Agbo Kan, Olùṣọ́ Àgùntàn Kan
“Ẹ̀yin tí ẹ ti tọ̀ mí lẹ́yìn yóò jókòó pẹ̀lú sórí ìtẹ́ méjìlá, ẹ óò máa ṣèdájọ́ ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.”—MÁT. 19:28.
1. Báwo ni Jèhófà ṣe bá àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù lò, kí sì nìdí tí ìyẹn ò fi túmọ̀ sí pé kò ka àwọn èèyàn tó wá láti orílẹ̀-èdè mìíràn sí?
JÈHÓFÀ fẹ́ràn Ábúráhámù, torí náà Ó fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀. Ó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ ọdún [1,500] tó fi ń wo orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, tó ṣẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ábúráhámù, gẹ́gẹ́ bí àwọn èèyàn tí òun yàn, tí wọ́n sì jẹ́ “àkànṣe dúkìá” fún òun. (Ka Diutarónómì 7:6.) Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé Jèhófà ò ka àwọn èèyàn tó bá wá láti àwọn orílẹ̀-èdè míì sí? Rárá o. Nígbà yẹn, Jèhófà gbà pé kí àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, tí wọ́n sì fẹ́ láti máa jọ́sìn òun, dara pọ̀ mọ́ orílẹ̀-èdè àkànṣe yìí. Àwọn tó dara pọ̀ mọ́ wọn lọ́nà yìí la mọ̀ sí aláwọ̀ṣe, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń wò wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára wọn. Wọ́n sì gbọ́dọ̀ máa bá wọn lò bí ọmọ ìbílẹ̀. (Léf. 19:33, 34) Àwọn náà sì gbọ́dọ̀ máa pa gbogbo òfin Jèhófà mọ́.—Léf. 24:22.
2. Ọ̀rọ̀ tí ń múni ta kìjí wo ni Jésù sọ, ìbéèrè wo nìyẹn sì mú wá?
2 Àmọ́, Jésù sọ ọ̀rọ̀ kan tí ń múni ta kìjí fáwọn Júù ìgbà ayé rẹ̀, ó ní: “A ó gba ìjọba Ọlọ́run kúrò lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ jáde.” (Mát. 21:43) Àwọn wo ló máa para pọ̀ di orílẹ̀-èdè tuntun yìí, báwo sì ni ìyípadà tó wáyé yìí ṣe kàn wá lónìí?
Orílẹ̀-Èdè Tuntun Náà
3, 4. (a) Báwo ni àpọ́sítélì Pétérù ṣe jẹ́ ká mọ orílẹ̀-èdè tuntun náà? (b) Àwọn wo ló para pọ̀ di orílẹ̀-èdè tuntun yìí?
3 Lọ́nà tó ṣe kedere, àpọ́sítélì Pétérù jẹ́ ká mọ orílẹ̀-èdè tuntun yìí. Ó kọ̀wé sáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni pé: “Ẹ̀yin jẹ́ ‘ẹ̀yà àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́, àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní, kí ẹ lè polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá’ ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.” (1 Pét. 2:9) Bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn Júù àbínibí tí wọ́n gba Jésù gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà ni wọ́n kọ́kọ́ di ara orílẹ̀-èdè tuntun náà. (Dán. 9:27a; Mát. 10:6) Lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì di ara orílẹ̀-èdè náà, torí Pétérù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ẹ kì í ṣe ènìyàn nígbà kan rí, ṣùgbọ́n nísinsìnyí ẹ jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run.”—1 Pét. 2:10.
4 Àwọn wo ni Pétérù ń bá wí nínú ẹsẹ yìí? Ní ìbẹ̀rẹ̀ lẹ́tà rẹ̀, ó sọ pé: “[Ọlọ́run] fún wa ní ìbí tuntun sí ìrètí tí ó wà láàyè nípasẹ̀ àjíǹde Jésù Kristi kúrò nínú òkú, sí ogún tí ó jẹ́ aláìlè-díbàjẹ́ àti aláìlẹ́gbin àti aláìlèṣá. A fi í pa mọ́ ní ọ̀run de ẹ̀yin.” (1 Pét. 1:3, 4) Torí náà, àwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn, tí wọ́n ní ìrètí lílọ sí ọ̀run, ló para pọ̀ di orílẹ̀-èdè tuntun yìí. Àwọn ni “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gál. 6:16) Nínú ìran kan, àpọ́sítélì Jòhánù rí i pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ni gbogbo àwọn tó jẹ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run yìí. A “rà” wọ́n “lára aráyé gẹ́gẹ́ bí àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà” kí wọ́n lè jẹ́ “àlùfáà” kí wọ́n sì “ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú [Jésù] fún ẹgbẹ̀rún ọdún.”—Ìṣí. 5:10; 7:4; 14:1, 4; 20:6; Ják. 1:18.
