Ẹ Wà Lójúfò Bíi Ti Jésù
“Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà.”—MÁT. 26:41.
BÁWO LO ṢE MÁA DÁHÙN?
․․․․․
Báwo ni àwọn àdúrà wa ṣe lè fi hàn pé a wà lójúfò?
․․․․․
Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé a wà lójúfò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa?
․․․․․
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa wà lójúfò nígbà tá a bá dojú kọ àdánwò, báwo la sì ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
1, 2. (a) Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa bí Jésù ṣe wà lójúfò, àwọn ìbéèrè wo ló lè wá síni lọ́kàn? (b) Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe fún ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀ láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ pípé tí Jésù fi lélẹ̀? Ṣàpèjúwe.
O LÈ máa ṣe kàyéfì pé: ‘Ṣé òótọ́ ni pé ó ṣeé ṣe láti wà lójúfò bíi ti Jésù? Ó ṣe tán, ẹni pípé ni Jésù! Yàtọ̀ síyẹn, ìgbà míì wà tí Jésù máa ń ní òye tó ṣe kedere nípa ọjọ́ iwájú, kódà ó mọ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rún ọdún! Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ pọn dandan pé kí Jésù wà lójúfò?’ (Mát. 24:37-39; Héb. 4:15) Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí ká lè rí bó ṣe bá a mu tó pé ká wà lójúfò àti ìdí tó fi jẹ́ kánjúkánjú.
2 Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe fún ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ látinú àpẹẹrẹ pípé? Bẹ́ẹ̀ ni, torí pé ó ṣeé ṣe láti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ olùkọ́ rere ká sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ọkùnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń ta ọfà. Kò tíì mọ ọfà ta dáadáa, àmọ́ ó ń bá a nìṣó láti máa gba ìdálẹ́kọ̀ọ́, ó sì ń fi ọfà títa dánra wò. Kí ọwọ́ rẹ̀ lè gún, ó ń fara balẹ̀ kíyè sí olùkọ́ rẹ̀ tó jẹ́ ọ̀jáfáfá. Ó máa ń kíyè sí i, ó ń wo bó ṣe máa ń dúró, bó ṣe máa ń gbá ọrun mú àti bó ṣe máa ń fa ọṣán, ìyẹn okùn tín-ín-rín tó máa ń rán ọfà lọ sí ibi tí tafàtafà bá ta á sí. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ yìí mọ bí ọṣán ṣe gbọ́dọ̀ le tantan tó; ó ń kíyè sí bí afẹ́fẹ́ ṣe lè gbé ọfà gba ibòmíràn lọ, ó sì ń bá a nìṣó láti máa sapá. Bó ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ olùkọ́ rẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ á máa gún síwájú àti síwájú sí i títí tó fi máa di atamátàsé. Bíi ti ọkùnrin tó ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń ta ọfà yìí, àwa náà lè máa sunwọ̀n síwájú àti síwájú sí i bá a ṣe ń sapá láti ṣègbọràn sí àwọn ìtọ́ni Jésù tá a sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ pípé tó fi lélẹ̀.
3. (a) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé ó yẹ kí òun wà lójúfò? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Ǹjẹ́ ìdí èyíkéyìí tiẹ̀ wà tí Jésù fi ní láti máa wà lójúfò? Bẹ́ẹ̀ ni. Bí àpẹẹrẹ, ní alẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí Jésù kú, ó rọ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ pé: “Ẹ . . . máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà pẹ̀lú mi.” Ó fi kún un pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ má bàa bọ́ sínú ìdẹwò.” (Mát. 26:38, 41) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé látilẹ̀ wá ni Jésù ti ń wà lójúfò, ó túbọ̀ fẹ́ láti wà lójúfò ní àwọn wákàtí tó nira, èyí tó lò kẹ́yìn kí wọ́n tó pa á, kó sì tún sún mọ́ Baba rẹ̀ ọ̀run bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Ó mọ̀ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun náà gbọ́dọ̀ wà lójúfò nígbà yẹn àti ní ọjọ́ iwájú. Torí náà, ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun tó fà á tí Jésù fi fẹ́ ká wà lójúfò. Lẹ́yìn náà, a máa jíròrò ọ̀nà mẹ́ta tá a lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù ká lè máa wà lójúfò bá a ti ń gbé ìgbé ayé wa ojoojúmọ́.
ÌDÍ TÍ JÉSÙ FI FẸ́ KÁ WÀ LÓJÚFÒ
4. Kí nìdí tó fi yẹ ká wà lójúfò torí àwọn ohun tí a kò mọ̀ nípa ọjọ́ iwájú?
4 Ní kúkúrú, Jésù fẹ́ ká wà lójúfò nítorí ohun tí a kò mọ̀ àti nítorí ohun tá a mọ̀. Nígbà tí Jésù gbé gẹ́gẹ́ bí èèyàn lórí ilẹ̀ ayé, ǹjẹ́ gbogbo ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ló mọ̀? Rárá o. Òun fúnra rẹ̀ tiẹ̀ sọ pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹnì kankan tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba nìkan.” (Mát. 24:36) Nígbà yẹn, Jésù tó jẹ́ “Ọmọ” Ọlọ́run pàápàá kò mọ ìgbà náà gan-an tí òpin ayé búburú yìí máa dé. Àwa tá à ń gbé láyé lónìí ńkọ́? Ṣé àwọn ohun kan wà nípa ọjọ́ iwájú tí a kò mọ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n wà! A kò mọ ìgbà tí Jèhófà máa rán Ọmọ rẹ̀ wá láti fi òpin sí ètò àwọn nǹkan búburú yìí. Tá a bá mọ̀ ọ́n, ǹjẹ́ ó tún máa pọn dandan pé ká máa ṣọ́nà? Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ, òpin máa dé lójijì, nígbà tí a kò rò tẹ́lẹ̀; torí náà ó pọn dandan pé ká máa wà lójúfò ní gbogbo ìgbà.—Ka Mátíù 24:43.
5, 6. (a) Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn ohun tá a mọ̀ nípa ọjọ́ iwájú àti àwọn ètè Ọlọ́run nípa lórí wíwà lójúfò wa? (b) Kí nìdí tí ohun tá a mọ̀ nípa Sátánì fi gbọ́dọ̀ mú ká túbọ̀ wà lójúfò?
5 Ohun mìíràn tún ni pé, Jésù mọ ọ̀pọ̀ ohun àgbàyanu nípa ọjọ́ iwájú, ìyẹn òtítọ́ tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tó wà nígbà yẹn kò mọ̀ rárá. A kò ní ìmọ̀ tó pọ̀ tó ti Jésù, síbẹ̀ òun ló jẹ́ ká mọ ohun tó pọ̀ gan-an nípa Ìjọba Ọlọ́run àti ohun tó máa gbé ṣe lọ́jọ́ iwájú tí kò pẹ́ mọ́. Bá a ti ń kíyè sí àwọn ohun tó ń lọ láyìíká wa, yálà nílé ẹ̀kọ́, níbi iṣẹ́ tàbí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, ǹjẹ́ a kì í rí i pé inú òkùnkùn biribiri ni ọ̀pọ̀ èèyàn tí kò mọ àwọn òtítọ́ ológo yìí wà? Èyí sì tún jẹ́ ìdí mìíràn tá a fi ní láti wà lójúfò. Bíi ti Jésù, a gbọ́dọ̀ máa wà lójúfò nígbà gbogbo, ká sì máa sọ ohun tá a mọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run fáwọn ẹlòmíì nígbàkigbà tá a bá ní àǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀. Irú àǹfààní bẹ́ẹ̀ ṣeyebíye, a kò sì ní fẹ́ láti fi ṣòfò, torí pé ìwàláàyè àwọn èèyàn wà nínú ewu!—1 Tím. 4:16.
6 Jésù tún mọ ohun mìíràn tó mú kóun wà lójúfò. Ó mọ̀ pé Sátánì ti pinnu láti dán òun wò, láti ṣe inúnibíni sí òun, kó sì ba ìdúróṣinṣin òun jẹ́. Gbogbo ìgbà ni ọ̀tá burúkú yẹn ń wá “àkókò mìíràn tí ó wọ̀” láti dán Jésù wò. (Lúùkù 4:13) Jésù kò fìgbà kan dẹ́kun láti máa wà lójúfò. Ó fẹ́ láti wà ní ìmúratán de ìdánwò èyíkéyìí, ì báà jẹ́ àtakò, inúnibíni tàbí ìdẹwò. Ǹjẹ́ bí ọ̀rọ̀ tiwa náà ṣe rí kọ́ nìyẹn? A mọ̀ pé Sátánì ṣì dà “bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.” Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi gba gbogbo Kristẹni níyànjú pé: “Ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyè sára.” (1 Pét. 5:8) Àmọ́, báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
BÍ ÀDÚRÀ ṢE LÈ RÀN WÁ LỌ́WỌ́ LÁTI WÀ LÓJÚFÒ
7, 8. Ìmọ̀ràn wo ni Jésù fún wa nípa àdúrà, irú àpẹẹrẹ wo ló sì fi lélẹ̀?
