Ṣé O Máa Ń Mú Kí Àwọn Ìpàdé Ìjọ Gbéni Ró?
“Nígbà tí ẹ bá kóra jọpọ̀, . . . kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ fún ìgbéniró.”—1 KỌ́R. 14:26.
1. Gẹ́gẹ́ bí 1 Kọ́ríńtì orí 14 ṣe sọ, kí ni àwọn ìpàdé ìjọ wà fún?
‘ÌPÀDÉ yìí mà gbéni ró gan-an ni o!’ Ṣé ìwọ náà ti sọ irú ọ̀rọ̀ yìí rí lẹ́yìn tí ìpàdé parí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba? Ó dájú pé wàá ti sọ bẹ́ẹ̀ rí! A máa ń rí ìṣírí gbà gan-an láwọn ìpàdé ìjọ, ìyẹn kò sì yani lẹ́nu. Ó ṣe tán, ohun táwọn ìpàdé ìjọ wà fún lákòókò àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní náà ni wọ́n ṣì wà fún lónìí, ìyẹn ni pé kí wọ́n lè fún àwọn tó wà níbẹ̀ lókun nípa tẹ̀mí. Kíyè sí bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe tẹnu mọ́ ohun tí àwọn ìpàdé ìjọ wà fún nínú lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sí àwọn ará Kọ́ríńtì. Jálẹ̀ orí 14, ó sọ léraléra pé ohun kan náà ni apá kọ̀ọ̀kan tá à ń gbádùn ní ìpàdé ìjọ gbọ́dọ̀ wà fún, ìyẹn ni “fún gbígbé ìjọ ró.”—Ka 1 Kọ́ríńtì 14:3, 12, 26.a
2. (a) Kí ló máa ń mú kí àwọn ìpàdé wa gbéni ró? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?
2 A mọ̀ pé ẹ̀mí Ọlọ́run tó ń darí wa ló fà á táwọn ìpàdé wa fi máa ń gbéni ró, tí wọ́n sì máa ń kún fún ẹ̀kọ́. Nítorí náà, a máa ń bẹ̀rẹ̀ ìpàdé kọ̀ọ̀kan nípa gbígba àdúrà àtọkànwá sí Jèhófà, a sì ń tipa bẹ́ẹ̀ bẹ Baba wa ọ̀run pé kó bù kún ìpéjọpọ̀ wa nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Síbẹ̀, a mọ̀ pé àwọn ará nínú ìjọ máa ń sa gbogbo ipá wọn láti mú kí àwọn ìpàdé wa gbéni ró. Torí náà, kí ni díẹ̀ lára ohun tá a lè ṣe lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ká lè rí i dájú pé ìgbà gbogbo ni àwọn ìpàdé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tá à ń ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wa ń túni lára tó sì ń fúnni ní ìṣírí?
3. Báwo ni àwọn ìpàdé Kristẹni ti ṣe pàtàkì tó?
3 Láti dáhùn ìbéèrè yìí, a máa ṣàgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ohun tí àwọn tó ń darí àwọn ìpàdé náà gbọ́dọ̀ máa fi sọ́kàn. A tún máa ṣàgbéyẹ̀wò bí ìjọ lápapọ̀ ṣe lè kópa nínú mímú kí àwọn ìpàdé náà máa gbé àwọn tó bá wá síbẹ̀ ró. Ohun tá a fẹ́ jíròrò yìí ṣe pàtàkì gan-an ni, torí pé àwọn ìpàdé wa jẹ́ àpéjọ mímọ́. Kódà, apá pàtàkì lára ìjọsìn wa sí Jèhófà ló jẹ́ láti máa lọ sáwọn ìpàdé náà ká sì máa lóhùn sí i.—Sm. 26:12; 111:1; Aísá. 66:22, 23.
Ìpàdé Tá A Ti Ń Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
4, 5. Kí ni Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ wà fún?
