Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Yàtọ̀ sí wáìnì, irú ọtí wo ni wọ́n máa ń ṣe nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì?
▪ Nínú Bíbélì, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ nípa “wáìnì àti ọtí tí ń pani” pa pọ̀. (Diutarónómì 14:26; Lúùkù 1:15) Kò yẹ ká rò pé ọ̀rọ̀ náà “ọtí” túmọ̀ sí pé ńṣe ni wọ́n sè é, torí pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í lo irú ọ̀nà yìí láti fi mú ọtí jáde. Kì í ṣe inú àwọn èso bí èso àjàrà, déètì, ọ̀pọ̀tọ́, ápù àti èso pómégíránétì nìkan ni wọ́n ti máa ń rí ọtí, wọ́n tún máa ń rí i nínú oyin.
Kódà, “ọtí tí ń pani” tún lè túmọ̀ sí bíà. Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n túmọ̀ sí “ọtí tí ń pani” jẹmọ́ ọ̀rọ̀ Ákádì tí wọ́n fi ń pe ọtí bíà tí wọ́n fi ọkà bálì ṣe nílẹ̀ Mesopotámíà. Ohun tó ń mú kí nǹkan pani lọ́bọ̀ọ́lọ̀ kò pọ̀ nínú ọtí yìí, àmọ́ ó máa ń pani téèyàn bá mu ún lámujù. (Òwe 20:1) Ilé ìpọntí tí wọ́n fi amọ̀ mọ àti àwòrán àwọn tó ń pọn ọtí ni wọ́n ti rí nínú àwọn ibojì ilẹ̀ Íjíbítì àtijọ́. Lójoojúmọ́ ní ìlú Bábílónì, ibi gbogbo ni wọ́n ti máa ń mu ọtí bíà, wọ́n máa ń mu ún ní àwọn ààfin àti nínú ilé àwọn tálákà pàápàá. Bákan náà, àwọn ará Filísínì náà máa ń mu irú ọtí yìí. Níbi gbogbo nílẹ̀ Palẹ́sínì, àwọn awalẹ̀pìtàn ti ṣàwárí àwọn ife ńlá tí wọ́n ṣe asẹ́ sí. Wọ́n máa ń fi àwọn ife yìí sẹ́ ọtí bíà káwọn tó ń mutí má bàa mu èèpo ọkà bálì tí wọ́n fi ṣe ọtí bíà náà.
Nígbà ayé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, kí nìdí tó fi máa ń ṣòro láti tukọ̀ lójú agbami láwọn àkókò kan láàárín ọdún?
▪ Nítorí ìjì líle, ọkọ̀ òkun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wọ̀ lo àkókò tó pọ̀ bó ṣe forí lé ìwọ̀ oòrùn etíkun Éṣíà Kékeré. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé nígbà tó di àárín kan ó “léwu . . . láti tukọ̀ nítorí pé ààwẹ̀ ọjọ́ ètùtù pàápàá ti kọjá lọ ná.” Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn tí wọ́n jọ wà nínú ọkọ̀ náà pé ó léwu táwọn bá gbìyànjú láti máa bá ìrìn àjò náà lọ torí pé àwọn yóò pàdánù àwọn nǹkan “kì í ṣe kìkì . . . ẹrù àti ọkọ̀ ojú omi nìkan ni, ṣùgbọ́n . . . ọkàn [àwọn] pẹ̀lú.”—Ìṣe 27:4-10.
Apá ìparí oṣù September tàbí ìbẹ̀rẹ̀ oṣù October ni ààwẹ̀ Ọjọ́ Ètùtù máa ń bọ́ sí. Àwọn ará Róòmù tó ń tukọ̀ òkun mọ̀ pé kò séwu téèyàn bá tukọ̀ lójú agbami láti May 27 sí September 14. Wọ́n sọ pé ewu lè wà téèyàn bá tukọ̀ lójú agbami láti September 14 sí November 11, àmọ́ ìgbà tó wá léwu jù láti tukọ̀ lójú agbami ni November 11 sí March 10. Gẹ́gẹ́ bí ìrírí Pọ́ọ̀lù ti fi hàn, ojú ọjọ́ tí kò dúró sójú kan jẹ́ ìdí kan tó fi máa ń rí bẹ́ẹ̀. (Ìṣe 27:13-44) Àwọn tó ń tukọ̀ ojú omi máa ń kojú ẹ̀fúùfù líle, ó sì tún máa ń ṣòro fún wọn gan-an láti tukọ̀ lójú agbami. Àwọsánmà kì í jẹ́ kí wọ́n rí ìmọ́lẹ̀ oòrùn lọ́sàn-án, ó sì tún máa ń ṣú bo ìràwọ̀ lálẹ́. Kùrukùru àti òjò kì í jẹ́ kí wọ́n lè ríran dáadáa, èyí sì máa ń jẹ́ kó ṣòro láti rí àwọn nǹkan tó lè fa ewu.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Igi táwọn ará Íjíbítì gbẹ́ bí ìgò bíà
[Credit Line]
Erich Lessing/Art Resource, NY
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ọkọ̀ òkun akẹ́rù ti àwọn ará Róòmù ní nǹkan bí ọdún 100 sí 200 sànmánì Kristẹni
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.