Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Ó Jẹ́ Adúróṣinṣin Nígbà Ìdánwò
PÉTÉRÙ ń wojú àwọn tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀. Inú Sínágọ́gù tó wà nílùú Kápánáúmù ni wọ́n wà. Ìlú yìí ni Pétérù ń gbé; ibẹ̀ ló ti ń ṣiṣẹ́ ẹja pípa, ìyẹn létí Òkun Gálílì, ibẹ̀ náà sì ni ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, mọ̀lẹ́bí rẹ̀ àtàwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ ẹja pípa ń gbé. Kò sí àní-àní pé Pétérù fẹ́ káwọn ará ìlú rẹ̀ náà fojú ara wọn rí Jésù, kí inú tiwọn náà lè dùn bíi tiẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run látọ̀dọ̀ olùkọ́ tó ju gbogbo olùkọ́ lọ lórí ilẹ̀ ayé. Kò dájú pé inú àwọn èèyàn yìí máa dùn bíi ti Pétérù lọ́jọ́ tá à ń wí yìí.
Ọ̀pọ̀ nínú wọn ni kò tẹ́tí sí ohun tí Jésù ń bá wọn sọ mọ́. Àwọn kan tiẹ̀ ń ráhùn, wọ́n ń ta ko ọ̀rọ̀ Jésù. Ohun tí àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe ló jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára jù lọ fún Pétérù. Ó hàn lójú wọn pé inú wọn kò dùn bó ti máa ń rí tẹ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń kọ́ ẹ̀kọ́ tó ṣe pàtàkì, tí wọ́n ń mọ àwọn nǹkan tuntun, tí wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́dọ̀ Jésù. Lọ́jọ́ tá à ń wí yìí, ṣe ni wọ́n ń bínú, tí ojú wọn sì fà ro. Àwọn kan lára wọn sọ pé àwọn ọ̀rọ̀ Jésù ti le jù. Wọn kò fetí sílẹ̀ mọ́, wọ́n jáde nínú sínágọ́gù, wọ́n sì pa dà lẹ́yìn Jésù.
Nǹkan kò rọrùn fún Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù lákòókò tá à ń wí yìí. Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ lọ́jọ́ yẹn kò fi bẹ́ẹ̀ yé Pétérù pàápàá. Láìsí àní-àní, Pétérù mọ̀ pé ọ̀rọ̀ yẹn lè múnú bíni téèyàn ò bá ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yẹn. Kí wá ni Pétérù máa ṣe báyìí? Èyí kọ́ ni ìgbà àkọ́kọ́ tí nǹkan kan máa dán Pétérù wò bóyá ó jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọ̀gá rẹ̀, èyí sì kọ́ ni ìgbà tírú ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ kẹ́yìn. Jẹ́ ká wo bí ìgbàgbọ́ Pétérù ṣe ràn án lọ́wọ́ láti dúró ṣinṣin nígbà ìṣòrò yìí.
Ó Dúró Ṣinṣin Nígbà Táwọn Yòókù Yẹsẹ̀
Ohun tí Jésù ń ṣe sábà máa ń ya Pétérù lẹ́nu. Léraléra ni Jésù máa ń sọ tó sì máa ń ṣe ohun táwọn èèyàn kò retí. Ní ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ yẹn, Jésù ti bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn lọ́nà ìyanu. Ìyẹn mú káwọn èèyàn yẹn fẹ́ láti fi Jésù jọba. Ohun tí Jésù ṣe ya ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́nu, ó kọ̀ jálẹ̀, ó sì fi dandan lé e fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi kí wọ́n sì kọjá lọ sí Kápánáúmù. Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ń lọ lójú òkun ní òru, Jésù tún ṣe ohun tó yà wọ́n lẹ́nu nígbà tó rìn lórí Òkun Gálílì tó ń ru gùdù, tó sì kọ́ Pétérù ní ẹ̀kọ́ pàtàkì nípa ìgbàgbọ́.a
Nígbà tí ilẹ̀ fi máa mọ́, wọ́n wá rí i pé àwọn èèyàn tí àwọn fi sílẹ̀ ní etíkun ti wá pàdé àwọn ní òdìkejì adágún náà. Ó ṣe kedere pé, torí wọ́n fẹ́ kí Jésù tún fi iṣẹ́ ìyanu pèsè oúnjẹ fún wọn ni wọ́n ṣe ń wá a, kì í ṣe nítorí pé wọ́n fẹ́ gbọ́ òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Jésù dẹ́bi fún wọn torí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún àwọn nǹkan tara. Jésù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ nínú sínágọ́gù ní Kápánáúmù, ohun tó tún sọ yàtọ̀ pátápátá sóhun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń retí nítorí pé ó fẹ́ kọ́ wọn ní òtítọ́ pàtàkì kan tí kò ní dùn-ún gbọ́ létí.