7 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àdúrà ṣe pàtàkì gan-an ká lè wà lójúfò, kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà má bàa bà jẹ́. (Kól. 4:2; 1 Pét. 4:7) Láìpẹ́ lẹ́yìn tí Jésù ti sọ pé káwọn ọmọlẹ́yìn òun máa ṣọ́nà pẹ̀lú òun, ó ní: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ má bàa bọ́ sínú ìdẹwò.” (Mát. 26:41) Ṣé ìgbà tí wọ́n ń dojú kọ ipò lílekoko yẹn nìkan ni Jésù fẹ́ kí wọ́n fi ìmọ̀ràn yẹn sílò? Rárá o, ìmọ̀ràn náà jẹ́ ìlànà tó yẹ kó máa darí ìgbésí ayé wa lójoojúmọ́.
8 Àpẹẹrẹ àtàtà tí Jésù fi lélẹ̀ jẹ́ ká rí bí àdúrà ti ṣe pàtàkì tó. O lè rántí pé Jésù ti fìgbà kan rí gbàdúrà sí Baba rẹ̀ láti òru mọ́jú. Jẹ́ ká fojú yàwòrán ohun tó ṣẹlẹ̀. (Ka Lúùkù 6:12, 13.) Ó jẹ́ ìgbà ìrúwé, ó sì ṣeé ṣe kí Jésù wà nítòsí ìlú Kápánáúmù táwọn èèyàn ti máa ń pẹja, tó jẹ́ ibi tó máa ń dé sí ní àgbègbè náà. Bó ti ń di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, Jésù lọ sórí ọ̀kan lára àwọn òkè tó wà níbẹ̀ téèyàn ti lè máa rí Òkun Gálílì. Ilẹ̀ ti ń ṣú lọ, bó sì ṣe ń bojú wo ìsàlẹ̀, ó ṣeé ṣe kó rí àwọn iná àtùpà elépo tó ń jó lọ́úlọ́ú nínú àwọn ilé tó wà ní Kápánáúmù àti àwọn abúlé míì tó wà nítòsí. Àmọ́, nígbà tí Jésù ń gbàdúrà sí Jèhófà, ó pa gbogbo ọkàn rẹ̀ pọ̀ sórí àdúrà tó ń gbà. Ọ̀pọ̀ ìṣẹ́jú, àti lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀ wákàtí kọjá lọ. Kò fiyè sí i títí tí àwọn iná tó ń jó lọ́úlọ́ú náà fi kú tán níkọ̀ọ̀kan tàbí tí òṣùpá fi lé sójú sánmà tàbí tí àwọn ẹran afòrujẹ̀ fi bẹ̀rẹ̀ sí í wá oúnjẹ kiri nínú igbó. Ó ṣeé ṣe kí àdúrà rẹ̀ dá lórí ìpinnu ńlá tó wà níwájú rẹ̀ láti ṣe, ìyẹn ni yíyan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá. A lè ronú nípa bí Jésù ṣe ń sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ àti gbogbo ohun tó jẹ ẹ́ lógún nípa ọmọ ẹ̀yìn kọ̀ọ̀kan fún Bàbá rẹ̀ nígbà tó ń fi ìtara bẹ̀ ẹ́ pé kó tọ́ òun sọ́nà kó sì fún òun ní ọgbọ́n.
9. Kí la lè rí kọ́ látinú bí Jésù ṣe gbàdúrà láti òru mọ́jú?
9 Kí la lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Jésù? Ṣé ohun tó ń kọ́ wa ni pé ká máa fi àkókò gígùn gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ gbàdúrà? Rárá o, torí pé ìgbatẹnirò mú kó sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀mí ń háragàgà, ṣùgbọ́n ẹran ara ṣe aláìlera.” (Mát. 26:41) Síbẹ̀, a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ a máa ń gbàdúrà sí Baba wa ọ̀run ká tó ṣe ìpinnu èyíkéyìí tó lè nípa lórí wa, lórí ìdílé wa tàbí lórí àjọṣe àárín àwa àtàwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́? Ǹjẹ́ a máa ń mú ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn nípa àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà? Ǹjẹ́ a máa ń gbàdúrà látọkàn wá dípò ká kàn máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan náà ní àsọtúnsọ? Tún ṣàkíyèsí pé nígbà tí Jésù bá dá wà, ó mọrírì kó máa sọ ohun tó bá wà lọ́kàn rẹ̀ fún Baba rẹ̀. Nínú ayé oníkìràkìtà tí ọwọ́ ti máa ń dí yìí, kì í pẹ́ tí kòókòó jàn-ánjàn-án ìgbésí ayé fi máa ń mú kéèyàn gbàgbé ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ. Tá a bá ń wá àkókò tó pọ̀ tó láti dá gbàdúrà látọkàn wá, á óò túbọ̀ máa wà lójúfò nípa tẹ̀mí. (Mát. 6:6, 7) A máa túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, a óò túbọ̀ fẹ́ kí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú rẹ dára sí i, a ó sì máa sá fún ṣíṣe ohunkóhun tó lè ba àjọṣe náà jẹ́.—Sm. 25:14.
BÁ A ṢE LÈ WÀ LÓJÚFÒ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
10. Àpẹẹrẹ wo ló fi hàn wá bí Jésù ṣe wà lójúfò láti lo àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ láti wàásù?
10 Jésù wà lójúfò lẹ́nu iṣẹ́ tí Jèhófà gbé lé e lọ́wọ́. Àwọn iṣẹ́ kan lè wà tó gba kí ọkàn òṣìṣẹ́ máa rìn gbéregbère láìsí àbájáde búburú kankan. Àmọ́, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ló gba kéèyàn pọkàn pọ̀ kó sì wà lójúfò, bí iṣẹ́ ìwàásù wa sì ṣe rí nìyẹn. Gbogbo ìgbà ni Jésù máa ń wà lójúfò bó ṣe ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀, ó sì máa ń wá bó ṣe máa wàásù ìhìn rere. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dé ìlú Síkárì, lẹ́yìn tí wọ́n ti rìnrìn àjò gígùn ní òwúrọ̀ ọjọ́ náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ ra oúnjẹ. Jésù dúró ní itòsí kànga tó wà ní ìlú náà kó lè sinmi, àmọ́ ó wà lójúfò, àǹfààní sì ṣí sílẹ̀ fún un láti wàásù. Obìnrin ará Samáríà kan wá sí ìdí kànga náà láti wá fa omi. Jésù lè yàn nígbà yẹn láti lọ fi oorun rajú. Ó lè ronú pé ìdí púpọ̀ wà tí òun kò fi fẹ́ láti bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀. Àmọ́, kò panu mọ́, ó bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú obìnrin náà, ó sì jẹ́rìí fún un tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀rọ̀ tó gbọ́ fi nípa lórí rẹ̀ àti lórí ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn tó ń gbé nínú ìlú náà. (Jòh. 4:4-26, 39-42) Ṣé àwa náà lè túbọ̀ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìwàlójúfò Jésù, bóyá nípa sísapá láti túbọ̀ máa wà lójúfò ká sì máa wàásù ìhìn rere fún àwọn tá à ń bá pàdé lójoojúmọ́, nígbàkigbà tá a bá ní àǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀?
11, 12. (a) Kí ni Jésù ṣe nígbà tí àwọn kan kò fẹ́ jẹ́ kó gbájú mọ́ iṣẹ́ rẹ̀? (b) Kí ló fi hàn pé Jésù wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ọ̀nà tó gbà ṣe iṣẹ́ rẹ̀?
11 Nígbà míì, àwọn tí kò ní in lọ́kàn láti ṣe Jésù níbi máa ń ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kó gbájú mọ́ iṣẹ́ rẹ̀. Ní ìlú Kápánáúmù, inú àwùjọ àwọn èèyàn tó rí bí Jésù ṣe fi iṣẹ́ ìyanu ṣèwòsàn dùn débi pé wọ́n fẹ́ kó máa gbé lọ́dọ̀ àwọn. Ó rọrùn láti lóye ìdí tí wọ́n fi fẹ́ bẹ́ẹ̀. Àmọ́, iṣẹ́ Jésù gba pé kó wàásù fún gbogbo “àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tí wọ́n sọnù,” kì í ṣe kìkì àwọn tó ń gbé nínú ìlú kan ṣoṣo. (Mát. 15:24) Torí náà, ó sọ fún àwọn èèyàn yẹn pé: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú ńlá mìíràn pẹ̀lú, nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.” (Lúùkù 4:40-44) Ó ṣe kedere pé Jésù gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀. Kò jẹ́ kí ohunkóhun darí àfiyèsí òun gba ibòmíì.
