A Mú Wọn Jáde Kúrò Nínú Òkùnkùn
“[Jèhófà] pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.” —1 PÉT. 2:9.
1. Sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run.
LỌ́DÚN 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Ọba Nebukadinésárì Kejì kó ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ àwọn ọmọ ogun Bábílónì, wọ́n sì lọ gbógun ja ìlú Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí Bíbélì ń ròyìn bí ogun yẹn ṣe rí, ó sọ pé: “[Nebukadinésárì] fi idà pa àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn nínú ilé ibùjọsìn wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìyọ́nú sí ọ̀dọ́kùnrin tàbí wúńdíá, arúgbó tàbí ọ̀jọ̀kútọtọ. . . . Ó sì tẹ̀ síwájú láti fi iná sun ilé Ọlọ́run tòótọ́, ó sì bi ògiri Jerúsálẹ́mù wó; gbogbo àwọn ilé gogoro ibùgbé rẹ̀ sì ni wọ́n fi iná sun àti gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀ fífani-lọ́kàn-mọ́ra pẹ̀lú, láti lè mú ìparun wá.”—2 Kíró. 36:17, 19.
2. Ìkìlọ̀ wo ni Jèhófà fáwọn Júù, kí ló sì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn?
2 Kò yẹ kí ìparun Jerúsálẹ́mù ya àwọn Júù lẹ́nu. Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ ọdún làwọn wòlíì Ọlọ́run ti kìlọ̀ fáwọn èèyàn náà pé tí wọn ò bá yéé tàpá sí òfin Ọlọ́run, àwọn ará Bábílónì máa kó wọn lẹ́rú. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n máa fi idà pa ọ̀pọ̀ lára wọn, èyí tí kò bá sì tojú idà kú á di ẹrú àwọn ará Bábílónì, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbèkùn yẹn ló máa kú sí. (Jer. 15:2) Báwo ni nǹkan ṣe rí fáwọn Júù tí wọ́n kó lọ sígbèkùn? Ǹjẹ́ a lè sọ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Júù yẹn bá ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni mu? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ìgbà wo ni tàwọn Kristẹni wáyé?
BÍ NǸKAN ṢE RÍ NÍ ÌGBÈKÙN
3. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín bí nǹkan ṣe rí fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n wà nígbèkùn Bábílónì àti ìgbà tí wọ́n jẹ́ ẹrú ní Íjíbítì?
3 Bí àwọn wòlíì yẹn ṣe sọ lọ̀rọ̀ rí. Àmọ́ Jèhófà tipasẹ̀ Jeremáyà gba àwọn èèyàn náà nímọ̀ràn pé kí wọ́n jẹ́ kára wọn mọlé nígbèkùn tí wọ́n ń lọ. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ kọ́ ilé [ní Bábílónì], kí ẹ sì máa gbé inú wọn, ẹ gbin ọgbà kí ẹ sì máa jẹ èso wọn. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹ wá àlàáfíà ìlú ńlá tí mo mú kí a kó yín lọ ní ìgbèkùn, ẹ sì gbàdúrà nítorí rẹ̀ sí Jèhófà, nítorí nínú àlàáfíà rẹ̀, àlàáfíà yóò wà fún ẹ̀yin fúnra yín.” (Jer. 29:5, 7) Àwọn tó ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn yẹn ń bá ìgbésí ayé wọn lọ nílùú Bábílónì. Àwọn tó mú wọn lẹ́rú gbà wọ́n láyè déwọ̀n àyè kan pé kí wọ́n máa bójú tó ara wọn. Kódà, àwọn Júù tó wà nígbèkùn yẹn lè lọ síbi tó wù wọ́n nílùú Bábílónì. Tá a bá ń sọ̀rọ̀ káràkátà àti òwò ṣíṣe, ojúkò ni Bábílónì jẹ́ láyé ọjọ́hun. Àwọn àkọsílẹ̀ tí wọ́n wú jáde nínú ilẹ̀ ìlú náà fi hàn pé ọ̀pọ̀ Júù ló di akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nídìí káràkátà, àwọn míì sì di ọ̀gá nídìí iṣẹ́ ọnà. Kódà, àwọn kan lára wọn di ọlọ́rọ̀. Ó ṣe kedere pé bí nǹkan ṣe rí nígbèkùn Bábílónì yàtọ̀ pátápátá sí bó ṣe rí nígbà tí wọ́n jẹ́ ẹrú lábẹ́ àwọn ará Íjíbítì ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú ìgbà yẹn.—Ka Ẹ́kísódù 2:23-25.
