Àjíǹde—Ni Ìrètí Tó Wà fún Àwọn Òkú
Ǹjẹ́ o gba ìlérí tó wà nínú Bíbélì gbọ́, pé Ọlọ́run máa jí àwọn òkú dìde?a Ká sòótọ́, tá a bá rántí pé lọ́jọ́ kan, a tún máa pa dà rí àwọn èèyàn wa tó ti kú, inú wa máa ń dùn gan-an. Àmọ́, ṣé kì í ṣe pé àlá tí kò lè ṣẹ ni ìrètí yìí? Àpẹẹrẹ àwọn àpọ́sítélì Jésù lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí.
Ó dá àwọn àpọ́sítélì Jésù lójú pé lóòótọ́ ni àwọn òkú máa jíǹde. Kí nìdí tí wọ́n fi gbà bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká gbé méjì lára rẹ̀ yẹ̀wò. Àkọ́kọ́, ohun tó mú kí ìrètí wọn dájú ni pé Jésù kú, ó sì jíǹde. Yàtọ̀ sí àwọn àpọ́sítélì Jésù, àwọn tó “ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lọ nínú àwọn ará lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo” ni wọ́n rí Jésù lẹ́yìn tó jíǹde. (1 Kọ́ríńtì 15:6) Láfikún sí i, ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin fi hàn pé, àwọn èèyàn jẹ́rìí sí i, wọ́n sì gbà pé lóòtọ́ ni Jésù jíǹde.—Mátíù 27:62–28:20; Máàkù 16:1-8; Lúùkù 24:1-53; Jòhánù 20:1–21:25.
Ìdí kejì ni pé, àwọn àpọ́sítélì yẹn fojú ara wọn rí i tí Jésù jí àwọn èèyàn mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ dìde, ọ̀kan ní ìlú Náínì, òmíràn ní Kápánáúmù àti ní Bẹ́tánì pẹ̀lú. (Lúùkù 7:11-17; 8:49-56; Jòhánù 11:1-44) Nínú ọ̀kan lára àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde tó ṣẹlẹ̀ ní Bẹ́tánì. Ìdílé kan tó sún mọ́ Jésù tímọ́tímọ́ ló ṣẹlẹ̀ sí. Ẹ jẹ́ ká túbọ̀ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀.
“ÈMI NI ÀJÍǸDE”
Lẹ́yìn ọjọ́ kẹrin tí Lásárù kú, Jésù sọ fún Màtá tó jẹ́ arábìnrin Lásárù pé: “Arákùnrin rẹ yóò dìde.” Ṣùgbọ́n, ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yẹn kò tètè yé Màtá. Ó wá sọ fún Jésù pé: “Mo mọ̀ pé yóò dìde,” ṣe ni Màtá rò pé ọjọ́ iwájú nìyẹn máa tó ṣẹlẹ̀. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún un lẹ́yìn tí Jésù sọ pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè,” ohun tó rí ni pé Jésù ti jí arákùnrin rẹ̀ dìde! Fojú inú wo bí ìdùnnú ṣe ṣubú layọ̀ fún Màtá.—Jòhánù 11:23-25.
Níbo ni Lásárù wà fún ọjọ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó fi kú? Lásárù ò sọ ohunkóhun tó fihàn pé òun wà láàyè níbì kan láàárín ọjọ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yẹn. Lẹ́yìn tó kú ọkàn rẹ̀ kò lọ sí ọ̀run. Torí náà, nígbà tí Jésù jí i dìde, kì í ṣe pé ó fipá mú un kúrò ní ọ̀run níbì kan tó ti ń gbádùn nítòsí Ọlọ́run. Níbo wá ni Lásárù wà ní ọjọ́ mẹ́rin yẹn? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ńṣe ló ń sùn nínú sàréè.—Oníwàásù 9:5, 10.
Rántí pé, Jésù fi ikú wé oorun téèyàn sùn àmọ́ tó jẹ́ pé nípasẹ̀ àjíǹde ló fi máa pa dà jí . Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “‘Lásárù ọ̀rẹ́ wa ti sùn, ṣùgbọ́n mo ń rìnrìn àjò lọ sí ibẹ̀ láti jí i.’ Àwọn ọmọ ẹ̀yìn wí fún un pé: ‘Olúwa, bí ó bá jẹ́ pé ó ń sùn ni, ara rẹ̀ yóò yá.’ Àmọ́ ṣá, ọ̀rọ̀ nípa ikú rẹ̀ ni Jésù ń bá wọn sọ. Ṣùgbọ́n wọ́n lérò pé ó ń sọ̀rọ̀ nípa sísinmi nínú oorun. Nítorí náà, Jésù wí fún wọn ní kedere pé: ‘Lásárù ti kú.’” (John 11:11-14) Bí Jésù ṣe jí Lásárù dìde mú kó làǹfààní láti pa dà wà láàyè kó lè wà pẹ̀lú ìdílé rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan si. Àbí ẹ̀ ò rí i pé, ẹ̀bùn àgbàyanu ni Jésù fún ìdílé Lásárù!
Bí Jésù ṣe jí àwọn òkú dìde nígbà tó wà láyé jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tó máa ṣe fún aráyé lọ́jọ́ iwájú tó bá di Ọba Ìjọba Ọlọ́run.b Nígbà tí Jésù bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé, ó máa jí àwọn èèyàn tó ń sùn nínú ibojì dìde. Ìdí nìyẹn tó fi sọ pé, “Èmi ni àjíǹde.” Inú rẹ máa dùn kọjá àfẹnusọ, tó o bá rí àwọn èèyàn rẹ tí wọ́n jíǹde. Ìyẹn nìkan kọ́ o, inú àwọn tó jíǹde pàápàá máa dùn dọ́ba!—Lúùkù 8:56.
Ronú nípa bí wàá ṣe láyọ̀ tó tí àwọn èèyàn rẹ tó ti kú bá jíǹde!
ÌGBÀGBỌ́ TÓ Ń FÚNNI NÍ ÌYÈ AYÉRAYÉ
Jésù sọ fún Màtá pé: “Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè, àti olúkúlùkù ẹni tí ó wà láàyè, tí ó sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, kì yóò kú láé.” (Jòhánù 11:25, 26) Bí àwọn tí Jésù máa jí dìde nígbà ẹgbẹ̀rún ọdún ìṣàkóso rẹ̀ bá lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ lóòótọ́, wọ́n máa láǹfààní láti wà láàyè títí láé.
“Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè.”—Jòhánù 11:25
Lẹ́yìn tí Jésù sọ ọ̀rọ̀ tó gbàfiyèsí yẹn, ó wá bi Màtá ní ìbéèrè kan tó ń múni ronú jinlẹ̀ pé: “‘Ìwọ ha gba èyí gbọ́ bí?’ Ó wí fún un pé: ‘Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, mo ti gbà gbọ́ pé ìwọ ni Kristi Ọmọ Ọlọ́run.’” (Jòhánù 11: 26, 27) Ìwọ ń kọ́, ṣé ó wù ẹ́ láti ní ìgbàgbọ́ nínú ìrètí àjíǹde bí i tí Màtá? Tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, ohun àkọ́kọ́ tó o gbọ́dọ̀ ṣe ní pé, kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe fún aráyé. (Jòhánù 17:3; 1 Tímótì 2:4) Ìmọ̀ yẹn lè jẹ́ kí o ní ìgbàgbọ́. O ò ṣe béèrè lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí wọ́n fi ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa àjíǹde hàn ẹ́. Inú wọn á dùn láti bá ẹ ìjíròrò nípa ìrètí àgbàyanu yìí.
a Wo àpilẹ̀kọ náà “Ikú Kọ́ Ni Òpin Ìgbésí Ayé Ẹ̀dá!” lójú ìwé 6 nínú ìwé yìí.
b Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa ìlérí tí Bíbélì ṣe nípa ìrètí àjíǹde tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, ka orí 7 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Inú rẹ máa dùn kọjá àfẹnusọ, tó o bá rí àwọn èèyàn rẹ tí wọ́n jíǹde!