“Àwa Yóò Bá Yín Lọ”
“Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.”—SEKARÁYÀ 8:23.
1, 2. (a) Kí ni Jèhófà sọ pé á máa ṣẹlẹ̀ lákòókò wa yìí? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
JÈHÓFÀ sọ pé ní àkókò wa yìí, “ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè yóò dì í mú, bẹ́ẹ̀ ni, ní ti tòótọ́, wọn yóò di ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ ọkùnrin kan tí ó jẹ́ Júù mú, pé: ‘Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.’” (Sekaráyà 8:23) “Júù” náà dúró fún àwọn tí Ọlọ́run ti fi ẹ̀mí mímọ́ yàn. Àwọn ni Bíbélì tún pè ní “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gálátíà 6:16) “Ọkùnrin mẹ́wàá” náà dúró fún àwọn tó nírètí láti gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Wọ́n mọ̀ pé Jèhófà ti bù kún àwùjọ àwọn ẹni àmì òróró yìí, wọ́n sì gbà pé àǹfààní ńlá ni báwọn àtàwọn ẹni àmì òróró yìí ṣe jọ ń sin Jèhófà.
2 Bíi ti wòlíì Sekaráyà, Jésù náà sọ pé àwọn èèyàn Jèhófà máa wà níṣọ̀kan. Ó pe àwọn tó nírètí láti gbé lọ́run ní “agbo kékeré,” ó sì pe àwọn tó nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé ní “àwọn àgùntàn mìíràn.” Àmọ́ Jésù sọ pé gbogbo wọn á jẹ́ “agbo kan,” wọ́n á sì máa tẹ̀ lé òun tóun jẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn kan” ṣoṣo tí wọ́n ní. (Lúùkù 12:32; Jòhánù 10:16) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwùjọ èèyàn méjì ló wà, àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí lè jẹ yọ: (1) Ǹjẹ́ kò yẹ kí àwọn àgùntàn mìíràn mọ orúkọ gbogbo àwọn tó jẹ́ ẹni àmì òróró lákòókò wa yìí? (2) Ojú wo ló yẹ káwọn ẹni àmì òróró máa fi wo ara wọn? (3) Bí ẹnì kan bá bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ búrẹ́dì tó sì ń mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi nínú ìjọ tí mo wà, báwo ló ṣe yẹ kí n máa ṣe sírú ẹni bẹ́ẹ̀? (4) Ṣó yẹ kí n máa dara mi láàmú bí iye àwọn tó ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n sì ń mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi bá ń pọ̀ sí i? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí.
ṢÓ LẸ́TỌ̀Ọ́ KÁ MỌ ORÚKỌ GBOGBO ÀWỌN TÓ JẸ́ ẸNI ÀMÌ ÒRÓRÓ BÁYÌÍ?
3. Kí nìdí tá ò fi lè fọwọ́ sọ̀yà pé ẹnì kan wà lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tàbí kò sí lára wọn?
3 Ṣó lẹ́tọ̀ọ́ pé kí àwọn àgùntàn mìíràn mọ orúkọ gbogbo àwọn tó jẹ́ ẹni àmì òróró báyìí? Rárá. Kí nìdí? Ìdí ni pé kò ṣeé ṣe fún ẹnikẹ́ni láti mọ̀ dájú bóyá wọ́n máa gba èrè wọn tàbí wọn ò ní gbà á.[1] (Wo àfikún àlàyé.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ti fẹ̀mí yàn wọ́n láti lọ sọ́run, bí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀délẹ̀ nìkan ni wọ́n máa gba èrè wọn. Sátánì mọ èyí, ìdí nìyẹn tó fi ń gbìyànjú láti ‘ṣì wọ́n lọ́nà’ nípasẹ̀ “àwọn èké wòlíì.” (Mátíù 24:24) Ìgbà tí Jèhófà bá mú kó ṣe kedere sí àwọn ẹni àmì òróró yìí pé òun ti kà wọ́n sí olóòótọ́ nìkan ló tó lè dá wọn lójú pé wọ́n máa gba èrè wọn. Tó bá kù díẹ̀ kí “ìpọ́njú ńlá” bẹ̀rẹ̀ tàbí kí wọ́n tó kú ni Jèhófà máa fún wọn ní èdìdì ìkẹyìn tó túmọ̀ sí pé ó ti tẹ́wọ́ gbà wọ́n pátápátá.—Ìṣípayá 2:10; 7:3, 14.
Jésù ni Aṣáájú wa, òun nìkan la sì gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé
4. Bó bá wá jẹ́ pé kò ṣeé ṣe fún wa láti mọ orúkọ gbogbo àwọn ẹni àmì òróró tó wà lórí ilẹ̀ ayé báyìí, báwo la ṣe lè ‘bá wọn lọ’?
4 Bó bá wá jẹ́ pé kò ṣeé ṣe fún àwọn àgùntàn mìíràn láti mọ orúkọ gbogbo àwọn ẹni àmì òróró tó wà lórí ilẹ̀ ayé báyìí, báwo ni wọ́n ṣe lè ‘bá wọn lọ’? Bíbélì sọ pé “ọkùnrin mẹ́wàá” máa “di ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ ọkùnrin kan tí ó jẹ́ Júù mú, pé: ‘Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.’” Júù kan ni ẹsẹ Bíbélì yìí mẹ́nu bà. Àmọ́ àwọn tí “yín” méjèèjì tó wà nínú ẹsẹ náà ń tọ́ka sí ju ẹnì kan lọ. Èyí túmọ̀ sí pé kì í ṣe ẹnì kan ṣoṣo ni Júù náà ń tọ́ka sí, àmọ́ ó dúró fún àwùjọ àwọn ẹni àmì òróró. Àwọn àgùntàn mìíràn mọ èyí, àwọn àti àwùjọ yìí ló sì jùmọ̀ ń sin Jèhófà. Kò pọn dandan kí wọ́n mọ orúkọ gbogbo àwọn tó jẹ́ ara àwùjọ yìí kí wọ́n lè máa tẹ̀ lé wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Jésù ni Aṣáájú wa, Bíbélì sì jẹ́ ká mọ̀ pé òun nìkan la gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé.—Mátíù 23:10.
OJÚ WO LÓ YẸ KÁWỌN ẸNI ÀMÌ ÒRÓRÓ MÁA FI WO ARA WỌN?
5. Ìkìlọ̀ wo ló yẹ káwọn ẹni àmì òróró ronú lé lórí dáadáa, kí sì nìdí?
5 Ó yẹ káwọn ẹni àmì òróró ronú dáadáa lórí ìkìlọ̀ tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 11:27-29. (Kà á.) Báwo ni ẹni àmì òróró kan ṣe lè jẹ búrẹ́dì kó sì mu wáìnì “láìyẹ” níbi Ìrántí Ikú Kristi? Bí ẹni àmì òróró kan ò bá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, tí kò sì jẹ́ olóòótọ́ sí i, tó wá ń jẹ búrẹ́dì tó sì ń mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi, ìwà àìlọ́wọ̀ gbáà nìyẹn máa jẹ́. (Hébérù 6:4-6; 10:26-29) Ìkìlọ̀ pàtàkì yìí rán àwọn ẹni àmì òróró létí pé wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ adúróṣinṣin jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn bí wọ́n bá fẹ́ gba “ẹ̀bùn eré ìje ti ìpè Ọlọ́run sí òkè nípasẹ̀ Kristi Jésù.”—Fílípì 3:13-16.
6. Ojú wo ló yẹ káwọn ẹni àmì òróró máa fi wo ara wọn?
6 Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn ẹni àmì òróró pé: “Èmi, ẹlẹ́wọ̀n nínú Olúwa, pàrọwà fún yín láti máa rìn lọ́nà tí ó yẹ ìpè tí a fi pè yín.” Báwo ló ṣe yẹ káwọn ẹni àmì òróró ṣe èyí? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ pátápátá ti èrò inú àti ìwà tútù, pẹ̀lú ìpamọ́ra, ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì nínú ìfẹ́, kí ẹ máa fi taratara sakun láti máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà.” (Éfésù 4:1-3) Ńṣe ni ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà máa ń mú káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kì í sọ wọ́n di agbéraga. (Kólósè 3:12) Torí náà, àwọn ẹni àmì òróró kì í ronú pé àwọn sàn ju àwọn ẹlòmíì lọ. Wọ́n mọ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ tí Jèhófà fún àwọn kò ju èyí tó fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó kù lọ. Wọn kì í sì í ronú pé àwọn lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ ju gbogbo àwọn yòókù lọ. Wọn ò sì jẹ́ sọ fẹ́nì kan pé Ọlọ́run ti fẹ̀mí yàn án torí náà kóun náà bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ búrẹ́dì kó sì máa mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, wọ́n sì mọ̀ pé Jèhófà nìkan ló ń yan àwọn tó máa lọ sọ́run.
7, 8. Kí ni àwọn ẹni àmì òróró kì í retí, kí sì nìdí?
7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àǹfààní ńlá làwọn ẹni àmì òróró kà á sí bí Jèhófà ṣe yàn wọ́n láti lọ sọ́run, wọn kì í retí pé káwọn èèyàn máa fún àwọn láfiyèsí àrà ọ̀tọ̀. (Éfésù 1:18, 19; ka Fílípì 2:2, 3.) Wọ́n sì mọ̀ pé nígbà tí Jèhófà fẹ̀mí yan àwọn, kò sọ fún ẹnikẹ́ni nípa ẹ̀. Torí náà, ẹni àmì òróró kan ò ní jẹ́ kó ya òun lẹ́nu táwọn kan ò bá tètè gbà pé Jèhófà ti fẹ̀mí yan òun. Ó mọ̀ pé Bíbélì pàápàá sọ pé ká má ṣe yára gbà gbọ́ tẹ́nì kan bá sọ pé Jèhófà ti gbé àkànṣe iṣẹ́ kan lé òun lọ́wọ́. (Ìṣípayá 2:2) Torí pé ẹni àmì òróró kan ò retí pé káwọn èèyàn máa fún òun láfiyèsí àrà ọ̀tọ̀, kò ní máa sọ fáwọn èèyàn tó bá pàdé fúngbà àkọ́kọ́ pé ẹni àmì òróró lòun. Kódà, ó tiẹ̀ lè má sọ fún ẹnikẹ́ni pàápàá. Kò sì ní máa fọ́nnu nípa àwọn ohun tó máa gbé ṣe lọ́run.—1 Kọ́ríńtì 1:28, 29; ka 1 Kọ́ríńtì 4:6-8.
8 Àwọn ẹni àmì òróró kì í ronú pé àwọn ẹni àmì òróró bíi tiwọn nìkan ló yẹ káwọn máa bá ṣọ̀rẹ́ bí ẹní ń ṣẹgbẹ́ àwa-ara-wa. Wọn kì í wá àwọn ẹni àmì òróró míì kiri bóyá torí kí wọ́n lè jọ máa sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe máa ń rí téèyàn bá di ẹni àmì òróró tàbí kí wọ́n lè jọ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀. (Gálátíà 1:15-17) Ìjọ ò ní wà níṣọ̀kan táwọn ẹni àmì òróró bá ń hu irú ìwà yìí. Bí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ṣe ni wọ́n ń hùwà lòdì sí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tó ń jẹ́ kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ.—Ka Róòmù 16:17, 18.
OJÚ WO LÓ YẸ KÓ O MÁA FI WÒ WỌ́N?
9. Kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣọ́ra nípa ojú tó o fi ń wo àwọn tó ń jẹ búrẹ́dì tó sì ń mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi? (Wo àpótí náà, “Ìfẹ́ ‘Kì Í Hùwà Lọ́nà Tí Kò Bójú Mu.’”)
9 Ojú wo ló yẹ kó o máa fi wo àwọn ẹni àmì òróró lọ́kùnrin àti lóbìnrin? Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Arákùnrin ni gbogbo yín jẹ́.” Ó sọ síwájú sí i pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a ó rẹ̀ sílẹ̀, ẹnì yòówù tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óò gbé ga.” (Mátíù 23:8-12) Torí náà, kò dáa ká máa fún ẹnì kan láfiyèsí kọjá bó ṣe yẹ, kódà bí ẹni náà tìẹ jẹ́ arákùnrin Kristi. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn alàgbà, ó gbà wá níyànjú pé ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wọn, àmọ́ kò sọ pé ká sọ èèyàn èyíkéyìí di aṣáájú wa. (Hébérù 13:7) Òótọ́ ni pé Bíbélì sọ pé àwọn kan “yẹ fún ọlá ìlọ́po méjì.” Àmọ́ èyí jẹ́ nítorí pé wọ́n “ń ṣe àbójútó lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀,” wọ́n sì “ń ṣiṣẹ́ kára nínú ọ̀rọ̀ sísọ àti kíkọ́ni,” kì í ṣe torí pé wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró. (1 Tímótì 5:17) A máa dójú ti àwọn ẹni àmì òróró tá a bá ń fún wọn láfiyèsí tàbí tá a bá ń yìn wọ́n kọjá bó ṣe yẹ. Èyí tó tiẹ̀ wá burú jù ni pé a lè mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga. (Róòmù 12:3) Ó sì dájú pé kò sẹ́nì kankan nínú wa táá fẹ́ ṣe ohun tó lè mú kí ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin Kristi ṣe irú àṣìṣe ńlá bẹ́ẹ̀.—Lúùkù 17:2.
10. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o bọ̀wọ̀ fún àwọn ẹni àmì òróró?
10 Báwo la ṣe lè fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún àwọn tí Jèhófà fẹ̀mí yàn? A ò ní máa béèrè lọ́wọ́ wọn pé báwo ni wọ́n ṣe di ẹni àmì òróró. Ó yẹ ká mọ̀ pé ọ̀rọ̀ àárín àwọn àti Jèhófà ni, a ò sì lẹ́tọ̀ọ́ láti mọ̀. (1 Tẹsalóníkà 4:11; 2 Tẹsalóníkà 3:11) Kò sì yẹ ká máa ronú pé Ọlọ́run ti fẹ̀mí yan ọkọ tàbí aya wọn, àwọn òbí wọn tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí wọn. Ó yẹ ká mọ̀ pé ìrètí táwọn ẹni àmì òróró ní kì í ṣe ogún ìdílé. (1 Tẹsalóníkà 2:12) Kò sì tún yẹ ká máa béèrè àwọn ìbéèrè tó lè kó ẹ̀dùn ọkàn báni. Bí àpẹẹrẹ, a ò ní máa béèrè lọ́wọ́ ìyàwó ẹni àmì òróró kan pé báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ̀ tó bá ń rántí pé òun máa gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé tí ọkọ rẹ̀ sì máa wà lọ́run. Ó ṣe tán, ó dá wa lójú pé, nínú ayé tuntun, Jèhófà máa “tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.”—Sáàmù 145:16.
11. Tí a kì í bá “kan sáárá” sáwọn ẹni àmì òróró, báwo nìyẹn ṣe lè dáàbò bò wá?
11 A máa dáàbò bo ara wa tá a bá ń fojú tó tọ́ wo àwọn ẹni àmì òróró, tí a kì í wò wọ́n bí ẹni pé wọ́n ṣe pàtàkì ju àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó kù lọ. Lọ́nà wo? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé “àwọn èké arákùnrin” lè wà nínú ìjọ, wọ́n tiẹ̀ lè máa sọ pé ẹni àmì òróró làwọn. (Gálátíà 2:4, 5; 1 Jòhánù 2:19) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ẹni àmì òróró kan lè di aláìṣòótọ́. (Mátíù 25:10-12; 2 Pétérù 2:20, 21) Àmọ́, tí a kì í bá “kan sáárá” sáwọn èèyàn, a ò ní sọ ẹnikẹ́ni di ọlọ́run wa, yálà ẹni àmì òróró ni tàbí ẹnì kan táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa tàbí àwọn tó ti ń sin Jèhófà tipẹ́tipẹ́ pàápàá. Tírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bá wá lọ di aláìṣòótọ́ tàbí tí wọ́n fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀, ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Jèhófà ò ní wọmi, a ò sì ní pa ìjọsìn Jèhófà tì.—Júúdà 16.
ṢÓ YẸ KÁ MÁA DARA WA LÁÀMÚ BÍ WỌ́N BÁ Ń PỌ̀ SÍ I?
12, 13. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa da ara wa láàmú bí àwọn tó ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n sì ń mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi bá ń pọ̀ sí i?
12 Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ńṣe ni iye àwọn tó ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n sì ń mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi ń dín kù. Àmọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ṣe ni iye wọn ń pọ̀ sí i lọ́dọọdún. Ṣó yẹ ká máa dara wa láàmú nítorí èyí? Rárá. Ẹ jẹ́ ká wo ìdí tí kò fi yẹ kíyẹn kó ìdààmú ọkàn bá wa.
13 “Jèhófà mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀.” (2 Tímótì 2:19) Àwọn arákùnrin tó ń ka iye àwọn tó ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n sì ń mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi kì í ṣe Jèhófà, torí náà wọn ò lè mọ àwọn tó jẹ́ ẹni àmì òróró lóòótọ́. Torí náà, àwọn tí wọ́n rò pé ẹni àmì òróró làwọn àmọ́ tí wọn kì í ṣe ẹni àmì òróró wà lára àwọn tó ń jẹ àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan tí wọ́n ti máa ń jẹ àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà tẹ́lẹ̀ kò jẹ ẹ́ mọ́ nígbà tó yá. Àwọn kan lè ní ìṣòro ọpọlọ tàbí ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, kí wọ́n sì máa rò pé àwọn wà lára àwọn tó máa bá Kristi jọba lọ́run. Ó ṣe kedere pé a ò mọ iye àwọn ẹni àmì òróró tó kù láyé báyìí.
14. Kí ni Bíbélì sọ nípa iye àwọn ẹni àmì òróró tó máa wà láyé nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀?
14 Àwọn ẹni àmì òróró máa wà ní ọ̀pọ̀ ibi lórí ilẹ̀ ayé nígbà tí Jésù bá dé láti kó wọn lọ sọ́run. Bíbélì sọ pé Jésù máa “rán àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ jáde pẹ̀lú ìró ńlá kàkàkí, wọn yóò sì kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọpọ̀ láti inú ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, láti ìkángun kan ọ̀run sí ìkángun rẹ̀ kejì.” (Mátíù 24:31) Bíbélì tún fi hàn pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn ẹni àmì òróró díẹ̀ máa ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 12:17) Àmọ́, kò sọ iye àwọn tó máa ṣẹ́ kù nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀.
15, 16. Kí ló yẹ ká mọ̀ nípa àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí Jèhófà fẹ̀mí yàn?
15 Jèhófà ló ń pinnu ìgbà tó máa fẹ̀mí yan ẹnì kan. (Róòmù 8:28-30) Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde ni Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í yan àwọn ẹni àmì òróró. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé gbogbo àwọn Kristẹni tòótọ́ tó wà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ni ẹni àmì òróró. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà ni kò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù ní ti gidi. Síbẹ̀ náà, láàárín àwọn ọdún yẹn, Jèhófà fẹ̀mí yan ìwọ̀nba àwọn tó jẹ́ Kristẹni tòótọ́. Ńṣe ni wọ́n dà bí àlìkámà tí Jésù sọ pé á máa dàgbà láàárín àwọn èpò. (Mátíù 13:24-30) Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, Jèhófà ń bá a nìṣó láti yan àwọn èèyàn tó máa di ara àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì.[2] (Wo àfikún àlàyé.) Torí náà, bí Ọlọ́run bá pinnu láti yan àwọn kan lára wọn ní àkókò díẹ̀ ṣáájú kí òpin tó dé, ó dájú pé kò sẹ́ni tó lè yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò. (Aísáyà 45:9; Dáníẹ́lì 4:35; ka Róòmù 9:11, 16.)[3] (Wo àfikún àlàyé.) A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí ọ̀rọ̀ wa má bàa dà bíi tàwọn òṣìṣẹ́ tó ń bínú sí ọ̀gá wọn torí iye owó tó san fún àwọn òṣìṣẹ́ tó dé kẹ́yìn.—Ka Mátíù 20:8-15.
16 Kì í ṣe gbogbo àwọn tó nírètí láti lọ sọ́run ló jẹ́ ara “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mátíù 24:45-47) Bó ṣe rí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ìwọ̀nba èèyàn kéréje ni Jèhófà àti Jésù ń lò láti bọ́, tàbí láti kọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí. Ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ni Jèhófà lò láti kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Bákan náà lónìí, ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn ẹni àmì òróró ni Jèhófà gbé iṣẹ́ lé lọ́wọ́ pé kí wọ́n máa fún àwọn èèyàn òun ní ‘oúnjẹ ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.’
17. Kí lo ti rí kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí?
17 Kí la ti rí kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí? Jèhófà ti pinnu láti fún èyí tó pọ̀ jù lára àwọn èèyàn rẹ̀ ní ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé, ó sì ti pinnu láti fún àwọn tó máa bá Jésù jọba lọ́run ní ìyè ti ọ̀run. Gbogbo àwa ìránṣẹ́ Jèhófà, ì báà jẹ́ “Júù” tàbí àwọn “ọkùnrin mẹ́wàá” náà, ni Jèhófà máa fún lérè. Òfin kan náà ló retí pé kí gbogbo wa máa pa mọ́, ó sì retí pé kí gbogbo wa jẹ́ olóòótọ́ sí òun. Gbogbo wa gbọ́dọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Gbogbo wa gbọ́dọ̀ máa sìn ín pa pọ̀ ká sì wà ní ìṣọ̀kan. Gbogbo wa gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun táá mú kí àlááfíà máa wà nínú ìjọ. Bí àkókò òpin ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa máa sin Jèhófà nìṣó, ká sì máa tẹ̀ lé Kristi gẹ́gẹ́ bí agbo kan.
^ [1] (ìpínrọ̀ 3) Bí Sáàmù 87:5, 6 ṣe sọ, lọ́jọ́ iwájú, ó ṣeé ṣe kí Ọlọ́run jẹ́ ká mọ orúkọ gbogbo àwọn tó ń bá Jésù jọba lọ́run.—Róòmù 8:19.
^ [2] (ìpínrọ̀ 15) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìṣe 2:33 fi hàn pé Jésù náà máa ń mọ̀ sí i tẹ́nì kan bá di ẹni àmì òróró, Jèhófà ló yan onítọ̀hún.
^ [3] (ìpínrọ̀ 15) Tó o bá ń fẹ́ àlàyé síwájú sí i, wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ May 1, 2007, ojú ìwé 30 sí 31.