Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
KÍ LÓ mú kí àgbẹ̀ kan tó ń gbin tábà fi iṣẹ́ yẹn sílẹ̀, tó sì tún yí ẹ̀sìn tó fẹ́ràn gan-an tẹ́lẹ̀ pa dà? Kí ló ran obìnrin kan tó jẹ́ ọ̀mùtí lọ́wọ́ tó fi lè yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà? Gbọ́ ohun tí wọ́n sọ.
“Inú mi dùn gan-an pé mo jẹ́ ara ìdílé ńlá yìí.”—DINO ALI
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1949
ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: ỌSIRÉLÍÀ
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ÀGBẸ̀ TÓ Ń GBIN TÁBÀ NI MÍ
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ọmọ orílẹ̀-èdè Alibéníà ni àwọn òbí mi, àmọ́ lọ́dún 1939, wọ́n kó lọ sí ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Mareeba ní ìpínlẹ̀ Queensland lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Ọ̀pọ̀ àwọn ará ilẹ̀ Bosnia, Gíríìsì, Ítálì àti Serbia àtàwọn míì náà tẹ̀ dó síbẹ̀, kálukú ló ní ìlànà ìwà híhù, ìṣe àti àṣà ìbílẹ̀ tirẹ̀. Tábà làwọn èèyàn sábà máa ń gbin ní gbogbo àgbègbè ìlú Mareeba, nítorí náà, àwọn òbí mi bẹ̀rẹ̀ sí í dá oko tábà.
Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, wọ́n bí ẹ̀gbọ́n mi obìnrin, wọ́n tún bí ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin méjèèjì, wọ́n sì wá bí èmi náà. Àmọ́, ó dùn mí pé, nígbà tí mo di ọmọ ọdún kan, àrùn ọkàn pa bàbá mi. Màmá mi wá fẹ́ ọkọ míì, ó sì bí ọmọkùnrin mẹ́rin fún un. Iṣẹ́ oko tábà ọkùnrin yẹn ni gbogbo wa jọ ń ṣe títí tá a fi dàgbà.
Mi ò tíì pé ọmọ ogún [20] ọdún tí mo fi kúrò nílé. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún [23], èmi àti Saime ṣègbéyàwó ní mọ́ṣáláṣí kan ládùúgbò wa, torí pé Mùsùlùmí ni àwa méjèèjì. Mùsùlùmí náà ni gbogbo mọ̀lẹ́bí mi. Mo ka Kùránì, mo sì ka ìwé kan tó sọ ìtàn òjíṣẹ́ náà, Mọ̀ọ́mọ́dù. Mo tún ka Bíbélì kékeré kan nígbà yẹn. Kùránì sọ̀rọ̀ nípa àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run kan, èyí tí Bíbélì sọ ìtàn wọn, Bíbélì tí mo kà sì jẹ́ kí n mọ ìgbà tí wọ́n gbé ayé.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wá sí ilé mi déédéé láti fún mi ní àwọn ìwé ìròyìn àti ìwé ńlá wọn. Èmi àti Saime máa ń kà wọ́n, a sì máa ń gbádùn wọn. Mo rántí bí èmi àti àwọn Ẹlẹ́rìí yẹn ṣe jọ máa ń jíròrò onírúurú ìbéèrè lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn pa pọ̀. Ní gbogbo ìgbà tá a bá ń jíròrò, ohun tó wà nínú Bíbélì ni wọ́n fi máa ń dáhùn àwọn ìbéèrè mi, dípò kí wọ́n máa sọ èrò orí tiwọn. Ìyẹn jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn túbọ̀ wọ̀ mí lọ́kàn gan-an.
Àwọn Ẹlẹ́rìí yẹn máa ń sọ pé àwọn fẹ́ kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì tún máa ń sọ pé kí n wá sí ìpàdé àwọn, ṣùgbọ́n mi ò kì í gbà. Ohun tó ṣáà jẹ mí lógún ni bí mo ṣe máa ní oko tábà témi kí n sì ní ìdílé ńlá. Lóòótọ́, kò ṣeé ṣe fún mi láti ní oko tèmi fúnra mi, àmọ́ inú mi dùn pé mo bí ọmọ márùn-ún tí mo fẹ́ràn gidigidi.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Ọdún mẹ́sàn-án lẹ́yìn ìgbà tí mo kọ́kọ́ bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé, mo ṣì ń bá ẹ̀sìn tí mo ń ṣe lọ. Ṣùgbọ́n, mo máa ń ka gbogbo ìwé tí wọ́n ń fún mi, mo sì ń gbádùn rẹ̀ gan-an. Ọjọọjọ́ Sunday ni èmi àti Saime máa ń fara balẹ̀ ka ìwé wọ̀nyẹn. Gbogbo ìwé ìròyìn wọn tí à ń gbà ní gbogbo ìgbà yẹn ni a tọ́jú pa mọ́. Àwọn ìwé ìròyìn yẹn ràn mí lọ́wọ́ gan-an nígbà táwọn èèyàn kan fẹ́ dán ìgbàgbọ́ mi tí kò tíì jinlẹ̀ wò.