4. Àwọn míì wo ló pín nínú ìyà tó jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ tó lọ sígbèkùn? Àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run wo ni wọn ò lè ṣe?
4 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù tó wà nígbèkùn kò níṣòro àtijẹ àtimu, àmọ́ ọ̀rọ̀ tó kan ìjọsìn wọn ńkọ́? Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará Bábílónì ti finá sun tẹ́ńpìlì Jèhófà àti pẹpẹ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ṣeé ṣe fún àwọn àlùfáà láti máa rúbọ lọ́nà tó wà létòlétò. Lára àwọn tí wọ́n kó lọ sígbèkùn làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò ṣe ohun tó yẹ fún ìjìyà, síbẹ̀ wọ́n pín lára ìyà tó jẹ àwọn èèyàn náà. Bó ti wù kó rí, wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti pa Òfin Ọlọ́run mọ́. Àpẹẹrẹ kan ni ti Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta, ìyẹn Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, tí wọn ò jẹ àwọn oúnjẹ tí Ọlọ́run kà léèwọ̀ fáwọn Júù. A sì mọ̀ pé Dáníẹ́lì ò fọ̀rọ̀ àdúrà ṣeré rárá ní gbogbo ìgbà tó wà nígbèkùn. (Dán. 1:8; 6:10) Síbẹ̀, torí pé abọ̀rìṣà làwọn tó jọ̀gá lé wọn lórí, kò rọrùn fáwọn Júù tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run láti ṣe gbogbo ohun tí Òfin Ọlọ́run pa láṣẹ.
5. Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe fáwọn èèyàn rẹ̀, kí sì nìdí tí ìlérí yẹn fi jọni lójú?
5 Ṣó ṣì máa ṣeé ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti máa jọ́sìn Ọlọ́run bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ? Lásìkò tí wọ́n wà nígbèkùn yẹn, kò dájú pé wọ́n á lè ṣe bẹ́ẹ̀. A sì gbọ́ pé Bábílónì kì í dá àwọn ẹrú rẹ̀ sílẹ̀. Àmọ́ o, èrò èèyàn nìyẹn, kì í ṣe ti Jèhófà Ọlọ́run. Ìdí sì ni pé Jèhófà ti ṣèlérí pé òun máa dá àwọn èèyàn òun nídè, ohun tó sì ṣe gan-an nìyẹn. Ó dájú pé ìlérí Ọlọ́run kò ní lọ láìṣẹ.—Aísá. 55:11.
ṢÉ ÀWỌN KRISTẸNI NÁÀ LỌ SÍGBÈKÙN BÁBÍLÓNÌ?
6, 7. Kí nìdí tó fi pọn dandan pé ká tún gbé ọ̀rọ̀ ìgbà táwọn Kristẹni lọ sígbèkùn Bábílónì yẹ̀ wò?
6 Ǹjẹ́ a rí ohunkóhun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni tá a lè fi wé bí àwọn Júù ṣe lọ sí ìgbèkùn Bábílónì? Ọ̀pọ̀ ọdún ni ìwé ìròyìn yìí ti sọ pé Bábílónì mú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní nígbèkùn lọ́dún 1918 àti pé wọ́n jáde kúrò nígbèkùn Bábílónì lọ́dún 1919. Àmọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé, a máa jíròrò àwọn ìdí tó fi yẹ ká tún ọ̀rọ̀ náà gbé yẹ̀ wò.
7 Jẹ́ ká wò ó báyìí ná: Àpapọ̀ àwọn ìsìn èké ayé yìí là ń pè ní Bábílónì Ńlá. Torí náà, tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wà nígbèkùn Bábílónì lọ́dún 1918, a jẹ́ pé wọ́n ti wà lábẹ́ ìsìnrú ìsìn èké lọ́nà kan tàbí òmíì nígbà yẹn. Àmọ́, ẹ̀rí fi hàn pé ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú ọdún 1914 tí wọ́n ja Ogun Àgbáyé Kìíní, ńṣe làwọn ẹni àmì òróró ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń jáwọ́ kúrò nínú ohun tó jẹ mọ́ Bábílónì Ńlá, kì í ṣe pé wọ́n ń di ẹrú rẹ̀. Lóòótọ́ wọ́n ṣenúnibíni sí àwọn ẹni àmì òróró nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, àmọ́ àwọn aláṣẹ ayé ló sábà máa ń ṣe inúnibíni sí wọn, kì í ṣe Bábílónì Ńlá. Torí náà, kò jọ pé àwọn èèyàn Jèhófà lọ sígbèkùn Bábílónì Ńlá lọ́dún 1918.