4 Ó wu gbogbo wa pé ká máa jàǹfààní kíkún látinú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tá à ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Torí náà, ká bàa lè ní òye tó ṣe kedere nípa ohun tí ìpàdé yìí wà fún, ẹ jẹ́ ká ṣe àtúnyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn àtúnṣe tó ti bá ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti àwọn àpilẹ̀kọ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́.
5 Bẹ̀rẹ̀ látorí Ilé Ìṣọ́ January 15, 2008, tó jẹ́ àkọ́kọ́ lára ẹ̀dà tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́, la ti ń fi àwọn ohun pàtàkì kan kún ohun tó wà lára èèpo ẹ̀yìn rẹ̀. Ǹjẹ́ o kíyè sí i? Fara balẹ̀ wo èèpo ẹ̀yìn ìwé ìròyìn tó wà lọ́wọ́ rẹ yìí. Ní ìsàlẹ̀ ilé ìṣọ́ tá a yà síbẹ̀, wàá rí Bíbélì kan tó wà ní ṣíṣí sílẹ̀. Àwòrán tá a fi kún un yìí ló sọ ìdí pàtàkì tá a fi máa ń ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Ó jẹ́ láti fi ìwé ìròyìn yìí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bẹ́ẹ̀ ni, bá a ṣe ń ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ńṣe ni à ń “làdí” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a sì “ń fi ìtumọ̀ sí i” bí wọ́n ti ṣe nígbà ayé Nehemáyà.—Neh. 8:8; Aísá. 54:13.
6. (a) Àtúnṣe wo ló bá Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́? (b) Kí ló yẹ ká máa fi sọ́kàn nípa àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a kọ “ka” sí?
6 Nítorí pé Bíbélì ni lájorí ìwé tá à ń kẹ́kọ̀ọ́, a ṣe àtúnṣe kan sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ wa. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mélòó kan tá a tọ́ka sí nínú àpilẹ̀kọ náà ni a kọ “ka” sí. Gbogbo wa la fún ní ìṣírí pé, ká máa fojú bá àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà lọ nínú Bíbélì tiwa nígbà tí wọ́n bá ń kà wọ́n nípàdé. (Ìṣe 17:11) Kí nìdí? Bá a bá rí ìtọ́ni Ọlọ́run nínú Bíbélì tiwa, ó máa wọ̀ wá lọ́kàn. (Héb. 4:12) Torí náà, kí wọ́n tó ka ẹsẹ Bíbélì yẹn sókè ketekete, kí ẹni tó ń darí ìpàdé náà fún àwọn tó wà láwùjọ ní àkókò tó pọ̀ tó láti rí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí kí wọ́n sì máa fojú bá kíkà rẹ̀ lọ.
Àkókò Púpọ̀ sí I Wà Láti Ṣàlàyé Ohun Tá A Gbà Gbọ́
7. Àǹfààní wo la ní nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́?
7 Àtúnṣe míì tó bá àwọn àpilẹ̀kọ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú Ilé Ìṣọ́ wa ní í ṣe pẹ̀lú bí wọ́n ṣe máa ń gùn tó. Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, wọn kò gùn tó ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Torí náà, nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, àkókò tá a fi ń ka àwọn ìpínrọ̀ ti dín kù, èyí sì mú kí àkókò tó wà fun jíjíròrò ìpínrọ̀ náà gùn sí i. Ọ̀pọ̀ àwọn ará nínú ìjọ lè ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́ ní gbangba yálà nípa dídáhùn àwọn ìbéèrè tá a tẹ̀ sínú àpilẹ̀kọ náà, ṣíṣàlàyé ẹsẹ ìwé mímọ́, sísọ ìrírí kúkúrú tó ṣàlàyé ọgbọ́n tó wà nínú títẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, tàbí ní àwọn ọ̀nà míì. A tún lè lo àkókò díẹ̀ láti ṣàlàyé àwọn àwòrán tó wà níbẹ̀.—Ka Sáàmù 22:22; 35:18; 40:9.
8, 9. Kí ni ojúṣe ẹni tó ń darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́?
