“Jèhófà Kan Ṣoṣo” Ń kó Ìdílé Rẹ̀ Jọ
‘Mo pàrọwà fún yín pé kí ẹ máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́.’—ÉFÉ. 4:1, 3.
BÁWO LO ṢE MÁA ṢÀLÀYÉ?
Kí ni iṣẹ́ àbójútó Ọlọ́run wà fún?
Báwo la ṣe lè máa “pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́”?
Kí ló máa mú ká “di onínúrere sí ara [wa] lẹ́nì kìíní-kejì”?
1, 2. Kí ni ìpinnu Jèhófà nípa ilẹ̀ ayé àtàwọn èèyàn inú rẹ̀?
ÌDÍLÉ. Kí ló máa ń wá sí ẹ lọ́kàn tó o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí? Ṣé ó máa ń mú ẹ rántí ibi tí ìfẹ́ àti ayọ̀ ti ń gbilẹ̀? Ṣé ó ń mú ẹ rántí bó o ṣe lè máa bá àwọn míì ṣiṣẹ́ pọ̀ ní ìṣọ̀kan? Àbí, ńṣe ló máa ń rán ẹ létí ibi tí kò léwu tó o ti lè dàgbà, kó o kẹ́kọ̀ọ́, kó o sì lè sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ? Ó ṣeé ṣe kó o ronú lọ́nà yìí bó bá jẹ́ pé inú ìdílé tí wọ́n ti ń gba tẹni rò lo ti wá. Jèhófà fúnra rẹ̀ ló dá ìdílé sílẹ̀. (Éfé. 3:14, 15) Ìpinnu rẹ̀ ni pé kí gbogbo ohun tó dá ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé máa gbé láìséwu, kí wọ́n fọkàn tán ara wọn, kí wọ́n sì ní ojúlówó ìṣọ̀kan.
2 Lẹ́yìn tí aráyé ti dẹ́ṣẹ̀, wọn kò sí nínú ìdílé Ọlọ́run mọ́. Síbẹ̀, ìyẹn kò yí ìpinnu Ọlọ́run pa dà. Ó máa rí i dájú pé àwọn ọmọ Ádámù àti Éfà kún inú Párádísè ilẹ̀ ayé. (Jẹ́n. 1:28; Aísá. 45:18) Ó ti múra ohun gbogbo sílẹ̀ kó lè ṣe ohun tó pinnu yìí. A máa rí ìsọfúnni tó pọ̀ nípa ètò tí Ọlọ́run ṣe yìí nínú ìwé Éfésù tó sọ̀rọ̀ nípa ìṣọ̀kan. Ẹ jẹ́ ká jíròrò díẹ̀ lára àwọn ẹsẹ tó wà níbẹ̀ ká lè rí bá a ṣe máa kọ́wọ́ ti ìpinnu Jèhófà láti mú kí gbogbo ẹ̀dá láyé àti lọ́run wà ní ìṣọ̀kan.
IṢẸ́ ÀBÓJÚTÓ NÁÀ ÀTI OHUN TÓ WÀ FÚN
3. Kí ni iṣẹ́ àbójútó Ọlọ́run tí ìwé Éfésù 1:10 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ìgbà wo sì ni apá àkọ́kọ́ lára rẹ̀ bẹ̀rẹ̀?
3 Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni.” (Diu. 6:4) Jèhófà máa ń ṣe nǹkan ní ìbámu pẹ̀lú ìpinnu rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, “ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀,” Ọlọ́run mú kí “iṣẹ́ àbójútó” kan bẹ̀rẹ̀, ìyẹn ìṣètò kan táá mú kí gbogbo ẹ̀dá rẹ̀ olóye wà ní ìṣọ̀kan. (Ka Éfésù 1:8-10.) Apá méjì ni iṣẹ́ àbójútó yìí pín sí. Ní apá àkọ́kọ́, Ọlọ́run múra ìjọ àwọn ẹni àmì òróró sílẹ̀ láti lọ gbé lọ́run. Níbẹ̀ Jésù Kristi tí Ọlọ́run yàn ṣe Orí wọn ni yóò máa darí wọn. Apá yìí bẹ̀rẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi lókè ọ̀run jọ. (Ìṣe 2:1-4) Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti polongo àwọn ẹni àmì òróró ní olódodo fún ìyè lọ́lá ẹbọ ìràpadà Kristi, èyí mú kí wọ́n mọ̀ pé àwọn ti gba ìsọdọmọ gẹ́gẹ́ bí “ọmọ Ọlọ́run.”—Róòmù 3:23, 24; 5:1; 8:15-17.
4, 5. Kí ni apá kejì lára iṣẹ́ àbójútó náà?
4 Ní apá kejì iṣẹ́ àbójútó náà, Ọlọ́run ṣe àkójọ àwọn tó máa gbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Mèsáyà. “Ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí ìwé Ìṣípayá sọ̀rọ̀ nípa wọn ni apá àkọ́kọ́ lára àwùjọ àwọn èèyàn yìí. (Ìṣí. 7:9, 13-17; 21:1-5) Nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún Kristi, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó jíǹde máa dara pọ̀ mọ́ àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá náà. (Ìṣí. 20:12, 13) Fojú inú yàwòrán bí àjíǹde ṣe máa mú ká túbọ̀ fi hàn pé a wà ní ìṣọ̀kan! Ní òpin ẹgbẹ̀rún ọdún ìṣàkóso Kristi, “àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé,” ìyẹn ogunlọ́gọ̀ ńlá àtàwọn tó jíǹde ni a máa dán wò fún ìgbà ìkẹyìn. Àwọn tó bá yege ìdánwò náà máa gba ìsọdọmọ gẹ́gẹ́ bí àwọn “ọmọ Ọlọ́run” lórí ilẹ̀ ayé.—Róòmù 8:21; Ìṣí. 20:7, 8.
5 Ní báyìí, Ọlọ́run ń ṣiṣẹ́ lórí apá méjèèjì tí iṣẹ́ àbójútó rẹ̀ pín sí. Àmọ́, báwo ni àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ṣe lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú iṣẹ́ àbójútó Ọlọ́run nísinsìnyí?
“PA ÌṢỌ̀KANṢOṢO Ẹ̀MÍ MỌ́”
6. Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé ó yẹ káwọn Kristẹni máa pé jọ pọ̀ pẹ̀lú ara wọn?
6 Ìwé Mímọ́ fi hàn pé àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ máa pé jọ pọ̀ pẹ̀lú ara wọn. (1 Kọ́r. 14:23; Héb. 10:24, 25) Irú ìpéjọpọ̀ bẹ́ẹ̀ ré kọjá ti àwọn tó bára wọn pàdé ní ibì kan náà, tí wọ́n sì wà pa pọ̀ fún àkókò díẹ̀, irú bí àwọn tó pàdé ní ọjà tàbí níbi eré ìdárayá. Ojúlówó ìṣọ̀kan kọjá bẹ́ẹ̀. Tá a bá ń fi àwọn ìtọ́ni Jèhófà sílò tá a sì ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run mọ wá la tó lè wà ní ìṣọ̀kan lọ́nà yìí.
7. Kí ló túmọ̀ sí láti máa “pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́”?
7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lọ́lá ẹbọ ìràpadà Kristi, Jèhófà ti polongo àwọn ẹni àmì òróró rẹ̀ ní olódodo gẹ́gẹ́ bí ọmọ, tó sì ti polongo àwọn àgùntàn mìíràn ní olódodo gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ rẹ̀, èdèkòyédè á ṣì máa wáyé níwọ̀n ìgbà tí èyíkéyìí nínú wa bá ṣì ń gbé láyé nínú ètò àwọn nǹkan yìí. (Róòmù 5:9; Ják. 2:23) Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, Ọlọ́run kò ní gbà wá nímọ̀ràn nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ká máa ‘fara dà á fún ara wa lẹ́nì kìíní kejì.’ Ṣùgbọ́n kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè máa wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ará wa? A gbọ́dọ̀ ní “ìrẹ̀lẹ̀ pátápátá ti èrò inú àti ìwà tútù.” Láfikún sí ìyẹn, Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé ká máa fi taratara sakun “láti máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà.” (Ka Éfésù 4:1-3.) Ká lè máa fi ìmọ̀ràn yìí sílò, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wa ká sì máa fi àwọn ànímọ́ rẹ̀ ṣèwà hù. Àwọn ànímọ́ tó jẹ́ apá kan èso ti ẹ̀mí yìí á jẹ́ ká yanjú èdèkòyédè tó bá wáyé láàárín àwa àtàwọn míì, ó sì yàtọ̀ sí àwọn iṣẹ́ ti ara tó máa ń fa ìpínyà.
8. Báwo ni àwọn iṣẹ́ ti ara ṣe máa ń fa ìpínyà?
8 Kíyè sí bí “àwọn iṣẹ́ ti ara” ṣe máa ń fa ìpínyà. (Ka Gálátíà 5:19-21.) Bí ẹnì kan bá ń ṣe àgbèrè, ńṣe ló máa pín irú ẹni bẹ́ẹ̀ níyà kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà àti nínú ìjọ. Panṣágà sì lè tú ìdílé ká. Ìwà àìmọ́ kì í jẹ́ kéèyàn wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run àtàwọn tó nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀. Ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn fẹ́ lẹ nǹkan méjì pọ̀ mọ́ra, ojú ibi tá a fẹ́ lẹ̀ mọ́ra náà gbọ́dọ̀ wà ní mímọ́ kó tó lè lẹ̀ mọ́ èkejì dáadáa. Bí ẹnì kan bá ń lọ́wọ́ nínú ìwà ọ̀dájú ńṣe ló ń fi hàn pé òun kò ní ọ̀wọ̀ kankan fún àwọn òfin òdodo Ọlọ́run. Ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ ti ara yòókù kì í jẹ́ kí àwọn èèyàn wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ara wọn àti pẹ̀lú Ọlọ́run. Irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ sì lòdì sí àwọn ànímọ́ rere tí Jèhófà ní.
9. Báwo la ṣe lè yẹ ara wa wò ká lè mọ̀ bóyá òótọ́ ni à ń “fi taratara sakun láti máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́”?
9 Nítorí èyí, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ bi ara rẹ̀ pé: ‘Báwo ni mo ṣe ń fi taratara sakun tó “láti máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà”? Kí ni mo máa ń ṣe bí aáwọ̀ bá wà láàárín èmi àti ẹnì kan? Ṣé ńṣe ni mo máa ń rojọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ mi kí wọ́n lè gbè sẹ́yìn mi? Ṣé àwọn alàgbà ni mo máa ń retí pé kí wọ́n bá mi yanjú ọ̀ràn náà láìjẹ́ pé mo kọ́kọ́ lọ bá onítọ̀hún kí àwa méjèèjì sì yanjú ọ̀rọ̀ náà láàárín ara wa? Bí mo bá sì mọ̀ pé ẹnikẹ́ni ní ohun kan lòdì sí mi, ṣé mi ò kì í sá fún onítọ̀hún ká má bàa sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro náà?’ Bí a bá ń ṣe èyíkéyìí nínú àwọn ohun tá a mẹ́nu kàn yìí, ǹjẹ́ ó máa fi hàn pé à ń ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìpinnu Jèhófà láti tún kó ohun gbogbo jọ pọ̀ nínú Kristi?
10, 11. (a) Báwo ló ti ṣe pàtàkì tó pé ká wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ará wa? (b) Irú ìwà wo ló máa mú ká wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn, ká sì máa rí ìbùkún Jèhófà gbà?
10 Jésù sọ pé: “Nígbà náà, bí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ bọ̀ níbi pẹpẹ, tí o sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ ní ohun kan lòdì sí ọ, fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ; kọ́kọ́ wá àlàáfíà, ìwọ pẹ̀lú arákùnrin rẹ, àti lẹ́yìn náà, nígbà tí o bá ti padà wá, fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ. Bẹ̀rẹ̀ sí yanjú àwọn ọ̀ràn ní kíákíá.” (Mát. 5:23-25) Jákọ́bù kọ̀wé pé “èso òdodo ni a ń fún irúgbìn rẹ̀ lábẹ́ àwọn ipò tí ó kún fún àlàáfíà fún àwọn tí ń wá àlàáfíà.” (Ják. 3:17, 18) Torí náà, àyàfi tá a bá wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn nìkan la tó lè máa bá a nìṣó láti hùwà tó tọ́.
11 Àpèjúwe kan rèé: Wọ́n fojú bù ú pé bí a bá pín gbogbo ilẹ̀ tó wà ní àwọn orílẹ̀-èdè kan tí ogun ti ṣọṣẹ́ sí ọ̀nà mẹ́ta, ó ju ìdá kan lọ lára ilẹ̀ náà táwọn èèyàn lè máa fi ṣọ̀gbìn. Àmọ́, èyí kò ṣeé ṣe torí àwọn ohun abúgbàù tí wọ́n rì mọ́lẹ̀ níbẹ̀. Bí ohun abúgbàù bá dún lórí ilẹ̀ táwọn àgbẹ̀ ti ń ṣọ̀gbìn, wọ́n á sá fi ibẹ̀ sílẹ̀, àtigbọ́bùkátà ìdílé á di ìṣòro fún wọn, ìyẹn á sì wá bẹ̀rẹ̀ sí í febi pa àwọn aráàlú. Lọ́nà kan náà, ó máa ṣòro láti mú kí àwọn ànímọ́ Kristẹni wa máa sunwọ̀n sí i bí ìwà wa bá mú kó ṣòro fún wa láti máa wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ará wa. Ṣùgbọ́n, tá a bá ń tètè dárí jini tá a sì ń ṣe ohun tó lè mú ká wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn, ńṣe là ń fira wa sípò táá mú ká máa rí ìbùkún Jèhófà gbà.
12. Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè mú ká máa wà ní ìṣọ̀kan?
12 Síwájú sí i, “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” lè ṣe púpọ̀ láti pa kún ìṣọ̀kan ìjọ. Ọlọ́run ti fi wọ́n fún wa kí wọ́n lè mú ká “dé ìṣọ̀kanṣoṣo nínú ìgbàgbọ́.” (Éfé. 4:8, 13) Bí àwọn alàgbà ṣe ń bá wa ṣiṣẹ́ pọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tí wọ́n sì ń pe àfiyèsí wa sí àwọn ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ, ńṣe ni wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa tẹ̀ síwájú nínú bá a ṣe ń gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀. (Éfé. 4:22-24) Bí àwọn alàgbà bá fún ẹ nímọ̀ràn, ǹjẹ́ o máa ń rí i pé ńṣe ni Jèhófà ń lò wọ́n láti múra rẹ sílẹ̀ kó o lè gbé nínú ayé tuntun lábẹ́ ìṣàkóso Ọmọ rẹ̀? Ẹ̀yin alàgbà, bí ẹ bá ń tọ́ àwọn èèyàn sọ́nà, ṣé ẹ máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó fi hàn pé ẹ fẹ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́?—Gál. 6:1.
“Ẹ DI ONÍNÚRERE SÍ ARA YÍN LẸ́NÌ KÌÍNÍ-KEJÌ”
13. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ bí a kò bá fetí sí ìmọ̀ràn tó wà nínú Éfésù 4:25-32?
13 Ìwé Éfésù 4:25-29 sọ àwọn ìwà kan tó yẹ ká dìídì yẹra fún. Lára irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ ni èké ṣíṣe, ìrunú tàbí ìwà ọ̀lẹ àti sísọ ọ̀rọ̀ jíjẹrà dípò kéèyàn máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó dára tó sì ń gbéni ró. Bí ẹnì kan bá kùnà láti gba ìmọ̀ràn yìí, ó máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀mí Ọlọ́run, torí pé ńṣe ni ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń mú kéèyàn fẹ́ láti gbé ìṣọ̀kan lárugẹ. (Éfé. 4:30) Ó tún ṣe pàtàkì pé ká fi ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ síwájú sí i sọ́kàn, kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan lè máa jọba. Ó ní: “Kí ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìwà búburú. Ṣùgbọ́n kí ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run pẹ̀lú ti tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà.”—Éfé. 4:31, 32.
