Àdánwò Mú Ká Túbọ̀ Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
Gẹ́gẹ́ bí Ada Dello Stritto ṣe sọ ọ́
Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ ọ̀rọ̀ ẹsẹ ojoojúmọ́ sínú ìwé mi tán ni. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógójì [36 ] ni mí, àmọ́ wákàtí méjì gbáko ni mo fi kọ ìwọ̀nba ọ̀rọ̀ yẹn. Kí ló mú kó pẹ́ mi tó bẹ́ẹ̀? Màmá mi á ṣàlàyé.—Joel
ỌDÚN 1968 ni èmi àti ọkọ mi ṣèrìbọmi tí a sì di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn tá a ti bí àwọn ọmọkùnrin méjì tí ara wọn le dáadáa, ìyẹn David àti Marc, a tún wá bí ọmọkùnrin wa kẹta, Joel. Oṣù rẹ̀ kò tíì pé nígbà tá a bí i lọ́dún 1973, ní ilé ìwòsàn kan ní ìlú Binche, lórílẹ̀-èdè Belgium; ìlú yìí wà ní nǹkan bí ọgọ́ta [60] kìlómítà sí gúúsù ìlú Brussels. Ọmọ wa yìí kò wọ̀n ju kìlógíráàmù kan àti ẹ̀sún méje lọ. Nígbà tí mo kúrò ní ilé ìwòsàn, a ṣì ní láti fi Joel sílẹ̀ níbẹ̀ kó fi tóbi díẹ̀ sí i.
Nígbà tá a rí i pé kò sí ìyàtọ̀ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀, èmi àti Luigi, ọkọ mi, gbé ọmọ wa lọ sọ́dọ̀ dókítà tó ń tọ́jú àwọn ọmọdé. Lẹ́yìn tí dókítà náà ṣàyẹ̀wò Joel tán, ó sọ pé: “Ó mà ṣe o. Ó jọ pé Joel ní gbogbo ìṣòro táwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kò ní.” Kẹ́kẹ́ pa mọ́ gbogbo wa lẹ́nu. Ìgbà yẹn ni mo wá mọ̀ pé ọmọ wa jòjòló ní ìṣòro àìsàn tó burú jáì. Dókítà náà wá mú ọkọ mi lọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ó sì sọ fún un pé: “Ọmọ yín ní àìsàn trisomy 21,” ìyẹn irú àìsàn kan tí kì í jẹ́ kí ọpọlọ ọmọdé jí pépé, wọ́n tún ń pè é ní Down syndrome.a
Ohun tí dókítà yìí sọ bà wá nínú jẹ́ gan-an, a sì pinnu láti kàn sí dókítà míì. Nígbà tá a débẹ̀, dókítà náà fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò Joel fún nǹkan bíi wákàtí kan, láìsọ ọ̀rọ̀ kan. Ó sì ti sú èmi àti Luigi ọkọ mi. Nígbà tó yá, dókítà náà gbójú sókè, ó sì sọ pé, “Kò sí ohun tí ọmọ yín á lè ṣe láìsí yín.” Lẹ́yìn náà, ó sọ̀rọ̀ tàánútàánú pé: “Àmọ́ Joel á láyọ̀ gan-an torí pé ẹ̀yin òbí rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀!” Ìbànújẹ́ sorí wa kodò, mo sì rọra gbé Joel, ó dilé. Nígbà yẹn ó ti pé ọmọ oṣù méjì.
Ìpàdé Kristẹni àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Fún Wa Lókun
Àyẹ̀wò ìṣègùn síwájú sí i tún fi hàn pé Joel ní àrùn ọkàn àti àrùn tó máa ń mú kí ẹ̀dọ̀ wú, tí kì í sì í jẹ́ kí eegun gbó. Torí pé ọkàn rẹ̀ ti tóbi jù, ó máa ń tẹ ẹ̀dọ̀fóró rẹ̀ mọ́lẹ̀, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kó tètè kó àrùn. Nígbà tí Joel wà ní ọmọ oṣù mẹ́rin, ó kó àrùn tí kì í jẹ́ kéèyàn mí délẹ̀, a gbé e pa dà sí ilé ìwòsàn, wọn ò sì jẹ́ kó wà láàárín àwọn aláìsàn tó kù. Ó máa ń ro wá lára láti rí bó ṣe ń jẹ̀rora. Ó máa ń wù wá pé ká di ọwọ́ rẹ̀ mú, ká sì fi ọwọ́ pa á lára, àmọ́ ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá gbáko ni wọn ò fi gbà wá láyè láti fọwọ́ kàn án rárá. Kò sóhun tí èmi àti Luigi lè ṣe ju pé ká máa wò ó, ká di ara wa mú, ká sì máa gbàdúrà.
