KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | IBO LO TI LÈ RÍ ÌTÙNÚ?
Bí Ọlọ́run Ṣe ń tù Wá Nínú
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé Jèhófàa jẹ́ “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4) Bíbélì tipa báyìí mú kó dá wa lójú pé gbogbo èèyàn pátá ni Ọlọ́run lè ràn lọ́wọ́, àti pé kò sí ìṣòro tó lè dé bá wa tí Baba wa ọ̀run kò ní lè tù wá nínú.
Àmọ́ ṣá o, àwa náà ní ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run tù wá nínú. Ǹjẹ́ dókítà kan lè ràn wá lọ́wọ́ tí àwa fúnra wa kò bá ṣètò láti rí i? Wòlíì Ámósì béèrè pé: “Ṣé eniyan meji lè jọ máa lọ sí ibìkan láìjẹ́ pé wọ́n ní àdéhùn?” (Ámósì 3:3, Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀) Èyí ló mú kí Ìwé Mímọ́ rọ̀ wá pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—Jákọ́bù 4:8.
Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run máa sún mọ́ wa? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Ọlọ́run sọ fún wa léraléra pé òun fẹ́ ràn wá lọ́wọ́. (Wo àpótí tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí.) Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ni Ọlọ́run ti tù nínú, lákòókò wa yìí àti nígbà àtijọ́.
Oríṣiríṣi àjálù ló dé bá Dáfídì Ọba, ó sì bẹ Ọlọ́run pé kó ran òun lọ́wọ́, bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe máa ń bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run lóde òní. Ìgbà kan wà tí Dáfídì bẹ Jèhófà pé: “Gbọ́ ohùn ìpàrọwà mi nígbà tí mo bá kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́.” Ǹjẹ́ Ọlọ́run dá a lóhùn? Bẹ́ẹ̀ ni. Dáfídì sọ pé: “A sì ti ràn mí lọ́wọ́, tí ó fi jẹ́ pé ọkàn-àyà mi ń yọ ayọ̀ ńláǹlà.”—Sáàmù 28:2, 7.
BÍ JÉSÙ ṢE Ń TU ÀWỌN TÓ Ń ṢỌ̀FỌ̀ NÍNÚ
Ọlọ́run fẹ́ kí Jésù náà máa tu àwọn èèyàn nínú. Lára iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé Jésù lọ́wọ́ ni pé kó “di ọgbẹ́ àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn” kó sì “tu gbogbo àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú.” (Aísáyà 61:1, 2) Bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, Jésù fi ọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ àwọn “tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn.”—Mátíù 11:28-30.
Jésù tu àwọn èèyàn nínú nípa bó ṣe ń fún wọn ní ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n, ó máa ń hùwà tó dáa sí wọn, kódà ó mú àwọn míì lára dá. Lọ́jọ́ kan, adẹ́tẹ̀ kan bẹ Jésù pé: “Bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́.” Jésù káàánú ọkùnrin yìí, ó sì dáhùn pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.” (Máàkù 1:40, 41) Ara adẹ́tẹ̀ náà sì yá.
Jésù Ọmọ Ọlọ́run kò sí lórí ilẹ̀ ayé báyìí láti máa fúnra rẹ̀ tù wá nínú. Àmọ́, Bàbá rẹ̀ Jèhófà tó jẹ́ “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo,” ṣì ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. (2 Kọ́ríńtì 1:3) Wo ọ̀nà pàtàkì mẹ́rin tí Ọlọ́run ń gbà tu àwọn èèyàn nínú.
Bíbélì. “Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.”—Róòmù 15:4.
Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run. Kété lẹ́yìn tí Jésù kú, gbogbo ìjọ Kristẹni wọ àkókò àlááfíà. Ohun tó jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe ni pé ìjọ náà ń “rìn ní ìbẹ̀rù Jèhófà àti ní ìtùnú ẹ̀mí mímọ́.” (Ìṣe 9:31) Ẹ̀mí mímọ́, tó jẹ́ agbára Ọlọ́run, máa ń ṣiṣẹ́ gan-an. Ọlọ́run lè lò ó láti tù wá nínú láìka bí ìṣòro wa ṣe le tó.
Àdúrà. Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun.” Lẹ́yìn náà ó sọ pé, “kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín.”—Fílípì 4:6, 7.
Àwọn Tá A Jọ Jẹ́ Kristẹni jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tó lè tù wá nínú nígbà ìṣòro. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn ọ̀rẹ́ òun jẹ́ ìtùnú fún òun nínú gbogbo àìní àti ìpọ́njú òun.—Kólósè 4:11; 1 Tẹsalóníkà 3:7.
Àmọ́ o lè máa ronú pé báwo ni àwọn nǹkan yìí ṣe lè tù ẹ́ nínú nígbà ìṣòro. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn èèyàn tó ti dojú kọ àwọn ìṣòro tá a mẹ́nu bà nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú. Bíi ti àwọn èèyàn yẹn, ìwọ náà á rí i pé Ọlọ́run ṣì ń mú ìlérí tó tuni nínú yìí ṣẹ, ó ní: “Bí ènìyàn tí ìyá rẹ̀ ń tù nínú, bẹ́ẹ̀ ni èmi fúnra mi yóò ṣe máa tù yín nínú.”—Aísáyà 66:13.
a Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.