8 Àmọ́ ṣá o, kí àfikún àkókò tó máa mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ará lóhùn sí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà tó lè gbéṣẹ́, àfi kí àwọn tó wà láwùjọ máa ṣe àlàyé ṣókí, kí olùdarí náà sì yẹra fún ṣíṣe àlàyé lemọ́lemọ́ nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Bọ́rọ̀ ṣe rí yìí, kí ló lè ran olùdarí lọ́wọ́ tí kò fi ní máa ṣe àlàyé lórí gbogbo ìdáhùn àwọn ará, kí ìpàdé náà lè gbé gbogbo wọn ró?
9 Láti dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká gbé àpèjúwe kan yẹ̀ wò. Ńṣe ni Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tá a darí bó ṣe yẹ dà bí ìdì òdòdó rírẹwà tó jojú ní gbèsè. Bó ṣe jẹ́ pé ẹyọ òdòdó kọ̀ọ̀kan ló para pọ̀ di ìdì òdòdó ńlá, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀kan-kò-jọ̀kan ìdáhùn ṣe máa ń para pọ̀ di Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Bí àwọ̀ tó wà lára ẹyọ òdòdó kọ̀ọ̀kan ṣe máa ń yàtọ̀ síra tí ọ̀kan sì máa ń tóbi ju èkejì lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni gígùn ìdáhùn àwọn ará ṣe máa ń yàtọ̀ síra, a kì í sì í gbé wọn kalẹ̀ lọ́nà kan náà. Kí wá ni ojúṣe ẹni tó jẹ́ olùdarí? Àwọn àlàyé tó ń fi kún un lóòrèkóòrè dà bí ewéko tó tutù yọ̀yọ̀ tí wọ́n máa ń kì sáàárín ìdì òdòdó láti fi gbé ẹwà rẹ̀ yọ. Àwọn ewéko yìí kì í bo òdòdó tó kù mọ́lẹ̀; kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n máa ṣàlékún ẹwà ìdì òdòdó náà. Bákàn náà, ó yẹ kí ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ fi í sọ́kàn pé dípò kí òun máa kó àlàyé palẹ̀, ojúṣe òun ni láti máa kín ọ̀rọ̀ ìyìn tí ìjọ bá ń sọ lẹ́yìn. Bẹ́ẹ̀ ni o, tá a bá pa ọ̀kan-kò-jọ̀kan àlàyé tí ìjọ ṣe àti àfikún tó bọ́ sójú ẹ̀ tí olùdarí ṣe pọ̀ sójú kan, bí ìdì òdòdó rírẹwà, ńṣe ló máa para pọ̀ di ọ̀rọ̀ rírẹwà tó máa mú kí inú gbogbo àwọn tó wà láwùjọ dùn.
“Ẹ Jẹ́ Ká Máa Rú Ẹbọ Ìyìn sí Ọlọ́run Nígbà Gbogbo”
10. Ojú wo ni àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní fi ń wo àwọn ìpàdé ìjọ?
10 Bí Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàpèjúwe àwọn ìpàdé ìjọ nínú ìwé 1 Kọ́ríńtì 14:26-33 túbọ̀ jẹ́ ká lóye bí wọ́n ṣe ń darí àwọn àpéjọ wọ̀nyí ní ọ̀rúndún kìíní. Nígbà tí ọ̀gbẹ́ni kan tó ní ìmọ̀ Bíbélì ń ṣàlàyé lórí ẹsẹ yìí, ó kọ̀wé pé: “Ohun tó gbàfiyèsí jù lọ nípa ìpàdé Ìjọ ní ọ̀rúndún kìíní ni pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ẹni tó ń lọ síbẹ̀ ló ti mọ̀ pé àǹfààní àti ohun àìgbọ́dọ̀máṣe ló jẹ́ fún òun láti fi kún àṣeyọrí ìpàdé náà. Kò sẹ́ni tó ń lọ síbẹ̀ láti lọ fetí sílẹ̀ lásán; wọ́n kì í lọ nítorí àtirí gbà nìkan, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n máa ń fẹ́ láti fúnni.” Ní tòótọ́, àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní máa ń wo àwọn ìpàdé ìjọ gẹ́gẹ́ bí ibi tí wọ́n ti láǹfààní láti ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́.—Róòmù 10:10.
11. (a) Kí ló máa ń mú káwọn ìpàdé gbéni ró, kí sì nìdí? (b) Àwọn ìdámọ̀ràn wo ló yẹ ká fi sílò káwọn ìdáhùn wa bàa lè sunwọ̀n sí i láwọn ìpàdé ìjọ? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
11 Bá a bá ń ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́ láwọn ìpàdé, ó máa fi kún “gbígbé ìjọ ró.” Dájúdájú, wàá gbà pé bó ti wù kó pẹ́ tó tá a ti ń lọ sí àwọn ìpàdé, ó ṣì máa ń dùn mọ́ni láti gbọ́ ìdáhùn àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Ìdáhùn tí àgbàlagbà kan tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ bá mú wá máa ń wọ̀ wá lọ́kàn; ó máa ń wú wa lórí bí alàgbà kan tó bìkítà nípa àwọn ẹlòmíì bá pe ohun kan tó gba àròjinlẹ̀ sí àfiyèsí wa; a sì máa ń rẹ́rìn-ín músẹ́ nígbà tí ọmọdé kan bá ṣe àlàyé tó fi hàn pé ó ní ojúlówó ìfẹ́ fún Jèhófà. Ó ṣe kedere pé nípa lílóhùn sí ìpàdé ìjọ, gbogbo wa á máa ṣe ipa tiwa láti mú kó gbéni ró.b
12. (a) Kí la lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Mósè àti Jeremáyà? (b) Ipa wo ni àdúrà ń kó nínú dídáhùn?
12 Àmọ́, ní ti àwọn tó máa ń tijú, ó lè ṣòro gan-an fún wọn láti dáhùn. Bó o bá ń tijú, ó dáa kó o rántí pé bí ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì náà ṣe rí nìyẹn. Kódà, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó jẹ́ olóòótọ́, bíi Mósè àti Jeremáyà sọ pé ó ṣòro fún àwọn láti sọ̀rọ̀ ní gbangba. (Ẹ́kís. 4:10; Jer. 1:6) Síbẹ̀, bí Jèhófà ṣe ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́ wọ̀nyẹn lọ́wọ́ láti yìn ín ní gbangba, Ó máa ran ìwọ náà lọ́wọ́ láti máa rú ẹbọ ìyìn. (Ka Hébérù 13:15.) Báwo lo ṣe lè rí ìrànlọ́wọ́ Jèhófà gbà kó o lè borí ẹ̀rù tó ń bà ẹ́ láti máa dáhùn? Lákọ̀ọ́kọ́, máa múra sílẹ̀ dáadáa fún ìpàdé. Lẹ́yìn náà, kó o tó lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà kó o sì bẹ̀ ẹ́ ní tààràtà pé kó fún ẹ ní ìgboyà tí wàá fi lè dáhùn. (Fílí. 4:6) Ohun tó wà “ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀” lò ń béèrè, torí náà jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa dáhùn àdúrà rẹ.—1 Jòh. 5:14; Òwe 15:29.
Àwọn Ìpàdé Tó Ń ‘Gbéni Ró, Tó Ń Fúnni Níṣìírí Tó sì Ń Tuni Nínú’
13. (a) Ipa wo ló yẹ káwọn ìpàdé wa ní lórí àwọn tó wá síbẹ̀? (b) Ìbéèrè wo ló ṣe pàtàkì gan-an fáwọn alàgbà?
13 Pọ́ọ̀lù sọ pé ohun pàtàkì táwọn ìpàdé ìjọ wà fún ni láti ‘gbéni ró, láti fúnni níṣìírí àti láti pèsè ìtùnú’ fún àwọn tó wá síbẹ̀.c (1 Kọ́r. 14:3) Lóde òní, báwo làwọn Kristẹni tó jẹ́ alàgbà ṣe lè rí i dájú pé apá ìpàdé kọ̀ọ̀kan ń ta àwọn ará jí lọ́kùnrin àti lóbìnrin, àti pé ó ń tù wọ́n nínú? Láti dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ìpàdé kan tí Jésù ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kété lẹ́yìn tó jíǹde.
14. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ kí ìpàdé tí Jésù ṣètò láti bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe tó wáyé? (b) Kí nìdí tí ọkàn àwọn àpọ́sítélì fi ní láti balẹ̀ nígbà tí “Jésù tọ̀ wọ́n wá láti bá wọn sọ̀rọ̀”?
14 Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ kíyè sí ohun tó ṣẹlẹ̀ kí ìpàdé náà tó wáyé. Kí wọ́n tó pa Jésù, àwọn àpọ́sítélì “pa á tì, wọ́n sì sá lọ,” àti pé gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, a “tú [wọn] ká, olúkúlùkù sí ilé tirẹ̀.” (Máàkù 14:50; Jòh. 16:32) Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó pe àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ tí ọkàn wọn ti rẹ̀wẹ̀sì sí ìpàdé kan tó jẹ́ àkànṣe.d Ní ìdáhùn sí ìkésíni náà, “àwọn ọmọ ẹ̀yìn mọ́kànlá lọ sí Gálílì sí òkè ńlá níbi tí Jésù ti ṣètò fún wọn.” Nígbà tí wọ́n débẹ̀, “Jésù sì sún mọ́ tòsí, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀.” (Mát. 28:10, 16, 18) Ẹ wo bí ara ṣe ní láti tu àwọn àpọ́sítélì náà tó nígbà tí Jésù lo ìdánúṣe yẹn! Kí ni Jésù bá wọn sọ?
15. (a) Kí ni Jésù bá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sọ, kí ni kò sì bá wọn sọ? (b) Ipa wo ni ìpàdé náà ní lórí àwọn àpọ́sítélì?
15 Jésù bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa kíkéde pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ ni a ti fi fún mi ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.” Lẹ́yìn náà, ó gbé iṣẹ́ kan lé wọn lọ́wọ́, ó sọ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” Lákòótán, ó mú un dá wọn lójú pé: “Mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́.” (Mát. 28:18-20) Àmọ́, ǹjẹ́ o mọ ohun tí Jésù kò ṣe? Kò bá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ wí; kò sì bi wọ́n ìdí tí wọ́n fi ṣe ohun tí wọ́n ṣe tàbí kó mú kí wọ́n túbọ̀ máa dá ara wọn lẹ́bi nípa títọ́ka sí ìgbàgbọ́ wọn tó mì. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù gbé iṣẹ́ bàǹtàbanta lé wọn lọ́wọ́ láti fi hàn pé òun àti Bàbá òun nífẹ̀ẹ́ wọn. Ipa wo ni ọ̀nà tí Jésù gbà bá àwọn àpọ́sítélì sọ̀rọ̀ ní lórí wọn? Ó gbé wọn ró, ó fún wọn níṣìírí, ó sì tù wọ́n nínú débi pé ní àkókò díẹ̀ lẹ́yìn ìpàdé náà, wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í ‘kọ́ni wọ́n sì ń polongo ìhìn rere.’—Ìṣe 5:42.
16. Lónìí, báwo làwọn Kristẹni tó jẹ́ alàgbà ṣe ń fara wé àpẹẹrẹ Jésù nínú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà darí àwọn ìpàdé tó ń túni lára?
16 Ní àfarawé Jésù, lónìí àwọn alàgbà máa ń wo àwọn ìpàdé gẹ́gẹ́ bí ibi tí wọ́n ti ní àǹfààní láti mú kí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ rí àrídájú ìfẹ́ tí kì í kùnà, èyí tí Jèhófà ní sí àwọn èèyàn rẹ̀. (Róòmù 8:38, 39) Torí náà, bí àwọn alàgbà bá ń bójú tó apá tá a yàn fún wọn ní ìpàdé, ibi tí àwọn ará dáa sí ni wọ́n máa ń tẹnu mọ́, kì í ṣe ibi tí wọ́n kù sí. Wọ́n kì í ní ìfura òdì sí àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ wọn máa ń fi hàn pé wọ́n ń wo àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì ń fẹ́ láti ṣe ohun tó tọ́. (1 Tẹs. 4:1, 9-12) Àmọ́ ṣá o, ìgbà míì wà tó máa pọn dandan pé káwọn alàgbà fún ìjọ lápapọ̀ ní ìmọ̀ràn tó máa mú kí wọ́n ṣàtúnṣe, àmọ́ tó bá jẹ́ pé ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló yẹ kí wọ́n mú pa dà bọ̀ sípò, ó máa dára jù lọ kí wọ́n bá àwọn tí ọ̀ràn kàn sọ̀rọ̀ ní ìdákọ́ńkọ́. (Gál. 6:1; 2 Tím. 2:24-26) Nígbà táwọn alàgbà bá ń bá ìjọ lápapọ̀ sọ̀rọ̀, wọ́n máa ń sapá láti gbóríyìn fún wọn nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. (Aísá. 32:2) Wọ́n ń sapá láti sọ̀rọ̀ lọ́nà tó fi jẹ́ pé bí ìpàdé bá parí, ará máa tu gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀, a ó sì sọ agbára wọn dọ̀tun.—Mát. 11:28; Ìṣe 15:32.
Ibi Tá A Ti Ń Rí Ìtùnú Gbà
17. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ju ti ìgbàkigbà rí lọ pé káwọn ìpàdé wa jẹ́ ibi tá a ti ń rí ìtùnú gbà? (b) Kí ni ìwọ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan lè ṣe láti mú káwọn ìpàdé wa máa gbéni ró? (Wo àpótí náà, “Ọ̀nà Mẹ́wàá Tó O Lè Gbà Mú Kí Ìpàdé Máa Gbé Ìwọ Àtàwọn Míì Ró.”)
17 Bí ayé Sátánì ṣe túbọ̀ ń le koko sí i, a gbọ́dọ̀ máa rí i dájú pé àwọn ìpàdé wa jẹ́ ibi tá a ti ń rí ìtùnú gbà. (1 Tẹs. 5:11) Arábìnrin kan tí òun àti ọkọ rẹ̀ dojú kọ ìṣòro tó le koko ní àwọn ọdún mélòó kan sẹ́yìn rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Tá a bá wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, ńṣe ló máa ń dà bíi pé Jèhófà gbé wa sọ́wọ́ rẹ̀. Ní gbogbo àkókò tá a bá fi wà láàárín àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, a máa ń mọ̀ ọ́n lára pé a ti kó ẹrù ìnira wa lé Jèhófà lọ́wọ́, ara sì máa ń tù wá.” (Sm. 55:22) Ǹjẹ́ kí gbogbo àwọn tó ń wá sí ìpàdé wa lè máa rí irú ìṣírí yìí gbà, kí ara sì máa tù wọ́n. Kó bàa lè rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa ṣe ipa tiwa nìṣó láti mú kí àwọn ìpàdé Kristẹni máa gbéni ró.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn kan lára ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní máa dópin. Bí àpẹẹrẹ, a kò “sọ̀rọ̀ ní àwọn ahọ́n àjèjì” mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì “sọ tẹ́lẹ̀” mọ́. (1 Kọ́r. 13:8; 14:5) Síbẹ̀ náà, ìtọ́ni Pọ́ọ̀lù fún wa ní ìjìnlẹ̀ òye nípa bó ṣe yẹ ká máa darí àwọn ìpàdé ìjọ lónìí.
b Àwọn ìdámọ̀ràn nípa bá a ṣe lè mú kí àwọn ìdáhùn wa sunwọ̀n sí i láwọn ìpàdé ìjọ wà nínú Ilé Ìṣọ́ September 1, 2003, ojú ìwé 19 sí 22.
c Ní ti ìyàtọ̀ tó wà láàárín “fún níṣìírí” àti “tù nínú,” ìwé atúmọ̀ èdè Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words ṣàlàyé pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n túmọ̀ sí “tù nínú” ń sọ nípa “ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn tó jinlẹ̀ ju ti ká [fúnni ní ìṣírí] lọ.”—Fi wé Jòhánù 11:19.
d Ó lè jẹ́ pé ìpàdé yìí ni Pọ́ọ̀lù wá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tó sọ pé Jésù “fara han èyí tí ó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta.”—1 Kọ́r. 15:6.
Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
• Báwo ni àwọn ìpàdé ìjọ ti ṣe pàtàkì tó?
• Kí nìdí tí àwọn ìdáhùn wa ní ìpàdé fi máa ń fi kún “gbígbé ìjọ ró”?
• Kí la rí kọ́ látinú ìpàdé tí Jésù bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe?
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22, 23]
Ọ̀NÀ MẸ́WÀÁ TÓ O LÈ GBÀ MÚ KÍ ÌPÀDÉ MÁA GBÉ ÌWỌ ÀTÀWỌN MÍÌ RÓ
Máa múra sílẹ̀. Bó o bá ti múra àwọn ohun tá a máa sọ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba sílẹ̀, ìpàdé náà máa gba gbogbo àfiyèsí rẹ, ohun tó o kọ́ á sì wọ̀ ẹ́ lọ́kàn.
Máa lọ sí ìpàdé déédéé. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé bí àwọn tó pọ̀ bá wá sí ìpàdé, ó máa ń fún olúkúlùkù níṣìírí, nígbà náà ó ṣe pàtàkì pé kó o máa wà níbẹ̀.
Máa tètè dé. Bó o bá ti wà ní ìjókòó kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀, wàá lè dara pọ̀ nínú orin àti àdúrà ìbẹ̀rẹ̀, èyí tó jẹ́ apá kan ìjọsìn wa sí Jèhófà.
Kó gbogbo nǹkan tó o nílò dání. Mú Bíbélì rẹ àtàwọn ìtẹ̀jáde tá a máa lò nípàdé dání kó o bàa lè máa fojú bá a lọ kó o sì lè túbọ̀ lóye ohun tá à ń jíròrò.
Ṣọ́ra fún ìpínyà ọkàn. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ kí ìpàdé parí kó o tó ka ìsọfúnni tí wọ́n bá fi ránṣẹ́ sórí fóònù rẹ, má ṣe kà á nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́. Lọ́nà yẹn, wàá fi ọ̀ràn ara ẹni sí àyè tó yẹ kó wà.
Kópa nínú ìpàdé. Bí ọ̀pọ̀ sí i lára wa bá lóhùn sí ìpàdé, onírúurú ọ̀rọ̀ tó ń gbé ìgbàgbọ́ ró tá a bá sọ máa fún àwọn púpọ̀ sí i ní ìṣírí, ó sì máa gbé ìgbàgbọ́ wọn ró.
Jẹ́ kí ìdáhùn rẹ máa ṣe ṣókí. Èyí á mú káwọn tó pọ̀ lè lóhùn sí ìpàdé náà nípa dídáhùn.
Ṣe iṣẹ́ tí wọ́n bá gbé fún ẹ. Bó o bá jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run tàbí tó o bá níṣẹ́ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, múra sílẹ̀ dáadáa, fi iṣẹ́ náà dánra wò kí ọjọ́ tó pé, kó o sì sapá gidigidi láti má ṣe wọ́gi lé iṣẹ́ náà.
Gbóríyìn fún àwọn tó ṣiṣẹ́. Kí àwọn tó ṣiṣẹ́ ní ìpàdé tàbí àwọn tó dáhùn, kó o sì sọ bó o ṣe mọrírì ìsapá wọn tó.
Kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará. Ìkíni ọlọ́yàyà àti ìjíròrò tó gbéni ró ṣáájú àti lẹ́yìn ìpàdé máa ń ṣe àlékún ìgbádùn àti àǹfààní téèyàn ń rí tó bá wà níbẹ̀.