Kọ́ Ọmọ Rẹ
Kí Nìdí Tí Jésù Kò Fi Kánjú
JÉSÙ ti gbọ́ pé Lásárù ọ̀rẹ́ òun àtàtà ń ṣàìsàn gan-an. Màríà àti Màtá tí wọ́n jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti rán ońṣẹ́ láti sọ fún Jésù. Ońṣẹ́ náà wá láti Bẹ́tánì níbi tí Lásárù àtàwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ń gbé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ibi tó jìn ní òdì kejì Odò Jọ́dánì ni wọ́n ń gbé, àwọn ẹ̀gbọ́n Lásárù gbà gbọ́ pé Jésù lè wo àbúrò wọn sàn láti ibi tó wà. Wọ́n mọ̀ pé láwọn ìgbà kan rí, Jésù ti ṣèwòsàn àwọn èèyàn tí wọ́n wà ní ibi tó jìnnà síbi tó wà.—Mátíù 8:5-13; Jòhánù 11:1-3.
Nígbà tí ońṣẹ́ náà fi ìròyìn tí kò bára dé náà tó Jésù létí, Jésù kò ṣe nǹkan nípa rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ó dúró ní ti gidi fún ọjọ́ méjì ní ibi tí ó wà.” (Jòhánù 11:6) Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Jésù kò fi kánjú láti lọ ran Lásárù lọ́wọ́?—a Jẹ́ ká gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò.
Jésù mọ̀ pé àìsàn náà ti pa Lásárù, nítorí náà, ó sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí a tún lọ sí Jùdíà.” Wọ́n kọ̀ jálẹ̀, wọ́n sọ pé: “Àìpẹ́ yìí ni àwọn ará Jùdíà ń wá ọ̀nà láti sọ ọ́ ní òkúta, ìwọ ha sì tún ń lọ sí ibẹ̀ bí?” Jésù ṣàlàyé pé: “Lásárù ọ̀rẹ́ wa ti lọ sinmi, ṣùgbọ́n mo ń rìnrìn àjò lọ sí ibẹ̀ láti jí i kúrò lójú oorun.”
Àwọn àpọ́sítélì fèsì pé: “Olúwa, bí ó bá jẹ́ pé ó lọ sinmi ni, ara rẹ̀ yóò dá.” Jésù wá ṣàlàyé pé: “Lásárù ti kú.” Nígbà náà ló sọ ohun kan tó ti gbọ́dọ̀ yà wọ́n lẹ́nu, ó ní: “Mo sì yọ̀ ní tìtorí yín pé èmi kò sí níbẹ̀ . . . Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.”
Tọ́másì fìgboyà sọ̀rọ̀, ó ní: ‘Ẹ jẹ́ kí àwa pẹ̀lú lọ, kí a lè bá Jésù kú.’ Tọ́másì mọ̀ pé àwọn ọ̀tá á tún gbìyànjú láti pa Jésù, wọ́n sì lè pa àwọn àpọ́sítélì pẹ̀lú. Àmọ́ gbogbo wọn lọ ṣá. Lẹ́yìn nǹkan bí ọjọ́ méjì, wọ́n dé Bẹ́tánì ìlú ìbílẹ̀ Lásárù. Ó fi nǹkan bíi kìlómítà mẹ́ta jìn sí Jerúsálẹ́mù.—Jòhánù 11:7-18.
Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí inú Jésù fi dùn pé òun kò tètè dé ṣáájú ìgbà yẹn?— Òótọ́ ni pé Jésù ti jí àwọn kan dìde tẹ́lẹ̀ rí, àmọ́ wákàtí díẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n kú ni Jésù jí wọn dìde. (Lúùkù 7:11-17, 22; 8:49-56) Ṣùgbọ́n ní ti Lásárù, òkú rẹ̀ ti wà nínú ibojì fún ọjọ́ mélòó kan. Kò sí ẹni tí kò mọ̀ pé ó ti kú!