Bí àpẹẹrẹ, ajíhìnrere kan láti ṣọ́ọ̀ṣì kan ń fúngun mọ́ mi pé àfi kí n gba Jésù ní Olùgbàlà mi. Ó ṣẹlẹ̀ pé ó ti yí àbúrò Saime kan tó jẹ́ ọkùnrin àti àwọn àbúrò mi kan tó jẹ́ ọmọ ìyá mi lọ́kàn pa dà, wọ́n sì ti ń tẹ̀ lé e lọ ṣọ́ọ̀ṣì. Kò sì pẹ́ tí àwọn ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ mi tí wọ́n ń ṣe onírúurú ẹ̀sìn fi bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ mí pé kí n wá máa ṣe ẹ̀sìn àwọn. Àwọn míì lára wọn tiẹ̀ fún mi ní ìwé kan tó ta ko ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo ní kí àwọn tó ń ta ko ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹn fi ibi tí àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn tiwọn wà nínú Bíbélì hàn mí, àmọ́ wọn ò lè dáhùn àwọn ìbéèrè mi.
Ṣe ni gbogbo àwọn àtakò yìí ń mú kí n túbọ̀ ṣèwádìí jinlẹ̀ nínú Bíbélì àti nínú àwọn ìtẹ̀jáde tí mo gbà lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí yẹn. Níkẹyìn, mo rí i pé àkókò tó wàyí kí n ṣiṣẹ́ lórí ohun tí mò ńkọ́, kí n ṣe àwọn àyípadà tó yẹ.
Kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan tó kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, fúnra mi ni mo kàn bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé wọn. Lákọ̀ọ́kọ́, àyà mi máa ń já, ojú sì máa ń tì mí, ṣùgbọ́n mo rí i pé ara àwọn tó wà níbẹ̀ yọ̀ mọ́ èèyàn dáadáa, mo sì tún ń gbádùn ohun tí mo ń kọ́. Ni mo bá pinnu pé èmi náà fẹ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo sì ṣe ìrìbọmi lọ́dún 1981 láti fi hàn pé mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún Ọlọ́run.
Ìyàwó mi kò ta kò mí bí mo ṣe di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó máa ń bi mí pé ṣe kì í ṣe pé wọ́n kàn ń tàn mí jẹ? Síbẹ̀síbẹ̀, ó wá sí ibi tí mo ti ṣe ìrìbọmi. Èmi náà sì ń bá a lọ láti máa ṣàlàyé ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí mò ń kọ́ fún un. À ń ti ìrìn àjò bọ̀ lọ́jọ́ kan, lẹ́yìn nǹkan bí ọdún kan tí mo ti ṣe ìrìbọmi, ni Saime bá sọ fún mi pé òun náà fẹ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ẹnu yà mí débi pé díẹ̀ ló kù kí n yí ọwọ́ ọkọ̀ tí mò ń wà wọgbó! Ó sì ṣe ìrìbọmi lọ́dún 1982.
Kò rọrùn rárá láti ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ ní ìgbésí ayé wa. Mi ò dá oko tábà mọ́ nítorí pé kò bá ìlànà Bíbélì mu. (2 Kọ́ríńtì 7:1; Jákọ́bù 2:8) Ó wá pẹ́ díẹ̀ ká tó rí iṣẹ́ tó bójú mu, tí á máa mówó wọlé fún wa déédéé. Bákan náà, ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn mọ̀lẹ́bí wa kan fi pa wá tì, wọn kì í dé ọ̀dọ̀ wa. Àmọ́ ní tiwa, à ń fi ìfẹ́ bá wọn lò bí ìlànà Bíbélì ṣe ní ká máa ṣe. Nígbà tó yá, inú àwọn mọ̀lẹ́bí wa bẹ̀rẹ̀ sí í yọ́ sí wa, wọn kò sì pa wá tì mọ́.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Onírúurú ìṣòro tí mo ní ti jẹ́ kí n rí bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe mú sùúrù fún mi tó sì ràn mí lọ́wọ́ kí n lè borí àwọn ìṣòro mi, ì bàá jẹ́ ìṣòro bí mo ṣe máa ń tijú, àníyàn nípa bí a ó ṣe máa rí owó gbọ́ bùkátà, àti àtakò látọ̀dọ̀ àwọn ẹbí mi. Bí àpẹẹrẹ, mo ti di alàgbà ìjọ, mo sì ní láti máa kọ́ni látorí pèpéle. Èyí kò rọrùn fún mi rárá nítorí pé akólòlò ni mí, tí àyà mi bá sì ti ń já, máa bẹ̀rẹ̀ sí í kólòlò. Àmọ́ lọ́lá àdúrà àti ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, mò ń ṣe ojúṣe mi lẹ́nu iṣẹ́ náà.