Ní gbogbo ìgbà tí ìṣòro líle koko yìí ń lọ lọ́wọ́, a máa ń lọ sí ìpàdé pa pọ̀ pẹ̀lú David tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà àti Marc tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ta nígbà yẹn. Tá a bá wà ní ìpàdé ńṣe ló máa ń dà bíi pé Jèhófà gbé wa sọ́wọ́ rẹ̀. Ní gbogbo àkókò tá a bá fi wà láàárín àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, a máa ń mọ̀ ọ́n lára pé a ti kó ẹrù ìnira wa lé Jèhófà lọ́wọ́, ara sì máa ń tù wá. (Sm. 55:22) Kódà àwọn nọ́ọ̀sì tó ń tọ́jú Joel sọ pé, àwọn ṣàkíyèsí pé bá a ṣe ń lọ sí ìpàdé Kristẹni ń jẹ́ ká lè wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì.
Láàárín àkókò yẹn mo tún bẹ Jèhófà pé kó fún mi lókun kí n lè máa lọ sóde ẹ̀rí. Dípò tí màá fi jókòó sílé tí màá sì máa sunkún, ó wù mí kí n bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ìlérí Ọlọ́run pé ayé kan ń bọ̀ níbi tí kò ti ní sí àìsàn mọ́, kí n sì jẹ́ kí wọ́n rí bí ìgbọ́kànlé tí mo ní nínú ìlérí yìí ṣe ń fún mi lókun. Ìgbàkígbà tí mo bá láǹfààní láti lọ fún iṣẹ́ ìsìn pápá, mo máa ń mọ̀ ọ́n lára pé Jèhófà dáhùn àdúrà mi.
“Èyí Jọ Wá Lójú O!”
Ọjọ́ ayọ̀ ni ọjọ́ tá a gbé Joel wálé láti ilé ìwòsàn. Àmọ́ lọ́jọ́ kejì, ayọ̀ wa tún di ìbànújẹ́. Ìṣòro Joel burú sí i, a sì ní láti tètè dá a pa dà sílé ìwòsàn. Lẹ́yìn tí dókítà ti ṣàyẹ̀wò rẹ̀, ó sọ fún wa pé “Joel kò lè lò ju oṣù mẹ́fà sí i mọ́ kó tó kú.” Ní oṣù méjì lẹ́yìn náà, nígbà tí Joel wà ní nǹkan bí ọmọ oṣù mẹ́jọ, ó dà bíi pé ohun tí dókítà sọ yẹn máa ṣẹlẹ̀ torí pé ìlera Joel burú sí i. Dókítà kan jókòó tì wá, ó sì sọ pé: “Ẹ máa mọ́kàn ni o. Kò tún sí ohun tá a lè ṣe sọ́rọ̀ rẹ̀ mọ́.” Lẹ́yìn náà, ó wá fi kún un pé: “Níbi tí ọ̀rọ̀ dé yìí, Jèhófà nìkan ló lè kó o yọ.”