Jésù kò fẹ́ káwọn èèyàn yẹn máa retí oúnjẹ ti ara látọ̀dọ̀ òun nígbà gbogbo, àmọ́ ó fẹ́ kí wọ́n máa wo òun gẹ́gẹ́ bí ìpèsè tẹ̀mí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí wíwá tó wá sáyé àti ikú tó máa kú máa jẹ́ káwọn èèyàn lè ní ìyè ayérayé. Torí náà, ó ṣe àpèjúwe kan fún wọn, ó fi ara rẹ̀ wé mánà, ìyẹn oúnjẹ tó wá láti ọ̀run nígbà ayé Mósè. Nígbà táwọn kan ta kò ó, óṣe àpèjúwe kan tó ṣe kedere, ó ní ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n jẹ ara òun, kí wọ́n sì mu ẹ̀jẹ̀ òun kí wọ́n bàa lè ní ìyè. Ìgbà tó sọ̀rọ̀ yìí ni wọ́n túbọ̀ wá ta kò ó. Àwọn kan sọ pé: “Ọ̀rọ̀ yìí ń múni gbọ̀n rìrì; ta ní lè fetí sí i?” Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ló pa dà lẹ́yìn rẹ̀.b—Jòhánù 6:48-60, 66.
Kí ni Pétérù máa wá ṣe? Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí ti ní láti ya òun náà lẹ́nu. Kò tí ì lóye pé Jésù ní láti kú kó bàa lè mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. Síbẹ̀, Pétérù kò ronú láti kúrò lẹ́yìn Jésù bíi tàwọn aláìnípinnu ọmọ ẹ̀yìn tó pa dà lẹ́yìn Jésù lọ́jọ́ náà. Ó dájú pé ohun kan tó ṣe pàtàkì mú kí Pétérù yàtọ̀ pátápátá sáwọn ọkùnrin wọ̀nyẹn. Kí ni nǹkan ọ̀hún?
Jésù yíjú sí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin kò fẹ́ lọ pẹ̀lú, àbí?” (Jòhánù 6:67) Gbogbo àwọn méjìlá náà ló ń bá wí, àmọ́ Pétérù ló fèsì. Bó sì ṣe sábà máa ń rí nìyẹn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Pétérù ló dàgbà jù láàárín wọn. Ohun yòówù kó jẹ́, ó dájú pé òun ni kì í fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ nínú wọn. Ìdí nìyẹn tí Pétérù kì í fi í lọ́ra láti sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, gbólóhùn mánigbàgbé kan tó dára gan-an ló wà lọ́kàn rẹ̀, ó ní: “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa yóò lọ? Ìwọ ni ó ní àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 6:68.
Ǹjẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ yìí kò wọ̀ ẹ́ lọ́kàn? Ìgbàgbọ́ tí Pétérù ní nínú Jésù ti ràn án lọ́wọ́ láti ní ànímọ́ kan tó ta yọ, ìyẹn ìdúróṣinṣin. Pétérù mọ̀ dájú pé kò sí Olùgbàlà míì tó yàtọ̀ sí Jésù àti pé ẹ̀kọ́ Jésù lè gba àwa èèyàn là, ìyẹn ẹ̀kọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Pétérù mọ̀ pé ká tiẹ̀ ní àwọn ohun kan wà tí kò yé òun, kò síbòmíì tóun lè lọ, bóun bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run àti ìbùkún ìyè àìnípẹ̀kun.
Ṣé bó ṣe rí lára tìẹ náà nìyẹn? Ó ṣeni láàánú pé, ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé lónìí ló ń sọ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Jésù, àmọ́ tí wọ́n á yẹsẹ̀ nígbà tí ìdánwò bá dé. Tá a bá fẹ́ fi hàn pé a jẹ́ adúróṣinṣin sí Kristi, irú ojú tí Pétérù fi ń wo ẹ̀kọ́ Jésù làwa náà gbọ́dọ̀ máa fi wò ó. A ní láti kọ́ ẹ̀kọ́ látọ̀dọ̀ Jésù, ká lóye wọn, ká sì máa fi wọ́n sílò nígbèésí ayé wa, kódà táwọn ẹ̀kọ́ yìí bá yà wá lẹ́nu tórí pé wọ́n yàtọ̀ sáwọn ohun tá à ń retí tàbí sí àwọn ohun tá a nífẹ̀ẹ́ sí. Tá a bá fẹ́ ní ìyè àìnípẹ̀kun tí Jésù ń fẹ́ ká rí gbà, à gbọ́dọ̀ jẹ́ adúróṣinṣin.
Ó Dúró Ṣinṣin Nígbà Tí Wọ́n Tọ́ Ọ Sọ́nà
Lákòókò díẹ̀ lẹ́yìn tí ọwọ́ wọn dí gan-an yìí, Jésù mú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn kan lọ sí ìrìn-àjò jíjìn kan lápá àríwá. Nígbà míì láti orí Òkun Gálílì tó mọ́ roro, wọ́n máa ń rí ṣóńṣó orí Òkè Hámónì tí yìnyín bò, tó wà ní ìkángun àríwá Ilẹ̀ Ìlérí. Díẹ̀díẹ̀ ló ń dà bíi pé òkè yìí ń ga sí i, bí wọ́n ti ń sún mọ́ ọn, tí wọ́n sì ń gbà àwọn ọ̀nà olókè tó lọ sáwọn abúlé tó wà ní agbègbè Kesaréà nílùú Fílípì.c Ní àgbègbè tó fani lọ́kàn mọ́ra yìí, níbi tí wọ́n ti lè rí èyí tó pọ̀ jù nínú Ilẹ̀ Ìlérí láti apá gúúsù, Jésù béèrè ìbéèrè pàtàkì kan lọ́wọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀.
Ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Ta ni àwọn ogunlọ́gọ̀ ń sọ pé mo jẹ́?” A lè fojú inú wo bí Pétérù á ṣe máa wojú Jésù, tó sì ń ronú nípa bí Ọ̀gá rẹ̀ yìí ṣe jẹ́ aláàánú àti bó ṣe ní ìmọ̀ lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Jésù fẹ́ mọ èrò àwọn èèyàn náà lẹ́yìn tí wọ́n ti rí òun, tí wọ́n sì ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ òun. Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn máa fèsì, àwọn èrò tí kò tọ̀nà tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní nípa Jésù láwọn náà tún sọ. Àmọ́ Jésù tún fẹ́ mọ̀ síwájú sí i. Ó fẹ́ mọ̀ bóyá àwọn ọmọlẹ́yìn tí wọ́n sún mọ́ òun dáadáa ń ṣe irú àṣìṣe kan náà. Torí náà, ó bi wọ́n pé: “Ṣùgbọ́n, ẹ̀yin, ta ni ẹ sọ pé mo jẹ́?”—Lúùkù 9:18-22.
Pétérù ló tún kọ́kọ́ fèsì lọ́tẹ̀ yìí. Ó fi ìgboyà sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, ó ní: “Ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.” A lè fojú inú wo bí Jésù ṣe rẹ́rìn músẹ́ sí Pétérù láti fi hàn pé òun fara mọ́ ohun tó sọ, òun sì gbóríyìn fún un. Jésù wá rán Pétérù létí pé Jèhófà Ọlọ́run ló jẹ́ káwọn tó ní ojúlówó ìgbàgbọ́ mọ òtítọ́ tó ṣe pàtàkì yìí, kì í ṣe èèyàn. Jèhófà ti jẹ́ kí Pétérù fòye mọ ọ̀kan lára àwọn òtítọ́ pàtàkì tí òun kò tíì ṣí payá, ìyẹn nípa Mèsáyà tí Ọlọ́run ti ṣèlérí tipẹ́tipẹ́ tàbí Kristi náà!—Mátíù 16:16, 17.