12 Ǹjẹ́ bí Jésù ṣe gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ wá sọ ọ́ di aláṣejù tàbí ẹni tó ń fi adùn du ara rẹ̀ bí? Ṣé iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ gbà á lọ́kàn débi pé kò mọ ohun táwọn èèyàn nílò? Rárá o, Jésù fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ nípa wíwà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Kò fi adùn du ara rẹ̀, òun àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ jùmọ̀ ṣe àwọn nǹkan tó mú wọn láyọ̀. Ó fọwọ́ pàtàkì mú àwọn èèyàn, bó bá rí àwọn ìdílé tó ṣaláìní tàbí tí wọ́n ní ìṣòro, àánú wọ́n máa ń ṣe é, ó sì tún nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọdé lọ́pọ̀lọpọ̀.—Ka Máàkù 10:13-16.
13. Báwo la ṣe lè wà lójúfò ká sì wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì bíi ti Jésù lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run?
13 Bá a ti ń kọ́ láti wà lójúfò bíi ti Jésù, báwo la ṣe lè máa sapá láti wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì? A kò ní jẹ́ kí ayé yìí pín ọkàn wa níyà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. Àwọn ọ̀rẹ́ àti ìbátan tí kò ní in lọ́kàn láti ṣe wá níbi tiẹ̀ lè rọ̀ wá pé ká máa tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa tàbí pé ká máa gbé irú ìgbé ayé tí wọ́n kà sí èyí tó yẹ. Àmọ́, tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, àwa náà á máa ka iṣẹ́ ìwàásù wa sí oúnjẹ. (Jòh. 4:34) Iṣẹ́ ìwàásù wa máa ń mú kí àjọse wa pẹ̀lú Ọlọ́run dára sí i, ó sì tún máa ń fún wa láyọ̀. Síbẹ̀, a kò fẹ́ di ẹni tí kò wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, tó jẹ́ olódodo lójú ara rẹ̀ tàbí tó ń fi adùn du ara rẹ̀. “Ọlọ́run aláyọ̀” là ń sìn, torí náà bíi ti Jésù, àwa náà fẹ́ jẹ́ aláyọ̀, ká sì wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì.—1 Tím. 1:11.
BÁ A ṢE LÈ WÀ LÓJÚFÒ NÍGBÀ ÀDÁNWÒ
14. Nígbà àdánwò, àwọn nǹkan wo ló yẹ ká ṣọ́ra fún, kí sì nìdí?
14 Bá a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, ìgbà tí Jésù wà lábẹ́ àdánwò tó le koko ló sọ díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú tó jẹ́ kánjúkánjú jù lọ pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun wà lójúfò. (Ka Máàkù 14:37.) Ó pọn dandan pé ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, pàápàá jù lọ tá a bá wà nínú ìṣòro. Òtítọ́ tó ṣe kókó kan wà tí ọ̀pọ̀ èèyàn kì í pẹ́ gbàgbé bí wọ́n bá wà nínú ìṣòro. Òtítọ́ yìí ṣe pàtàkì débi pé ìgbà méjì ni ìwé Òwe sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ó ní: “Ọ̀nà kan wà tí ó dúró ṣánṣán lójú ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà ikú ni òpin rẹ̀ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.” (Òwe 14:12; 16:25) Tá a bá gbára lé ìrònú wa, ní pàtàkì nígbà tá a bá dojú kọ ìṣòro tó le koko, ó ṣeé ṣe ká kó ara wa àtàwọn tá a nífẹ̀ẹ́ sínú ewu.
15. Ìdẹwò wo ni olórí ìdílé kan lè dojú kọ nígbà tó bá ṣòro láti gbọ́ bùkátà ìdílé?
15 Bí àpẹẹrẹ, ó lè ṣòro fún olórí ìdílé kan láti pèsè ohun tí “àwọn tí í ṣe tirẹ̀” nílò nípa tara. (1 Tím. 5:8) Èyí lè mú kó gba iṣẹ́ táá jẹ́ kó máa pa ìpàdé jẹ léraléra, tí kò ní jẹ́ kó máa darí Ìjọsìn Ìdílé tàbí kó máa lọ sóde ẹ̀rí. Tó bá gbára lé ìrònú èèyàn, ó lè máà rí ohun tó burú nínú ṣíṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀. Àmọ́, èyí lè sọ ẹni náà di aláìsàn nípa tẹ̀mí tàbí kó kú nípa tẹ̀mí. Ẹ ò rí i pé ó dára gan-an ká máa fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Òwe 3:5, 6 sílò! Sólómọ́nì sọ pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.”
16. (a) Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ nípa gbígbẹ́kẹ̀lé ọgbọ́n Jèhófà dípò kó gbára lé ọgbọ́n tara rẹ̀? (b) Báwo ni ọ̀pọ̀ olórí ìdílé ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nípa gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà nígbà tí nǹkan kò bá rọgbọ?
16 Nígbà tí Jésù dojú kọ àdánwò, ó kọ̀ láti gbára lé òye tirẹ̀. Rò ó wò ná! Ọkùnrin tó gbọ́n jù lọ tó tíì gbé orí ilẹ̀ ayé rí yàn láti má ṣe wá ojútùú sí ọ̀ràn ara rẹ̀ nípa gbígbára lé ọgbọ́n ara rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Sátánì dán Jésù wò, léraléra ni Jésù fún Sátánì lésì pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé.” (Mát. 4:4, 7, 10) Jésù gbára lé ọgbọ́n Bàbá rẹ̀ láti borí ìdẹwò náà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tí Sátánì tẹ́ńbẹ́lú tí kò sì ní rárá. Ṣé àwa náà máa ń ṣe bíi ti Jésù? Olórí ìdílé tó bá wà lójúfò bíi ti Jésù máa ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run darí òun, ní pàtàkì nígbà àdánwò. Ohun tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olórí ìdílé ń ṣe jákèjádò ayé gan-an nìyẹn. Ìgbà gbogbo ni wọ́n ń fi Ìjọba Ọlọ́run àti ìjọsìn mímọ́ sí ipò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé wọn, kódà wọ́n kà á sí pàtàkì ju àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú nǹkan tara lọ. Wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ bójú tó ìdílé wọn lọ́nà tó dára jù lọ. Jèhófà sì máa ń bù kún ìsapá wọn nípa pípèsè àwọn nǹkan tí wọ́n ṣaláìní nípa tara, gẹ́gẹ́ bó ti ṣèlérí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀.—Mát. 6:33.
17. Kí ló ń mú kó o máa wà lójúfò bíi ti Jésù?
17 Láìsí àní-àní, àpẹẹrẹ tó ta yọ ni Jésù fi lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ wíwà lójúfò. Àpẹẹrẹ rẹ̀ wúlò, ó ṣàǹfààní, ó sì ń gbẹ̀mí là. Má ṣe gbàgbé pé Sátánì fẹ́ kó o sùn lọ nípa tẹ̀mí, ìyẹn ni pé ó fẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ di ahẹrẹpẹ, kó o má fi ìtara jọ́sìn Ọlọ́run mọ́, kó sì ba ìdúróṣinṣin rẹ jẹ́. (1 Tẹs. 5:6) Má ṣe jẹ́ kó ṣàṣeyọrí o! Bíi ti Jésù, máa fi hàn pé o wà lójúfò nípa gbígbàdúrà, lílọ́ sí òde ẹ̀rí, kó o sì gbára lé Jèhófà nígbà àdánwò. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá láyọ̀, ìgbésí ayé rẹ á sì nítumọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àkókò tí ètò àwọn nǹkan yìí ń kógbá sílé la wà yìí. Tó o bá ń ṣe àwọn ohun tó fi hàn pé o wà lójúfò, ó dájú pé bí Ọ̀gá rẹ bá dé láti fòpin sí ètò àwọn nǹkan yìí, ó máa rí i pé o wà lójúfò, o sì ń ṣe ìfẹ́ Bàbá òun. Inú Jèhófà máa dùn gan-an láti san ẹ́ lẹ́san nítorí ìṣòtítọ́ rẹ!—Ìṣí. 16:15.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Jésù wàásù fún obìnrin kan nídìí kànga. Ǹjẹ́ ìwọ náà máa ń wá ọ̀nà láti wàásù lójoojúmọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Tó o bá ń ran ìdílé rẹ lọ́wọ́ láti mú kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run dára sí i, ìyẹn á fi hàn pé o wà lójúfò