Irú Ẹ̀mí Wo Lò Ń fi Hàn?
“Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Kristi Olúwa wà pẹ̀lú ẹ̀mí tí ẹ fi hàn.”—FÍLÉM. 25.
1. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ léraléra nígbà tó ń kọ̀wé sí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́?
NÍGBÀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ lẹ́tà sí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́, ó sọ léraléra pé òun ní ìrètí pé Ọlọ́run àti Kristi máa bù kún ẹ̀mí táwọn ìjọ náà fi hàn. Bí àpẹẹrẹ, ó kọ̀wé sáwọn ará ní ìlú Gálátíà pé: “Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Olúwa wa Jésù Kristi wà pẹ̀lú ẹ̀mí tí ẹ ń fi hàn, ẹ̀yin ará. Àmín.” (Gál. 6:18) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn pẹ̀lú gbólóhùn náà, “ẹ̀mí tí ẹ ń fi hàn”?
2, 3. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù máa ń ní lọ́kàn nígbà míì tó bá lo ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀mí”? (b) Àwọn ìbéèrè wo la lè bi ara wa nípa irú ẹ̀mí tí à ń fi hàn?
2 Nínú ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù yìí, ohun tí “ẹ̀mí” túmọ̀ sí ni ohun tó ń mú ká máa sọ̀rọ̀ tàbí ṣe nǹkan lọ́nà pàtó kan. Èèyàn kan lè jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́, agbatẹnirò, onínú tútù, ọ̀làwọ́, tàbí ẹni tó lẹ́mìí ìdáríjì. Bíbélì sọ̀rọ̀ dáadáa nípa ẹni tó ní “ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù” àti ẹni tó “tutù ní ẹ̀mí.” (1 Pét. 3:4; Òwe 17:27) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ẹlòmíì lè jẹ́ apẹ̀gàn, olùfẹ́ ọrọ̀, onínúfùfù tàbí aṣetinú-ẹni. Àwọn míì sì wà tí wọ́n ní ẹ̀mí tó ń mú kí wọ́n máa ro èròkérò, kí wọ́n máa ṣàìgbọràn, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa ṣọ̀tẹ̀.
3 Nípa bẹ́ẹ̀, láwọn ìgbà tí Pọ́ọ̀lù bá lo àwọn gbólóhùn bíi “kí Olúwa wà pẹ̀lú ẹ̀mí tí o fi hàn,” ńṣe ló ń fún àwọn arákùnrin rẹ̀ níṣìírí láti fi ẹ̀mí tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run àti ìwà Kristi mu hàn. (2 Tím. 4:22; ka Kólósè 3:9-12.) Lóde òní, ó dára ká bi ara wa pé: ‘Irú ẹ̀mí wo ni mò ń fi hàn? Báwo ni ẹ̀mí tí mò ń fi hàn ṣe lè túbọ̀ máa múnú Ọlọ́run dùn? Kí ni mo lè ṣe láti mú kí ẹ̀mí tó dára máa gbilẹ̀ nínú ìjọ?’ Bí àpẹẹrẹ, nínú ọgbà tí wọ́n gbin àwọn òdòdó rírẹwà sí, àwọ̀ tó wà lára òdòdó kọ̀ọ̀kan ló para pọ̀ di àwọ̀ mèremère tó wà níbẹ̀. Ṣé bíi ti òdòdó kọ̀ọ̀kan yẹn làwa náà rí? Ṣé à ń ṣe ipa tiwa láti mú kí ìjọ lẹ́wà? Ohun tó yẹ ká máa sapá láti ṣe gan-an nìyẹn. Wàyí o, ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè ṣe kí ẹ̀mí tí à ń fi hàn lè máa múnú Ọlọ́run dùn.