Ṣé Àwọn Míì Wà Lára Wọn?
5. (a) Àwọn wo ni gbólóhùn náà, “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” ń tọ́ka sí? (b) Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ náà “Ísírẹ́lì” fi máa ń ní ìtumọ̀ tó ju ẹyọ kan lọ nígbà míì?
5 Ó ṣe kedere pé àwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn nìkan ni gbólóhùn náà, “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” tá a lò nínú Gálátíà 6:16, ń tọ́ka sí. Àmọ́, ǹjẹ́ ìgbà kankan tiẹ̀ wà tí Jèhófà ṣe àpèjúwe èyíkéyìí nípa orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lọ́nà tó fi hàn pé wọ́n dúró fún àwọn Kristẹni míì yàtọ̀ sáwọn ẹni àmì òróró? A lè rí ìdáhùn èyí nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olùṣòtítọ́ pé: “Èmi sì bá yín dá májẹ̀mú kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú kan, fún ìjọba kan, kí ẹ lè máa jẹ, kí ẹ sì máa mu nídìí tábìlì mi nínú ìjọba mi, kí ẹ sì jókòó lórí ìtẹ́ láti ṣèdájọ́ ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.” (Lúùkù 22:28-30) Èyí máa wáyé nígbà “àtúndá,” tàbí àkókò ìsọdọ̀tun, nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún Kristi.—Ka Mátíù 19:28.
6, 7. Àwọn wo ni gbólóhùn náà, “ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá,” tí Mátíù 19:28 àti Lúùkù 22:30 sọ̀rọ̀ wọn dúró fún?
6 Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] máa jẹ́ ọba, àlùfáà àti onídàájọ́ lókè ọ̀run nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. (Ìṣí. 20:4) Ìdájọ́ àwọn wo ni wọ́n máa ṣe, ta ni wọ́n sì máa ṣàkóso lé lórí? Nínú Mátíù 19:28 àti Lúùkù 22:30, a sọ fún wa pé wọ́n máa ṣèdájọ́ “ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.” Àwọn wo ni “ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá” dúró fún nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí? Wọ́n dúró fún gbogbo àwọn tó ní ìrètí ti orí ilẹ̀ ayé, àwọn tó ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ Jésù, àmọ́ tí wọn kì í ṣe ara ẹgbẹ́ àlùfáà. (Kò sí ẹ̀yà Léfì lára orúkọ ẹ̀yà méjìlá tó jẹ́ ti Ísírẹ́lì nípa ti ara.) Àwọn tí Bíbélì pè ní ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ni àwọn tó máa jàǹfààní nípa tẹ̀mí látinú iṣẹ́ àlùfáà tí àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ń ṣe. Bí àwọn olùjàǹfààní wọ̀nyí ò tiẹ̀ sí lára àwọn àlùfáà, èèyàn Ọlọ́run ni wọ́n jẹ́, ó fẹ́ràn wọn, ó sì tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Ó bá a mu wẹ́kú nígbà náà pé a fi wọ́n wé àwọn èèyàn Ọlọ́run láyé ìgbàanì.
7 Ó ṣe wẹ́kú pé lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Jòhánù rí i tí à ń fi èdìdì ìkẹyìn di àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí wọ́n jẹ́ Ísírẹ́lì tẹ̀mí kó tó di pé ìpọ́njú ńlá bẹ̀rẹ̀, ó tún kíyè sí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí a kò sọ iye wọn, tí wọ́n wá “láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Ìṣí. 7:9) Àwọn wọ̀nyí máa la ìpọ́njú ńlá já, wọ́n á sì bọ́ sínú Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún Kristi. Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tí a jí dìde á sì dara pọ̀ mọ́ wọn níbẹ̀. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣí. 20:13) Àwọn wọ̀nyí ló máa para pọ̀ di “ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá” ìṣàpẹẹrẹ, tí Jésù àti àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí wọ́n máa bá a ṣàkóso, á ṣèdájọ́ wọn.—Ìṣe 17:31; 24:15; Ìṣí. 20:12.