Kristi yìí ni àsọtẹ́lẹ̀ àtijọ́ pè ní òkúta táwọn akọ́lé máa pa tì. (Sáàmù 118:22; Lúùkù 20:17) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó ṣí i payá pé Jèhófà máa fi ìpìlẹ̀ ìjọ kan lélẹ̀ lórí òkúta tàbí àpáta ràbàtà tí Pétérù ṣẹ̀ṣẹ̀ fi hàn.d Lẹ́yìn náà ló wá gbé àwọn iṣẹ́ pàtàkì kan lé Pétérù lọ́wọ́ nínú ìjọ náà. Kò fi Pétérù ṣe olórí àwọn àpọ́sítélì yòókù gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣe rò, àmọ́ ńṣe ló gbé àwọn iṣẹ́ kan lé e lọ́wọ́. Ó fún Pétérù ní “àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba” náà. (Mátíù 16:19) Iṣẹ́ Pétérù ni láti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwùjọ èèyàn mẹ́ta lára aráyé, kí wọ́n lè nírètí láti wọ Ìjọba Ọlọ́run. Àwùjọ àkọ́kọ́ ni àwọn Júù, lẹ́yìn náà àwọn ará Samáríà àti nígbẹ̀yìngbẹ́yín àwọn Kèfèrí, ìyẹn àwọn tí kì í ṣe Júù.
Àmọ́, lẹ́yìn náà Jésù sọ pé a máa béèrè ohun tó pọ̀ lọ́wọ́ àwọn tá a bá fi ohun tó pọ̀ sí níkàáwọ́, bọ́rọ̀ Pétérù náà sì ṣe rí nìyẹn. (Lúùkù 12:48) Jésù ń bá a nìṣó láti máa sọ àwọn òtítọ́ tó ṣe pàtàkì fún wọn nípa Mèsáyà, títí kan ìjìyà àti ikú rẹ̀ tó dájú pé ó máa wáyé nílùú Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí Pétérù gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó bà á lọ́kàn jẹ́. Torí náà, ó mú Jésù lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó sì bá a wí lọ́nà tó múná, ó ní: “Ṣàánú ara rẹ, Olúwa; ìwọ kì yóò ní ìpín yìí rárá.”—Mátíù 16:21, 22.
Torí pé Pétérù kò ní ohun búburú kankan lọ́kàn, èsì tí Jésù fún un ti ní láti yà á lẹ́nu gan-an. Ó kọ ẹ̀yìn sí Pétérù, ó sì yíjú sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù, tó ṣeé ṣe kí èrò wọn dọ́gba pẹ̀lú ti Pétérù, ó wá sọ pé: “Kó ara rẹ̀ kúrò niwaju mi, Satani. Ohun ìkọsẹ̀ ni o jẹ́ fún mi, nitori o kò ro nnkan ti Ọlọ́run, ti eniyan ni o ń rò.” (Matiu 16:23; Maku 8:32, 33; Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀) Ìmọ̀ràn tó wúlò fún gbogbo wa ló wà nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí. Ó rọrùn fún wa gan-an láti jẹ́ kí èrò èèyàn gbà wá lọ́kàn ju ti Ọlọ́run lọ. Tá a bá sì jẹ́ kí èrò èèyàn gbà wá lọ́kàn, kódà tó bá jẹ́ ohun rere la ní lọ́kàn, a lè di ẹni tó ń ti ìfẹ́ ọkàn Sátánì lẹ́yìn láìmọ̀ dípò ti Ọlọ́run. Kí ni Pétérù wá ṣe?
Pétérù mọ̀ dájú pé Jésù kò pe òun ní Sátánì Èṣù. Ó ṣe tán, kì í ṣe ohun tí Jésù sọ fún Sátánì ló sọ fún Pétérù. Ó sọ fún Sátánì pé: “Padà kúró lẹ́hìn mi,” àmọ́ ó sọ fún Pétérù pé, “Kó ara rẹ̀ kúrò níwájú mi.” (Matiu 4:10; Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀) Jésù kò sọ pé kí àpọ́sítélì yìí má ṣe tọ òun lẹ́yìn mọ́, torí ó mọ̀ pé Pétérù ṣì máa ṣe àwọn ohun tó dára lọ́jọ́ iwájú, àmọ́ ńṣe ló kàn fẹ́ tọ́ ọ sọ́nà nínú ọ̀ràn yìí. Ó ṣe kedere pé kò yẹ kí Pétérù sọ ara rẹ̀ di òkúta ìkọ̀sẹ̀ níwájú Ọ̀gá rẹ̀, àmọ́ ńṣe ló yẹ kí Pétérù kúrò níwájú Ọ̀gá rẹ̀ kó bọ́ sẹ́yìn rẹ̀ kó sì máa tì í lẹ́yìn.
Ǹjẹ́ Pétérù jiyàn, kí inú bí i tàbí kó di kùrùgbùn? Rárá o, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló fi ìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́ gba ìtọ́sọ́nà. Ó tún tipa báyìí fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin. Gbogbo àwọn tó bá ń tẹ̀ lé Kristi ní yóò máa nílò ìtọ́sọ́nà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Kìkì tá a bá ń gba ìbáwí tá a sì ń kẹ́kọ̀ọ́ látinú rẹ̀ nìkan la fi lè máa bá a nìṣó láti máa sún mọ́ Jésù Kristi àti Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Bàbá rẹ̀.—Òwe 4:13.
Ó Rí Èrè Gbà Nítorí Pé Ó Dúró Ṣinṣin
Lẹ́yìn ìgbà náà ni Jésù tún sọ gbólóhùn kan tó yani lẹ́nu, ó ní: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé àwọn kan wà lára àwọn tí wọ́n dúró níhìn-ín tí kì yóò tọ́ ikú wò rárá títí wọn yóò fi kọ́kọ́ rí Ọmọ ènìyàn tí ń bọ̀ nínú ìjọba rẹ̀.” (Mátíù 16:28) Ó dájú pé Pétérù ń hára gàgà láti mọ ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ yìí. Kí ló ṣeé ṣe kí Jésù ní lọ́kàn? Pétérù lè máa ronú pé, bóyá lòun lè ní irú àǹfààní tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yẹn, nítorí ìbáwí tó lágbára tí òun gbà yìí.
Àmọ́ ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn ìgbà náà, Jésù mú Jákọ́bù, Jòhánù àti Pétérù lọ sí orí “òkè ńlá kan tí ó ga fíofío,” ó lè jẹ́ orí Òkè Hámónì tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí wọn. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ lọ́wọ́ alẹ́, nítorí oorun ti ń kun àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Àmọ́ bí Jésù ti ń gbàdúrà, ohun kan tó mú kí oorun dá lójú wọn ṣẹlẹ̀.—Mátíù 17:1; Lúùkù 9:28, 29, 32.
Ìrísí Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà lójú wọn. Ojú rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í dán, ó sì ń kọ mànà títí tó fi mọ́lẹ̀ yòò bí oòrùn. Ẹ̀wù rẹ̀ pàápàá di funfun ti ń dán yinrin. Lẹ́yìn náà, ìran kan wáyé, àwọn méjì tí wọ́n fara hàn pẹ̀lú Jésù nínú ìran náà sì ṣàpẹrẹ Mósè àti Èlíjà. Wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀ nípa “lílọ rẹ̀ tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ fún un láti mú ṣẹ ní Jerúsálẹ́mù,” ìyẹn ọ̀rọ̀ nípa ikú àti àjíǹde Jésù. Ó wá ṣe kedere pé èrò Pétérù kò tọ̀nà bó ṣe sọ pé òun ò fẹ́ kí Jésù fojú winá àwọn ohun tó wà níwájú rẹ̀!—Lúùkù 9:30, 31.
Ó di dandan fún Pétérù láti kópa lọ́nà kan nínú ìran tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí. Nígbà tó yá, ó dà bíi pé Mósè àti Èlíjà fẹ́ kúrò lọ́dọ̀ Jésù. Torí náà, Pétérù sọ pé: “Olùkọ́ni, ó dára púpọ̀ fún wa láti wà níhìn-ín, nítorí náà, jẹ́ kí a gbé àgọ́ mẹ́ta nà ró, ọ̀kan fún ọ àti ọ̀kan fún Mósè àti ọ̀kan fún Èlíjà.” Ní ti gidi, àwọn méjì tó ṣàpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti kú tipẹ́ yìí kò nílò àgọ́. Pétérù kò mọ ohun tó ń sọ ní ti gidi. Ǹjẹ́ ìtara àti ọ̀yàyà tí Pétérù ní yìí kò mú kó o fẹ́ láti sún mọ́ ọn?—Lúùkù 9:33.
Pétérù àti Jákọ́bù pẹ̀lú Jòhánù tún rí èrè míì gbà lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Àwọsánmà kan gbára jọ, ó sì ṣíji bò wọ́n lórí òkè náà. Ohùn kan jáde wá látinú àwọsánmà náà, ohùn Jèhófà Ọlọ́run ni! Ó ní: “Èyí ni Ọmọ mi, ẹni tí a ti yàn. Ẹ fetí sí i.” Lẹ́yìn èyí, ìran náà parí, ló bá ku àwọn àti Jésù nìkan lórí òkè náà.—Lúùkù 9:34-36.
Ẹ ò rí i pé ẹ̀bùn àtàtà ni ìran yìí jẹ́ fún Pétérù àti fún àwa náà! Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà náà, ó kọ̀wé nípa àǹfààní tó ní lálẹ́ ọjọ́ náà, ó ní òun “fi ojú rí ọlá ńlá rẹ̀,” ó fojú ara rẹ̀ rí ìran Jésù tí a ṣe lógo gẹ́gẹ́ bí Ọba ọ̀run! Ìran yìí jẹ́ ẹ̀rí sí ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sì fún ìgbàgbọ́ Pétérù lókun kó bàa lè kojú àwọn àdánwò tó máa dé bá a. (2 Pétérù 1:16-19) Bíi ti Pétérù ìran yìí lè fún ìgbàgbọ́ tiwa náà lókun, tá a bá dúró ṣinṣin ti Ọ̀gá tí Jèhófà ti yàn fún wa, tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀, tá à ń gba ìbáwí àti ìtọ́sọ́nà rẹ̀, tá a sì ń fi ìrẹ̀lẹ̀ tẹ̀ lé e lójoojúmọ́.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn—Ó Gbógun Ti Ìbẹ̀rù àti Iyèméjì” nínú Ilé Ìṣọ́ October 1, 2009.
b Tá a bá fi ohun tí wọ́n ṣe lọ́jọ́ tí wọ́n fìtara pòkìkí Jésù pé ó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run wé ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kejì nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ṣe kedere pé èrò àwọn èèyàn tó wà ní sínágọ́gù náà kò dúró sójú kan.—Jòhánù 6:14.
c Etí Òkun Gálílì tí wọ́n wà jẹ́ pẹ̀tẹ́lẹ̀ tó lọọlẹ̀ gan-an ní nǹkan bí igba-ó-lé-mẹ́wàá [210] mítà, wọ́n wá rìnrìn àjò kìlómítà méjìdínláàádọ́ta [48] lọ sáwọn ibi gíga tó ga tó àádọ́ta-dín-nírinwó [350] mítà. Ẹwà àrímáleèlọ ló wà ní gbogbo àgbègbè olókè náà.
d Wo àpótí tá a pe àkọlé rẹ̀ ní: “Ta Ni Àpáta Ràbàtà Náà?” lójú ìwé 28.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Ta Ni Àpáta Ràbàtà Náà?
“Mo sọ fún ọ, Ìwọ ni Pétérù, orí àpáta ràbàtà yìí sì ni èmi yóò kọ́ ìjọ mi sí dájúdájú.” (Mátíù 16:18) Ohun táwọn èèyàn sábà máa ń túmọ̀ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún àpọ́sítélì Pétérù sí ni pé, Pétérù ló máa di ìpìlẹ̀ ìjọ Kristẹni. Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì fi kọ́ni pé ńṣe ni Jésù fi Pétérù ṣe olórí àwọn àpọ́sítélì yòókù, tó sì wá tipa bẹ́ẹ̀ sọ ọ́ di póòpù àkọ́kọ́. Ní ilé ìjọsìn Saint Peter’s Basilica nílùú Róòmù, wọ́n kọ ọ̀rọ̀ Jésù lédè Látìn sínú òrùlé gogoro. Lẹ́tà tí wọ́n fi kọ àwọn ọ̀rọ̀ náà ga ju èèyàn lọ ní ìdúró.
Ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé Pétérù ni àpáta ràbàtà tóun máa kọ́ ìjọ òun lé? Rárá o. Jẹ́ ká wo ohun mẹ́ta tó jẹ́ ká mọ̀ pé Pétérù kì í ṣe àpáta ràbàtà náà. Àkọ́kọ́ ni pé, àwọn àpọ́sítélì yòókù wà níbẹ̀, wọn kò sì lóye ọ̀rọ̀ Jésù bẹ́ẹ̀. Tó bá jẹ òótọ́ ni pé Jésù fi Pétérù ṣe olórí àwọn àpọ́sítélì yòókù, kí wá nìdí tí wọ́n fi ń jiyàn lọ́pọ̀ ìgbà lórí ẹni tó tóbi jù? (Máàkù 9:33-35; Lúùkù 22:24-26) Èkejì ni pé, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn nígbà tó yá pé Jésù Kristi ni àpáta ràbàtà yẹn kì í ṣe Pétérù. (1 Kọ́ríńtì 3:11; 10:4) Ìkẹta ni pé, lọ́pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Pétérù fúnra rẹ̀ fi hàn pé, òun kò ka ara òun sí àpáta ràbàtà náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó kọ̀wé pé, Jésù ni Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ látọjọ́ pípẹ́ pé ó jẹ́ “òkúta ìpìlẹ̀ igun ilé” tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yàn.—1 Pétérù 2:4-8.
Síbẹ̀, àwọn kan ṣì ń sọ pé, níwọ̀n ìgbà tí orúkọ Pétérù ti túmọ̀ sí “Àpáta,” ńṣe ni Jésù ń tọ́ka sí i pé ó jẹ́ àpáta ràbàtà náà. Nínú ẹsẹ yẹn, orúkọ Pétérù kò túmọ̀ sí “àpáta ràbàtà.” Ohun tí orúkọ Pétérù túmọ̀ sí ni “ègé òkúta,” ó sì jẹ́ orúkọ tí wọ́n fi ń pe ohun tó bá jẹ́ akọ. Àmọ́, ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò fún “àpáta ràbàtà” jẹ́ orúkọ tí wọ́n fi ń pe ohun tó bá jẹ́ abo. Kí ni ọ̀rọ̀ Jésù wá túmọ̀ sí? Ohun tó ń sọ fún Pétérù ni pé: “Ìwọ tí mo pè ní Pétérù tàbí Àpáta, ti wá mọ ẹni tí ‘àpáta ràbàtà’ náà jẹ́ gan-an, ìyẹn Kristi, ẹni tó máa jẹ́ ìpìlẹ̀ ìjọ Kristẹni.” Àǹfààní ńlá ni Pétérù ní láti jẹ́ ká mọ òtítọ́ pàtàkì yìí!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]
Pétérù jẹ́ adúróṣinṣin kódà nígbà tí wọ́n tọ́ ọ sọ́nà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ìran tó fani lọ́kàn mọ́ra tí Pétérù rí yìí jẹ́ èrè fún un nítorí pé ó jẹ́ adúróṣinṣin