SÁ FÚN Ẹ̀MÍ AYÉ
4. Kí ni “ẹ̀mí ayé”?
4 Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé: “Kì í ṣe ẹ̀mí ayé ni àwa gbà, bí kò ṣe ẹ̀mí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.” (1 Kọ́r. 2:12) Kí ni “ẹ̀mí ayé”? Ohun kan náà ló jẹ́ pẹ̀lú irú ẹ̀mí tí Éfésù 2:2 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pé: “Ẹ ti rìn ní àkókò kan rí ní ìbámu pẹ̀lú ètò àwọn nǹkan ti ayé yìí, ní ìbámu pẹ̀lú olùṣàkóso ọlá àṣẹ afẹ́fẹ́, ẹ̀mí tí ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ àìgbọ́ràn.” “Afẹ́fẹ́” yìí túmọ̀ sí ẹ̀mí ayé tàbí ọ̀nà tí ayé ń gbà ronú, ńṣe ló sì wà káàkiri bí afẹ́fẹ́. Kò sí ibi tí kò sí. Ẹ̀mí yìí ló ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa hù ìwà tinú-mi-ni-màá-ṣe tàbí kí wọ́n máa fi torí tọrùn jà fẹ́tọ̀ọ́ wọn. Irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ló wá para pọ̀ di “àwọn ọmọ àìgbọ́ràn” inú ayé Sátánì.
5. Ẹ̀mí tí kò dára wo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan fi hàn?
5 Ó ti pẹ́ táwọn èèyàn ti ń hu irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀. Nígbà ayé Mósè, Kórà ta ko àwọn tó wà nípò àṣẹ nínú ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ńṣe ló dìídì dájú sọ Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ní àǹfààní láti máa sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà. Ó ṣeé ṣe kó ti rí àwọn àṣìṣe wọn. Tàbí kó ti máa sọ pé ńṣe ni Mósè ń ṣe ojúsàájú torí pé àwọn ìbátan rẹ̀ nìkan ló ń fún ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn. Èyí ó wù kó jẹ́, ó ṣe kedere pé Kórà kò fi ojú tí Jèhófà fi ń wo ọ̀ràn wò ó, ó sọ̀rọ̀ sí àwọn tí Jèhófà yàn, ó sì sọ fún wọn lọ́nà tí kò fi ọ̀wọ̀ hàn pé: “Ó tó gẹ́ẹ́ yín . . . Kí wá ni ìdí tí ẹ fi gbé ara yín sókè lórí ìjọ?” (Núm. 16:3) Dátánì àti Ábírámù pẹ̀lú ṣàríwísí Mósè, wọ́n sọ fún un pé ńṣe ló ń ‘gbìyànjú láti ṣe bí ọmọ aládé lórí àwọn dé góńgó?’ Nígbà tí wọ́n jíṣẹ́ fún wọn pé Mósè ń pè wọ́n, pẹ̀lú ìgbéraga ni wọ́n fi sọ pé: “Àwa kì yóò gòkè wá!” (Núm. 16:12-14) Ó dájú pé inú Jèhófà kò dùn sí irú ẹ̀mí tí wọ́n fi hàn. Ó sì pa gbogbo àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà.—Núm. 16:28-35.
6. Ní ọ̀rúndún kìíní, báwo ni àwọn kan ṣe fi hàn pé àwọn ní ẹ̀mí tí kò dára, kí ló sì ṣeé ṣe kó fà á?
6 Àwọn kan tún wà ní ọ̀rúndún kìíní tí wọ́n ṣe àríwísí àwọn tó wà nípò àṣẹ nínú ìjọ, wọ́n “ń ṣàìka ipò olúwa sí.” (Júúdà 8) Ó jọ pé àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí àwọn ọkùnrin yẹn ní kò tẹ́ wọn lọ́rùn, wọ́n sì ń gbìyànjú láti mú kí àwọn míì máa ṣàríwísí àwọn ọkùnrin tí a yàn sípò, tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún wọn tọkàntọkàn.—Ka 3 Jòhánù 9, 10.
7. Kí nìdí tá a fi nílò ìṣọ́ra nínú ìjọ lónìí?
7 Ó ṣe kedere pé kò yẹ kí irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ wà nínú ìjọ Kristẹni. Ìdí nìyẹn tá a fi nílò ìṣọ́ra. Àwọn àgbà ọkùnrin tó wà nínú ìjọ kì í ṣe ẹni pípé, bó sì ṣe rí nígbà ayé Mósè àti nígbà ayé àpọ́sítélì Jòhánù náà nìyẹn. Àwọn alàgbà lè ṣe àṣìṣe tó máa dùn wá. Bí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ohun tí kò bójú mu gbáà ló máa jẹ́ tí ẹnikẹ́ni nínú ìjọ bá lọ fi ẹ̀mí ayé hàn, tó ń fi ìgbónára sọ pé kò yẹ kí wọ́n fi “ẹ̀tọ́” òun du òun tàbí pé “ó yẹ kí wọ́n ṣèdájọ́ arákùnrin yìí”! Jèhófà lè yàn láti gbójú fo àwọn àṣìṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kan. Ṣé àwa náà ò lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni? Àwọn kan tó hùwà àìtọ́ tó burú jáì ti kọ̀ jálẹ̀ láti lọ bá ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà tí wọ́n yàn pé kí wọ́n ràn wọ́n lọ́wọ́ torí pé wọ́n ti rí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan lára àwọn alàgbà náà. Ńṣe lọ̀rọ̀ wọn dà bíi ti aláìsàn kan tó kọ̀ láti gba ìtọ́jú tí dókítà fẹ́ fún un torí pé nǹkan kan wà lára dókítà náà tí kò fẹ́ràn.
8. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ló lè mú ká máa fi ojú tó tọ́ wo àwọn tó ń mú ipò iwájú nínú ìjọ?
8 Tá a bá fẹ́ yẹra fún irú ẹ̀mí yẹn, ó yẹ ká máa rántí pé Bíbélì sọ pé Jésù ní “ìràwọ̀ méje ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.” Àwọn “ìràwọ̀” náà dúró fún àwọn alábòójútó tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró. Ní àfikún sí ìyẹn, wọ́n tún dúró fún gbogbo àwọn alábòójútó nínú ìjọ. Jésù lè darí àwọn “ìràwọ̀” tó wà ní ọwọ́ rẹ̀ lọ́nà tó bá tọ́ ní ojú rẹ̀. (Ìṣí. 1:16, 20) Torí náà, gẹ́gẹ́ bí Orí ìjọ Kristẹni, Jésù ní gbogbo agbára pátápátá láti máa darí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà. Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ló yẹ kí alàgbà kan ṣe àwọn àtúnṣe kan, Ẹni tí ‘ojú rẹ̀ dà bí ọwọ́ iná ajófòfò’ yóò ṣe nǹkan kan nípa ọ̀ràn náà ní àkókò tó tọ́ lójú Rẹ̀ àti ní ọ̀nà tó wù Ú. (Ìṣí. 1:14) Ní báyìí ná, ẹ jẹ́ ká máa ní ọ̀wọ̀ tó yẹ fún àwọn tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ yàn, torí Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba, nítorí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn yín bí àwọn tí yóò ṣe ìjíhìn; kí wọ́n lè ṣe èyí pẹ̀lú ìdùnnú, kì í sì í ṣe pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn, nítorí èyí yóò ṣe ìpalára fún yín.”—Héb. 13:17.
9. (a) Báwo ni ìtọ́sọ́nà tàbí ìbáwí tí wọ́n fún Kristẹni kan ṣe lè fi irú ẹ̀mí tó ní hàn? (b) Kí ló dára jù pé ká ṣe tí wọ́n bá fún wa ní ìbáwí?
9 Irú ẹ̀mí tí Kristẹni kan ní tún lè fara hàn tó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n tọ́ ọ sọ́nà tàbí tí wọ́n bá gba àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan lọ́wọ́ rẹ̀ nínú ìjọ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn alàgbà fi ọgbọ́n fun ọ̀dọ́kùnrin kan nímọ̀ràn pé kó má ṣe máa gbá àwọn géèmù fídíò tó jẹ́ oníwà ipá. Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀dọ́kùnrin náà kò fi ọkàn tó dára gba ìmọ̀ràn tí wọ́n fún un, wọ́n sì ní láti mú un kúrò nípò ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, torí pé kò kúnjú ìwọ̀n àwọn ohun tí Ìwé Mímọ́ béèrè mọ́. (Sm. 11:5; 1 Tím. 3:8-10) Lẹ́yìn èyí, arákùnrin náà ń sọ káàkiri pé ìpinnu wọn kò tẹ́ òun lọ́rùn, ó kọ lẹ́tà léraléra sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, ó sọ ohun tí kò dára nípa àwọn alàgbà náà níbẹ̀, ó sì tún ń sọ fáwọn míì nínú ìjọ pé káwọn náà kọ lẹ́tà. Òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé tá a bá ń ṣe àwáwí nígbà tí wọ́n bá bá wa wí lórí nǹkan, wàhálà ni irú ìwà bẹ́ẹ̀ máa dá sílẹ̀ nínú ìjọ, ìyẹn ò sì lè tún ohunkóhun ṣe. Ohun tó dára jù ni pé ká wo ìbáwí gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tá a lè gbà rí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tá ò tiẹ̀ mọ̀ pé a ní, ká sì gba ìbáwí náà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́.—Ka Ìdárò 3:28, 29.
10. (a) Ṣàlàyé ohun tá a lè rí kọ́ nínú Jákọ́bù 3:16-18 nípa ẹ̀mí tó dára àti ẹ̀mí tí kò dára. (b) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tá a bá fi “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè” hàn?
10 Ìwé Jákọ́bù 3:16-18 jẹ́ ká mọ ẹ̀mí tó dára tó yẹ ká máa fi hàn nínú ìjọ àti ẹ̀mí tí kò dára tó yẹ ká máa yẹra fún. Ó sọ pé: “Nítorí níbi tí owú àti ẹ̀mí asọ̀ bá wà, níbẹ̀ ni rúdurùdu àti gbogbo ohun búburú wà. Ṣùgbọ́n ọgbọ́n tí ó wá láti òkè a kọ́kọ́ mọ́ níwà, lẹ́yìn náà, ó lẹ́mìí àlàáfíà, ó ń fòye báni lò, ó múra tán láti ṣègbọràn, ó kún fún àánú àti àwọn èso rere, kì í ṣe àwọn ìyàtọ̀ olójúsàájú, kì í ṣe àgàbàgebè. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, èso òdodo ni a ń fún irúgbìn rẹ̀ lábẹ́ àwọn ipò tí ó kún fún àlàáfíà fún àwọn tí ń wá àlàáfíà.” Tá a bá ń fi “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè” hùwà, ó máa ṣeé ṣe fún wa láti fìwà jọ Ọlọ́run a ó sì lè máa pa kún ẹ̀mí rere tí àwọn ará ní.
MÁA FI Ọ̀WỌ̀ HÀN NÍNÚ ÌJỌ
11. (a) Tá a bá ní ẹ̀mí tó dára kí ló máa jẹ́ ká yẹra fún? (b) Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Dáfídì?
11 Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé Jèhófà ti yan àwọn alàgbà “láti [máa] ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run.” (Ìṣe 20:28; 1 Pét. 5:2) Torí náà, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká bọ̀wọ̀ fún ètò tí Ọlọ́run ṣe, yálà a ní àǹfààní láti máa sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà tàbí a kò ní. Tá a bá ní ẹ̀mí tó dára, a ò ní ka wíwà nípò àṣẹ sí bàbàrà ju bó ṣe yẹ lọ. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù Ọba Ísírẹ́lì ronú pé Dáfídì fẹ́ gba ìjọba mọ́ òun lọ́wọ́, ńṣe ni Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí í “wo Dáfídì tìfuratìfura.” (1 Sám. 18:9) Ẹ̀mí burúkú wọnú ọba náà, ó sì fẹ́ láti pa Dáfídì. Torí náà, dípò tí a ó fi máa ka wíwà ní ipò àṣẹ sí bàbàrà ju bó ṣe yẹ lọ bíi ti Sọ́ọ̀lù, ńṣe ló yẹ ká dà bíi Dáfídì. Pẹ̀lú gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ tí wọ́n hù sí ọ̀dọ́kùnrin náà, ó fi ọ̀wọ̀ hàn fún ẹni tí Ọlọ́run fi sípò àṣẹ.—Ka 1 Sámúẹ́lì 26:23.
12. Kí ló máa mú kí ìṣọ̀kan túbọ̀ wà nínú ìjọ?
12 Nínú ìjọ, èrò tó yàtọ̀ síra lè mú káwọn ará máa bínú síra wọn, ìyẹn sì lè ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn alàgbà pàápàá. Bí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́ rèé: “Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú” àti “Ẹ má ṣe jẹ́ olóye ní ojú ara yín.” (Róòmù 12:10, 16) Dípò tí a ó fi máa sọ pé èrò tiwa ló tọ̀nà ṣáá, ó yẹ ká gbà pé ó sábà máa ń ju ọ̀nà kan ṣoṣo lọ tá a lè gbà wo ọ̀ràn kan. Tá a bá ń gbìyànjú láti lóye ojú táwọn míì fi ń wo nǹkan, a lè tipa bẹ́ẹ̀ máa pa kún ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ.—Fílí. 4:5.
13. Kí ló yẹ ká ṣe lẹ́yìn tá a bá ti sọ èrò wa lórí ọ̀ràn kan, àpẹẹrẹ wo nínú Bíbélì ló sọ ohun tó yẹ ká ṣe?
13 Ṣé ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé kò dára ká sọ ohun tó wà lọ́kàn wa tá a bá rí i pé ohun kan nílò àtúnṣe nínú ìjọ? Rárá o. Ní ọ̀rúndún kìíní, ọ̀ràn kan wáyé nínú ìjọ tó fa awuyewuye tó lágbára. Àwọn ará wá “ṣètò pé kí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà àti àwọn mìíràn kan lára wọn gòkè lọ sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin ní Jerúsálẹ́mù nípa awuyewuye yìí.” (Ìṣe 15:2) Láìsí àní-àní, ó ní ojú tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn arákùnrin yìí fi wo ọ̀ràn náà, wọ́n sì ní èrò tiwọn nípa ohun tí wọ́n rò pé ó yẹ kó jẹ́ ojútùú sí i. Àmọ́, lẹ́yìn tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sọ èrò tirẹ̀, tí ẹ̀mí Ọlọ́run sì jẹ́ kí wọ́n dórí ìpinnu kan, àwọn arákùnrin náà kò tún sọ èrò tiwọn mọ́. Nígbà tí àwọn ìjọ gba lẹ́tà nípa ìpinnu tí wọ́n ṣe yẹn, “wọ́n yọ̀ nítorí ìṣírí náà” wọ́n sì ń bá a lọ ní “fífìdímúlẹ̀ gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.” (Ìṣe 15:31; 16:4, 5) Bákan náà lónìí, lẹ́yìn tá a bá ti fi ọ̀ràn kan tó àwọn arákùnrin tó ń mú ipò iwájú létí, ó yẹ ká fọkàn balẹ̀ pé wọ́n á fara balẹ̀ ronú lórí ọ̀ràn náà wọ́n á sì gbàdúrà nípa rẹ̀ kí wọ́n tó ṣe ìpinnu.
FI Ẹ̀MÍ TÓ DÁRA HÀN NÍNÚ ÀJỌṢE RẸ PẸ̀LÚ ÀWỌN ẸLÒMÍÌ
14. Báwo la ṣe lè fi ẹ̀mí tó dára hàn nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì?
14 Nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, ọ̀pọ̀ ọ̀nà la lè gbà fi ẹ̀mí tó dára hàn. Ohun tó dára gan-an ló jẹ́ tí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan bá lè máa fi hàn pé a ní ẹ̀mí ìdáríjì nígbà táwọn ẹlòmíì bá ṣẹ̀ wá. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe.” (Kól. 3:13) Gbólóhùn náà, “bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́” fi hàn pé àwọn ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ lè wà tó lè mú ká bínú sí àwọn ẹlòmíì. Àmọ́, dípò tí a ó fi jẹ́ kí ohun tí a kò fẹ́ràn nínú ìwà wọn gbà wá lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ, tí èyí á sì dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìjọ, ẹ jẹ́ ká sapá láti fìwà jọ Jèhófà ká dárí jì wọ́n ní fàlàlà, ká sì jọ máa bá iṣẹ́ ìsìn wa nìṣó.
15. (a) Kí la lè rí kọ́ lára Jóòbù nípa ìdáríjì? (b) Báwo ni àdúrà ṣe lè mú ká máa fi ẹ̀mí tó dára hàn?
15 Tó bá dọ̀ràn pé ká máa dárí jini, kí la lè rí kọ́ lára Jóòbù? Àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́ta tó yẹ kí wọ́n tù ú nínú sọ àwọn ọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí i. Síbẹ̀, ó dárí jì wọ́n. Lọ́nà wo? “Ó gbàdúrà nítorí àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀.” (Jóòbù 16:2; 42:10) Ojú tá a fi ń wo àwọn èèyàn lè yí pa dà, tá a bá ń gbàdúrà fún wọn. Ó máa rọrùn fún wa láti máa fi ojú tí Jésù fi ń wo gbogbo àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni wò wọ́n, tá a bá ń gbàdúrà fún wọn. (Jòh 13:34, 35) Láfikún sí gbígbàdúrà fún àwọn ará wa, a gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Lúùkù 11:13) Ẹ̀mí Ọlọ́run á mú ká lè máa fi àwọn ànímọ́ Kristẹni hàn nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn èèyàn.—Ka Gálátíà 5:22, 23.
PA KÚN Ẹ̀MÍ RERE TÓ WÀ NÍNÚ ÈTÒ ỌLỌ́RUN
16, 17. Irú ẹ̀mí wo lo pinnu pé wàá máa fi hàn?
16 Ẹ wo bó ṣe máa dára tó bí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bá fi ṣe àfojúsùn rẹ̀ láti máa pa kún ẹ̀mí rere tó wà nínú ìjọ! Ó ṣeé ṣe kí àpilẹ̀kọ yìí ti mú kó o rí i pé ó yẹ kó o pinnu láti ṣe àwọn àtúnṣe kan kó o lè túbọ̀ máa fi ẹ̀mí tó ń gbéni ró hàn. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, tètè yáa jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi bó o ṣe lè ṣe àwọn àtúnṣe náà hàn ẹ́. (Héb. 4:12) Pọ́ọ̀lù tó ń sapá láti jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú ìjọ sọ pé: “Èmi kò ní ìmọ̀lára ohunkóhun lòdì sí ara mi. Síbẹ̀, nípa èyí, a kò fi mí hàn ní olódodo, ṣùgbọ́n ẹni tí ń wádìí mi wò ni Jèhófà.”—1 Kọ́r. 4:4.
17 Bá a ṣe ń sapá láti máa fi ọgbọ́n tó wá láti òkè hùwà, tí a kò ka ara wa tàbí ipò wa sí bàbàrà ju bó ṣe yẹ lọ, a ó máa pa kún ẹ̀mí rere tó wà nínú ìjọ. Tá a bá ní ẹ̀mí ìdáríjì, tá a sì ń ní èrò tó dára nípa àwọn èèyàn, àwa àtàwọn tá a jọ ń sin Jèhófà á lè máa bára wa gbé ní àlàáfíà. (Fílí. 4:8) Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, a lè ní ìdánilójú pé inú Jèhófà àti Jésù máa dùn sí ‘ẹ̀mí tí a fi hàn.’—Fílém. 25.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Tó o bá ń ṣàṣàrò lórí ipò tí Jésù wà, báwo ni èyí ṣe lè nípa lórí ojú tó o fi ń wo ìmọ̀ràn?