8. Báwo ni ayẹyẹ Ọjọ́ Ètùtù ọdọọdún ṣe ṣàpẹẹrẹ àjọṣe tó wà láàárín àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì àti aráyé yòókù?
8 Àjọṣe tó wà láàárín àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] àti aráyé yòókù yìí ni ayẹyẹ Ọjọ́ Ètùtù ọdọọdún ṣàpẹẹrẹ. (Léf. 16:6-10) Ní ọjọ́ yẹn, Àlùfáà àgbà ní láti kọ́kọ́ fi akọ màlúù kan rúbọ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ “nítorí ara rẹ̀ àti ilé rẹ̀.” Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn àlùfáà ọmọ abẹ́, tó máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù lọ́run, ni ẹbọ rẹ̀ á kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ fún. Bákan náà, ní Ọjọ́ Ètùtù ìgbàanì, àlùfáà máa ń mú ewúrẹ́ méjì wá fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù. Nínú àkọsílẹ̀ yìí, níwọ̀n bí ẹ̀yà àlùfáà ti ṣàpẹẹrẹ àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000], ìyókù àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣàpẹẹrẹ gbogbo àwọn tó nírètí àtijogún ayé. Àlàyé yìí jẹ́ ká rí i pé gbólóhùn náà, “ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá” tí Mátíu 19:28 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ kò tọ́ka sí àwọn àlùfáà ọmọ abẹ́ Jésù tá a fẹ̀mí yàn bí kò ṣe gbogbo àwọn míì tí wọ́n bá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ Jésù.a
9. Nínú ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí, ta ni àwọn àlùfáà ṣàpẹẹrẹ, tá sì ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí kì í ṣe àlùfáà ṣàpẹẹrẹ?
9 Gbé àpẹẹrẹ mìíràn yẹ̀ wò. Wòlíì Ìsíkíẹ́lì rí ìran gbígbòòrò nípa tẹ́ńpìlì Jèhófà. (Ìsík., orí 40 sí 48) Nínú ìran yẹn, àwọn àlùfáà ń ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì, wọ́n ń fúnni nítọ̀ọ́ni, wọ́n sì ń gba ìmọ̀ràn àti ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ Jèhófà. (Ìsík. 44:23-31) Nínú ìran kan náà yìí, àwọn èèyàn látinú ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ń wá láti jọ́sìn àti láti rúbọ. (Ìsík. 45:16, 17) Nínú ìran yìí, àwọn àlùfáà ṣàpẹẹrẹ àwọn ẹni àmì òróró, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n ti inú ẹ̀yà tí kì í ṣe ti àlùfáà wá sì ṣàpẹẹrẹ àwọn tó nírètí àtijogún ayé. Ìran yìí mú kó ṣe kedere pé ẹgbẹ́ méjèèjì ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan, àmọ́ ẹgbẹ́ àlùfáà ló ń múpò iwájú nínú ìjọsìn mímọ́.
10, 11. (a) Àwọn ìmúṣẹ tó ń gbé ìgbàgbọ́ ró wo ni àwọn ọ̀rọ̀ Jésù ti ní? (b) Ìbéèrè wo ló wáyé nípa àwọn àgùntàn mìíràn?
10 Jésù sọ nípa “àwọn àgùntàn mìíràn,” tí wọn ò ní jẹ́ “ara ọ̀wọ́” kan náà pẹ̀lú “agbo kékeré,” ìyẹn àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tá a fẹ̀mí yàn. (Jòh. 10:16; Lúùkù 12:32) Ó sọ pé: “Àwọn pẹ̀lú ni èmi yóò mú wá, wọn yóò sì fetí sí ohùn mi, wọn yóò sì di agbo kan, olùṣọ́ àgùntàn kan.” Ẹ wo bó ti fúnni lókun tó láti rí bí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ṣe ń ní ìmúṣẹ! Àwùjọ àwọn èèyàn méjì ti para pọ̀ di ọ̀kan ṣoṣo, ìyẹn àwùjọ kékeré ti àwọn ẹni àmì òróró àti ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn àgùntàn mìíràn. (Ka Sekaráyà 8:23.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àgùntàn mìíràn kì í sìn lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nínú àgbàlá inú lọ́hùn-ún ti tẹ́ńpìlì tẹ̀mí, wọ́n ń sìn ní òde àgbàlá tẹ́ńpìlì yẹn.
