KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | JÉSÙ GBÀ WÁ—LỌ́WỌ́ KÍ NI?
Ìdí Tí A Fi Nílò Ìgbàlà
“Ènìyàn, tí obìnrin bí, ọlọ́jọ́ kúkúrú ni, ó sì kún fún ṣìbáṣìbo. Ó jáde wá bí ìtànná, a sì ké e kúrò, ó sì fẹsẹ̀ fẹ bí òjìji, kò sì sí mọ́.”—Jóòbù 14:1, 2.
Láti àtètèkọ́ṣe ló ti máa ń wu àwa èèyàn láti wà láàyè títí láé, kí ara wa le, kó sì máa jà yọ̀yọ̀ bí tọmọdé jòjòló. Àmọ́ òótọ́ tó ń bani nínú jẹ́ ni pé, ikú ò ṣe é yẹ̀ sílẹ̀. Ọ̀rọ̀ Bíbélì yìí tí Jóòbù sọ láti bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọdún sẹ́yìn ṣì jóòótọ́ títí dòní.
Kò sẹ́ni tí kò wù kó wà láàyè títí láé. Ìdí sì ni pé Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ti fi ìfẹ́ láti ní ẹ̀mí gígùn sí wa lọ́kàn. (Oníwàásù 3:11) Bó bá jẹ́ pé kò ṣeé ṣe láti wà títí lọ kánrin, ṣé ó máa bọ́gbọ́n mu kí Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ wa fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ sí wa lọ́kàn? Ó dájú pé kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi pe ikú ní ọ̀tá wa, tó sì tún ṣèlérí pé ‘a ó sọ ọ́ di asán.’—1 Kọ́ríńtì 15:26.
Ọ̀tá ni ikú jẹ́ lóòótọ́, ìdí sì nìyẹn tí kò fi sẹ́ni tó fẹ́ kó sọ́wọ́ rẹ̀. Abájọ tó fi jẹ́ pé bí a bá rí ewu kan, ńṣe la máa fara pamọ́ tàbí ká yẹra tàbí ká tiẹ̀ sá pàápàá. Bó bá sì jẹ́ àìsàn ló ń ṣe wá, a máa ń sapá ká lè rí ìwòsàn. Lẹ́nu kan, a máa ń sá fún ohunkóhun tó lè dá ẹ̀mí wa légbodò.
Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe pé kí ikú tó ń pọ́n aráyé lójú látọdúnmọ́dún pa dà di asán lọ́jọ́ kan? Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run ò kàn dá wa láti lo ọdún díẹ̀ láyé ká sì kú. Kódà, ikú ò sí lára ohun tó fẹ́ fáwa èèyàn. Ohun tó fẹ́ fún wa ni pé ká máa gbélé ayé kánrin kése. Ohun tí Ọlọ́run bá sì pinnu, dandan ni kó di ṣíṣe.—Aísáyà 55:11.
Báwo wá ni ikú ṣe máa di asán? Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ń wá ojútùú sí ikú, àmọ́ títí dòní olónìí, pàbó ni gbogbo ìsapá wọn já sí. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí ṣe oríṣiríṣi oògùn tó lè dènà àwọn àìsàn kan, kódà wọ́n ti tú fìn-ín-ìdí-kókò nínú ìpìlẹ̀ àbùdá wa kí wọ́n lè wá ọ̀nà láti dènà ikú. Wọ́n kúkú ṣàṣeyọrí díẹ̀ torí pé láwọn ibì kan, ẹ̀mí àwọn èèyàn ti ń gùn ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Síbẹ̀, àwa èèyàn ṣì ń kú. Bíbélì sọ pé, “gbogbo wọ́n sì ń padà sí ekuru.”—Oníwàásù 3:20.
Àmọ́, ohun ayọ̀ ló jẹ́ pé a kò nílò láti gbára lé èèyàn fún ojútùú sí ìṣòro yìí. Ìdí ni pé, Jèhófà Ọlọ́run ti ṣe ọ̀nà àbáyọ tá a fi máa bọ́ lọ́wọ́ ikú. Ẹni tó sì jẹ́ òléwájú nínú ètò yẹn ni Jésù Kristi.