Nígbà tí Màtá ẹ̀gbọ́n Lásárù gbọ́ pé Jésù ti sún mọ́ Bẹ́tánì, ó sáré lọ pàdé rẹ̀. Ó sọ pé: “Olúwa, ká ní o ti wà níhìn-ín ni, arákùnrin mi kì bá kú.” Jésù fi dá a lójú pé: “Arákùnrin rẹ yóò dìde.” Màtá sáré pa dà lọ sọ́dọ̀ Màríà arábìnrin rẹ̀, ó sọ fún un kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé: “Olùkọ́ ti wà níhìn-ín, ó sì ń pè ọ́.”
Màríà gbéra lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti lọ bá Jésù. Àmọ́, àwọn èrò náà rò pé ó ń lọ sí ibojì ni, nítorí náà wọ́n tẹ̀ lé e. Nígbà tí Jésù rí Màríà àti èrò tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ tí wọ́n ń sunkún, òun pẹ̀lú “da omijé.” Nígbà tó yá wọ́n dé ibojì, èyí tí wọ́n fi òkúta ńlá dí ẹnu rẹ̀ pa. Jésù pàṣẹ pé: “Ẹ gbé òkúta náà kúrò.” Àmọ́, Màtá kọ̀ jálẹ̀, ó ní: “Olúwa, ní báyìí yóò ti máa rùn, nítorí ó di ọjọ́ mẹ́rin.”
Àwọn èèyàn náà gbọ́ràn sí Jésù lẹ́nu, wọ́n yí òkúta náà kúrò. Lẹ́yìn náà, ó gbàdúrà, ó ń yin Ọlọ́run lógo nítorí ó mọ̀ pé Ọlọ́run á fun òun lágbára láti jí Lásárù dìde. Jésù ké jáde “ní ohùn rara pé: ‘Lásárù, jáde wá!’” Lásárù sì rìn jáde, “pẹ̀lú ẹsẹ̀ àti ọwọ́ rẹ̀ tí a fi àwọn aṣọ ìdìkú dì.” Nítorí náà, Jésù pàṣẹ pé: “Ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ.”—Jòhánù 11:19-44.
Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Jésù kò fi kánjú?— Jésù mọ̀ pé bí òun kò ṣe tètè dé síbẹ̀ máa fún òun láǹfààní láti jẹ́rìí tó dára jù nípa Jèhófà Bàbá rẹ̀. Àti nítorí pé ó lọ ní àkókò tó dára jù lọ, ọ̀pọ̀ èèyàn di onígbàgbọ́. (Jòhánù 11:45) Ǹjẹ́ a lè rí nǹkan kan kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jésù?—
Ìwọ náà lè wá àkókò tó dára láti fi jẹ́rìí nípa àwọn ohun àgbàyanu tí Ọlọ́run ti ṣe àtàwọn èyí tó máa ṣe. O lè bá akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ tàbí kó o bá olùkọ́ rẹ sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe. Kódà nínú kíláàsì, àwọn ọ̀dọ́ kan ti lo àǹfààní yẹn láti sọ àgbàyanu ìbùkún tí Ìjọba Ọlọ́run máa mú wá fún aráyé. Ó dájú pé ìwọ kò lè jí òkú dìde, àmọ́ o lè ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láti wá mọ Ọlọ́run tó lè jí àwọn èèyàn wa tó ti kú dìde, tó sì máa jí wọn dìde.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó bá jẹ́ ọmọdé lò ń ka ìwé yìí fún, má gbàgbé láti dánu dúró níbi tó o bá ti rí àmì dáàṣì (—), kó o sì jẹ́ kí ọmọ náà sọ tinú rẹ̀.
ÌBÉÈRÈ:
▪ Kí nìdí tí Jésù kò fi kánjú láti lọ ran Lásárù lọ́wọ́?
▪ Kí nìdí tí Tọ́másì fi sọ pé: ‘Ẹ jẹ́ kí àwa pẹ̀lú lọ, ká lè bá Jésù kú’?
▪ Kí ló mú kí Jésù lè jí Lásárù dìde?
▪ Kí lo lè ṣe tó máa fi hàn pé o ti kẹ́kọ̀ọ́ látinú àpẹẹrẹ Jésù?