11 Àmọ́, bó bá jẹ́ pé ìgbà míì wà tí Jèhófà máa ń lo àwọn tí kì í ṣe àlùfáà lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì láti ṣàpẹẹrẹ àwọn àgùntàn mìíràn, ṣó yẹ káwọn tó nírètí àtijogún ayé náà máa jẹ búrẹ́dì kí wọ́n sì máa mu wáìnì nígbà Ìrántí Ikú Kristi? Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí la máa gbé yẹ̀ wò báyìí.
Májẹ̀mú Tuntun
12. Ìṣètò tuntun wo ni Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀?
12 Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìṣètò tuntun tó kan àwọn èèyàn rẹ̀ nígbà tó sọ pé: “Èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lì dá lẹ́yìn ọjọ́ wọnnì. . . . Èmi yóò fi òfin mi sínú wọn, inú ọkàn-àyà wọn sì ni èmi yóò kọ ọ́ sí. Èmi yóò sì di Ọlọ́run wọn, àwọn fúnra wọn yóò sì di ènìyàn mi.” (Jer. 31:31-33) Nípasẹ̀ májẹ̀mú tuntun yìí, ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Ábúráhámù máa ní ìmúṣẹ ológo, tí yóò wà pẹ́ títí.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 22:18.
13, 14. (a) Àwọn wo ló ń nípìn-ín nínú májẹ̀mú tuntun? (b) Àwọn wo ló ń jàǹfààní nínú májẹ̀mú tuntun, báwo ni wọ́n sì ṣe “rọ̀ mọ́” májẹ̀mú tuntun yìí?
13 Ní alẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí èèyàn lórí ilẹ̀ ayé, ó sọ nípa májẹ̀mú tuntun yìí pé: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun nípa agbára ìtóye ẹ̀jẹ̀ mi, tí a óò tú jáde nítorí yín.” (Lúùkù 22:20; 1 Kọ́r. 11:25) Ṣé gbogbo Kristẹni la mú wọnú májẹ̀mú tuntun yìí? Rárá o. Àwọn kan, bí àwọn àpọ́sítélì tó mu nínú ìfe yẹn lálẹ́ ọjọ́ yẹn, nípìn-ín nínú májẹ̀mú tuntun náà.b Jésù bá wọn dá májẹ̀mú míì pé wọ́n á bá òun ṣàkóso nínú Ìjọba òun. (Lúùkù 22:28-30) Wọ́n máa nípìn-ín nínú Ìjọba Jésù.—Lúùkù 22:15, 16.
14 Àwọn tá á máa gbé lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba rẹ̀ ńkọ́? Ńṣe ni wọ́n ń jàǹfààní nínú májẹ̀mú tuntun náà. (Gál. 3:8, 9) Bí wọn ò tiẹ̀ nípìn-ín nínú májẹ̀mú náà, wọ́n “rọ̀ mọ́” ọ́n nípa ṣíṣe àwọn ohun tá a béèrè lọ́wọ́ wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí wòlíì Aísáyà ṣe sọ pé: “Àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí ó sì ti dara pọ̀ mọ́ Jèhófà láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún un àti láti nífẹ̀ẹ́ orúkọ Jèhófà, láti lè di ìránṣẹ́ fún un, gbogbo àwọn tí ń pa sábáàtì mọ́ kí wọ́n má bàa sọ ọ́ di aláìmọ́, tí wọ́n sì rọ̀ mọ́ májẹ̀mú mi, dájúdájú, èmi yóò mú wọn wá sí òkè ńlá mímọ́ mi pẹ̀lú, èmi yóò sì mú kí wọ́n máa yọ̀ nínú ilé àdúrà mi.” Lẹ́yìn náà ni Jèhófà wá sọ pé: “Nítorí pé ilé mi ni a óò máa pè ní ilé àdúrà fún gbogbo ènìyàn.”—Aísá. 56:6, 7.
Àwọn Wo Ló Yẹ Kó Máa Jẹ Búrẹ́dì Kí Wọ́n sì Máa Mu Wáìnì?
15, 16. (a) Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù so májẹ̀mú tuntun náà mọ́? (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ káwọn tó nírètí àtijogún ayé máa jẹ búrẹ́dì kí wọ́n sì máa mu wáìnì nígbà Ìrántí Ikú Kristi?
15 Àwọn tó wà nínú májẹ̀mú tuntun “ní àìṣojo fún ọ̀nà ìwọlé sínú ibi mímọ́.” (Ka Hébérù 10:15-20.) Àwọn wọ̀nyí ni yóò “gba ìjọba kan tí kò ṣeé mì.” (Héb. 12:28) Torí bẹ́ẹ̀, àwọn tó máa jẹ́ ọba àti àlùfáà pẹ̀lú Jésù Kristi lókè ọ̀run nìkan ló gbọ́dọ̀ mu látinú “ife” tó ṣàpẹẹrẹ májẹ̀mú tuntun. Àwọn tó nípìn-ín nínú májẹ̀mú tuntun yìí jẹ́ àfẹ́sọ́nà Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà. (2 Kọ́r. 11:2; Ìṣí. 21:2, 9) Ńṣe ni gbogbo àwọn yòókù tó ń pésẹ̀ síbi Ìrántí Ikú Kristi tá à ń ṣe lọ́dọọdún máa ń wà níbẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, wọ́n á máa wo ohun tó ń lọ, wọn kì í jẹ búrẹ́dì, wọn kì í sì í mu wáìnì.
16 Pọ́ọ̀lù tún jẹ́ kó yé wa pé àwọn tó nírètí àtijogún ayé kì í jẹ búrẹ́dì, wọn kì í sì í mu wáìnì nígbà Ìrántí Ikú Kristi. Ó sọ fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró pé: “Nítorí nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń jẹ ìṣù búrẹ́dì yìí, tí ẹ sì ń mu ife yìí, ẹ ń pòkìkí ikú Olúwa, títí yóò fi dé.” (1 Kọ́r. 11:26) Ìgbà wo ni Olúwa yóò “dé”? Ìgbà tó bá wá láti mú èyí tó kẹ́yìn lára ẹgbẹ́ ìyàwó rẹ̀ tá a fẹ̀mí yàn lọ sí ilé wọn lókè ọ̀run ni. (Jòh. 14:2, 3) Ìyẹn mú kó ṣe kedere pé Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa kò ní máa bá a lọ títí láé. “Àwọn tí ó ṣẹ́ kù” lórí ilẹ̀ ayé lára irú ọmọ obìnrin náà á máa bá a nìṣó láti jẹ oúnjẹ yìí títí tí gbogbo wọn á fi gba èrè ti ọ̀run. (Ìṣí. 12:17) Àmọ́, bó bá jẹ́ pé àwọn tí yóò máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé lẹ́tọ̀ọ́ láti máa jẹ búrẹ́dì kí wọ́n sì máa mu wáìnì ni, a jẹ́ pé Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa á máa bá a nìṣó títí láé nìyẹn.
“Ní Ti Tòótọ́, Wọn Yóò sì Di Ènìyàn Mi”
17, 18. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ìsíkíẹ́lì 37:26, 27 ṣe ń ní ìmúṣẹ?
17 Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn òun máa wà ní ìṣọ̀kan. Ó ní: “Èmi yóò bá wọn dá májẹ̀mú àlàáfíà; májẹ̀mú tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin ni ohun tí yóò wà pẹ̀lú wọn. Ṣe ni èmi yóò gbé wọn kalẹ̀, èmi yóò sọ wọ́n di púpọ̀, èmi yóò sì fi ibùjọsìn mi sí àárín wọn fún àkókò tí ó lọ kánrin. Àgọ́ mi yóò sì wà lórí wọn ní ti tòótọ́, èmi yóò sì di Ọlọ́run wọn dájúdájú, àwọn pàápàá yóò sì di ènìyàn mi.”—Ìsík. 37:26, 27.
