KỌ́ ỌMỌ RẸ
Ohun Tí O Bá Ṣe Lè Dun Ọlọ́run—Bí O Ṣe Lè Mú Inú Rẹ̀ Dùn
Ǹjẹ́ ẹnì kan ti ṣe ohun tó dùn ẹ́ rí débi pé o bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún?—a Kó sí ẹni tí kò tíì ṣẹlẹ̀ sí rí. Nígbà míì, ó lè máà jẹ́ torí pé ẹnì kan nà wá lẹ́gba. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni ẹnì kan parọ́ mọ́ wa. Ìyẹn máa dùn wá gan-an, àbí?— Bákan náà, ó máa ń dun Ọlọ́run tí àwọn èèyàn bá pa irọ́ mọ́ ọn. Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí a ṣe lè mú inú Ọlọ́run dùn dípò ká máa ṣe ohun tó máa dùn ún.
Bíbélì sọ pé àwọn èèyàn kan láwọn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, àmọ́ wọ́n máa ń ṣe ohun tó “mú kí inú rẹ̀ bàjẹ́,” kódà ‘wọ́n ṣe ohun tí ó dun’ Ọlọ́run! Ṣùgbọ́n a mọ̀ pé kò sí ẹni tó lè ṣe Jèhófà léṣe, torí pé òun ni Olódùmarè. Jẹ́ ká wá wo ìdí tí inú Jèhófà fi máa ń bà jẹ́ tí a kò bá ṣe ohun tó ní ká ṣe.
Àwọn méjì tí Jèhófà kọ́kọ́ dá sórí ilẹ̀ ayé ṣe nǹkan tó dun Jèhófà gan-an. Ọlọ́run fi àwọn méjì yẹn sínú Párádísè, ibẹ̀ jẹ́ ibi kan tó rẹwà lórí ilẹ̀ ayé, tí à ń pè ní “ọgbà Édẹ́nì.” Ta ni àwọn méjì yẹn?— O gbà á, Ádámù lẹni àkọ́kọ́, ìgbà tó yá ni Ọlọ́run wá dá Éfà. Jẹ́ ká wo ohun tí wọ́n ṣe tó dun Jèhófà.
Lẹ́yìn tí Ọlọ́run fi wọ́n sínú ọgbà yẹn, ó sọ fún wọn pé kí wọ́n máa tọ́jú rẹ̀. Ó tún sọ fún wọn pé wọ́n lè bímọ, kí wọ́n sì jọ máa gbé pọ̀ nínú ọgbà yẹn títí láé. Àmọ́, kí Ádámù àti Éfà tó bímọ, nǹkan búburú kan ṣẹlẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀?— Áńgẹ́lì kan tan Éfà pé kó ṣàìgbọràn sí Jèhófà, lẹ́yìn èyí, Ádámù náà ṣàìgbọràn. Jẹ́ ká wo bí ó ṣe ṣẹlẹ̀.
Áńgẹ́lì yẹn mú kí ejò kan máa ṣe bíi pé ó ń sọ̀rọ̀. Inú Éfà dùn nígbà tí ejò náà sọ fún un pé ó máa “dà bí Ọlọ́run.” Torí náà, ó ṣe ohun tí ejò náà sọ pé kó ṣe. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣe?—
Éfà jẹ èso igi tí Jèhófà sọ fún Ádámù pé wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ. Kí Ọlọ́run tó dá Éfà, Ó sọ fún Ádámù pé: “Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ ti máa jẹ àjẹtẹ́rùn. Ṣùgbọ́n ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.”
Éfà mọ òfin yẹn. Àmọ́, ojú rẹ̀ kò kúrò lára igi yẹn, ó wá “rí i pé igi náà dára fún oúnjẹ àti pé ohun kan tí ojú ń yánhànhàn fún ni . . . Nítorí náà, ó mú nínú èso rẹ̀, ó sì jẹ ẹ́.” Nígbà tí ó yá, ó fún Ádámù ní èso yẹn, òun náà sì jẹ ẹ́.” Kí lo rò pé ó fà á tí Ádámù fi ṣe bẹ́ẹ̀?— Ohun tó fà á ni pé Ádámù ti wá nífẹ̀ẹ́ Éfà ju bó ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lọ. Ìyẹn ló mú kó ṣe ohun tí ìyàwó rẹ̀ fẹ́ dípò ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Ohun tó dára jù ni pé ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà ju bí a ṣe ń ṣègbọràn sí àwọn èèyàn!
Ǹjẹ́ o rántí ejò tó bá Éfà sọ̀rọ̀? Ṣé o mọ̀ pé èèyàn lè ṣeé kó dà bíi pé bèbí kan ń sọ̀rọ̀? Torí náà, ẹnì kan ló mú kí ó dà bíi pé ejò ń sọ̀rọ̀. Ohùn ta ni Éfà gbọ́ látẹnu ejò yẹn?— Ohùn Èṣù ni o, ẹni tí à ń pè ní ‘ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà àti Sátánì.’
Ǹjẹ́ o mọ ohun tí o lè ṣe tí wàá fi mú inú Jèhófà dùn?— Tí o bá ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ní gbogbo ìgbà, wàá mú inú rẹ̀ dùn. Àmọ́ Sátánì sọ pé òun á mú kí gbogbo èèyàn máa ṣe ohun tí òun bá fẹ́. Torí náà, Ọlọ́run sọ fún wa pé: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.” Ńṣe ni Sátánì ń fi Jèhófà ṣe yẹ̀yẹ́. Ó ní òun lè mú kí gbogbo èèyàn kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà, kí wọ́n má sì jọ́sìn rẹ̀ mọ́. Torí náà, ó máa dára gan-an ti ìwọ náà bá ń gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu, tí o sì ń jọ́sìn rẹ̀, wàá lè máa mú inú rẹ̀ dùn! Ṣé wàá máa ṣe bẹ́ẹ̀?—
Kà á nínú Bíbélì rẹ
a Tó bá jẹ́ ọmọdé lò ń ka ìwé yìí fún, má gbàgbé láti dánu dúró níbi tó o bá ti rí àmì dáàṣì (—), kó o sì jẹ́ kí ọmọ náà sọ tinú rẹ̀.