14. (a) Kí ni gbólóhùn náà, “ẹ di onínúrere” túmọ̀ sí? (b) Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti di onínúrere?
14 Ohun tí gbólóhùn náà, “ẹ di onínúrere” túmọ̀ sí ni pé ó ṣeé ṣe ká máà jẹ́ onínúrere tó bó ṣe yẹ, ó sì yẹ ká wá bá a ṣe lè sunwọ̀n sí i. Ẹ sì wo bó ṣe bá a mú wẹ́kú tó pé ká kọ́ bá a ṣe lè máa fi hàn pé bí ọ̀ràn ṣe rí lára àwọn ẹlòmíì ṣe pàtàkì ju bó ṣe rí lára wa lọ! (Fílí. 2:4) Bóyá ohun kan tí à ń fẹ́ láti sọ máa pa àwọn èèyàn lẹ́rìn-ín tàbí ó máa mú ká dà bí ọlọgbọ́n, àmọ́ ṣé ohun tó máa fi hàn pé a jẹ́ onínúrere ni? Tá a bá ń ronú ṣáájú lórí èyí ká tó sọ̀rọ̀, ó máa jẹ́ ká “di onínúrere.”
KỌ́ BÓ O ṢE LÈ MÁA FI ÌFẸ́ ÀTI Ọ̀WỌ̀ HÀN NÍNÚ ÌDÍLÉ
15. Èwo lára àwọn ọ̀nà tí Kristi gbà bá ìjọ lò ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú Éfésù 5:28?
15 Bíbélì fi àjọṣe tó wà láàárín ìjọ àti Kristi wé àjọṣe tó wà láàárín ọkọ àti aya rẹ̀. Èyí á mú ká tètè rántí bó ṣe yẹ kí ọkọ máa darí aya rẹ̀, kó máa fìfẹ́ hàn sí i, kó sì máa bójú tó o àti bó ṣe yẹ kí aya máa tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀ bí àwọn méjèèjì ṣe ń gbé pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya. (Éfé. 5:22-33) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Lọ́nà yìí, ó yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn,” ‘ọ̀nà’ wo ló ní lọ́kàn? (Éfé. 5:28) Ọ̀rọ̀ tó kọ́kọ́ sọ darí àfiyèsí wa sí ọ̀nà tí ‘Kristi gbà nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un, ní wíwẹ̀ ẹ́ mọ́ pẹ̀lú ìwẹ̀ omi nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ náà.’ Èyí wá mú kó ṣe kedere pé kí ọkọ kan tó lè ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ètè Jèhófà láti tún kó ohun gbogbo jọ pọ̀ nínú Kristi, ó gbọ́dọ̀ wà lójúfò kó sì ran ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run.
16. Kí ló máa ń jẹ́ àbájáde rẹ̀ bí àwọn òbí bá ṣe ojúṣe tí Ìwé Mímọ́ là kalẹ̀ fún wọn nínú ilé?
16 Ó dára káwọn òbí rántí pé iṣẹ́ tí Jèhófà yàn fún wọn ni wọ́n ń bójú tó. Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé nínú ayé lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò ní “ìfẹ́ni àdánidá.” (2 Tím. 3:1, 3) Àìmọye àwọn baba ni wọ́n ti pa ojúṣe wọn tì. Èyí ń ní ipa tí kò dára lórí àwọn ọmọ wọn, ó sì ń bà wọ́n nínú jẹ́. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ baba níyànjú pé: “Ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfé. 6:4) Ibo sì làwọn ọmọ ti lè kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ ohun tó túmọ̀ sí láti nífẹ̀ẹ́ àti láti máa tẹrí ba fún àṣẹ bí kò ṣe nínú ìdílé? Ńṣe ni àwọn òbí tó ti kọ́ àwọn ọmọ wọn nírú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ ń kọ́wọ́ ti iṣẹ́ àbójútó Jèhófà. Bí a bá jẹ́ kí ìfẹ́ gbilẹ̀ nínú ilé wa, tá a mú gbogbo ìbínú àti ìrunú àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò, a jẹ́ pé ẹ̀kọ́ pàtàkì la fi ń kọ́ àwọn ọmọ wa nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa fi ìfẹ́ hàn àti bó ṣe yẹ kí wọ́n máa tẹrí ba fún àṣẹ. Èyí á múra wọn sílẹ̀ láti gbé nínú ayé tuntun Ọlọ́run.
17. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká bàa lè kọjúùjà sí Èṣù?
17 Èṣù ló kọ́kọ́ ba àlàáfíà jẹ́ láyè àtọ̀run, a sì gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ó máa jà fitafita kó lè gbéjà kò wá bá a ṣe ń sapá láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ohun tó wu Sátánì ni ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe bí ìkọ̀sílẹ̀ ṣe ń pọ̀ sí i, tí tọkùnrin tobìnrin ń bára wọn gbé bíi tọkọtaya láìṣe ìgbéyàwó, tí àwọn ọkùnrin àti ọkùnrin tàbí obìnrin àti obìnrin sì ń gbéra wọn níyàwó. Àmọ́, a kì í hu irú ìwà táwọn èèyàn ń hù nínú ayé lóde òní. Àpẹẹrẹ tí Kristi fi lélẹ̀ là ń tẹ̀ lé. (Éfé. 4:17-21) Torí náà, ká bàa lè kẹ́sẹ járí bá a ti ń kọjúùjà sí Èṣù àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀, a gbà wá níyànjú pé ká “gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀.”—Ka Éfésù 6:10-13.
‘Ẹ MÁA BÁ A LỌ NÍ RÍRÌN NÍNÚ ÌFẸ́’
18. Kí ni ohun tó ń mú kí àwa Kristẹni wà ní ìṣọ̀kan?
18 Ìfẹ́ ni ohun pàtàkì tó ń mú kí àwa Kristẹni wà ní ìṣọ̀kan. Níwọ̀n bí ọkàn wa ti kún fún ìfẹ́ fún “Olúwa kan,” àti “Ọlọ́run kan” tá à ń sìn àti fún àwọn ará wa, a ti pinnu “láti máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà.” (Éfé. 4:3-6) Jésù gbàdúrà nípa irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀. Ó ní: “Èmi kò ṣe ìbéèrè nípa àwọn wọ̀nyí nìkan, ṣùgbọ́n nípa àwọn tí yóò ní ìgbàgbọ́ nínú mi pẹ̀lú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn; kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi, tí èmi sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí àwọn náà lè wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú wa . . . Mo sì ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀ fún wọn, ṣe ni èmi yóò sì sọ ọ́ di mímọ̀, kí ìfẹ́ tí ìwọ fi nífẹ̀ẹ́ mi lè wà nínú wọn àti èmi ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú wọn.”—Jòh. 17:20, 21, 26.
19. Kí lo pinnu láti ṣe?
19 Bí ohun kan bá wà nínú ìwà wa tó ṣòro láti yí pa dà torí pé a jẹ́ aláìpé, ǹjẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà sún wa láti gbàdúrà bíi ti onísáàmù pé: “Mú ọkàn-àyà mi ṣọ̀kan láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.” (Sm. 86:11) Ẹ jẹ́ ká pinnu láti kọjúùjà sí Èṣù kó má bàa sọ wá di àjèjì sí Baba wa onífẹ̀ẹ́ àtàwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Ẹ ṣiṣẹ́ taápọntaápọn láti “di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n, kí ẹ sì máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ́” nínú ìdílé, lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti nínú ìjọ.—Éfé. 5:1, 2.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Ó fi ẹ̀bùn rẹ̀ sílẹ̀ níwájú pẹpẹ, ó lọ wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Ẹ̀yin òbí, ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín láti máa fi ọ̀wọ̀ hàn