18 Gbogbo èèyàn Ọlọ́run ló láǹfààní láti gbádùn ìlérí àgbàyanu tí Ọlọ́run ṣe nígbà tó bá àwọn Kristẹni dá májẹ̀mú pé wọ́n á gbádùn àlàáfíà. Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà mú kó dá gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó bá jẹ́ onígbọràn lójú pé wọ́n máa gbádùn àlàáfíà. Wọ́n ń fi èso ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ṣèwà hù. Ibùjọsìn rẹ̀, tó ṣàpẹẹrẹ ìjọsìn Kristẹni nínú àkọsílẹ̀ yìí, wà láàárín wọn. Wọ́n ti di èèyàn rẹ̀ ní tòótọ́, torí pé wọ́n ti kọ gbogbo onírúurú ìbọ̀rìṣà sílẹ̀, Jèhófà nìkan sì ni Ọlọ́run tí wọ́n ń sìn.
19, 20. Àwọn wo ló wà lára àwọn tí Jèhófà pè ní “ènìyàn mi,” kí sì ni májẹ̀mú tuntun mú kó ṣeé ṣe?
19 Ó jẹ́ ohun tó ń múni láyọ̀ láti rí bí Ọlọ́run ṣe ń mú kí àwùjọ méjèèjì yìí wà ní ìṣọ̀kan ní àkókò wa! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ogunlọ́gọ̀ ńlá tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i kò ní ìrètí láti lọ sọ́rùn, inú wọn dùn láti jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó nírètí àtilọ sọ́rùn. Wọ́n ti dara pọ̀ mọ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ sì ti mú kí wọ́n wà lára àwọn tí Jèhófà pè ní “ènìyàn mi.” Àwọn ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ mọ́ lára, pé: “Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè yóò sì dara pọ̀ mọ́ Jèhófà ní ọjọ́ náà dájúdájú, ní ti tòótọ́, wọn yóò sì di ènìyàn mi; dájúdájú, èmi yóò sì máa gbé ní àárín rẹ.”—Sek. 2:11; 8:21; ka Aísáyà 65:22; Ìṣípayá 21:3, 4.
20 Nípasẹ̀ májẹ̀mú tuntun ni Jèhófà fi mú kí gbogbo èyí ṣeé ṣe. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè ti dara pọ̀ mọ́ orílẹ̀-èdè tí Jèhófà fojúure hàn sí. (Míkà 4:1-5) Wọ́n ti pinnu pé àwọn ò ní dẹ́kun láti máa rọ̀ mọ́ májẹ̀mú yẹn nípa títẹ́wọ́gba gbogbo ìpèsè rẹ̀ àti ṣíṣègbọràn sí i. (Aísá. 56:6, 7) Bí wọ́n ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ísírẹ́lì Ọlọ́run, wọ́n ń gbádùn àlàáfíà tí kò lópin, èyí tó jẹ́ ìbùkún jìngbìnnì. Ǹjẹ́ kí irú ìbùkún bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ tìrẹ náà, nísinsìnyí àti títí láé!
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bákan náà, àwọn ẹni àmì òróró ni ọ̀rọ̀ náà, “ìjọ” sábà máa ń tọ́ka sí. (Héb. 12:23) Àmọ́, “ìjọ” tún lè ní ìtumọ̀ mìíràn, èyí tó kan gbogbo Kristẹni, yálà wọn nírètí àtijogún ọ̀run tàbí ayé.—Wo Ilé Ìṣọ́, April 15, 2007, ojú ìwé 21 sí 23.
b Jésù ò nípìn-ín nínú májẹ̀mú yẹn, Alárinà rẹ̀ ló jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí Alárinà, ó dájú pé kò jẹ nínú búrẹ́dì, kò sì mu nínú wáìnì náà.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Àwọn wo ni “ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá” tí ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì máa ṣèdájọ́ wọn?
• Ọ̀nà wo ni májẹ̀mú tuntun gbà kan àwọn tá a fẹ̀mí yàn àtàwọn àgùntàn mìíràn?
• Ǹjẹ́ ó yẹ kí gbogbo Kristẹni máa jẹ búrẹ́dì kí wọ́n sì máa mu wáìnì nígbà Ìrántí Ikú Kristi?
• Ìṣọ̀kan wo ni Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa wà ní ọjọ́ wa?
[Graph/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ní báyìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ń dara pọ̀ mọ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run nínú ìjọsìn
7,313,173
4,017,213
1,483,430
373,430
1950 1970 1990 2009