Èmi àti aya mi túbọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ gan-an, ọ̀rọ̀ wa sì wọ̀ dọ́ba. Lóòótọ́, a ṣe àwọn àṣìṣe nígbà tí a ń tọ́ àwọn ọmọ wa, àmọ́ a sa gbogbo ipá wa láti gbin ẹ̀kọ́ Bíbélì tí a kọ́ sí wọn lọ́kàn. (Diutarónómì 6:6-9) Kódà, míṣọ́nnárì, tó ń ṣiṣẹ́ Ọlọ́run nílẹ̀ òkèèrè, ni ọmọkùnrin mi àgbà àti ìyàwó rẹ̀.
Mo rántí ọjọ́ kan láìpẹ́ sí ìgbà tí èmi àti ìdílé mi bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pa pọ̀. Mo wa ọkọ̀ dé ibi ìgbọ́kọ̀sí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, mo sì wo àwọn èrò tó ń wọnú gbọ̀ngàn náà. Mo wá bi ìdílé mi pé, “Ṣé ẹ̀yin náà ń rí i?” Onírúurú àwọn èèyàn, àti olówó àti tálákà, láti onírúurú èdè àti ẹ̀yà, irú bí àwọn Ọmọ Onílẹ̀ Ọsirélíà, àwọn ará Alibéníà, Ọsirélíà àti àwọn ará Croatia wà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba náà, tí gbogbo wọn jọ ń fi ọ̀yàyà kí ara wọn bí ọmọ ìyá. Inú mi dùn gan-an pé mo jẹ́ ara ìdílé ńlá yìí, tí mo wà lára àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí ẹ̀sìn Ọlọ́run sọ di ẹgbẹ́ ará, tí kò mọ sí ilẹ̀ Ọsirélíà nìkan, ṣùgbọ́n tó kárí ayé.—1 Pétérù 5:9.
“Ẹ̀gbọ́n mi kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi sú òun.”—YELENA VLADIMIROVNA SYOMINA
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1952
ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: RỌ́SÍÀ
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ỌTÍ MÍMU DI BÁRAKÚ FÚN MI, MO GBÌYÀNJÚ LÁTI PARA MI
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ìlú Krasnogorsk, tó jẹ́ ìlú kékeré kan tó tura nítòsí ìlú Moscow ni wọ́n bí mi sí. Olùkọ́ ilé ìwé ni bàbá àti ìyá mi. Mo ń ṣe dáadáa gan-an nílé ìwé, mo sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa orin. Ó sì dà bíi pé nǹkan máa ṣẹnuure fún mi lọ́jọ́ iwájú.
Nígbà tí mo lọ́kọ, èmi àti ọkọ mi kó lọ sí àdúgbò kan tí ìmutípara, sìgá mímu àti èpè ṣíṣẹ́ ti wọ́pọ̀ gan-an. Mi ò fura pé ó lè ràn mí nígbà tá a débẹ̀, àmọ́ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ó ran èmi náà. Níbẹ̀rẹ̀, mo kàn máa ń lọ sí agbo àríyá láti kọrin àti láti fi gìtá dá wọn lára yá. Àmọ́ tí mo bá ti débẹ̀, ṣe ni àwọn èèyàn máa ń fi sìgá àti ọtí mímu lọ̀ mí. Kò sì pẹ́ tí ọtí mímu fi di bárakú fún mi.
Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọtí yìí bẹ̀rẹ̀ sí í bà mí láyé jẹ́. Ó ṣe díẹ̀ kí n tó di ọ̀mùtí paraku, àmọ́ nígbà tí ọtí gbà mí lọ́kàn, mi ò kì í fi bẹ́ẹ̀ jẹun mọ́. Ayé wá sú mi, mo sì gbìyànjú láti para mi. Àmọ́, mo dúpẹ́ pé mi ò rí i ṣe.