Mo pa dà sínú yàrá tí Joel wà nílé ìwòsàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ẹ̀ ti tojú sú mi, okun mi sì ti tán, mo pinnu pé mi ò ní kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀dì rẹ̀. Àwọn arábìnrin mélòó kan ń gbọwọ́ fúnra wọn láti dúró tì mí, nígbà tí Luigi bá lọ bójú tó àwọn ọmọ wa méjì tó kù. Ọ̀sẹ̀ kan kọjá lọ. Lójijì, ìṣòro àrùn ọkàn Joel burú sí i. Àwọn nọ́ọ̀sì sáré wọlé, àmọ́ kò sóhun tí wọ́n lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́. Lẹ́yìn ìṣẹ́jú díẹ̀, ọ̀kan lára wọn rọra sọ pé, “Ó ti dákẹ́ . . .” Ọ̀rọ̀ náà tojú sú mi, mo bú sẹ́kún, mo sì kúrò nínú yàrá náà. Mo gbìyànjú láti gbàdúrà sí Jèhófà, àmọ́ mi ò mọ ọ̀rọ̀ tí màá fi ṣàlàyé ìrora mi. Nǹkan bí ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kọjá, ni nọ́ọ̀sì kan bá ké sí mi pé, “Ara Joel mà ti ń yá!” Ó dì mí lọ́wọ́ mú, ó sì sọ pé, “Máa bọ̀, o lè rí i báyìí.” Nígbà tí mo pa dà dé ọ̀dọ̀ Joel, ọkàn rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí lù kìkì pa dà! Lójú ẹsẹ̀, ìròyìn ti tàn kálẹ̀ pé ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í mí pa dà. Àwọn nọ́ọ̀sì àtàwọn dókítà wá wò ó, ọ̀pọ̀ nínú wọn sì sọ pé, “Èyí jọ wá lójú o!”
Ohun Ìyanu Kan Wáyé Nígbà Tó Pé Ọmọ Ọdún Mẹ́rin
Láàárín ọdún mélòó kan tí Joel dáyé, dókítà tó ń tọ́jú rẹ̀ sábà máa ń sọ fún wa pé, “Ẹ gbọ́dọ̀ máa fìfẹ́ hàn sí Joel gan-an.” Níwọ̀n bí èmi àti Luigi sì ti rí ọwọ́ ìfẹ́ Jèhófà lára wa látìgbà tá a ti bí Joel, àwa náà fẹ́ fìfẹ́ tó pọ̀ gan-an hàn sí Joel. A ní ọ̀pọ̀ àǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀, torí pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ó máa ń nílò ìrànlọ́wọ́ wa nínú gbogbo ohun tó bá ń ṣe.
Fún ọdún méje àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé Joel, ohun kan náà là ń ṣe ṣá lọ́dọọdún. Láàárín oṣù October àti March, ńṣe ló ń tinú ìṣòro àìlera kan bọ́ sínú òmíràn, a sì ní láti máa gbé e pààrà ilé ìwòsàn. Mo sì tún sapá láti máa fi àkókò tó pọ̀ tó bójú tó àwọn ọmọ wa tó kù, David àti Marc. Àwọn náà sì wá bẹ̀rẹ̀ sí ran Joel lọ́wọ́ kó lè máa tẹ̀ síwájú, àbájáde èyí sì jọ wá lójú gan-an. Bí àpẹẹrẹ, àwọn dókítà mélòó kan ti sọ fún wa pé Joel kò ní lè rìn. Àmọ́ lọ́jọ́ kan nígbà tí Joel wà lọ́mọ ọdún mẹ́rin, Marc ọmọ wa sọ fún un pé, “Joel, ó yá, jẹ́ kí Mọ́mì mọ̀ pé o lè ṣe é!” Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi pé Joel rìn fún ìgbà àkọ́kọ́! Inú wa dùn gan-an, gbogbo ìdílé wa sì gbàdúrà sí Jèhófà látọkànwá láti dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Láwọn ìgbà míì, tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ìtẹ̀síwájú díẹ̀ ni Joel ní lọ́nà kan tàbí lọ́nà míì, a máa ń gbóríyìn fún un.
Kíkọ́ Tá A Kọ́ Ọ Lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Láti Kékeré Sèso Rere
Gbogbo ìgbà tó bá ti ṣeé ṣe la máa ń gbé Joel lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ká lè dáàbò bò ó lọ́wọ́ àwọn kòkòrò àrùn tó lè tètè mú kó ṣàìsàn, a máa ń gbé e sínú kẹ̀kẹ́ àkànṣe kan tí wọ́n fi ike tó ń dán bíi gíláàsì bo gbogbo ara ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú kẹ̀kẹ́ yìí ló ń jókòó sí, ó máa ń gbádùn wíwà pẹ̀lú àwọn ará ìjọ.
Orísun ìṣírí làwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin jẹ́ fún wa, wọ́n ń fìfẹ́ bá wa lò, wọ́n sì ń pèsè ìrànlọ́wọ́ gidi fún wa. Arákùnrin kan tiẹ̀ sábà máa ń rán wa létí ọ̀rọ̀ inú Aísáyà 59:1, tó sọ pé: “Wò ó! Ọwọ́ Jèhófà kò kúrú jù tí kò fi lè gbani là, bẹ́ẹ̀ ni etí rẹ̀ kò wúwo jù tí kò fi lè gbọ́.” Àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tuni nínú yẹn jẹ́ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.
Bí Joel ṣe ń dàgbà, a jẹ́ kí sísin Jèhófà jẹ́ ohun pàtàkì nígbèésí ayé rẹ̀. Ní gbogbo ìgbà tí àyè ẹ̀ bá yọ, a máa ń bá a sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà lọ́nà táá mú kó nífẹ̀ẹ́ Baba rẹ̀ ọ̀run. A bẹ Jèhófà pé kó bù kún ìsapá wa, kí ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí à ń kọ́ Joel lè so èso rere.
Nígbà tí Joel pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá, inú wa dun láti rí i pé ó máa ń fẹ́ bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Bí ara rẹ̀ ti ń le bọ̀ díẹ̀díẹ̀ lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ tó ṣe nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá, inú mi dùn gan-an nígbà tó bi mí pé, “Mọ́mì, ṣé mo lè fún oníṣẹ́ abẹ yìí ní ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye”? Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà Joel tún pa dà lọ ṣe iṣẹ́ abẹ. A mọ̀ dáadáa pé ó lè ṣàì rù ú là. Kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ abẹ yẹn, Joel mú lẹ́tà tá a jọ kọ fún dókítà rẹ̀. Ó ṣàlàyé ìpinnu rẹ̀ lórí ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀. Oníṣẹ́ abẹ náà bi Joel pé, “Ṣó o fara mọ́ ohun tó wà nínú lẹ́tà yìí?” Joel fìgboyà dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Dókítà.” Orí wa wú pé ọmọ wa gbẹ́kẹ̀ lé Ẹlẹ́dàá rẹ̀ àti pé ó pinnu láti ṣe ohun tó fẹ́. A sì tún mọrírì bí àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn náà ṣe tì wá lẹ́yìn gan-an.
Joel Tẹ̀ Síwájú Nipa Tẹ̀mí
Nígbà tí Joel wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún, ó ṣe ìrìbọmi láti fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ̀ hàn. Ọjọ́ mánigbàgbé mà lọjọ́ yìí o! Bó ṣe ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí mú inú wa dùn gan-an ni. Látìgbà yẹn ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà àti ìtara rẹ̀ fún òtítọ́ kò tíì dín kù. Kódà gbogbo èèyàn tí Joel bá bá pàdé ló máa ń sọ fún pé, “Òtítọ́ ló jẹ́ kí n wà láàyè!”
Nígbà tó kù díẹ̀ kí Joel pé ọmọ ogún ọdún, ó kọ́ láti di ẹni tó mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà. Èyí gba ìsapá gan-an. Àṣeyọrí ni ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan tó bá jàjà kọ sílẹ̀. Látìgbà yẹn ló ti jẹ́ pé kíka ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ ló fi máa ń bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, á wá fara balẹ̀ ṣe àdàkọ ẹsẹ ìwé mímọ́ ọjọ́ náà sínú ìwé rẹ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan ló sì ti kọ sínú ìwé náà báyìí!
