu Tó Wà Nínú Ààwẹ̀ Gbígbà
Ọ̀kan lára àwọn ewu téèyàn gbọ́dọ̀ yẹra fún nígbà téèyàn bá ń gbààwẹ̀ ni òdodo àṣelékè. Bíbélì kìlọ̀ pé ká ṣọ́ra fún “ìrẹ̀lẹ̀ ẹlẹ́yà.” (Kólósè 2:20-23) Àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa Farisí tó rò pé ìwà òun sàn ju tàwọn ẹlòmíì lọ nítorí pé òun máa ń gbààwẹ̀ déédéé jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run ò fọwọ́ sírú ìwà bẹ́ẹ̀.—Lúùkù 18:9-14.
Yàtọ̀ síyẹn, àṣìṣe gbáà ló máa jẹ́ tó o bá jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ pó ò ń gbààwẹ̀ tàbí tó ò ń gbààwẹ̀ torí pé ẹnì kan sọ fún ẹ pé kó o ṣe bẹ́ẹ̀. Jésù gbà wá nímọ̀ràn nínú Mátíù 6:16-18 pé ọ̀ràn ara ẹni lọ̀ràn ààwẹ̀ gbígbà, àárín ìwọ àti Ọlọ́run ló yẹ kọ́rọ̀ náà wà, kò sì ní bọ́gbọ́n mu kó o máa lùlù ẹ̀ sétí àwọn ẹlòmíì.
A ò gbọ́dọ̀ máa ronú pé Ọlọ́run máa tìtorí àwọn ààwẹ̀ tá à ń gbà gbójú fo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tá ò jáwọ́ nínú ẹ̀. Tá a bá fẹ́ kínú Ọlọ́run dùn sáàwẹ̀ tá a bá gbà, a ní láti máa ṣègbọràn sáwọn àṣẹ rẹ̀. (Aísáyà 58:3-7) Tá a bá ronú pìwà dà látọkàn wá ni Ọlọ́run tó lè darí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, kì í ṣọ̀rọ̀ bá a ṣe ń gbààwẹ̀ tó. (Jóẹ́lì 2:12, 13) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Jèhófà fi hàn sí wa, nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà tí Kristi fara ẹ̀ ṣe, ló jẹ́ ká máa rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. Kò sóhun míì tá a lè ṣe tá a fi lè lẹ́tọ̀ọ́ sí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, kódà bá a gbààwẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ.—Róòmù 3:24, 27, 28; Gálátíà 2:16; Éfésù 2:8, 9.
Ìwé Aísáyà 58:3 tún sọ àṣìṣe míì táwọn èèyàn sábà máa ń ṣe. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ronú pé ó yẹ kí Jèhófà máa fáwọn ní nǹkan kan nítorí ààwẹ̀ táwọn ń gbà, bíi pé wọn ń fàwọn ààwẹ̀ tí wọ́n ń gbà ṣe Jèhófà lóore kan. Wọ́n ń béèrè pé: “Fún ìdí wo ni a fi ń gbààwẹ̀ tí ìwọ kò sì rí i, tí a sì ń ṣẹ́ ọkàn wa níṣẹ̀ẹ́ tí ìwọ kò sì fiyè sí i?” Lónìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn náà ló máa ń ronú pé ó yẹ kí Ọlọ́run tìtorí àwọn ààwẹ̀ táwọn ń gbà ṣàwọn lóore. Kò ní dáa ká fìwà jọ irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, torí pé wọn ò fọ̀wọ̀ wọ Jèhófà, ohun tí wọ́n sì ń ṣe yẹn ò bá Ìwé Mímọ́ mu!
Àwọn míì gbà pé àwọn máa rójúure Ọlọ́run táwọn bá ń febi para àwọn, táwọn ń na ara àwọn nínàkunà, tàbí táwọn ń fìyà jẹra àwọn láwọn ọ̀nà míì. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò fọwọ́ sírú àwọn ìwàkiwà bẹ́ẹ̀, torí Bíbélì jẹ́ kó ye wa pé “ìfìyàjẹ ara [ẹni] . . . kò níye lórí rárá nínú gbígbógunti” èròkerò.—Kólósè 2:20-23.
Ìrònú Tó Tọ́
Ààwẹ̀ gbígbà kì í ṣọ̀ràn-anyàn; kò sì burú béèyàn bá gbààwẹ̀. Nígbà míì, àǹfààní máa ń wà nínú ààwẹ̀ gbígbà, téèyàn bá ṣáà ti yẹra fáwọn ewu tá a ti sọ̀rọ̀ nípa wọn. Àmọ́, a ò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé ààwẹ̀ gbígbà kọ́ ni olórí ohun tó máa jẹ́ kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa. “Ọlọ́run aláyọ̀” ni Jèhófà, ó sì fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ òun máa láyọ̀. (1 Tímótì 1:11) Ọ̀rọ̀ ẹ̀ sọ pé: “Kò sí ohun tí ó sàn ju pé . . . kí olúkúlùkù ènìyàn máa jẹ, kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.”—Oníwàásù 3:12, 13.
Inú wa gbọ́dọ̀ máa dùn bá a ti ń jọ́sìn Ọlọ́run, àmọ́ Bíbélì ò fìgbà kankan sọ pé ààwẹ̀ gbígbà máa ń jẹ́ kínú èèyàn dùn. Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá lọ febi para wa débi tá ò fi lókun nínú tàbí tí àìsàn lọ kọ́lé sí wa lára, a ò ní lè ṣe iṣẹ́ aláyọ̀ tí Ẹlẹ́dàá wa gbé fáwa Kristẹni láti ṣe, ìyẹn iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn ò sì ní jẹ́ ká tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn wa.
Bóyá a pinnu láti gbààwẹ̀ tàbí pé a ò ní gbà á, a ò gbọ́dọ̀ dá ẹnikẹ́ni lẹ́jọ́. Kò yẹ kọ́rọ̀ yìí fa àríyànjiyàn láàárín àwa Kristẹni tòótọ́, “nítorí ìjọba Ọlọ́run kò túmọ̀ sí jíjẹ àti mímu, ṣùgbọ́n ó túmọ̀ sí òdodo àti àlàáfíà àti ìdùnnú pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́.”—Róòmù 14:17.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rí wà pé inú Jèhófà dùn sí ààwẹ̀ tí Ẹ́sítérì gbà ṣáájú Àjọyọ̀ Púrímù, Ọlọ́run kọ́ ló pàṣẹ pé kó gba ààwẹ̀ yẹn.
b Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan tún fàwọn ìsọfúnni kan nípa ààwẹ̀ gbígbà kún àwọn ìtumọ̀ wọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ ò sí nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ lédè Gíríìkì tí wọ́n fi tú Bíbélì.—Mátíù 17:21; Máàkù 9:29; Ìṣe 10:30; 1 Kọ́ríńtì 7:5; Bíbélì Mímọ́.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 28]
Ìrẹ̀lẹ̀ ẹlẹ́yà làwọn Farisí máa ń ní nígbà tí wọ́n bá ń gbààwẹ̀
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]
“Ìjọba Ọlọ́run kò túmọ̀ sí jíjẹ àti mímu, ṣùgbọ́n ó túmọ̀ sí òdodo àti àlàáfíà àti ìdùnnú pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]
Ààwẹ̀ Lẹ́ńtì Ńkọ́?
Àwọn tó máa ń gbààwẹ̀ ológójì ọjọ́ táwọn èèyàn máa ń pè ní lẹ́ńtì máa ń sọ pé ààwẹ̀ ológójì ọjọ́ tí Kristi gbà làwọn ń ṣèrántí ẹ̀. Àmọ́, Jésù ò pàṣẹ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n máa ṣèrántí ààwẹ̀ tóun gbà, kò sì sẹ́rìí pé àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. Inú àwọn lẹ́tà tí Átánéṣíọ́sì, tó jẹ́ bíṣọ́ọ̀bù àgbà ní ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, kọ lọ́dún 330 Sànmánì Kristẹni làwọn èèyàn ti kọ́kọ́ kà nípa gbígbà ààwẹ̀ ológójì ọjọ́ ṣáájú ọdún Àjíǹde.
Nígbà tó jẹ́ pé ẹ̀yìn tí Jésù ṣèrìbọmi tán ló gbààwẹ̀ kì í ṣe ọjọ́ mélòó kan ṣáájú ikú ẹ̀, kò sẹ́rìí kankan nínú Bíbélì táwọn onísìn tó ń gbààwẹ̀ Lẹ́ńtì láwọn ọ̀sẹ̀ mélòó kan ṣáájú ọdún Àjíǹdé lè fi ti ààwẹ̀ tí wọ́n ń gbà lẹ́yìn. Àmọ́, ẹ̀rí wà pé àwọn ará Bábílónì, àwọn ará Íjíbítì àtàwọn ará Gíríìsì máa ń gbààwẹ̀ ológójì ọjọ́ níbẹ̀rẹ̀ ọdún. Ó sì dájú pé àṣà àwọn Kèfèrí wọ̀nyí làwọn kan mú wọnú ẹ̀sìn Kristẹni.