Ní gbogbo àsìkò yẹn, ẹ̀gbọ́n mi obìnrin máa ń wá sọ́dọ̀ mi déédéé. Ó ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìgbà yẹn, ó sì gbìyànjú láti jẹ́ kí n mọ bí Bíbélì ṣe lè ràn mí lọ́wọ́. Àmọ́ torí pé mi ò nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì, mi ò jẹ́ kí ẹ̀gbọ́n mi wá mi wá mọ́. Ṣùgbọ́n ẹ̀gbọ́n mi kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi sú òun. Ó fi sùúrù àti ìfẹ́ ràn mí lọ́wọ́, títí mo fi gbà kí ó máa bá mi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo pinnu látọkàn wá láti jáwọ́ nínú ọtí mímu pátápátá. Lásìkò yẹn, ọkùnrin kan tó ti mutí yó bá mi jà, ó sì ṣe mí léṣe. Mo fara pa gan-an, wọ́n sì gbé mi lọ sí ọsibítù. Mẹ́rin nínú eegun ìhà mi ló kán, díẹ̀ ló sì kù kí ojú mi kan fọ́. Àmọ́, ọsibítù tí mo wà lákòókò yẹn jẹ́ kí n lè borí gbogbo ìnira tí jíjáwọ́ nínú ọtí mímu máa ń fà.
Lákòókò yẹn, mo máa ń gbàdúrà lemọ́lemọ́. Ẹsẹ Bíbélì kan tó máa ń tù mí nínú gan-an ni ìwé Ìdárò 3:55, 56. Ó ní: “Mo ti ké pe orúkọ rẹ, Jèhófà, láti inú kòtò irú èyí tí ó jìn jù lọ. Gbọ́ ohùn mi. Má fi etí rẹ pa mọ́ fún ìtura mi, fún igbe mi fún ìrànlọ́wọ́.”
Ó dá mi lójú pé Jèhófà dáhùn àwọn àdúrà mi. Ó sì fún mi lágbára tí kò jẹ́ kí n tún pa dà sínú àwọn ìwà ti mo ń hù tẹ́lẹ̀. Àwọn ìgbà kan wà tó ń ṣe mí bíi pé kí n tún bẹ̀rẹ̀ sí í mutí. Àmọ́ inú mi dùn pé mi ò gba ẹ̀mí yẹn láyè rárá.
Bí mo ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mò ń kọ́, mo rí i pé, ó yẹ kí n máa ti ọkọ mi lẹ́yìn bó ṣe ń ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé. (1 Pétérù 3:1, 2) Èyí kò rọrùn fún mi rárá torí pé ó ti mọ́ mi lára láti máa darí ọkọ mi bó ṣe wù mí. Àmọ́ mo gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́. Ó pẹ́ díẹ̀ kí n tó lè yí ìwà yẹn pa dà, àmọ́ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo dẹni tó ń ti ọkọ mi lẹ́yìn gan-an.
Nígbà tí baálé mi ń rí àwọn àyípadà tí mò ń ṣe yìí, ó yà á lẹ́nu gidigidi. Ní gbogbo ìgbà yẹn, kò nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì rárá. Àmọ́ nígbà tí mo pinnu láti jáwọ́ nínú sìgá mímu, ó sọ fún mi pé: “Bó o bá fi lè jáwọ́ nínú sìgá mímu, èmi náà yóò bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì!” Ọjọ́ kan náà làwa méjèèjì sì jáwọ́ nínú sìgá mímu.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Ọkọ mi mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní báyìí, a jọ ń ka Bíbélì pa pọ̀ lójoojúmọ́, à ń ṣàṣàrò lórí àwọn nǹkan tá à ń kà, a sì ń sapá láti fi àwọn ìmọ̀ràn náà sílò ní ìgbésí ayé wa.
Ìtẹ̀síwájú tó ti bá ìdílé wa kọjá àfẹnusọ, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ bí èmi fúnra mi ṣe ti jàǹfààní tó. Mo dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ Jèhófà tó fà mí wá sọ́dọ̀ rẹ̀. (Jòhánù 6:44) Mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀gbọ́n mi pé kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi sú òun. Èyí ti jẹ́ kí èmi fúnra mi rí i pé Bíbélì máa ń yí ìgbésí ayé ẹni pa dà lóòótọ́.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]
Mo rí i pé àkókò tó wàyí kí n ṣiṣẹ́ lórí ohun tí mò ń kọ́
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]
Ẹ̀gbọ́n mi fi sùúrù àti ìfẹ́ ràn mí lọ́wọ́, títí mo fi gbà kí wọ́n máa bá mi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì