“Ọ̀kan Ni Aṣáájú Yín, Kristi”
“Kí a má pè yín ní ‘aṣáájú,’ nítorí ọ̀kan ni Aṣáájú yín, Kristi.”—MÁT. 23:10.
1. Ta ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ sí Aṣáájú, kí sì nìdí?
ÀWỌN oníṣọ́ọ̀ṣì ní àwọn aṣáájú tó jẹ́ èèyàn, irú bíi póòpù ti ilẹ̀ Róòmù, àwọn bàbá ìjọ àtàwọn bíṣọ́ọ̀bù àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Ìlà Oòrùn, àtàwọn olórí àwọn ẹ̀sìn míì. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ka èèyàn èyíkéyìí sí aṣáájú wọn. Wọn kì í ṣe ọmọlẹ́yìn èèyàn kankan. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ kan tí Jèhófà sọ nípa Ọmọ rẹ̀ pé: “Wò ó! Mo ti fi í fún àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí, gẹ́gẹ́ bí aṣáájú àti aláṣẹ fún àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè.” (Aísá. 55:4) Kárí ayé, ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àti ti àwọn “àgùntàn mìíràn” tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn, kò fẹ́ aṣáájú míì yàtọ̀ sí èyí tí Jèhófà ti yàn fún wọn. (Jòh. 10:16) Wọ́n fara mọ́ ọ̀rọ̀ Jésù pé: “Ọ̀kan ni Aṣáájú yín, Kristi.”—Mát. 23:10.
Áńgẹ́lì Tí Í Ṣe Ọmọ Aládé Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì
2, 3. Ipa wo ni Ọmọ Ọlọ́run kó nínú ọ̀ràn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
2 Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú kí wọ́n tó dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀, Jèhófà ní áńgẹ́lì kan tó jẹ́ aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí wọ́n jẹ́ èèyàn rẹ̀. Lẹ́yìn tí Jèhófà kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde ní Íjíbítì, ó sọ fún wọn pé: “Kíyè sí i, èmi yóò rán áńgẹ́lì kan ṣáájú rẹ láti pa ọ́ mọ́ ní ojú ọ̀nà àti láti mú ọ wá sí ibi tí mo ti pèsè sílẹ̀. Ṣọ́ ara rẹ nítorí rẹ̀ kí o sì ṣègbọràn sí ohùn rẹ̀. Má ṣọ̀tẹ̀ sí i, nítorí kì yóò dárí ìrélànàkọjá yín jì; nítorí orúkọ mi wà lára rẹ̀.” (Ẹ́kís. 23:20, 21) Ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé áńgẹ́lì ‘tí orúkọ Jèhófà wà lára rẹ̀’ yìí jẹ́ àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run.
3 Ó ṣe kedere pé Máíkẹ́lì ni Ọmọ Ọlọ́run yìí ń jẹ́ ṣáájú kí wọ́n tó bí i gẹ́gẹ́ bí èèyàn. Nínú ìwé Dáníẹ́lì, a pe Máíkẹ́lì ní “ọmọ aládé” àwọn èèyàn Dáníẹ́lì, ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Dán. 10:21) Júúdà ọmọ ẹ̀yìn fi hàn pé Máíkẹ́lì ti ń lọ́wọ́ nínú ọ̀ràn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ìgbà ayé Dáníẹ́lì. Lẹ́yìn tí Mósè kú, ó hàn gbangba pé Sátánì gbìyànjú láti lo òkú Mósè láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, ìyẹn ni pé ó fẹ́ sún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sínú ìbọ̀rìṣà. Máíkẹ́lì dá sí ọ̀ràn náà, kò jẹ́ kó kẹ́sẹ járí. Júúdà ṣàlàyé pé: “Nígbà tí Máíkẹ́lì olú-áńgẹ́lì ní aáwọ̀ pẹ̀lú Èṣù, tí ó sì ń ṣe awuyewuye nípa òkú Mósè, kò dá a láṣà láti mú ìdájọ́ wá lòdì sí i ní àwọn ọ̀rọ̀ èébú, ṣùgbọ́n ó wí pé: ‘Kí Jèhófà bá ọ wí lọ́nà mímúná.’” (Júúdà 9) Ní àkókò díẹ̀ lẹ́yìn náà, ìyẹn kí wọ́n tó sàga ti ìlú Jẹ́ríkò, ó dájú pé Máíkẹ́lì, “olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jèhófà” yìí, ló fara han Jóṣúà, tó sì mú kó dá a lójú pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn rẹ̀. (Ka Jóṣúà 5:13-15.) Nígbà tí ọmọ aládé ẹ̀mí èṣù gbìyànjú láti dí áńgẹ́lì kan lọ́wọ́ kó má bàa jíṣẹ́ pàtàkì kan fún Dáníẹ́lì, Máíkẹ́lì tí í ṣe olú áńgẹ́lì wá láti ran áńgẹ́lì náà lọ́wọ́.—Dán. 10:5-7, 12-14.
Aṣáájú Tá A Sọ Tẹ́lẹ̀ Náà Dé
4. Àsọtẹ́lẹ̀ wo la sọ nípa dídé Mèsáyà?
4 Ṣáájú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Jèhófà ti rán áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sí wòlíì Dáníẹ́lì láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan fún un nípa “Mèsáyà Aṣáájú” tó ń bọ̀. (Dán. 9:21-25)a Gẹ́lẹ́ bó ṣe sọ tẹ́lẹ̀, lọ́wọ́ ìparí ọdún 29 Sànmánì Kristẹni, Jòhánù ṣe ìrìbọmi fún Jésù. Ọlọ́run wá tú ẹ̀mí mímọ́ sórí Jésù, ó sì sọ ọ́ di Ẹni Àmì Òróró, ìyẹn Kristi tó jẹ́ Mèsáyà náà. (Mát. 3:13-17; Jòh. 1:29-34; Gál. 4:4) Nípa bẹ́ẹ̀, ó máa di Aṣáájú tí kò láfiwé.
5. Àwọn nǹkan wo ni Kristi ṣe nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé tó fi hàn pé ó jẹ́ Aṣáájú?
5 Látìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé ló ti fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bíi “Mèsáyà Aṣáájú.” Láàárín ọjọ́ mélòó kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn ọmọ ẹ̀yìn jọ, ó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àkọ́kọ́. (Jòh. 1:35–2:11) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń tẹ̀ lé e bó ti ń rìnrìn-àjò jákèjádò ilẹ̀ náà, tó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Lúùkù 8:1) Ó kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe máa wàásù, ó sì mú ipò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún wọn. (Lúùkù 9:1-6) Ó yẹ kí àwọn alàgbà ìjọ náà máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀ yìí.
6. Ọ̀nà wo ni Kristi gbà jẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn àti Aṣáájú?
6 Jésù tọ́ka sí apá míì lára ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú nípa fífi ara rẹ̀ wé olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn ní apá ìlà oòrùn ayé máa ń darí àwọn agbo àgùntàn wọn. Nínú ìwé The Land and the Book, ọ̀gbẹ́ni W. M. Thomson kọ̀wé pé: “Àwọn olùṣọ́ àgùntàn ló máa ń ṣáájú, kì í ṣe pé wọ́n kàn fẹ́ fọ̀nà han agbo àgùntàn wọn, àmọ́ wọ́n tún fẹ́ rí i pé kò sí ewu níbẹ̀. . . . Ó ń lo ọ̀pá ìdaran láti darí agbo ẹran rẹ̀ sí ibi tí oúnjẹ wà, ó sì tún ń lò ó láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.” Kí Jésù lè fi hàn pé Olùṣọ́ Àgùntàn àtàtà àti Aṣáájú rere ni òun, ó sọ pé: “Èmi ni olùṣọ́ àgùntàn àtàtà; olùṣọ́ àgùntàn àtàtà fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn. Àwọn àgùntàn mi ń fetí sí ohùn mi, mo sì mọ̀ wọ́n, wọ́n sì ń tẹ̀ lé mi.” (Jòh. 10:11, 27) Níbàámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Jésù, ó kú ikú ìrúbọ nítorí àwọn àgùntàn rẹ̀, àmọ́ Jèhófà gbé e dìde ó sì “fi ṣe aṣiwaju àti olùgbàlà.”—Ìṣe 5:31, Ìròhìn Ayọ̀; Héb. 13:20.
Alábòójútó Ìjọ Kristẹni
7. Ipasẹ̀ kí ni Jésù ń gbà bójú tó ìjọ Kristẹni?
7 Gẹ́rẹ́ kí Jésù tó jíǹde tó gòkè re ọ̀run, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ ni a ti fi fún mi ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.” (Mát. 28:18) Jèhófà mú kí Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ẹ̀mí mímọ́ kó lè fún wọn lókun nípa ẹ̀kọ́ òtítọ́ Kristẹni. (Jòh. 15:26) Jésù tú ẹ̀mí mímọ́ yìí sórí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. (Ìṣe 2:33) Jésù dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀ nígbà tó tú ẹ̀mí mímọ́ sórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn. Jèhófà sọ Ọmọ rẹ̀ tó wà lọ́run di Aṣáájú fún gbogbo ìjọ Kristẹni tó wà lórí ilẹ̀ ayé. (Ka Éfésù 1:22; Kólósè 1:13, 18.) Jésù ń darí ìjọ Kristẹni nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà, àwọn áńgẹ́lì tá a fi “sábẹ́ rẹ̀” sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un.—1 Pét. 3:22.
8. Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn wo ni Kristi lò láti darí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, àwọn wo ló sì ń lò lóde òní?
8 Bákan náà, nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, Kristi fúnni ní “àwọn ẹ̀bùn [tí ó jẹ́] ènìyàn” nínú ìjọ, àwọn kan lára wọn jẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn àti olùkọ́.” (Éfé. 4:8, 11) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn alábòójútó nínú ìjọ Kristẹni pé: “Ẹ kíyè sí ara yín àti gbogbo agbo, láàárín èyí tí ẹ̀mí mímọ́ yàn yín ṣe alábòójútó, láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run.” (Ìṣe 20:28) Nígbà tí ìjọ Kristẹni bẹ̀rẹ̀, ẹni àmì òróró ni gbogbo àwọn alábòójútó yìí. Àwọn àpọ́sítélì àtàwọn alàgbà tó wà ní ìjọ Jerúsálẹ́mù ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìgbìmọ̀ olùdarí. Kristi lo ìgbìmọ̀ olùdarí yìí láti máa darí gbogbo àwọn “arákùnrin” rẹ̀ tó jẹ́ ẹni àmì òróró lórí ilẹ̀ ayé. (Héb. 2:11; Ìṣe 16:4, 5) Ní àkókò òpin yìí, Kristi ti fa “gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀,” ìyẹn gbogbo àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé, lé “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” àti Ìgbìmọ̀ Olùdarí tó ń ṣojú rẹ̀ lọ́wọ́. Ìgbìmọ̀ Olùdarí yìí jẹ́ àwùjọ àwọn Kristẹni ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró. (Mát. 24:45-47) Àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn alábàákẹ́gbẹ́ wọn mọ̀ pé, tí àwọn bá ń tẹ̀ lé ìdarí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti òde òní, Kristi tí í ṣe Aṣáájú àwọn ni àwọn ń tẹ̀ lé yẹn.
Kristi Ló Dá Iṣẹ́ Ìwàásù Sílẹ̀
9, 10. Báwo ni Kristi ṣe ń darí iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run?
9 Látìbẹ̀rẹ̀ ni Jésù fúnra rẹ̀ ti ń darí iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tá à ń ṣe kárí ayé. Ó ṣètò bí a ṣe máa mú ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ní ìtọ́ni yìí pé: “Ẹ má ṣe lọ sí ojú ọ̀nà àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ má sì wọ ìlú ńlá Samáríà kan; ṣùgbọ́n, dípò bẹ́ẹ̀, ẹ lọ léraléra sọ́dọ̀ àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tí wọ́n sọnù. Bí ẹ ti ń lọ, ẹ máa wàásù, pé, ‘Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.’” (Mát. 10:5-7) Wọ́n fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù yìí láàárín àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe, ní pàtàkì jù lọ lẹ́yìn ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni.—Ìṣe 2:4, 5, 10, 11; 5:42; 6:7.
10 Lẹ́yìn náà, nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, Jésù fún àwọn ará Samáríà láǹfààní láti gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, àti lẹ́yìn náà àwọn míì tí kì í ṣe Júù. (Ìṣe 8:5, 6, 14-17; 10:19-22, 44, 45) Kó lè ṣeé ṣe láti fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní ìṣírí láti mú ìhìn rere lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè, Jésù fúnra rẹ̀ mú kí Sọ́ọ̀lù ará Tásù di Kristẹni. Jésù sọ fún Ananíà ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Dìde, lọ sí ojú pópó tí a ń pè ní Títọ́, àti pé nínú ilé Júdásì, wá ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sọ́ọ̀lù, láti Tásù. . . . Mú ọ̀nà rẹ pọ̀n, nítorí ohun èlò tí a ti yàn ni ọkùnrin yìí jẹ́ fún mi láti gbé orúkọ mi lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” (Ìṣe 9:3-6, 10, 11, 15) “Ọkùnrin yìí” la wá mọ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù.—1 Tím. 2:7.
11. Báwo ni Kristi ṣe lo ẹ̀mí mímọ́ láti mú iṣẹ́ ìwàásù gbòòrò sí i?
11 Nígbà tí àkókò tó láti mú kí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run gbòòrò síwájú láàárín àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Júù, ẹ̀mí mímọ́ darí Pọ́ọ̀lù lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì láti ilẹ̀ Éṣíà Kékeré lọ sí ilẹ̀ Yúróòpù. Àkọsílẹ̀ Lúùkù nínú ìwé Ìṣe ròyìn pé: “Bí [àwọn wòlíì tó jẹ́ Kristẹni àti àwọn olùkọ́ tó wà nínú ìjọ Síríà Áńtíókù] ti ń ṣèránṣẹ́ fún Jèhófà ní gbangba, tí wọ́n sì ń gbààwẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ wí pé: ‘Nínú gbogbo ènìyàn, ẹ ya Bánábà àti Sọ́ọ̀lù sọ́tọ̀ gedegbe fún mi fún iṣẹ́ tí mo pè wọ́n sí.’ Nígbà náà ni wọ́n gbààwẹ̀, wọ́n sì gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn, wọ́n sì jẹ́ kí wọn lọ.” (Ìṣe 13:2, 3) Jésù fúnra rẹ̀ ti pe Sọ́ọ̀lù ará Tásù láti jẹ́ “ohun èlò tí a ti yàn” láti gbé orúkọ rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, torí náà, ọ̀dọ̀ Kristi tí í ṣe Aṣáájú ìjọ ni ìtọ́ni tó máa jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù tẹ̀ síwájú yìí ti wá. Bí Jésù ṣe ń lo ẹ̀mí mímọ́ láti darí iṣẹ́ náà wá túbọ̀ ṣe kedere nígbà ìrìn àjò ẹ̀ẹ̀kejì tí Pọ́ọ̀lù rìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì. Àkọsílẹ̀ náà fi hàn pé “ẹ̀mí Jésù” darí Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn-àjò, ìyẹn ni pé, Jésù fi ẹ̀mí mímọ́ darí wọn nígbà tí wọ́n ń yan ibi tí wọ́n máa lọ àti ìgbà tí wọ́n máa lọ, ìran kan sì darí wọn láti lọ sí ilẹ̀ Yúróòpù.—Ka Ìṣe 16:6-10.
Bí Jésù Ṣe Ń Darí Ìjọ Rẹ̀
12, 13. Báwo ni ìwé Ìṣípayá ṣe fi hàn pé Kristi ń fojú sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan?
12 Jésù ń fojú sí bí nǹkan ṣe ń lọ sí nínú ìjọ àwọn ẹni àmì òróró rẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni. Ó mọ ipò tí ìjọ kọ̀ọ̀kan wà nípa tẹ̀mí. Èyí á ṣe kedere sí wa tá a bá ka ìwé Ìṣípayá orí kejì àti orí kẹta. Ó dárúkọ ìjọ méje tí gbogbo wọn wà ní Éṣíà Kékeré. (Ìṣí. 1:11) Ó yẹ ká gbà gbọ́ dájú pé, bó ṣe mọ ipò tí àwọn ìjọ wọ̀nyẹn wà nípa tẹ̀mí náà ló ṣe mọ ipò àwọn ìjọ míì tí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wà ní àkókò yẹn.—Ka Ìṣípayá 2:23.
13 Jésù gbóríyìn fún àwọn ìjọ kan nítorí ìfaradà wọn, ìṣòtítọ́ wọn lábẹ́ àdánwò, jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti bí wọn kò ṣe tẹ́wọ́ gba àwọn apẹ̀yìndà. (Ìṣí. 2:2, 9, 13, 19; 3:8) Lọ́wọ́ kejì, ó fún àwọn ìjọ mélòó kan ní ìbáwí mímúná torí pé ìfẹ́ tí wọ́n ní fún un ti di tútù, wọ́n fàyè gba ìbọ̀rìṣà àti àgbèrè, wọ́n sì tún fàyè gba ẹ̀ya ìsìn. (Ìṣí. 2:4, 14, 15, 20; 3:15, 16) Gẹ́gẹ́ bí alábòójútó onífẹ̀ẹ́, Jésù tún sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ìjọ tó fún ní ìbáwí mímúná, ó sọ pé: “Gbogbo àwọn tí mo ní ìfẹ́ni fún ni mo ń fi ìbáwí tọ́ sọ́nà, tí mo sì ń bá wí. Nítorí náà, jẹ́ onítara, kí o sì ronú pìwà dà.” (Ìṣí. 3:19) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀run ni Jésù wà, ó ń darí ìjọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́. Ní ìparí àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ fún àwọn ìjọ yẹn, ó polongo pé: “Kí ẹni tí ó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.”—Ìṣí. 3:22.
14-16. (a) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun jẹ́ Aṣáájú onígboyà fún àwọn èèyàn Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé? (b) Kí ló ti jẹ́ àbájáde wíwà tí Jésù “wà pẹ̀lú” àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ “ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan”? (d) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
14 A ti rí i pé Máíkẹ́lì (Jésù) ti fi ẹ̀rí hàn pé òun jẹ́ áńgẹ́lì onígboyà tó jẹ́ Aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn náà, Jésù tún jẹ́ Aṣáájú tó nígboyà àti Olùṣọ́ Àgùntàn onífẹ̀ẹ́ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Lákòókò iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ó mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù. Lẹ́yìn tó sì jíǹde, ó ń bójú tó bí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń tàn kálẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.
15 Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Jésù yóò lo ẹ̀mí mímọ́ láti mú kí iṣẹ́ ìwàásù náà tàn dé ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé. Kí Jésù tó gòkè re ọ̀run, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8; ka 1 Pétérù 1:12.) Lábẹ́ ìdarí Kristi, àwọn ọmọ ẹ̀yìn jẹ́rìí kúnnákúnná ní ọ̀rúndún kìíní.—Kól. 1:23.
16 Àmọ́, Jésù fúnra rẹ̀ fi hàn pé iṣẹ́ yìí á máa bá a lọ títí fi di àkókò òpin. Lẹ́yìn tí Jésù ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ó ṣèlérí fún wọn pé: “Mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 28:19, 20) Látìgbà tí Jèhófà ti fi Kristi jọba lọ́run lọ́dún 1914, ó ti “wà pẹ̀lú” àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ, ó sì ń ṣe Aṣáájú wọn nìṣó. A máa ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ohun tó ti ń ṣe láti ọdún 1914 wá nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A jíròrò àsọtẹ́lẹ̀ yìí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ní orí 11 nínú ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì!
Àtúnyẹ̀wò
• Báwo ni Ọmọ Ọlọ́run ṣe fi hàn pé òun jẹ́ Aṣáájú ní Ísírẹ́lì?
• Ọ̀nà wo ni Kristi ń gbà darí ìjọ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé?
• Báwo ni Kristi ṣe darí mímú ìhìn rere náà lọ sọ́dọ̀ gbogbo èèyàn?
• Kí ló fi hàn pé Kristi ń kíyè sí bí nǹkan ṣe ń lọ sí nípa tẹ̀mí nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
“Èmi yóò rán áńgẹ́lì kan ṣáájú rẹ”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Bó ṣe rí nígbà àtijọ́, Kristi ń lo “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo