“Ẹ Lọ, Kí Ẹ sì Máa Sọ Àwọn Ènìyàn Gbogbo Orílẹ̀-Èdè Di Ọmọ Ẹ̀yìn”
“Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn . . . , ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.”—MÁT. 28:19, 20.
1, 2. Àwọn ìbéèrè wo ló jẹ yọ torí ohun tí Jésù sọ nínú Mátíù 24:14?
YÁLÀ àwọn èèyàn gba tiwa àbí wọn ò gba tiwa, agbára káká la máa fi rẹ́ni tó máa lóun ò mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. O tiẹ̀ lè ti pàdé àwọn kan lóde ẹ̀rí tí wọ́n sọ pé àwọn ò fara mọ́ àwọn ohun tá a gbà gbọ́, àmọ́ tí wọ́n fẹ́ràn iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. Bá a ṣe mọ̀, Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé a máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé. (Mát. 24:14) Àmọ́, kí ló mú kó dá wa lójú pé iṣẹ́ ìwàásù tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ là ń ṣe? Ṣé ìkọjá-àyè ni tá a bá sọ pé àwa nìkan là ń ṣe iṣẹ́ yìí?
2 Ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ló rò pé Ajíhìnrere làwọn tàbí pé àwọn ń wàásù ìhìn rere. Àmọ́, gbogbo tiwọn ò ju kí wọ́n máa ṣe ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́, kí wọ́n máa wàásù fáwọn ọmọ ìjọ tàbí kí wọ́n máa gbóhùn sáfẹ́fẹ́ lórí rédíò, tẹlifíṣọ̀n tàbí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Àwọn míì sì rò pé ọ̀nà táwọn ń gbà wàásù ni báwọn ṣe ń kọ́lé ìwòsàn, ilé ìwé tàbí ilé àwọn ọmọ aláìlóbìí. Àmọ́, ṣé iṣẹ́ tí Jésù pàṣẹ pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ máa ṣe nìyẹn?
3. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú Mátíù 28:19, 20, kí lohun mẹ́rin táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù gbọ́dọ̀ ṣe?
3 Ṣé ohun tí Jésù ní lọ́kàn ni pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun jókòó tẹtẹrẹ, kí wọ́n máa wá retí pé káwọn èèyàn wá bá àwọn? Ó dájú pé ohun tó ní lọ́kàn kọ́ nìyẹn! Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó sọ fún ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn . . . , ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mát. 28:19, 20) Torí náà, ohun mẹ́rin la gbọ́dọ̀ ṣe. A gbọ́dọ̀ máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, ká máa batisí wọn, ká sì máa kọ́ wọn. Àmọ́, kí lohun àkọ́kọ́ tá a gbọ́dọ̀ ṣe? Jésù sọ pé: “Ẹ lọ”! Nígbà tí ọ̀mọ̀wé Bíbélì kan ń sọ̀rọ̀ nípa àṣẹ tí Jésù pa yìí, ó ní: “Iṣẹ́ gbogbo onígbàgbọ́ ni pé kí wọ́n ‘lọ,’ yálà sójú pópó tàbí kí wọ́n ré kọjá òkun.”—Mát. 10:7; Lúùkù 10:3.
4. Irú iṣẹ́ wo ni iṣẹ́ “apẹja ènìyàn”?
4 Kí ni Jésù retí pé káwọn ọmọlẹ́yìn òun ṣe? Ṣé ohun tó ń sọ ni pé kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn máa dá ṣe iṣẹ́ náà bó ṣe wù ú àbí ó fẹ́ kí wọ́n pawọ́ pọ̀ wàásù ìhìn rere náà kí wọ́n sì wà létòletò? Níwọ̀n bí ẹnì kan ṣoṣo ò ti ní lè wàásù fún “gbogbo orílẹ̀-èdè,” iṣẹ́ yìí máa gba ìsapá ọ̀pọ̀ èèyàn. Ohun tí Jésù ní lọ́kàn nìyẹn nígbà tó sọ pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun wá di “apẹja ènìyàn.” (Ka Mátíù 4:18-22.) Ẹja pípa tó ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbí kì í ṣe ti apẹja kan tó ń lo ìdẹ àti ìwọ̀ fi pẹja, táá wá jókòó títí tí ìwọ̀ á fi gbé ẹja náà. Àwọ̀n ni wọ́n á fi mú àwọn ẹja tí Jésù ń sọ. Iṣẹ́ tó gba agbára, tó sì gba pé kí ọ̀pọ̀ èèyàn fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ni.—Lúùkù 5:1-11.
5. Àwọn ìbéèrè mẹ́rin wo ló pọn dandan ká dáhùn, kí sì nìdí?
5 Tá a bá fẹ́ mọ àwọn tó ń wàásù ìhìn rere tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ lónìí, ó pọn dandan ká dáhùn àwọn ìbéèrè mẹ́rin yìí:
Kí ló yẹ ká máa wàásù?
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa wàásù?
Àwọn ọ̀nà wo ló yẹ ká máa gbà wàásù?
Ibo ló yẹ kí iṣẹ́ ìwàásù náà gbòòrò dé, ìgbà wo ló sì máa dópin?
Ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí máa jẹ́ ká mọ àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà yìí, á sì tún jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká máa bá iṣẹ́ náà lọ, ká má sì jẹ́ kó sú wa.—1 Tím. 4:16.
KÍ LÓ YẸ KÁ MÁA WÀÁSÙ?
6. Kí ló mú kó dá ẹ lójú pé ohun tó yẹ káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wàásù rẹ̀ gan-an ni wọ́n ń wàásù rẹ̀?
6 Ka Lúùkù 4:43. “Ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run” ni Jésù wàásù rẹ̀, ohun tó sì retí pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ náà máa ṣe nìyẹn. Àwùjọ àwọn èèyàn wo ló ń wàásù ìhìn rere náà ní “gbogbo orílẹ̀-èdè”? Ìdáhùn náà ò lójú pọ̀ rárá, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ni. Kódà, àwọn kan tó ń ta kò wa náà gbà bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àlùfáà kan tó jẹ́ míṣọ́nnárì sọ fún Ẹlẹ́rìí kan pé òun ti gbé ní oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè, gbogbo orílẹ̀-èdè tóun bá sì ti dé lòun máa ń bi àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ pé kí ni lájorí ohun tí wọ́n ń wàásù. Kí làwọn Ẹlẹ́rìí náà máa ń sọ fún un? Àlùfáà náà sọ pé: “Inú wọn pò débi pé ìdáhùn kan náà ni gbogbo wọn ń fún mi, wọ́n á ní: ‘Ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni.’” Inú àwọn Ẹlẹ́rìí yẹn ò kúkú pò, torí pé gbogbo wọn wà níṣọ̀kan lohùn wọn ṣe ṣọ̀kan, bó sì ṣe yẹ káwọn Kristẹni tòótọ́ máa fohùn ṣọ̀kan nìyẹn. (1 Kọ́r. 1:10) Wọ́n sì tún ń wàásù ohun tó wà nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà. Ìwé ìròyìn yìí wà ní èdè igba ó lé mẹ́rìnléláàádọ́ta [254], iye ẹ̀dà tá a sì ń tẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mọ́kàndínláàádọ́ta [59,000,000], èyí ló sì wá mú kó jẹ́ ìwé ìròyìn tí ìpínkiri rẹ̀ pọ̀ jù lọ láyé.
7. Báwo la ṣe mọ̀ pé àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kì í wàásù ohun tó yẹ kí wọ́n wàásù?
7 Àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kì í wàásù Ìjọba Ọlọ́run. Bí wọ́n bá tiẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ rárá, ohun tí púpọ̀ lára wọn máa ń sọ ni pé inú ọkàn àwọn Kristẹni ni Ìjọba Ọlọ́run wà. (Lúùkù 17:21) Wọn ò jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ìjọba gidi kan ni Ìjọba Ọlọ́run àti pé Jésù Kristi ni Alákòóso Ìjọba náà, kàkà bẹ́ẹ̀, ọdún Kérésìmesì àti ayẹyẹ Ọdún Àjíǹde ni wọ́n ń ṣe, wọ́n á láwọn ń fìyẹn rántí Jésù. Bákan náà, wọn ò jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ìjọba yìí ló máa fòpin sí gbogbo ìṣòro táwọn èèyàn ń kojú, àti pé láìpẹ́ ó máa mú gbogbo ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣí. 19:11-21) Kò jọ pé wọ́n mọ àwọn ohun tí Jésù máa ṣe nígbà tí ìṣàkóso rẹ̀ bá nasẹ̀ dé ilẹ̀ ayé. Níwọ̀n ìgbà tí wọn o ti mọ ohun tó yẹ kí wọ́n máa wàásù, ṣó wá yẹ kó yà wá lẹ́nu pé wọn ò mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká wàásù?
KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA WÀÁSÙ?
8. Kí ni kò yẹ kó jẹ́ ìdí tá a fi ń wàásù?
8 Kí nìdí tó fi yẹ ká máa wàásù? Kò yẹ kó jẹ́ torí àtikówó jọ ká sì tún kọ́ àwọn ilé àwòṣífìlà. Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.” (Mát. 10:8) Kò yẹ ká máa ta Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (2 Kọ́r. 2:17) Kò yẹ káwọn tó ń wàásù máa wá bí wọ́n á ṣe fi iṣẹ́ náà wá èrè sápò ara wọn. (Ka Ìṣe 20:33-35.) Dípò káwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tẹ̀ lé ìtọ́ni kedere tí Jésù fún wa, eré bí wọ́n á ṣe máa rí owó kó jọ ni wọ́n ń sá, kí wọ́n ṣáà ti máa rówó ná ní tiwọn. Wọ́n ní láti san owó oṣù fáwọn àlùfáà wọn àtàwọn òṣìṣẹ́ rẹpẹtẹ míì tí wọ́n ní. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ọrọ̀ gègèrè làwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì sábà máa ń kó jọ.—Ìṣí. 17:4, 5.
9. Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe fi hàn pé ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Jèhófà àtàwọn aládùúgbò wọn ló ń mú kí wọ́n wàásù?
9 Ṣé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń gbégbá owó láwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàwọn àpéjọ wa? Rárá o. Ọrẹ àtinúwá la fi ń ṣe gbogbo iṣẹ́ tá à ń ṣe. (2 Kọ́r. 9:7) Síbẹ̀, lọ́dún tó kọjá nìkan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù méjì wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere, ó sì lé ní mílíọ̀nù mẹ́sàn-án èèyàn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ lóṣooṣù. Ohun tó tiẹ̀ tún wá yani lẹ́nu níbẹ̀ ni pé, yàtọ̀ sí pé wọn kì í gba owó kankan fún iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe yìí, tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n tún fi ń náwó nára lórí iṣẹ́ náà. Nígbà tí ẹnì kan tó ń ṣèwádìí ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìwàásù táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe, ó sọ pé: “Ohun tó jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lógún ni bí wọ́n á ṣe wàásù tí wọ́n á sì kọ́ni. . . . Wọn ò ní àlùfáà tí wọ́n ń sanwó fún, torí náà wọn kì í kó sí ìnáwó rẹpẹtẹ.” Kí wá nìdí tá a fi ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù? Ní kúkúrú, àwa fúnra wa la yàn láti máa wàásù torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn aládùúgbò wa. Bá a ṣe ń yọ̀ǹda ara wa tinútinú yìí jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Sáàmù 110:3. (Kà á.)
ÀWỌN Ọ̀NÀ WO LÓ YẸ KÁ MÁA GBÀ WÀÁSÙ?
10. Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbà wàásù?
10 Ọ̀nà wo ni Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbà wàásù ìhìn rere? Wọ́n máa ń wá àwọn èèyàn lọ síbikíbi tí wọ́n bá ti lè rí wọn, yálà ní ìta gbangba tàbí nínú ilé wọn. Iṣẹ́ ìwàásù náà gba pé kí wọ́n máa wá àwọn ẹni yíyẹ rí láti ilé dé ilé. (Mát. 10:11; Lúùkù 8:1; Ìṣe 5:42; 20:20) Ọ̀nà tí wọ́n ń gbà wàásù yìí fi hàn pé wọn kì í ṣojúsàájú.
11, 12. Tó bá dọ̀rọ̀ ká wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù?
11 Kí làwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń ṣe ní tiwọn? Ní ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì, àwọn àlùfáà tí wọ́n ń sanwó fún làwọn ọmọ ìjọ gbà pé ó yẹ kó máa wàásù. Dípò táwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì á sì fi máa ṣe iṣẹ́ “apẹja ènìyàn,” eré báwọn “ẹja,” ìyẹn àwọn ọmọ ìjọ tó ti wà ní ìkáwọ́ wọn ò ṣe ní pẹ̀dín ni wọ́n ń sá. Òótọ́ ni pé nígbà míì, àwọn àlùfáà kan máa ń sọ pé káwọn ọmọ ìjọ wọn náà máa wàásù. Bí àpẹẹrẹ, nínú lẹ́tà kan tí Póòpù John Paul Kejì kọ lọ́dún 2001, ó sọ pé: “Láti ọdún yìí wá, ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ti tẹnu mọ́ ọ pé ká mú ìṣẹ́ ajíhìnrere lákọ̀tun. Ohun kan náà ni mo wá ń sọ báyìí . . . Ó yẹ ká ní irú ẹ̀mí tí Pọ́ọ̀lù ní nígbà tó sọ pé: ‘Mo gbé bí èmi kò bá polongo Ìhìn Rere.’” Póòpù wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé “kò yẹ ká dá iṣẹ́ yìí dá ‘àwọn tá a rò pó mọ̀ nípa ẹ̀,’ gbogbo Èèyàn Ọlọ́run ló yẹ kó máa ṣe é.” Àmọ́, àwọn mélòó ló ti ṣiṣẹ́ lórí ohun tó sọ yẹn?
12 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ńkọ́? Àwọn nìkan ló ń wàásù pé Jésù ti di Ọba, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso látọdún 1914. Wọ́n ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Jésù fún wọn, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé iṣẹ́ ìwàásù yẹn ni wọ́n kà sí pàtàkì jù. (Máàkù 13:10) Ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹlẹ́sìn, ìyẹn Pillars of Faith—American Congregations and Their Partners sọ pé: “Iṣẹ́ ajíhìnrere làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kà sí iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù.” Òǹkọ̀wé náà wá sọ ọ̀rọ̀ tí Ẹlẹ́rìí kan sọ fún un, ó ní: “Táwọn Ẹlẹ́rìí bá pàdé àwọn tébi ń pa, àwọn tó níṣòro ìdánìkanwà, àtàwọn tó ń ṣàìsàn, wọ́n máa ń sapá láti ràn wọ́n lọ́wọ́, . . . àmọ́ wọn ò jẹ́ gbà gbé pé olórí iṣẹ́ àwọn ni láti wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa òpin tó ń bọ̀ àti ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n lè rí ìgbàlà.” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣì ń polongo ìhìn rere náà, ọ̀nà tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbà ṣe é làwọn náà sì ń gbà ṣe é.
IBO LÓ YẸ KÍ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ NÁÀ GBÒÒRÒ DÉ, ÌGBÀ WO LÓ SÌ MÁA DÓPIN?
13. Ibo ló yẹ kí iṣẹ́ ìwàásù náà gbòòrò dé?
13 Jésù sọ ibi tó yẹ kí iṣẹ́ ìwàásù náà gbòòrò dé nígbà tó sọ pé a máa wàásù ìhìn rere yìí “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Mát. 24:14) Látinú “àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè” la ti máa rí àwọn tó máa di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20) Èyí fi hàn pé iṣẹ́ náà gbọ́dọ̀ kárí gbogbo ayé.
14, 15. Kí ló fi hàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti mú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ṣẹ ní ti bó ṣe yẹ kí iṣẹ́ ìwàásù náà gbòòrò tó? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
14 Ká lè mọ bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń mú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ṣẹ pé ká wàásù kárí ayé, ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn kókó kan. Àwọn àlùfáà tó wà nínú onírúurú ẹ̀sìn lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tó nǹkan bí ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ [600,000], bẹ́ẹ̀ sì rèé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ tó mílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba [1,200,000]. Díẹ̀ làwọn àlùfáà Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì tó wà kárí ayé fi lé ní ogún ọ̀kẹ́ [400,000]. Ẹ jẹ́ ká wá wo iye àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá à ń wàásù ìhìn rere kárí ayé. Kárí ayé, nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́jọ làwọn òjíṣẹ́ tó ń yọ̀ǹda ara wọn láti wàásù ní igba ó lé lógójì [240] ilẹ̀. Ẹ ò rí bí iṣẹ́ bàǹtà-banta tá à ń ṣe yìí ṣe ń fi ìyìn àti ògo fún Jèhófà!—Sm. 34:1; 51:15.
15 Ohun táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ ni pé ká wàásù fún gbogbo èèyàn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó kí òpin tó dé. Torí náà, kò sí ẹlẹgbẹ́ wa tó bá dọ̀rọ̀ ká túmọ̀ Bíbélì àtàwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì ká sì tẹ̀ wọ́n jáde. Ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ìwé, ìwé ìròyìn, ìwé àṣàrò kúkúrú, ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi àti ìwé ìkésíni síbi àpèjọ la ti tẹ̀ tá a sì ń fáwọn èèyàn lọ́fẹ̀ẹ́. Onírúurú ìtẹ̀jáde la ti ṣe ní èdè tó ju ọgọ́rùn-ún méje [700] lọ. Ó lé ní igba mílíọ̀nù ẹ̀dà Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a ti tẹ̀ ní èdè tó ju àádóje [130] lọ. Lọ́dún tó kọjá nìkan, ó tó bílíọ̀nù mẹ́rin ààbọ̀ àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì tá a tẹ̀ jáde. Ìkànnì wa wà ní èdè tó ju àádọ́ta dín lẹ́gbẹ̀rin [750] lọ. Àwùjọ àwọn oníwàásù wo ló tún ń ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀?
16. Báwo la ṣe mọ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run wà lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
16 Ìgbà wo la máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà dà? Jésù sọ pé iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé yìí á máa bá a lọ títí di àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, “nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” Àwọn ẹlẹ́sìn míì wo ló tún ń wàásù ìhìn rere náà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tó jẹ́ mánigbàgbé yìí? Àwọn kan tá à ń bá pà dé lóde ẹ̀rí lè sọ pé, “Àwa ní ẹ̀mí mímọ́, àmọ́ ẹ̀yin lẹ̀ ń wàásù.” Àmọ́, ṣé bá a ṣe ń bá iṣẹ́ náà nìṣó tá ò sì jẹ́ kó sú wa ò fi hàn pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa? (Ìṣe 1:8; 1 Pét. 4:14) Látìgbàdégbà, àwùjọ àwọn onísìn kan máa ń gbìyànjú àtiṣe ohun táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe nígbà gbogbo, àmọ́ pàbó ni gbogbo ìsapá wọn máa ń já sí. Àwọn kan ti lọ́wọ́ nínú ohun tí wọ́n pè ní iṣẹ́ ajíhìnrere, àmọ́ kì í pẹ́ tí wọ́n á fi gbé e jù sílẹ̀ tí wọ́n á sì pa dà sídìí ohun tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀. Àwọn míì tiẹ̀ lè lọ wàásù láti ilé dé ilé, àmọ́ kí ni wọ́n ń báwọn èèyàn sọ? Ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn fi hàn pé kì í ṣe iṣẹ́ tí Jésù dá sílẹ̀ ni wọ́n ń ṣe.
ÀWỌN WO GAN-AN LÓ Ń WÀÁSÙ ÌHÌN RERE LÓNÌÍ?
17, 18. (a) Kí ló mú kó dá wa lójú pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà là ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lónìí? (b) Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti máa bá iṣẹ́ náà nìṣó?
17 Torí náà, àwọn wo gan-an ló ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lónìí? A lè fi gbogbo ẹnu sọ pé: “Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni!” Kí ló mú kó dá wa lójú tó bẹ́ẹ̀? Torí pé ohun tó yẹ ká wàásù là ń wàásù, ìyẹn ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Bá a ṣe ń lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn tún fi hàn pé ọ̀nà tó tọ́ là ń gbà ṣe iṣẹ́ náà. Ìdí tó yẹ la sì ń torí ẹ̀ wàásù, ìyẹn ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà àtàwọn èèyàn, kì í ṣe torí ká lè rí owó kó jọ. Iṣẹ́ ìwàásù wa ló gbòòrò jù lọ, torí pé àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà là ń wàásù fún. Láti ọdún dé ọdún, a ó máa bá iṣẹ́ náà nìṣó, a ò sì ní dáwọ́ dúró títí tí òpin fi máa dé.
18 Inú wa dùn bá a ṣe ń rí ohun táwa èèyàn Ọlọ́run ń gbé ṣe láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Àmọ́, kí ló mú kí gbogbo nǹkan yìí ṣeé ṣe? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dáhùn ìbéèrè yìí nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Fílípì, ó ní: “Ọlọ́run ni ẹni tí ń gbéṣẹ́ ṣe nínú yín, nítorí ti ìdùnnú rere rẹ̀, kí ẹ lè fẹ́ láti ṣe, kí ẹ sì gbé ìgbésẹ̀.” (Fílí. 2:13) Ǹjẹ́ kí Baba wa onífẹ̀ẹ́ fún gbogbo wa lókun bá a ṣe ń sa gbogbo ipá wa, ká lè ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ní kíkún.—2 Tím. 4:5.