Láwọn ọjọ́ ìpàdé, Joel máa ń rí i pé a tètè kúrò nílé lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, torí pé ó fẹ́ wà níbẹ̀ lásìkò kó lè fi ọ̀yàyà kí gbogbo àwọn tó bá ń wọ gbọ̀ngàn náà káàbọ̀. Ó fẹ́ràn kó máa dáhùn ìbéèrè kó sì máa kópa nínú àṣefihàn nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́. Ó sì máa ń bójú tó ẹ̀rọ̀ makirofóònù àtàwọn iṣẹ́ míì. Tí ìlera rẹ̀ bá gbé e, ó máa ń bá wa jáde òde ẹ̀rí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Lọ́dún 2007, wọ́n ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ pé Joel ti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Omije ayọ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí dà lójú wa. Ẹ ò rí i pé ìbùkún lèyí jẹ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà!
A Rí Ọwọ́ Ìrànwọ́ Jèhófà
Lọ́dún 1999, a tún dojú kọ ìṣòro míì. Awakọ̀ kan tó ń wa ìwàkuwà kọlu ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa, Luigi sì ṣèṣe gan-an. Wọ́n ní láti gé ẹsẹ̀ rẹ̀ kan, wọ́n sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ abẹ fún un ní eegun ògóóró ẹ̀yìn. Lẹ́ẹ̀kan sí i, torí pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, a rí okun tó ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà nínú ìṣòro gbà. (Fílí. 4:13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláàbọ̀ ara ni Luigi báyìí, a sapá láti wo ibi tó dáa lára ọ̀ràn náà. Torí pé kò lè ṣe iṣẹ́ mọ́, ó ní àyè tó pọ̀ láti máa bójú tó Joel. Èyí sì fún mi láyè láti ya àkókò púpọ̀ sí i sọ́tọ̀ fún àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí. Ó tún ṣeé ṣe fún Luigi láti fún àwọn nǹkan tẹ̀mí tí ìdílé wa àti ìjọ nílò láfiyèsí, níbi tó ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà.
Nítorí bí nǹkan ṣe rí nínú ìdílé wa, ọ̀pọ̀ ìgbà la jọ máa ń ṣe nǹkan pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, a ti kọ́ bá a ṣe ń fòye ṣe nǹkan, a kì í sì í ṣe kọjá agbára wa. Bí ohunkóhun bá mú wa rẹ̀wẹ̀sì, a máa ń sọ ẹ̀dùn ọkàn wa fún Jèhófà nínú àdúrà. Àmọ́, ó bà wá nínú jẹ́ pé nígbà tí àwọn ọmọ wa David àti Marc dàgbà, tí wọ́n sì ń dá gbé, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi Jèhófà sílẹ̀ díẹ̀díẹ̀ títí tí wọn ò fi sìn ín mọ́. A nírètí pé wọ́n ṣì lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.—Lúùkù 15:17-24.
Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, a ti rí ìtìlẹ́yìn Jèhófà, a sì ti kọ́ láti máa gbọ́kàn lé e nínú gbogbo ìṣòro tó bá ń dojú kọ wá. Ọ̀rọ̀ tó wà nínú Aísáyà 41:13, ṣe pàtàkì sí wa gan-an, ó ní: “Èmi, Jèhófà Ọlọ́run rẹ, yóò di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, Ẹni tí ń wí fún ọ pé, ‘Má fòyà. Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.’” Ìtùnú ló jẹ́ fún wa láti mọ̀ pé Jèhófà dí ọwọ́ wa mú gírígírí. Ní tòótọ́, a lè sọ pé àwọn àdánwò tó ń dojú kọ wá mú ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Baba wa ọ̀run, Jèhófà.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àìsàn trisomy 21 ni àìsàn kan tí wọ́n máa ń bí mọ́ èèyàn, kì í sì í jẹ́ kí ọpọlọ ṣiṣẹ́ bó ṣe tọ́. Méjì ni èròjà apilẹ̀ àbùdá tí wọ́n sábà máa ń bí mọ́ èèyàn, àmọ́ èròjà yìí máa ń ju méjì lọ lára àwọn ọmọ tí irú àìsàn yìí ń ṣe.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Joel àti màmá rẹ̀, Ada
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ada, Joel àti Luigi rèé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Joel gbádùn kó máa kí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin káàbọ̀ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba