Máa Ṣe Ojúṣe Rẹ Gẹ́gẹ́ Bí Ajíhìnrere
“Ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere, ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ ní kíkún.”—2 TÍM. 4:5.
1. Kí nìdí tá a fi lè pe Jèhófà ní Ajíhìnrere àkọ́kọ́?
TA NI ajíhìnrere? Ajíhìnrere ni ẹni tó bá ń kéde ìhìn rere. Jèhófà Ọlọ́run sì ni Ajíhìnrere àkọ́kọ́. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé gbàrà tí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ti dẹ́ṣẹ̀ ló ti kéde ìhìn rere tàbí ìròyìn ayọ̀ náà pé òun máa pa Sátánì Èṣù run. (Jẹ́n. 3:15) Lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó mí sí ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin tó jẹ́ olóòótọ́ láti ṣàkọsílẹ̀ bó ṣe máa sọ orúkọ ara rẹ̀ di mímọ́. Ó sì tún ní kí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ bí òun ṣe máa yanjú gbogbo wàhálà tí Sátánì ti dá sílẹ̀, tí aráyé á sì gba ohun iyebíye tí Ádámù àti Éfà gbé sọ nù pa dà.
2. (a) Kí nìdí tá a fi lè pe àwọn áńgẹ́lì ní ajíhìnrere? (b) Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ fún àwa ajíhìnrere?
2 Ajíhìnrere làwọn áńgẹ́lì náà. Àwọn náà máa ń kéde ìhìn rere, wọ́n sì máa ń ti àwọn tó ń wàásù ìhìn rere lẹ́yìn. (Lúùkù 1:19; 2:10; Ìṣe 8:26, 27, 35; Ìṣí. 14:6) Tó bá dọ̀rọ̀ pé ká máa kéde ìhìn rere, kí la lè sọ nípa Jésù tó jẹ́ olú áńgẹ́lì? Ajíhìnrere àtàtà lòun náà. Nígbà tó wà láyé, iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere ló jẹ ẹ́ lógún jù lọ. Ó sì yẹ káwa náà máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, ká jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù ṣe pàtàkì sí wa ju ohunkóhun míì lọ.—Lúùkù 4:16-21.
3. (a) Ìhìn rere wo là ń kéde rẹ̀? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká dáhùn?
3 Jésù pa á láṣẹ pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa wàásù ìhìn rere. (Mát. 28:19, 20; Ìṣe 1:8) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà sì gba Tímótì alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ níyànjú pé: “Ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere, ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ ní kíkún.” (2 Tím. 4:5) Ìhìn rere wo làwa ọmọlẹ́yìn Jésù ń polongo rẹ̀ gan-an? Lára ìhìn rere náà ni pé Jèhófà tó jẹ́ Baba wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa. (Jòh. 3:16; 1 Pét. 5:7) Ìjọba rẹ̀ tá a sì ń retí jẹ́ ẹ̀rí pàtàkì pé ó nífẹ̀ẹ́ aráyé lóòótọ́. À ń fi ìdùnnú kéde fáwọn èèyàn pé tí wọ́n bá ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, tí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́, wọ́n lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. (Sm. 15:1, 2) A tún ń kéde fáyé pé Jèhófà máa mú gbogbo ìyà àti ìrora kúrò, a ò sì ní máa banú jẹ́ mọ́ tá a bá rántí ìyà tá a ti jẹ sẹ́yìn. Ẹ ò rí i pé ìhìn rere ni lóòótọ́! (Aísá. 65:17) Níwọ̀n bí àwa náà ti jẹ́ ajíhìnrere, ẹ jẹ́ ká wá jíròrò àwọn ìbéèrè méjì yìí: Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn èèyàn gbọ́ ìhìn rere lónìí? Báwo la ṣe lè máa ṣe ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere?
KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁWỌN ÈÈYÀN GBỌ́ ÌHÌN RERE?
4. Ohun tí kì í ṣe òótọ́ wo làwọn èèyàn sábà máa ń sọ nípa Ọlọ́run?
4 Ká sọ pé o ò rí bàbá rẹ rí, àwọn kan wá sọ fún ẹ pé látìgbà tó o ti wà ní kékeré ni bàbá rẹ ti pa ìwọ àtàwọn yòókù nínú ìdílé yín tì. Wọ́n tún sọ pé kì í bá àwọn èèyàn ṣe, kì í fẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tóun ń ṣe, àti pé ìkà èèyàn ni. Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé kó o má wulẹ̀ yọ ara rẹ lẹ́nu láti wá bàbá rẹ, torí pé ó ti kú. Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tó o bá gbọ́ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀? Irú àwọn ọ̀rọ̀ tí kì í ṣòótọ́ yìí làwọn èèyàn máa ń sọ nípa Ọlọ́run. Wọ́n sọ pé Ọlọ́run kò ṣeé mọ̀ àti pé ìkà ni. Bí àpẹẹrẹ, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn kan sọ pé Ọlọ́run máa dá àwọn ẹni burúkú lóró nínú iná ọ̀run àpáàdì. Àwọn kan sọ pé Ọlọ́run ló ń fa àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ láyé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yẹn ń kan àwọn èèyàn rere náà, wọ́n sọ pé ńṣe ni Ọlọ́run ń fi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn jẹ àwa èèyàn níyà.
5, 6. Ipa wo ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n àtàwọn ẹ̀kọ́ èké míì ń ní lórí àwọn èèyàn?
5 Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé kò sí Ọlọ́run. Ẹ tiẹ̀ gbọ́ ohun táwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n sọ. Wọ́n sọ pé ayé kàn ṣàdédé wà ni, pé kì í ṣe ẹnì kan ló ṣẹ̀dá rẹ̀. Àwọn kan tún sọ pé oríṣi ẹranko kan làwa èèyàn jẹ́. Torí bẹ́ẹ̀, wọ́n ní kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé àwọn èèyàn máa ń hùwà bí ẹranko nígbà míì. Àwọn kan tún sọ pé kò sóhun tó burú nínú kí àwọn alágbára máa tẹ àwọn aláìní lórí ba, kí wọ́n sì máa hùwà ìkà sí wọn. Wọ́n ní bó ṣe wà látètèkọ́ṣe nìyẹn, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì máa rí. Torí náà, wọ́n gbà pé kò sígbà táwọn èèyàn ò ní máa hùwà ìrẹ́jẹ sí ara wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn tó gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́ kò ní ìrètí kankan.
6 Kò sí àní-àní pé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n àtàwọn ẹ̀kọ́ èké míì ti túbọ̀ pa kún ìyà tó ń jẹ aráyé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. (Róòmù 1:28-31; 2 Tím. 3:1-5) Àbí a lè sọ pé ìhìn rere làwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí? Rárá o! Kàkà bẹ́ẹ̀, bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ gan-an lọ̀rọ̀ rí, wọ́n tí mú káwọn èèyàn “wà nínú òkùnkùn ní ti èrò orí, tí a sì sọ wọ́n di àjèjì sí ìyè tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run.” (Éfé. 4:17-19) Yàtọ̀ síyẹn, ìgbàgbọ́ tí ọ̀pọ̀ ní nínú ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n àtàwọn ẹ̀kọ́ èké míì kò jẹ́ kí wọ́n tẹ́tí sí ìhìn rere tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.—Ka Éfésù 2:11-13.
7, 8. Kí lohun kan ṣoṣo tó lè mú káwọn èèyàn lóye ìhìn rere?
7 Káwọn èèyàn tó lè bá Ọlọ́run rẹ́, wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ gbà pé Ọlọ́run wà àti pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí wọ́n sún mọ́ ọn. Kí la lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́? A lè rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá. Táwọn èèyàn bá fara balẹ̀ kíyè sí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá láìsí ẹ̀tanú, wọ́n á gbà pé ọlọ́gbọ́n àti alágbára ni Ọlọ́run. (Róòmù 1:19, 20) Tá a bá fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọyì àwọn nǹkan àgbàyanu tí Ọlọ́run gbé ṣe nínú ìṣẹ̀dá, a lè lo ìwé náà Sún Mọ́ Jèhófà. Àmọ́, àwọn ìbéèrè pàtàkì kan wà táwọn èèyàn ò lè rí ìdáhùn sí tó bá jẹ́ pé ara ohun tí Ọlọ́run dá nìkan ni wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́. Irú bíi: Kí nìdí tí Ọlọ́run fi gbà kí ìyà máa jẹ àwa èèyàn? Kí ni Ọlọ́run ní lọ́kàn tó fi dá ilẹ̀ ayé yìí? Ǹjẹ́ Ọlọ́run bìkítà nípa mi?
8 Ohun kan ṣoṣo tó lè mú káwọn èèyàn lóye ìhìn rere nípa Ọlọ́run àtohun tó ní lọ́kàn láti ṣe ni pé kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá la ní láti máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọn! Tá a bá fẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa wọ àwọn èèyàn lọ́kàn, kì í ṣe pé a kàn fẹ́ máa to ẹ̀rí jọ pelemọ lásán, ńṣe la fẹ́ kí àlàyé wa yé wọn, débi tí wọ́n á fi yí èrò wọn pa dà. (2 Tím. 3:14) Tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, a tún lè kọ́ bá a ṣe lè máa ṣàlàyé ẹ̀kọ́ òtítọ́ lọ́nà táá mú káwọn èèyàn yí èrò wọn pa dà. Kí ló mú kí Jésù mọ bí wọ́n ṣe ń yíni lérò pa dà? Ohun kan ni pé ó mọ béèyàn ṣe ń lo ìbéèrè lọ́nà tó gbéṣẹ́. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?
ÀWỌN AJÍHÌNRERE TÓ MỌṢẸ́ MÁA Ń LO ÌBÉÈRÈ LỌ́NÀ TÓ GBÉṢẸ́
9. Tá a bá fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè sún mọ́ Ọlọ́run, kí la gbọ́dọ̀ máa ṣe?
9 Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lo ìbéèrè lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù bíi ti Jésù? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ yìí náà: Ká sọ pé ara rẹ kò yá, o wá lọ sílé ìwòsàn. Dókítà wá ní kó o fọkàn balẹ̀, pé òun máa ṣe iṣẹ́ abẹ kan tó lágbára fún ẹ, kí àìsàn tó ń ṣe ẹ́ lè lọ pátápátá. Ó ṣeé ṣe kí ọkàn rẹ balẹ̀, kó o sì gbà pẹ̀lú dókítà náà. Àmọ́, báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tó bá jẹ́ pé dókítà náà ò tiẹ̀ béèrè ohun tó ń ṣe ẹ́ rárá kó tó sọ pé òun máa ṣiṣẹ́ abẹ fún ẹ? Ó dájú pé ńṣe ni wàá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì bóyá dókítà náà mọṣẹ́. Kò sí bí dókítà kan ṣe lè mọṣẹ́ tó, ó yẹ kó kọ́kọ́ béèrè àwọn ìbéèrè kan lọ́wọ́ aláìsàn, kó gbọ́ bó ṣe ń ṣe é kó tó lè mọ irú ìtọ́jú tó máa fún un. Lọ́nà kan náà, ká tó lè mú káwọn èèyàn lóye ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ mọ béèyàn ṣe ń lo ìbéèrè lọ́nà tó gbéṣẹ́. Ìyẹn ló máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́.
Tá a bá fẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọ àwọn èèyàn lọ́kàn, a gbọ́dọ̀ mú kí wọ́n ronú jinlẹ̀ débi tí wọ́n á fi yí èrò wọn pa dà
10, 11. Àṣeyọrí wo la máa ṣe tá a bá tẹ̀ lẹ́ ọ̀nà tí Jésù gbà kọ́ni?
10 Jésù mọ̀ pé tí olùkọ́ bá bi akẹ́kọ̀ọ́ láwọn ìbéèrè tó ń múni ronú jinlẹ̀, ó máa jẹ́ kó mọ bí òye akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe tó, ó sì máa jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ náà lè sọ èrò rẹ̀ jáde. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù fẹ́ kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yín rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìwà ìrẹ̀lẹ̀, ó kọ́kọ́ bi wọ́n ní ìbéèrè kan tó ń múni ronú jinlẹ̀. (Máàkù 9:33) Kí Pétérù lè mọ béèyàn ṣe ń ronú lórí àwọn ìlànà dípò kéèyàn máa wá òfin pàtó nígbà tó bá fẹ́ ṣe nǹkan, Jésù bi í láwọn ìbéèrè kan, tó mú kó ronú kó sì yan èyí tó tọ́. (Mát. 17:24-26) Nígbà míì, torí kí Jésù lè mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó bi wọ́n ní oríṣiríṣi ìbéèrè tó máa ń jẹ́ kéèyàn sọ èrò ọkàn ẹni. (Ka Mátíù 16:13-17.) Àwọn ìbéèrè àti àlàyé Jésù mú káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ òtítọ́. Ó tún mú kí ọ̀rọ̀ náà wọ̀ wọ́n lọ́kàn, ó sì mú kí wọ́n fi ohun tí wọ́n gbọ́ sílò.
11 Tá a bá ń lo ìbéèrè lọ́nà tó gbéṣẹ́ bíi ti Jésù, a máa mọ ọ̀nà tó dára jù láti ran ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn èèyàn tá à ń wàásù fún lọ́wọ́. A máa mọ bá a ṣe lè mú kí wọ́n ronú jinlẹ̀ to bá ṣẹlẹ̀ pé wọn ò fara mọ́ ohun tá a sọ. A lè kọ́ àwọn èèyàn bí wọ́n ṣe lè ṣe ara wọn láǹfààní. Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà mẹ́ta tá a lè gbà lo ìbéèrè lọ́nà tó gbéṣẹ́.
12-14. Báwo lo ṣe lè ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kó lè máa fi ìdánilójú sọ̀rọ̀ nípa ohun tó gbà gbọ́? Sọ àpẹẹrẹ kan.
12 Àpẹẹrẹ kìíní: Kí lo máa ṣe tí ọmọ rẹ kan bá sọ fún ẹ pé òun ò mọ bí òun ṣe lè ṣàlàyé fún àwọn ọmọléèwé òun pé Ọlọ́run ló dá àwọn nǹkan? Ó dájú pé wàá ṣe ohun tó máa mú kí ọmọ náà lè fi ìdánilójú sọ ohun tó gbà gbọ́. Torí náà, dípò tí wàá fi bẹ̀rẹ̀ sí í bú u tàbí kí o kó àlàyé palẹ̀, o ò ṣe ṣe bíi ti Jésù, kó o bi í láwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kó o mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀? Báwo lo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
13 Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá jọ ka àwọn apá kan nínú ìwé Sún Mọ́ Jèhófà, o lè bi ọmọ rẹ pe: Níbi tá a kà yìí, àlàyé wo ló mú kí ìwọ alára gbà pé Ẹlẹ́dàá ló dá àwọn nǹkan? Kó o wá jẹ́ kí ọmọ rẹ sọ àwọn ìdí míì tó tún fi gbà pé Ẹlẹ́dàá ló dá àwọn nǹkan àti ìdí tó fi wù ú láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Róòmù 12:2) Jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ̀ pé ìdí tí ìwọ àti òun fi gbà pé Ọlọ́run ló dá àwọn nǹkan lè yàtọ̀ síra.
14 O lè wá sọ fún ọmọ rẹ pé òun náà lè lo irú ọ̀nà tó o gbà jíròrò pẹ̀lú rẹ̀ yìí nígbà tó bá ń jẹ́rìí fún àwọn ọmọléèwé rẹ̀. Lédè míì, ọmọ rẹ lè sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó kan, lẹ́yìn náà kó wá bi wọ́n ní ìbéèrè táá jẹ́ kí wọ́n sọ èrò wọn. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ rẹ lè sọ fún ọmọléèwé rẹ̀ pé kó ka ìwé Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 172, ìpínrọ̀ 12. Ó lè wá béèrè lọ́wọ́ ọmọléèwé rẹ̀ pé, ‘Ṣé òótọ́ ni pé ọpọlọ èèyàn lè gba gbogbo ìsọfúnni tó wà nínú ibi ìkówèésí tí ń bẹ láyé yìí pátá àti pé bóyá ni àyè ìkó-nǹkan-sí tí ọpọlọ ní á ṣeé díwọ̀n pàápàá?’ Ó ṣeé ṣe kí ọmọléèwé rẹ̀ sọ pé, òótọ́ ni. Lẹ́yìn náà, ọmọ rẹ lè wá béèrè pé, ‘Ǹjẹ́ o rò pé ńṣe ni ọpọlọ èèyàn tó jẹ́ ohun àgbàyanu tó sì lè gba àìmọye ìsọfúnni yìí kàn ṣàdédé wà láìjẹ́ pé ẹni kan ṣẹ̀dá rẹ̀?’ Kí ọmọ rẹ lè túbọ̀ nígboyà láti máa sọ ohun tó gbà gbọ́ fáwọn míì, á dára kẹ́ ẹ máa ṣe ìdánrawò látìgbàdégbà. Tó o bá ń kọ́ ọmọ rẹ bó ṣe lè máa lo ìbéèrè lọ́nà tó gbéṣẹ́, wàá tipa bẹ́ẹ̀ mú kí òun náà máa ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere.
15. Báwo la ṣe lè lo ìbéèrè láti mú kí ẹni tí kò gbà pé Ọlọ́run wà pèrò dà?
15 Àpẹẹrẹ Kejì: O lè bá ẹnì kan pà dé lóde ẹ̀rí tó sọ pé kò dá òun lójú bóyá Ọlọ́run wà. O sì lè rí ẹlòmíì tó máa sọ pé òun kò tiẹ̀ gbà gbọ́ rárá pé Ọlọ́run wà. Dípò tí wàá kàn fi onítọ̀hún sílẹ̀ bẹ́ẹ̀, o lè bi í pé ó ti tó ìgbà wo tó ti ní èrò yìí. O tún lè bi í pé ṣe ó lè sọ ìdí tó fi ní irú èrò bẹ́ẹ̀ fún ẹ. Lẹ́yìn tó bá ti sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀, gbóríyìn fún un dáadáa. Kó o wá sọ fún un pé: “Ó dájú pé ẹ ti máa ronú gan-an lórí ọ̀rọ̀ yìí.” O lè wá bi í bóyá ó máa fẹ́ láti ka ìwé kan tó sọ àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé ẹnì kan ló dá àwọn ohun alààyè. Tí onítọ̀hún kò bá ní ẹ̀tanú, ó ṣeé ṣe kó gbà láti ka irú ìwé bẹ́ẹ̀. O lè wá fún un ní ìwé Sún Mọ́ Jèhófà. Ní kí ó ka ìpínrọ̀ 12 lójú ìwé 172. Torí náà, téèyàn bá fọgbọ́n lo ìbéèrè, ó lè mú kẹ́ni tí kò fẹ́ gbọ́ ìhìn rere tẹ́lẹ̀ gbọ́ ọ.
16. Kí nìdí tó fi yẹ ká rí i dájú pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa ò kàn máa ka ìdáhùn jáde látinú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́?
16 Àpẹẹrẹ kẹta: Tá a bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí ló lè ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ́ pé ńṣe lonítọ̀hún kàn máa ń ka ìdáhùn jáde ní tààràtà látinú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́? Kò ní jẹ́ kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ yé akẹ́kọ̀ọ́ náà dáadáa. Torí pé tí akẹ́kọ̀ọ́ kan bá kàn ń ka ìdáhùn jáde, ńṣe ló máa dà bí igi tí gbòǹgbò rẹ̀ kò fìdí múlẹ̀. Kò sì dájú pé irú akẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ lè dúró lórí ohun tó gbà gbọ́ nígbà tí àwọn èèyàn bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàtakò sí i. (Mát. 13:20, 21) Tá ò bá fẹ́ kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀, ó yẹ ká jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ wa máa sọ èrò rẹ̀ nípa ohun tó ń kọ́. Gbìyànjú láti mọ̀ bóyá ó fara mọ́ àwọn àlàyé tó wà nínú ìwé náà. Ó tún ṣe pàtàkì gan-an pé kó o jẹ́ kó sọ ìdí tó fi fara mọ́ àwọn àlàyé náà tàbí ìdí tí kò fi fara mọ́ ọn. O lè ní kó ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ inú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, kó o sì béèrè àwọn ìbéèrè kan tó máa jẹ́ kí òun fúnra rẹ̀ dórí èrò tó tọ́. (Héb. 5:14) Tá a bá ń lo ìbéèrè lọ́nà tó gbéṣẹ́, ìgbàgbọ́ àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì á túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, wọn kò ní rẹ̀wẹ̀sì nígbà táwọn èèyàn bá ń ṣàtakò sí wọn, wọn ò sì ní gbà fún ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ ṣì wọ́n lọ́nà. (Kól. 2:6-8) Kí la tún lè ṣe ká bàa lè máa ṣe ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere?
ÀWỌN AJÍHÌNRERE TÓ MỌṢẸ́ MÁA Ń RAN ARA WỌN LỌ́WỌ́
17, 18. Báwo ni àwa àti ẹni tá a jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí ṣe lè máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀?
17 Méjì-méjì ni Jésù pín àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà tó rán wọn jáde láti lọ wàásù. (Máàkù 6:7; Lúùkù 10:1) Pọ́ọ̀lù náà mẹ́nu kan àwọn kan tí wọ́n jẹ́ “àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀” rẹ̀ “tí wọ́n ti làkàkà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú [rẹ̀] nínú ìhìn rere.” (Fílí. 4:3) Lọ́dún 1953, àwa èèyàn Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ ètò kan nínú èyí tí àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run ti ń dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ lóde ẹ̀rí.
18 Báwo ni ìwọ àtẹni tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí ṣe lè máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀? (Ka 1 Kọ́ríńtì 3:6-9.) Tí ẹnì kejì rẹ bá ń ka ẹsẹ ìwé Mímọ́ kan, ńṣe ni kí ìwọ náà ṣí i, kó o sì máa fojú bá a lọ. Fetí sí ẹni tẹ́ ẹ jọ ṣiṣẹ́ àti ẹni tó ń wàásù fún nígbà tí kálukú wọn bá ń sọ̀rọ̀. Máa fọkàn bá ìjíròrò náà lọ torí pé ẹni tẹ́ ẹ jọ ṣiṣẹ́ lè nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ láti mú kí kókó kan túbọ̀ yé ẹni tẹ́ ẹ̀ ń wàásù fún dáadáa. (Oníw. 4:12) Àmọ́ o, má ṣe já lu ọ̀rọ̀ nígbà tí ẹnì kejì rẹ ṣì ń fọgbọ́n ṣàlàyé ọ̀rọ̀ láti lè fa kókó kan yọ fún onílé. Tó o bá já lu ọ̀rọ̀ nígbà tí ẹnì kejì rẹ ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, èyí lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá a, ó sì lè mú kí ọ̀rọ̀ dàrú mọ́ onílé lójú. Lóòótọ́, kò burú láti dá sí ìjíròrò náà, àmọ́ kò yẹ kí ohun tó o máa fi kún ọ̀rọ̀ náà kọjá kókó kan tàbí méjì. Lẹ́yìn náà jẹ́ kí ẹnì kejì rẹ máa bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìṣó.
19. Kí ló yẹ ká máa fi sọ́kàn, kí sì nìdí?
19 Báwo ni ìwọ àti ẹni kejì rẹ ṣe lè máa ran ara yín lọ́wọ́ bẹ́ ẹ ṣe ń lọ láti ilé kan sí òmíràn? Ẹ ò ṣe máa fi àkókò yẹn jíròrò bẹ́ ẹ ṣe lè mú kí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ yín túbọ̀ dára sí i? Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe máa sọ̀rọ̀ tí kò dára nípa àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Bákan náà, ẹ má ṣe máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn ará. (Òwe 18:24) Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé aláìpé ni gbogbo wa. Àǹfààní ńláǹlà ni Jèhófà fún wa bó ṣe yọ̀ǹda pé ká máa wàásù ìhìn rere ológo yìí, ìṣúra iyebíye ló sì fi síkàáwọ́ wa. (Ka 2 Kọ́ríńtì 4:1, 7.) Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa fi hàn pé a mọrírì ìṣúra yìí, ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti rí i pé a ń ṣe ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere.