Ó Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn
“Àwọn ohun tí mo . . . ní ìfẹ́ni sí jẹ́ sípa àwọn ọmọ ènìyàn.” —ÒWE 8:31.
1, 2. Sọ ẹ̀rí kan tó fi hàn pé Jésù ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún àwọn èèyàn.
ÀKỌ́BÍ ọmọkùnrin Ọlọ́run ni ẹni àkọ́kọ́ tó gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n Jèhófà yọ. Bíbélì ṣàpèjúwe Jésù gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n àti “àgbà òṣìṣẹ́” tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Baba rẹ̀. Ẹ fojú inú wo ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn tó máa ní bó ṣe ń wo Baba rẹ̀ tó ń “pèsè ọ̀run” tó sì ń “fàṣẹ gbé àwọn ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé kalẹ̀.” Àmọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run dùn pé Baba rẹ̀ dá àwọn ohun tí kò lẹ́mìí yìí, ó “ní ìfẹ́ni” àrà ọ̀tọ̀ “sípa àwọn ọmọ ènìyàn.” (Òwe 8:22-31) Dájúdájú, Jésù ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún àwọn èèyàn tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kó tó wá sí ayé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn.
2 Nígbà tó yá, kí Àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run lè fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin àti pé òun nífẹ̀ẹ́ Baba òun, tí òun sì ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún “àwọn ọmọ ènìyàn,” ó fínnúfíndọ̀ “sọ ara rẹ̀ di òfìfo” ó sì wá ní ìrí èèyàn. Kí nìdí tó fi ṣe gbogbo èyí? Ó ṣe bẹ́ẹ̀ torí kó lè ṣe “ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Fílí. 2:5-8; Mát. 20:28) Ẹ ò rí i pé ìfẹ́ tí Jésù ní fún àwa èèyàn pọ̀ gan an! Nígbà tí Jésù wà láyé, Ọlọ́run fún un lágbára tó jẹ́ kó lè ṣe iṣẹ́ ìyanu láti fi hàn bí ìfẹ́ tó ní fún àwọn èèyàn ṣe pọ̀ tó. Ohun tí Jésù ṣe yìí jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn nǹkan àgbàyanu tó máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ kárí ayé.
3. Kí la máa jíròrò báyìí?
3 Bí Jésù ṣe wá sí ayé tún jẹ́ kó lè “polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 4:43) Jésù mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run yìí ló máa sọ orúkọ Baba rẹ̀ di mímọ́, tó sì máa mú ojútùú bá gbogbo ìṣòro àwọn èèyàn. Abájọ tó fi jẹ́ pé jálẹ̀ gbogbo iṣẹ́ ìwàásù Jésù, àwọn ẹ̀rí tó ṣe kedere wà tó fi hàn pé Jésù nífẹ̀ẹ́ ìran èèyàn dénúdénú. Kí nìdí tó fi yẹ kí èyí ṣe pàtàkì sí wa? Torí pé àwọn ohun tá a bá kọ́ máa jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ ká sì ní ìrètí pé ọjọ́ ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Jẹ́ ká gbé mẹ́rin lára àwọn iṣẹ́ ìyanu Jésù yẹ̀ wò.
‘AGBÁRA WÀ NÍBẸ̀ FÚN UN LÁTI ṢE ÌMÚLÁRADÁ’
4. Sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù rí adẹ́tẹ̀ kan.
4 Jésù kò fọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ ṣeré rárá. Nígbà tó wà ní àgbègbè kan níbi tó ti ń wàásù, ìyẹn ní ìlú kan ní Gálílì, ó rí ohun kan tó ṣe é láàánú gan-an. (Máàkù 1:39, 40) Ọkùnrin kan wà níwájú rẹ̀ tó ní àrùn kan tó ń lé àwọn èèyàn sá, ìyẹn àrùn ẹ̀tẹ̀. Lúùkù tó jẹ́ oníṣègùn jẹ́rìí sí i pé àìsàn ọkùnrin náà ti burú gan-an, ó sọ pé ọkùnrin náà “kún fún ẹ̀tẹ̀.” (Lúùkù 5:12) “Nígbà tí ó tajú kán rí Jésù, ó dojú bolẹ̀, ó sì bẹ̀ ẹ́, ó wí pé: ‘Olúwa, bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́.’” Ọkùnrin yẹn mọ̀ dájú pé Jésù lágbára tó fi lè wo òun sàn, àmọ́ ohun tó fẹ́ mọ̀ ni pé, ṣé ó wu Jésù kó wo òun sàn? Kí ni Jésù máa ṣe sí ohun tí ọkùnrin yìí ń fi taratara bẹ̀bẹ̀ fún? Kí lohun tí Jésù ń rò bó ṣe ń wo ọkùnrin tó ṣeé ṣe kó ti di aláàbọ̀ ara yìí? Ǹjẹ́ Jésù náà máa dà bí àwọn Farisí, tí kì í káàánú àwọn tí àìsàn yìí ń ṣe? Ká sọ pé ìwọ ni, kí lo máa ṣe?
5. Kí ló sún Jésù tó fi sọ pé “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀!” nígbà tó fẹ́ wo ọkùnrin tó lárùn ẹ̀tẹ̀ náà sàn?
5 Ó ṣeé ṣe kí ọkùnrin tó lárùn ẹ̀tẹ̀ yìí ti kùnà láti pariwo “Aláìmọ́, aláìmọ́!” bí Òfin Mósè ṣe sọ pé kí alárùn ẹ̀tẹ̀ kan ṣe tó bá wà láàárín àwọn èèyàn. Àmọ́, Jésù ò wulẹ̀ fi ẹ̀sùn ìyẹn kàn án, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ran ọkùnrin náà lọ́wọ́. (Léf. 13:43-46) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ ohun tó ṣeé ṣe kí Jésù máa rò, síbẹ̀ a mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Àánú mú kí Jésù ṣe ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde, ó fi kan adẹ́tẹ̀ náà, ó sì sọ̀rọ̀ lọ́nà tó fi hàn pé ó fẹ́ ṣèrànwọ́ àti pé ó káàánú ọkùnrin náà, ó sọ pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.” Lẹ́yìn náà, “ẹ̀tẹ̀ náà sì pòórá kúrò lára rẹ̀.” (Lúùkù 5:13) Láìsí àní-àní, Jèhófà fún Jésù lágbára. Yàtọ̀ sí pé Jésù ń lo agbára náà láti fi ṣe iṣẹ́ ìyanu, irú èyí tó ṣe yìí, ó tún ń lò ó láti fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an.—Lúùkù 5:17.
6. Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe, kí ni wọ́n sì fi hàn?
6 Agbára Ọlọ́run mú kí Jésù Kristi lè ṣe onírúurú iṣẹ́ ìyanu tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Kì í ṣe àwọn tó lárùn ẹ̀tẹ̀ nìkan ló wò sàn, ó tún mú àwọn tó ní onírúurú àìsàn lára dá. Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí sọ pé: “Ogunlọ́gọ̀ náà . . . ṣe kàyéfì bí wọ́n ti rí tí àwọn odi ń sọ̀rọ̀, tí àwọn arọ sì ń rìn, tí àwọn afọ́jú sì ń ríran.” (Mát. 15:31) Jésù ò nílò kí ẹnikẹ́ni fi ẹ̀yà ara rẹ̀ tọrọ kó tó lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló mú àwọn ẹ̀yà ara tó níṣòro náà pa dà bọ̀ sípò. Ó wo àwọn èèyàn sàn lójú ẹsẹ̀, kódà nígbà míì ẹni tó ń ṣàìsàn náà lè máà sí lọ́dọ̀ rẹ̀. (Jòh. 4:46-54) Kí ni àwọn àpẹẹrẹ àtàtà yìí jẹ́ ká mọ̀? Ó jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe pé Jésù ẹni tó ti di Ọba lókè ọ̀run báyìí wulẹ̀ ní agbára láti woni sàn nìkan ni, ó tún wù ú pé kí aráyé bọ́ pátápátá lọ́wọ́ àìsàn. Ohun tá a kọ́ nínú ọwọ́ tí Jésù fi mú àwọn èèyàn jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ pé nínú ayé tuntun, àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yìí máa ṣẹ, tó ní: “Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì.” (Sm. 72:13) Nígbà yẹn, Jésù yóò ṣe ohun tó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ láti ran gbogbo àwọn tójú ń pọ́n lọ́wọ́.
“DÌDE, GBÉ ÀKÉTE RẸ, KÍ O SÌ MÁA RÌN”
7, 8. Ṣàpèjúwe ohun tó ṣẹlẹ̀ tí Jésù fi lọ sọ́dọ̀ ọkùnrin arọ kan ní odò adágún Bẹtisátà.
7 Lẹ́yìn oṣù mélòó kan tí Jésù pàdé ọkùnrin adẹ́tẹ̀ kan nílẹ̀ Gálílì. Ó rìnrìn àjò láti Gálílì lọ dé ilẹ̀ Jùdíà kó lè wàásù kó sì sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn làwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe Jésù á ti nípa lórí ìgbésí ayé wọn. Ó dájú pé tọkàntọkàn ló fi polongo ìhìn rere fáwọn òtòṣì, tó pòkìkí ìdásílẹ̀ lómìnira fún àwọn tí a mú ní òǹdè, tó sì di ọgbẹ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn.—Aísá. 61:1, 2; Lúùkù 4:18-21.
8 Nígbà tó di oṣù Nísàn, Jésù rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù láti lọ ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá, ó ṣe èyí kó lè ṣègbọràn sí àṣẹ Baba rẹ̀. Ètò ti ń lọ lọ́tùn-ún lósì ní ìlú náà torí àwọn èèyàn ti ń dé fún àjọyọ̀ mímọ́ yìí. Odò kan wà ní apá àríwá tẹ́ńpìlì tí wọ́n ń pè ní Bẹtisátà, ibẹ̀ ni Jésù ti rí ọkùnrin kan tó ń ṣàìsàn.
9, 10. (a) Kí ló mú káwọn èèyàn máa lọ síbi odò adágún Bẹtisátà? (b) Kí ni Jésù ṣe níbi odò adágún náà, kí sì ni èyí kọ́ wa? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
9 Ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn àtàwọn aláìlera ló máa ń rọ́ wá sí odò adágún Bẹtisátà. Kí ni wọ́n wá ń ṣe létí odò yìí? Nítorí ìdí kan tí a kò mọ̀, wọ́n gbà gbọ́ pé tí ẹnì kan tó ń ṣàìsàn bá wọ inú odò náà nígbà tó ń ru gùdù, ara ẹni náà máa yá lọ́nà ìyanu. Ẹ fojú inú wo bí nǹkan ṣe rí níbẹ̀ nígbà yẹn! Láìsí àní-àní, àníyàn á mú àwọn kan lára àwọn èrò tó wà níbẹ̀, àwọn kan lè ti rò pé bóyá làwọn á lè wọ inú odò náà, bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn míì ò ní kọ ohun tó lè dà, wọ́n á ṣáà fẹ́ kó sínú odò náà ni tó bá ti ru. Àmọ́, kí ló mú kí Jésù tó jẹ́ ẹ̀dá pípé, tí kò sì láìsàn kankan lára lọ síbi odò náà? Àánú àwọn èèyàn ló ṣe Jésù ìdí nìyẹn tó fi lọ bá ọkùnrin kan tó ti ń ṣàìsàn tipẹ́tipẹ́, kódà ọdún ti ọkùnrin náà fi wà lórí àìsàn ju ọdún tí Jésù fúnra rẹ̀ ti lò lórí ilẹ̀ ayé lọ.—Ka Jòhánù 5:5-9.
10 Ẹ fojú inú yàwòrán bí ojú ọkùnrin aláìsàn náà ṣe dágùdẹ̀ nígbà tí Jésù bi í bóyá ó fẹ́ kí àìsàn náà kúrò lára rẹ̀. Ojú ẹsẹ̀ ni ọkùnrin náà dáhùn. Ó fẹ́ kí ara òun yá, àmọ́ kò rò pé ìyẹn ṣeé ṣe, torí kò sí ẹni tó máa gbé e sínú odò adágún náà. Jésù wá pàṣẹ fún ọkùnrin náà pé kó dìde, kó gbé àkéte rẹ̀, kó sì máa rìn, ó dà bí ohun tí kò lè ṣẹlẹ̀ láé. Ó ṣe ohun tí Jésù ní kó ṣe lóòótọ́, ọkùnrin náà gbé àkéte rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn. Àbí ẹ ò rí nǹkan, ìtọ́wò ohun tí Jésù máa ṣe nínú ayé tuntun nìyẹn o! A tún rí i nínú iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe yìí pé ó jẹ́ aláàánú. Ó dìídì lọ sọ́dọ̀ ẹni tó nílò ìrànwọ́. Ó yẹ kí ohun tí Jésù ṣe yìí mú káwa náà máa bá a nìṣó láti máa wá àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa tí àwọn nǹkan búburú tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé yìí ń kó ìbànújẹ́ bá.
“TA NÍ FỌWỌ́ KAN Ẹ̀WÙ ÀWỌ̀LÉKÈ MI?”
11. Báwo ni ìtàn tó wà nínú Máàkù 5:25-34 ṣe jẹ́ kó ṣe kedere pé Jésù máa ń ṣàánú àwọn tí àìsàn ń pọ́n lójú?
11 Ka Máàkù 5:25-34. Odindi ọdún méjìlá ni obìnrin yìí fi ṣàìsàn tó ń kó ìtìjú báni yìí. Àìsàn yìí nípa lórí gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ látòkèdélẹ̀ títí kan ìjọsìn rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “ọ̀pọ̀ oníṣègùn . . . ti mú ọ̀pọ̀ ìrora bá a, ó sì ti ná gbogbo ohun àmúṣọrọ̀ rẹ̀,” síbẹ̀ kàkà kí ewé àgbọn àìsàn náà dẹ̀, ńṣe ló ń le koko sí i. Àmọ́ lọ́jọ́ kan, obìnrin náà ronú ohun kan tó máa ṣe tí ara rẹ̀ á fi yá. Ó ronú pé nǹkan á sàn tí òun bá lè sún mọ́ ọkùnrin tó ń jẹ́ Jésù yẹn. Ló bá gbéra, ó wọ àárín èrò lọ, ó sì fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè Jésù. (Léf. 15:19, 25) Jésù mọ̀ pé agbára ti jáde lára òun, torí náà ó béèrè pé: “Ta ní fọwọ́ kàn mí?” ‘Jìnnìjìnnì bo obìnrin náà, ó sì ń wárìrì,’ torí náà ó “wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ gbogbo òtítọ́ náà fún un.” Bí Jésù ti mọ̀ pé Baba òun, ìyẹn Jèhófà ló mú obìnrin náà lára dá, ó fi pẹ̀lẹ́tù bá a sọ̀rọ̀, ó ní: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní àlàáfíà, kí o sì ní ìlera kúrò lọ́wọ́ àìsàn burúkú tí ń ṣe ọ́.”
12. (a) Báwo lo ṣe máa ṣàpèjúwe Jésù pẹ̀lú gbogbo ohun tá a ti sọ nípa rẹ̀ yìí? (b) Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ fún wa?
12 Tẹ̀gàn ni hẹ̀, onínúure ẹ̀dá ni Jésù! A ti rí i pé ó máa ń káàánú àwọn tí àìsàn ń bá fínra. Sátánì fẹ́ ká gbà pé Ọlọ́run ò nífẹ̀ẹ́ wa àti pé a ò já mọ́ nǹkan kan lójú Ọlọ́run. Àmọ́, àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe mú kó ṣe kedere sí wa pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa dénúdénú àti pé ó máa yanjú àwọn ìṣòro wa. Ẹ ò rí i pé Àlùfáà Àgbà àti Ọba wa yìí lójú àánú! (Héb. 4:15) A lè má fi bẹ́ẹ̀ mọ́ bí nǹkan ṣe rí lára àwọn tó ń ṣàìsàn kan tó le koko, pàápàá bí irú àìsàn bẹ́ẹ̀ kò bá tíì ṣe wá rí. Ṣùgbọ́n, kò yẹ ka gbàgbé pé Jésù káàánú àwọn tó ń ṣàìsàn bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò ṣàìsàn rí. Ǹjẹ́ kí àpẹẹrẹ Jésù mú káwa náà ṣe ohun kan náà, débi tí agbára wa gbé e dé.—1 Pét. 3:8.
“JÉSÙ BẸ̀RẸ̀ SÍ DA OMIJÉ”
13. Kí ni àjíǹde Lásárù jẹ́ ká mọ̀ nípa irú ẹni tí Jésù jẹ́?
13 Ó máa ń dun Jésù wọra tó bá rí i táwọn èèyàn ń kẹ́dùn. Jésù “kérora . . . ó sì dààmú” nígbà tó rí i táwọn èèyàn bara jẹ́ torí ikú Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó mọ̀ pé òun máa jí Lásárù dìde lójú ẹsẹ̀, síbẹ̀ ó ṣì bá àwọn èèyàn kẹ́dùn. (Ka Jòhánù 11:33-36.) Ojú ò ti Jésù rárá láti fi bí nǹkan ṣe dùn ún tó hàn. Àwọn èèyàn rí ìfẹ́ tí Jésù ní sí Lásárù àti ìdílé rẹ̀. Ẹ ò rí i pé ìyọ́nú ni Jésù fi hàn bó ṣe lo agbára tí Ọlọ́run fún un láti fi jí ọ̀rẹ́ rẹ̀ dìde!—Jòh. 11:43, 44.
14, 15. (a) Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé ó wu Jèhófà láti mú òpin dé bá ìpọ́njú tó ń bá àwa èèyàn fínra? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká fún gbólóhùn náà “ibojì ìrántí” ní àfiyèsí?
14 Bíbélì sọ pé Jésù ni “àwòrán náà gẹ́lẹ́ ti wíwà [Ẹlẹ́dàá] gan-an.” (Héb. 1:3) Torí náà, àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé òun àti Baba rẹ̀ múra tán láti mú ìrora tí àìsàn àti ikú máa ń fà kúrò. Èyí kò mọ sórí àjíǹde mélòó kan tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì nìkan. Jésù sọ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò . . . jáde wá.”—Jòh. 5:28, 29.
15 Bí Jésù ṣe lo gbólóhùn náà “ibojì ìrántí,” bá a mu gẹ́lẹ́ torí pé ọ̀rọ̀ náà kan agbára ìrántí Ọlọ́run. Ọlọ́run Olódùmarè tó dá gbogbo ohun tó wà lọ́run àti láyé lè rántí gbogbo nǹkan nípa ìgbésí ayé àwọn èèyàn wa tó ti kú, títí kan àwọn ìwà wọ́n àti àwọn ìwà tí wọ́n bá lọ́wọ́ àwọn míì. (Aísá. 40:26) Kì í ṣe pé Ọlọ́run lè rántí nìkan ni, àmọ́ ó wu òun àti Ọmọ rẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àjíǹde Lásárù àti tàwọn míì tí Bíbélì sọ nípa wọn jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ níbi gbogbo nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé.
IPA WO NI ÀWỌN IṢẸ́ ÌYANU TÍ JÉSÙ ṢE NÍ LÓRÍ RẸ?
16. Àǹfààní wo ni ọ̀pọ̀ Kristẹni tí wọ́n pa ìwà títọ́ wọn mọ́ lóde òní máa ní?
16 Tá a bá ń pa ìwà títọ́ wa mọ́ nìṣó, ọ̀kan lára iṣẹ́ ìyanu tó kàmàmà jù lọ lè ṣojú wa, ìyẹn sì ni bá a ṣe máa la ìpọ́njú ńlá já. Láìpẹ́ lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu ló ṣì máa wáyé, lára rẹ̀ ni bí ẹ̀dá èèyàn ṣe máa ní ìlera pípé. (Aísá. 33:24; 35:5, 6; Ìṣí. 21:4) Ẹ fojú inú wò ó pé kò sẹ́ni tó ń lo ìgò mọ́, wọn ò lo igi tàbí ọ̀pá mọ́, kò sẹ́ni tó ń lo kẹ̀kẹ́ arọ, ohun tí wọ́n ń kì sétí kí wọ́n tó lè gbọ́ràn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Jèhófà máa fún àwọn tó bá la ogun Amágẹ́dọ́nì já ní ìlera tó pé, wọ́n sì máa ní iṣẹ́ tó pọ̀ láti ṣe. Torí náà, wọ́n máa fi ìdùnnú sọ gbogbo ayé wa yìí tó jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run di Párádísè.—Sm. 115:16.
17, 18. (a) Kí ni ìdí pàtàkì tó ṣe kedere tí Jésù fi ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe? (b) Kí nìdí tó fi yẹ kó o sa gbogbo ipá rẹ kó o lè wà nínú ayé tuntun Ọlọ́run?
17 Bí Jésù ṣe wo àwọn èèyàn sàn nígbà kan sẹ́yìn ń fún àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” níṣìírí lóde òní, ó túbọ̀ jẹ́ kí ọkàn wọn balẹ̀ bí wọ́n ṣe ń fayọ̀ retí ìgbà tí àìsàn èyíkéyìí kò ní ṣe wọ́n mọ́. (Ìṣí. 7:9) Àwọn iṣẹ́ ìwòsàn náà fi bí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn ṣe rí lára rẹ̀ hàn, ó sì tún jẹ́ ká mọ̀ pé àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn gan-an. (Jòh. 10:11; 15:12, 13) Bí Jésù ṣe jẹ́ oníyọ̀ọ́nú jẹ́ àmì pé ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan jẹ ẹ́ lógún.—Jòh. 5:19.
18 Ẹ̀dá èèyàn ń kérora, torí pé wọ́n wà nínú ìrora, ikú sì ń pa wọ́n. (Róòmù 8:22) À ń retí ayé tuntun Ọlọ́run, níbi tí Ọlọ́run ti máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé kò ní sí àìsàn èyíkéyìí mọ́. Málákì 4:2 fún wa ní ìdí tí a fi lè fọkàn balẹ̀ pé àwọn tí Ọlọ́run bá mú lára dá yóò “fi àtẹ́sẹ̀ talẹ̀ bí àwọn ọmọ màlúù àbọ́sanra,” inú wọn máa dùn gan-an pé wọ́n bọ́ lọ́wọ́ àìpé tó mú wọn lẹ́rú. Ǹjẹ́ kí ìmọrírì àtọkànwá tá a ní fún Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ tá a ní nínú àwọn ìlérí rẹ̀ mú kí a ṣe gbogbo ohun tó bá gbà ká lè tóótun láti wọnú ayé tuntun náà. Ó múnú wa dùn gan-an láti mọ̀ pé àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe nígbà tó wà láyé jẹ́ àpẹẹrẹ ìtura ayérayé tó máa mú wá fún ẹ̀dá èèyàn, èyí tí wọ́n máa gbádùn láìpẹ́ nígbà tó bá ń ṣàkóso!