Lo Ẹ̀bùn Wíwà Láìní Ọkọ Tàbí Aya Lọ́nà Tó Dára Jù Lọ
“Kí ẹni tí ó bá lè wá àyè fún un wá àyè fún un.”—MÁT. 19:12.
1, 2. (a) Ojú wo ni Jésù, Pọ́ọ̀lù àtàwọn míì fi wo wíwà láìní ọkọ tàbí aya? (b) Kí ló lè mú káwọn kan má ka wíwà láìní ọkọ tàbí aya sí ẹ̀bùn?
KÒ SÍ àní-àní pé ìgbéyàwó jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀bùn tó dára jù lọ tí Ọlọ́run fún aráyé. (Òwe 19:14) Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tí kò ṣègbéyàwó ló ń gbádùn ìgbésí ayé wọn tí wọ́n sì ń ní ìtẹ́lọ́rùn. Arákùnrin Harold, tó jẹ́ ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rùn-ún [95], ṣùgbọ́n tí kò ní ìyàwó rí, sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo máa ń gbádùn àkókò tí mo máa ń lò pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì tí mo sì máa ń hùwà ọ̀làwọ́ sáwọn èèyàn, síbẹ̀ bó bá ku èmi nìkan, kì í ṣe mí bíi pé mo dá wà. Torí náà, mo lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé mo ní ẹ̀bùn wíwà ní àpọ́n.”
2 Kódà, Jésù Kristi àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé bí ìgbéyàwó ṣe jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ ni wíwà láìní ọkọ tàbí aya ṣe jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run. (Ka Mátíù 19:11, 12; 1 Kọ́ríńtì 7:7.) Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo àwọn tí kò ṣègbéyàwó ló wù kí wọ́n wà bẹ́ẹ̀. Nígbà míì bí ipò nǹkan ṣe rí máa ń mú kó ṣòro fún àwọn míì láti rí irú ọkọ tàbí aya tí wọ́n fẹ́. Tàbí kó jẹ́ pé lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún táwọn míì ti ṣègbéyàwó ló ṣàdédé ku àwọn nìkan torí pé ọkọ tàbí aya wọ́n kú tàbí ó kọ̀ wọ́n sílẹ̀. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni wíwà láìní ọkọ tàbí aya ṣe lè jẹ́ ẹ̀bùn? Báwo sì ni àwọn Kristẹni tí kò ṣègbéyàwó ṣe lè lo ẹ̀bùn wọn lọ́nà tó dára jù lọ?
Ẹ̀bùn Àrà Ọ̀tọ̀
3. Àǹfààní wo ni àwọn Kristẹni tí kò ṣègbéyàwó sábà máa ń gbádùn?
3 Ẹni tí kò ṣègbéyàwó sábà máa ń ní àkókò tó pọ̀ ju ti àwọn lọ́kọláya, ó sì tún máa ń ní òmìnira jù wọ́n lọ. (1 Kọ́r. 7:32-35) Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ lèyí jẹ́, torí pé ó máa jẹ́ kó lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, kó máa fìfẹ́ hàn sí àwọn míì, kó sì túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Torí náà, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ló ti wá mọyì àwọn àǹfààní tó wà nínú wíwà láìṣègbéyàwó, wọ́n sì ti pinnu láti “wá àyè fún un,” bó tiẹ̀ jẹ́ fún àkókò díẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan fẹ́ láti ṣègbéyàwó, àmọ́ nígbà tí wọn kò rí ọkọ tàbí aya tàbí tí wọn kò ní ọkọ tàbí aya mọ́, wọ́n tún ipò ara wọn gbé yẹ̀ wò tàdúràtàdúrà, wọ́n sì wá rí i pé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà àwọn lè wà láìní ọkọ tàbí aya. Nípa bẹ́ẹ̀ wọ́n fara mọ́ ipò tí wọ́n bá ara wọn, wọ́n sì ń bá a lọ láìní ọkọ tàbí aya.—1 Kọ́r. 7:37, 38.
4. Kí nìdí tí àwọn Kristẹni tí kò ṣègbéyàwó kò fi gbọ́dọ̀ máa ronú pé Ọlọ́run kò mọyì iṣẹ́ ìsìn àwọn?
4 Àwọn Kristẹni tí kò ṣègbéyàwó mọ̀ pé kò dìgbà táwọn bá ní ọkọ tàbí aya kí Jèhófà tàbí ètò rẹ̀ tó mọyì àwọn. Ọlọ́run fẹ́ràn gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. (Mát. 10:29-31) Kò sí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni tó lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run. (Róòmù 8:38, 39) Yálà a ṣègbéyàwó tàbí a kò ṣègbéyàwó, ìdí púpọ̀ wà tó fi yẹ ká gbà pé Ọlọ́run mọyì iṣẹ́ ìsìn wa.
5. Tá a bá fẹ́ gba èrè kíkún lọ́dọ̀ Jèhófà torí pé a wà láìní ọkọ tàbí aya, kí la gbọ́dọ̀ ṣe?
5 Àwọn tó ní ẹ̀bùn orin kíkọ tàbí eré ìdárayá máa ń sapá láti mú ẹ̀bùn náà sunwọ̀n sí i. Bíi tiwọn, ó gba ìsapá kéèyàn tó lè lo ẹ̀bùn wíwà láìní ọkọ tàbí aya lọ́nà tó dára jù lọ. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo làwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin tí wọ́n wà láìní ọkọ tàbí aya ṣe lè fi ìgbésí ayé wọn ṣe ohun tó dára jù lọ, yálà wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ tàbí wọ́n ti dàgbà, yálà wọ́n pinnu láti wà bẹ́ẹ̀ tàbí wọ́n bára wọn nírú ipò bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ tí ń gbéni ró látinú ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní yẹ̀ wò, ká sì wo ohun tá a lè rí kọ́ lára wọn.
Àwọn Ọ̀dọ́ Tí Kò Ṣègbéyàwó
6, 7. (a) Àǹfààní iṣẹ́ ìsìn wo ni àwọn ọmọbìnrin Fílípì tí wọ́n jẹ́ wúńdíá rí gbà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run? (b) Báwo ni Tímótì ṣe lo àwọn ọdún tó fi wà ní àpọ́n lọ́nà rere, ìbùkún wo ló sì rí gbà torí pé ó fínnúfíndọ̀ sin Jèhófà nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́?
6 Fílípì ajíhìnrere ní àwọn ọmọbìnrin mẹ́rin tí wọ́n jẹ́ wúńdíá, wọ́n sì ní ìtara bíi ti bàbá wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìjíhìnrere. (Ìṣe 21:8, 9) Sísọ tẹ́lẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́ mú kó ṣeé ṣe, àwọn ọmọbìnrin yìí sì lo ẹ̀bùn yẹn ní ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ inú Jóẹ́lì 2:28, 29.
7 Ọ̀dọ́kùnrin náà, Tímótì lo ìgbà àpọ́n rẹ̀ lọ́nà rere. Láti ìgbà ọmọdé jòjòló ni ìyá rẹ̀ Yùníìsì àti ìyá rẹ̀ àgbà Lọ́ìsì ti kọ́ ọ ní “ìwé mímọ́.” (2 Tím. 1:5; 3:14, 15) Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà tí Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ ṣèbẹ̀wò sí Lísírà tó jẹ́ ìlú ìbílẹ̀ wọn ní nǹkan bí ọdún 47 Sànmánì Kristẹni, ni wọ́n di Kristẹni. Ní ọdún méjì lẹ́yìn náà, nígbà ìbẹ̀wò ẹlẹ́ẹ̀kejì tí Pọ́ọ̀lù ṣe síbẹ̀, Tímótì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ogún ọdún tàbí kó lé díẹ̀ lọ́mọ ogún ọdún. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣì kéré lọ́jọ́ orí àti nínú òtítọ́, àwọn alàgbà ìjọ tó wà ní Lísírà àti Íkóníónì tó wà nítòsí ibẹ̀ “ròyìn rẹ̀ dáadáa.” (Ìṣe 16:1, 2) Torí náà, Pọ́ọ̀lù yan Tímótì kó lè máa bá òun rìnrìn àjò. (1 Tím. 1:18; 4:14) A kò lè sọ dájú pé Tímótì kò ṣègbéyàwó. Ṣùgbọ́n a mọ̀ pé gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́kùnrin, ó gbà láti máa bá Pọ́ọ̀lù rìnrìn-àjò, ó ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ó sì gbádùn iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì tó jẹ́ àpọ́n àti alábòójútó.—Fílí. 2:20-22.
8. Kí ló ran Jòhánù Máàkù lọ́wọ́ kó bàa lè lépa àwọn àfojúsùn tẹ̀mí, àwọn ìbùkún wo ló sì rí gbà nítorí èyí?
8 Nígbà tí Jòhánù Máàkù wà ní ọ̀dọ́, òun pẹ̀lú lo àwọn ọdún tó fi wà ní àpọ́n lọ́nà rere. Òun àti Màríà tó jẹ́ ìyá rẹ̀ àti Bánábà tó jẹ́ ìbátan rẹ̀ wà lára àwọn tó kọ́kọ́ dara pọ̀ mọ́ ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Ó ṣeé ṣe kí nǹkan rọ̀ ṣọ̀mù fún ìdílé Máàkù, torí pé wọ́n ní ilé tiwọn nínú ìlú yẹn, wọ́n sì ní ìránṣẹ́ kan. (Ìṣe 12:12, 13) Síbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àǹfààní tí Máàkù ní nígbà tó wà ní ọ̀dọ́ yìí, kò fi ìgbádùn kẹ́ ara rẹ̀ bà jẹ́ tàbí kó gbájú mọ́ ọ̀ràn ti ara rẹ̀ nìkan; kò sì dà bíi pé ó tẹ́ ẹ lọ́rùn pé kó wulẹ̀ gbéyàwó kó sì ní ìdílé tirẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé mímọ̀ tó ti mọ àwọn àpọ́sítélì láti kékeré ló mú kó fẹ́ láti ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Torí náà, inú rẹ̀ dùn láti dara pọ̀ mọ́ Pọ́ọ̀lù àti Bánábà nígbà ìrìn àjò wọn àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì, ó sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́. (Ìṣe 13:5) Lẹ́yìn náà, ó bá Bánábà rìnrìn àjò, nígbà tó sì tún ṣe, ó wà pẹ̀lú Pétérù ní Bábílónì. (Ìṣe 15:39; 1 Pét. 5:13) A kò mọ bó ṣe pẹ́ tó tí Máàkù fi wà nípò àpọ́n. Àmọ́, wọ́n ròyìn rẹ̀ ní rere pé ó máa ń fẹ́ láti ṣèránṣẹ́ fún àwọn míì, ó sì máa ń fẹ́ láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.
9, 10. Àǹfààní wo làwọn ọ̀dọ́ tí kò tíì ṣègbéyàwó ní lónìí láti fi mú iṣẹ́ ìsìn wọn gbòòrò sí i? Fúnni ní àpẹẹrẹ.
9 Bákan náà lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ nínú ìjọ ń fínnúfíndọ̀ lo àwọn ọdún tí wọ́n fi wà láìṣègbéyàwó láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Bíi ti Máàkù àti Tímótì, wọ́n mọrírì rẹ̀ pé wíwà láìṣègbéyàwó mú kó ṣeé ṣe fún àwọn láti máa ‘ṣiṣẹ́sin Olúwa nígbà gbogbo láìsí ìpínyà-ọkàn.’ (1 Kọ́r. 7:35) Àǹfààní gidi lèyí jẹ́. Onírúurú ọ̀nà làwọn tí kò ṣègbéyàwó lè gbà sin Jèhófà, wọ́n lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, kí wọ́n sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i, kí wọ́n kọ́ èdè ilẹ̀ òkèèrè, kí wọ́n lọ́wọ́ nínú kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí kíkọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì, kí wọ́n lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ tàbí kí wọ́n lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Bó o bá ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ tí kò tíì ṣègbéyàwó, ǹjẹ́ ò ń lo ẹ̀bùn tó o ní yìí lọ́nà tó dára jù lọ?
10 Kí arákùnrin kan tó ń jẹ́ Mark tó pé ọmọ ogún ọdún ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, lẹ́yìn náà ó lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, ó sì ti sìn ní onírúurú ibi káàkiri ayé. Lẹ́yìn tó ti lo ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, ó sọ pé: “Mo ti gbìyànjú láti jẹ́ orísun ìṣírí fún gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ, mo máa ń bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, mo máa ń ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ wọn, mo máa ń pè wọ́n wá jẹun nílé mi, mo sì máa ń pe àwọn àpèjẹ tó máa fún wa láǹfààní láti gbé ara wa ró. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ti mú kí n láyọ̀ gan-an.” Ọ̀rọ̀ Mark yìí fi hàn pé, èèyàn máa ń rí ayọ̀ tó pọ̀ jù lọ nínú fífúnni, téèyàn bá sì lo gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ó máa túbọ̀ láǹfààní láti ṣàjọpín ọ̀pọ̀ nǹkan pẹ̀lú àwọn èèyàn. (Ìṣe 20:35) Láìka ohun yòówù kó o nífẹ̀ẹ́ láti máa ṣe sí, òye iṣẹ́ yòówù kó o ní, tàbí ìrírí yòówù kó o ti ní nípa ìgbésí ayé, ó dájú pé púpọ̀ ṣì wà fún àwọn tó jẹ́ ọ̀dọ́ lónìí láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa.—1 Kọ́r. 15:58.
11. Àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn má ṣe kánjú ṣègbéyàwó?
11 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bópẹ́ bóyá èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ọ̀dọ́ ló máa fẹ́ láti ṣègbéyàwó, ìdí púpọ̀ wà tí wọn kò fi gbọ́dọ̀ kánjú ṣègbéyàwó. Pọ́ọ̀lù gba àwọn ọ̀dọ́ níyànjú pé bó ti wù kó rí, kí wọ́n dúró di àkókò tí “ìgbà ìtànná òdòdó èwe” bá kọjá, ìyẹn ìgbà tí ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ máa ń lágbára jù lọ. (1 Kọ́r. 7:36) O nílò àkókò láti fi mọ ohun tó o fẹ́ àti ohun tí o kò fẹ́ àti láti ní ìrírí nípa ìgbésí ayé, èyí tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti yan ọkọ tàbí aya tó tẹ́ ẹ lọ́rùn. Ohun pàtàkì ni ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó, ńṣe ló yẹ kó so tọkọtaya pọ̀ ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá fi wà láàyè.—Oníw. 5:2-5.
Àwọn Àgbàlagbà Tí Kò Ní Ọkọ Tàbí Aya
12. (a) Kí ni Ánà tó jẹ́ opó ṣe nígbà tí ipò nǹkan yí pa dà fún un? (b) Àǹfààní wo ló ní?
12 Ó ṣeé ṣe kí Ánà tí Ìhìn Rere Lúùkù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ banú jẹ́ gidigidi nígbà tí ọkọ rẹ̀ ṣàdédé kú ní ọdún keje lẹ́yìn tí wọ́n ṣègbéyàwó. A kò mọ̀ bóyá wọ́n bímọ tàbí bóyá Ánà tiẹ̀ ronú àtiní ọkọ míì. Àmọ́, Bíbélì sọ pé Ánà ṣì jẹ́ opó lẹ́yìn tó ti pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [84]. Ohun tí Bíbélì sọ jẹ́ ká mọ̀ pé nígbà tí ipò nǹkan yí pa dà fún Ánà, ńṣe ló túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ánà “kì í pa wíwà ní tẹ́ńpìlì jẹ, [ó] ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ lóru àti lọ́sàn-án pẹ̀lú ààwẹ̀ àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀.” (Lúùkù 2:36, 37) Ó dájú nígbà náà pé ìjọsìn Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Ìyẹn gba ìpinnu àtọkànwá àti ìsapá, àmọ́ Jèhófà bù kún un lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó láǹfààní láti rí ọmọdé jòjòló náà, Jésù, ó sì sọ fún àwọn míì nípa ìdáǹdè tí Mèsáyà náà máa tó mú wá.—Lúùkù 2:38.
13. (a) Kí ló fi hàn pé Dọ́káàsì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ rere nínú ìjọ? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe san èrè oore àti inú rere Dọ́káàsì fún un?
13 Obìnrin kan tó ń jẹ́ Dọ́káàsì tàbí Tàbítà, ń gbé ní Jópà, ibùdókọ̀ òkun tó wà ní àríwá ìwọ̀ oòrùn Jerúsálẹ́mù. Níwọ̀n bí Bíbélì kò ti sọ̀rọ̀ nípa ọkọ rẹ̀, ó ṣeé ṣe kó máà tíì lọ́kọ nígbà yẹn. Dọ́káàsì “pọ̀ gidigidi nínú àwọn iṣẹ́ rere àti àwọn ẹ̀bùn àánú.” Ó dájú pé ó ṣe ọ̀pọ̀ aṣọ fún àwọn òpó tó jẹ́ aláìní àtàwọn míì, èyí sì mú kí wọ́n fẹ́ràn rẹ̀ gan-an. Torí náà, nígbà tó ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ àìsàn tó sì kú, gbogbo ìjọ ránṣẹ́ sí Pétérù wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé kó bá àwọn jí arábìnrin ọ̀wọ́n náà dìde. Bí àwọn èèyàn ṣe ń gbọ́ nípa àjíǹde náà jákèjádò Jópà, ọ̀pọ̀ di onígbàgbọ́. (Ìṣe 9:36-42) Nítorí inú rere Dọ́káàsì tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ó ṣeé ṣe kí òun náà ti ran díẹ̀ lára wọn lọ́wọ́.
14. Kí ló ń mú káwọn Kristẹni tí kò ṣègbéyàwó túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?
14 Bíi ti Ánà àti Dọ́káàsì, ọ̀pọ̀ ló wà nínú ìjọ lónìí tí wọ́n ti dàgbà, àmọ́ tí wọn kò ní ọkọ tàbí aya. Ó lè jẹ́ pé ńṣe làwọn kan kò rí ọkọ tàbí aya tó tẹ́ wọn lọ́rùn. Àwọn míì kọra wọn sílẹ̀ tàbí kí ọkọ tàbí aya wọ́n kú. Níwọ̀n bí àwọn Kristẹni tí kò ní ọkọ tàbí aya kò ti ní ẹnì kejì tí wọ́n lè finú hàn, ó máa ń mú kí wọ́n túbọ̀ gbára lé Jèhófà. (Òwe 16:3) Arábìnrin Silvia tí kò lọ́kọ tó sì ti sìn ní Bẹ́tẹ́lì fún ọdún méjìdínlógójì [38] rí wíwà láìṣègbéyàwó gẹ́gẹ́ bí ìbùkún. Ó sọ pé: “Nígbà míì ó máa ń sú mi láti máa gba tàwọn míì rò. Mo sì máa ń ṣe kàyéfì pé, ‘Ta ló máa fún èmi náà ní ìṣírí?’” Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Bí mo ṣe ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà mọ ohun tí mo nílò ju èmi fúnra mi lọ máa ń mú kí n túbọ̀ sún mọ́ ọn. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń rí ìṣírí gbà, nígbà míì ó máa ń wá láti ibi tí mi ò fọkàn sí.” Gbogbo ìgbà tá a bá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ó máa ń gbọ́ tiwa lọ́nà tó máa fi wá lọ́kàn balẹ̀.
15. Báwo ni àwọn Kristẹni tí kò ṣègbéyàwó ṣe lè mú kí ìfẹ́ wọn “gbòòrò síwájú”?
15 Wíwà láìṣègbéyàwó máa ń fúnni láǹfààní àrà ọ̀tọ̀ láti mú kí ìfẹ́ ẹni “gbòòrò síwájú.” (Ka 2 Kọ́ríńtì 6:11-13.) Arábìnrin Jolene tí kò lọ́kọ, tó ti lo ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [34] lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, sọ pé: “Mo ti ṣiṣẹ́ kára láti ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú àwọn èèyàn ní ọlọ́kan-ò-jọ̀kan, láìka ọjọ́ orí wọn sí. Wíwà láìṣègbéyàwó máa fún ẹ láǹfààní láti lo ẹ̀bùn tó o ní fún Jèhófà, àwọn tẹ́ ẹ jọ wà nínú ìdílé, àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ, àtàwọn aládùúgbò rẹ pẹ̀lú. Bí mo ṣe ń dàgbà sí i ni mo túbọ̀ ń láyọ̀ pé mi ò lọ́kọ.” Ó dájú pé àwọn àgbàlagbà, àwọn aláìlera, àwọn òbí anìkàntọ́mọ, àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn mìíràn nínú ìjọ mọrírì bí àwọn tí kò ṣègbéyàwó ṣe ń tì wọ́n lẹ́yìn torí pé ọ̀rọ̀ àwọn míì jẹ wọ́n lógún. Kò sí iyè méjì pé nígbàkigbà tá a bá fìfẹ́ hàn sáwọn míì, inú àwa náà máa dùn. Ṣé ìwọ náà lè jẹ́ kí ìfẹ́ tó o ní sáwọn ẹlòmíì “gbòòrò síwájú”?
Àwọn Tó Pinnu Láti Wà Láìṣègbéyàwó
16. (a) Kí nìdí tí Jésù kò fi láya? (b) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fọgbọ́n lo àkókò tó fi wà láìní aya?
16 Jésù kò láya; ó ní láti múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ ti Baba rẹ̀ yàn fún un kó sì ṣe iṣẹ́ náà. Ó rìnrìn àjò lọ sí ibi tó pọ̀, ó ṣiṣẹ́ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀, ó sì fi ìwàláàyè rẹ̀ rúbọ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Bó ṣe wà láìní aya mú kó rọrùn fún un láti ṣe gbogbo ohun tó ṣe. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà, ó sì dojú kọ ìnira ńláǹlà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. (2 Kọ́r. 11:23-27) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù ti níyàwó rí, ó yàn láti wà láìní aya lẹ́yìn tó di àpọ́sítélì. (1 Kọ́r. 7:7; 9:5) Jésù àti Pọ́ọ̀lù gba àwọn tó bá ṣeé ṣe fún níyànjú láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn nítorí iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Àmọ́, wọn kò sọ pé àfi kéèyàn jẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé kó tó lè jẹ́ òjíṣẹ́ Ọlọ́run.—1 Tím. 4:1-3.
17. Báwo làwọn kan lónìí ṣe tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù àti Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀, kí sì nìdí tó fi lè dá wa lójú pé Jèhófà mọrírì àwọn tó bá ṣe irú ìrúbọ bẹ́ẹ̀?
17 Bákan náà lónìí, àwọn kan ti mọ̀ọ́mọ̀ pinnu pé àwọn kò ní ṣègbéyàwó kí wọ́n lè túbọ̀ gbájú mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Harold tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí ti lo ohun tó lé ní ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta [56] ní Bẹ́tẹ́lì. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo fi máa pé ọdún mẹ́wàá ní Bẹ́tẹ́lì, mo kíyè sí i pé ọ̀pọ̀ àwọn tọkọtaya ló ti fi Bẹ́tẹ́lì sílẹ̀ nítorí àìsàn tàbí kí wọ́n lè lọ tọ́jú àwọn òbí wọn tó ti dàgbà. Àwọn òbí mi méjèèjì ti kú, mo sì fẹ́ràn iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì débi pé mi ò fẹ́ ṣègbéyàwó kó má bàa gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn yìí lọ́wọ́ mi.” Bákan náà, ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, Arábìnrin Margaret tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àǹfààní ló ti ṣí sílẹ̀ fún mi láti lọ́kọ, mi ò kàn lo àwọn àǹfààní yẹn ni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ti ṣeé ṣe fún mi láti lo àfikún òmìnira tí mo ní torí pé mi ò lọ́kọ láti mú kí ọwọ́ mi dí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, èyí sì ti mú kí n láyọ̀ gan-an.” Ó dájú pé Jèhófà kò ní gbàgbé àwọn tó bá jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn míì jẹ wọ́n lógún débi tí wọ́n fi yááfì àwọn nǹkan kan torí ìjọsìn tòótọ́.—Ka Aísáyà 56:4, 5.
Lo Ẹ̀bùn Rẹ Lọ́nà Tó Dára Jù Lọ
18. Báwo làwọn míì ṣe lè máa fún àwọn Kristẹni tí kò ṣègbéyàwó ní ìṣírí kí wọ́n sì máa tì wọ́n lẹ́yìn?
18 Ó yẹ ká máa gbóríyìn látọkànwá fún gbogbo àwọn Kristẹni tí kò ṣègbéyàwó, tí wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ká sì máa fún wọn ní ìṣírí. A nífẹ̀ẹ́ wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, a sì mọrírì ipa ribiribi tí wọ́n ń kó nínú ìjọ. A kò ní jẹ́ kí wọ́n máa rò pé àwọn dá wà bí a bá jẹ́ “àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin àti àwọn ìyá àti àwọn ọmọ” fún wọn ní tòótọ́.—Ka Máàkù 10:28-30.
19. Kí lo lè ṣe kó o lè lo ẹ̀bùn àìṣègbéyàwó rẹ lọ́nà tó dára jù lọ?
19 Yálà o pinnu láti wà láìní ọkọ tàbí aya tàbí o bá ara rẹ nírú ipò bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ kí àwọn àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ àtàwọn àpẹẹrẹ òde òní tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí mú kó dá ẹ lójú pé o lè gbé ìgbé ayé aláyọ̀ àtèyí tó gbámúṣé. Àwọn ẹ̀bùn kan wà tá a máa ń fojú sọ́nà fún, àwọn ẹ̀bùn kan sì wà tó máa ń jẹ́ ìyàlẹ́nu fún wa torí pé a kò retí wọn. A máa ń tètè mọrírì àwọn ẹ̀bùn kan, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn la sì máa ń mọyì àwọn míì. Torí náà, ojú tá a bá fi wo ẹ̀bùn tá a ní ló ṣe pàtàkì. Báwo lo ṣe lè lo ẹ̀bùn àìṣègbéyàwó rẹ lọ́nà tó dára jù lọ? Túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, máa ní púpọ̀ láti ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, kó o sì jẹ́ kí ìfẹ́ tó o ní sáwọn ẹlòmíì gbòòrò síwájú. Bá a bá ń wo ẹ̀bùn ìgbéyàwó àti wíwà láìní ọkọ tàbí aya bí Ọlọ́run ṣe ń wò ó tá a sì ń fọgbọ́n lo ẹ̀bùn náà, a óò rí i pé méjèèjì ló máa ń mérè wá.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Àwọn ọ̀nà wo ni wíwà láìní ọkọ tàbí aya lè gbà jẹ́ ẹ̀bùn?
• Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ ṣe lè jàǹfààní nínú wíwà láìṣègbéyàwó?
• Àwọn àǹfààní wo ni àwọn Kristẹni tí kò ṣègbéyàwó ní láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà kí wọ́n sì mú ìfẹ́ wọn gbòòrò sí i?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ṣé ò ń lo àwọn àǹfààní tó o ní láti ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run lọ́nà tó dára jù lọ?