Ǹjẹ́ Ayé Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Ìwà Ipá?
Ǹjẹ́ wọ́n ti hùwà ipá sí ìwọ tàbí mọ̀lẹ́bí rẹ kan rí? Àbí ẹ̀rú ń bà ẹ́ pé ó ṣì lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ? Ìwà ipá ti di “àrùn tó gbalẹ̀ kan kárí ayé.” Wo àwọn àpẹẹrẹ yìí.
ÌLÙKULÙ ÀTI ÌFIPÁBÁNILÒPỌ̀: Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ròyìn pé “ìdá kan nínú mẹ́ta àwọn obìnrin ni àwọn ọkọ wọn máa ń lù lálùbolẹ̀ tàbí kí wọ́n fagídí bá lòpọ̀. Kódà, wọ́n fojú bù ú pé kárí ayé, obìnrin kan nínú márùn ni wọ́n ṣì máa fipá bá lòpọ̀ tàbí kí wọ́n gbìyànjú láti fipá bá lòpọ̀.”
ÌWÀ Ọ̀DARÀN: Ìròyìn fi hàn pé ẹgbẹ́ àwọn ọmọọ̀ta tó ń da orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láàmú ju ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ [30,000] lọ. Làwọn orílẹ̀-èdè tó wà lápá Látìn Amẹ́ríkà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹnì kan nínú mẹ́ta táwọn ọmọọ̀ta ti hàn léèmọ̀.
ÌPÀNÌYÀN: Wọ́n fojú bù ú pé àwọn èèyàn tí wọ́n ṣìkà pa lọ́dún àìpẹ́ yìí tó ìdajì mílíọ̀nù, èyí sì ju àwọn tí ogun pa lọ. Apá ibi tí wọ́n ti ń ṣìkà pànìyàn jù lọ ni Gúúsù ilẹ̀ Áfíríkà àti Central America. Ó lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] èèyàn tí wọ́n pa ní Latin America lọ́dún kan, nǹkan bí ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ [50,000] èèyàn ni wọ́n sì pa lórílẹ̀-èdè Brazil nìkan. Ṣé nǹkan kan wà tó lè mú ìwà ipá kúrò títí láé?
ṢÉ ÌWÀ IPÁ LÈ DÓPIN?
Kí ló fà á tí ìwà ipá fi gbòde kan? Oríṣiríṣi nǹkan ló fà á, lára rẹ̀ ni: bí àwọn kan ṣe rí towó ṣe ju àwọn míì lọ, bí àwọn ọmọdé ṣe ń rí ìwà ipá táwọn àgbàlagbà ń hù, ọtí líle àti oògùn olóró, bí ẹ̀mí èèyàn ò ṣe jọ àwọn kan lójú àti bí àwọn ọ̀daràn ṣe ń hùwà ipá tí wọ́n sì ń mú un jẹ.
Òótọ́ ni pé àwọn apá ibì kan wà láyé tí wọ́n ti ń gbógun ti ìwà ipá. Ìròyìn fi hàn pé láti nǹkan bí ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, ìpànìyàn ti dínkù gan-an nílùú São Paulo, lórílẹ̀-èdè Brazil. Síbẹ̀, onírúurú ìwà ìpáǹle ṣì wọ́pọ̀ nílùú yẹn àti pé ìpànìyàn kò tíì kásẹ̀ nílẹ̀ pátápátá. Ìgbà wo wá ni ìwà ipá máa kásẹ̀ nílẹ̀ tán pátápátá lórí ilẹ̀ ayé?
Ọwọ́ ẹni la fí ń tún ìwà ẹni ṣe, ìwà àti ìṣe wa ló lè mú kí ìṣòro yìí dópin. Kí ẹni tó ti ń hùwà ipá tó lè yí padà, ó ní láti jáwọ́ nínú ìgbéraga, ojúkòkòrò àti ìmọtara ẹni kúrò, kó sì fi ìfẹ́, ọ̀wọ̀ àti ìgbatẹnirò rọ́pò wọn.
Kí ló lè sún ẹnì kan láti ṣe irú ìyípadà tó lágbára yìí? Ronú nípa ohun tí Bíbélì kọ́ni:
“Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.”—1 Jòhánù 5:3.
Ohun tó lè mú kí ẹni tó jẹ́ oníwà ipá jáwọ́ ni pé kó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, kó sì ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run lọ́kàn. Èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán, ẹni náà gbọ́dọ̀ yí ìwà àti ìṣe rẹ̀ pa dà láìkù síbì kan. Ǹjẹ́ èyí lè ṣeé ṣe?
Wo àpẹẹrẹ Alex,b ó ti lo ọdún mọ́kàndínlógún lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lórílẹ̀-èdè Brazil torí oríṣiríṣi ìwà láabi tó ti hù. Ó di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ọdún 2000, lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ṣó ti fi ìwà ipá sílẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, Alex kábàámọ̀ gbogbo ìwà burúkú tó ti hù. Ó tiẹ̀ sọ pé: “Ní báyìí, mo ti wá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gan-an torí ó ti jẹ́ kí n nímọ̀lára pé òun ti dárí jì mí. Ẹ̀mí ìmoore àti bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ló jẹ́ kí n lè yí ìwà mi padà.”
Adigunjalè ni ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ César lorílẹ̀-èdè Brazil. Ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ló fi hùwà yìí. Kí ló mú kó fi ìwà yìí sílẹ̀? Ó bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé nígbà tó wà lẹ́wọ̀n, òun náà sì kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. César sọ pé: “Ayé mi ṣẹ̀ṣẹ̀ wá lójú báyìí ni. Mo kọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Mo sì tún kọ́ láti bẹ̀rù rẹ̀, ìbẹ̀rù àtọkànwá yìí ni kò jẹ́ kí n pa dà hùwà tó máa ba Ọlọ́run lọ́kàn jẹ́. Mi ò sì fẹ́ jẹ́ aláìmoore. Ìfẹ́ àti ìbẹ̀rù yìí ló sún mi láti yí pa dà sí rere.”
Kí la rí kọ́ nínú àwọn ìrírí yìí? Bíbélì ní agbára láti yí ìgbésí ayé àti ìrònú àwọn èèyàn pa dà sí rere. (Éfésù 4:23) Alex tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ́ lẹ̀ fi kú un pé: “Ńṣe ni ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ nínú Bíbélì dà bí ìgbà tí wọ́n da omi tó mọ́ sí mi lórí, tó sì ṣan gbogbo èròkérò kúrò lọ́kàn mi. Tẹ́lẹ̀, mi ò rò pé mo lè jáwọ́ nínú àwọn àṣà yẹn.” Tá a bá fi àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́ inú Bíbélì kún ọkàn wa, ó máa gbọn ìwà burúkú kúrò lọ́kàn wa tàbí kó fọ̀ ọ́ kúrò. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní agbára láti wẹ̀ wá mọ́. (Éfésù 5:26) Òun ló máa ń mú kí ọ̀dájú tàbí onímọtara ẹni nìkan yíwà pa dà, kó sì di onínúure àti ẹni àlááfíà. (Róòmù 12:18) Ọkàn wọn á sì balẹ̀ torí pé wọ́n ń fi àwọn ẹ̀kọ́ inú Bíbélì sílò.—Aísáyà 48:18.
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ, tá a sì wà ní igba ó lé ogójì [240] ilẹ̀ ti mọ béèyàn ṣe lè jáwọ́ nínú ìwà ipá. Àwọn èèyàn láti onírúurú ẹ̀yà tó wà jákèjádò ayé ti kọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, kí wọ́n sì bẹ̀rù rẹ̀. Lẹ́sẹ̀ kan náà, a nífẹ̀ẹ́ ara wa, a sì dà bí ìdílé ńlá kan tó wà níṣọ̀kan kárí ayé. (1 Pétérù 4:8) Ìgbé ayé wa fi hàn pé ilẹ̀ ayé lè bọ́ lọ́wọ́ ìwà ipá.
LÁÌPẸ́ KÒ NÍ SÍ ÌWÀ IPÁ MỌ́ LÓRÍ ILẸ̀ AYÉ!
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa mú ìwà ipá kúrò láyé láìpẹ́. Ayé tó kún fún ìwà ipá yìí máa dópin ní “ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Pétérù 3:5-7) Kò ní sí èèyàn burúkú kankan táá máa fìyà jẹ àwọn míì mọ́. Kí ló mú kó dá wa lojú pé Ọlọ́run fẹ́ dá sí ọ̀rọ̀ yìí àti pé ó máa mú ìwà ipá kúrò?
Bíbélì sọ pé Ọlọ́run “kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.” (Sáàmù 11:5) Ẹlẹ́dàá wa nífẹ̀ẹ́ àlááfíà àti ìdájọ́ òdodo. (Sáàmù 33:5; 37:28) Ìdí nìyẹn tí kò fi ní gba àwọn oníwà ipá láàyè títí láé.
Ó dájú pé ayé tuntun alálàáfíà máa tó dé. (Sáàmù 37:11; 72:14) Ṣé wàá fẹ́ mọ ohun tó o lè ṣe láti gbé nínú ayé tí kò ti ní sí ìwà ipá mọ́?