ÌGBÀ WO LÀWỌN KRISTẸNI LỌ SÍGBÈKÙN BÁBÍLÓNÌ?
8. Ṣàlàyé bí ẹ̀kọ́ èké ṣe wọnú ìjọ Kristẹni. (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
8 Nígbà àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ yan ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe. Àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn náà ló di “ẹ̀yà àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́, àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní.” (Ka 1 Pétérù 2:9, 10.) Ní gbogbo ìgbà táwọn àpọ́sítélì fi wà láyé, àwọn ni wọ́n ń bójú tó ìjọ àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà káàkiri. Àmọ́ nígbà táwọn àpọ́sítélì náà kú, àwọn ọkùnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí í sọ “àwọn ohun àyídáyidà” kí wọ́n lè “fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.” (Ìṣe 20:30; 2 Tẹs. 2:6-8) Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọkùnrin tá à ń sọ yìí ló jẹ́ alábòójútó nínú ìjọ, tí wọ́n wá sọ ara wọn di bíṣọ́ọ̀bù nígbà tó yá. Bó ṣe di pé wọ́n ka ara wọn sí àwùjọ aṣáájú nìyẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Arákùnrin ni gbogbo yín.” (Mát. 23:8) Àwọn ọkùnrin yẹn nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ ayé táwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí bí Aristotle àti Plato fi ń kọ́ni, ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ẹ̀kọ́ èké kọ́ ìjọ dípò ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
9. Báwo ni Ìjọba Róòmù ṣe ti ìsìn Kristẹni tó di apẹ̀yìndà lẹ́yìn, kí ló sì yọrí sí?
9 Lásìkò tí Kọnsitatáìnì abọ̀rìṣà di Olú Ọba Róòmù lọ́dún 313 Sànmánì Kristẹni, wọ́n ṣe òfin pé ẹ̀sìn Kristẹni ìgbà yẹn ni ìjọba fọwọ́ sí bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti di apẹ̀yìndà. Àtìgbà yẹn lọ ni Ṣọ́ọ̀ṣì àti ìjọba Róòmù ti di kòríkòsùn. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìpàdé kan tí wọ́n jọ ṣe nílùú Niséà, Kọnsitatáìnì lé àlùfáà kan tí wọ́n ń pè ní Arius jáde nípàdé náà, ó sì lé e kúrò nílùú torí pé àlùfáà náà kọ̀ láti gbà pé Jésù ni Ọlọ́run. Nígbà tó yá, Theodosius Kìíní (tó jẹ́ Olú Ọba Róòmù lọ́dún 379 sí 395 Sànmánì Kristẹni), sọ Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì tó jẹ́ ayédèrú Kristẹni di ìsìn tí ìjọba Róòmù fọwọ́ sí pé káwọn èèyàn máa ṣe. Àwọn òpìtàn tiẹ̀ sọ pé àsìkò yẹn ni ìlú Róòmù tó jẹ́ abọ̀rìṣà sọ ara wọn di onísìn Kristẹni. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, lásìkò tá à ń sọ yìí, àwọn Kristẹni tó ti di apẹ̀yìndà dara pọ̀ mọ́ àwọn abọ̀rìṣà tó wà lábẹ́ àkóso Ìjọba Róòmù, wọ́n wá jọ para pọ̀ di apá kan Bábílónì Ńlá. Bó ti wù kó rí, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró mélòó kan wà tí wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti máa jọ́sìn Ọlọ́run. Àmọ́ ṣe lọ̀rọ̀ wọn dà bí àlìkámà kéréje tó wà láàárín èpò rẹpẹtẹ, torí bẹ́ẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn ò tà. (Ka Mátíù 13:24, 25, 37-39.) Ó ṣe kedere pé wọ́n wà nígbèkùn Bábílónì!
10. Kí ló jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì kò bá Bíbélì mu láwọn ọgọ́rùn-ún ọdún mélòó kan lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì?
10 Síbẹ̀, ọgọ́rùn-ún ọdún mélòó kan lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, àwọn èèyàn ṣì ń rí Bíbélì kà lédè Gíríìkì tàbí Látìn. Torí náà, ó ṣeé ṣe fún wọn láti rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀kọ́ táwọn ṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni. Nígbà tí wọ́n bá sì ti lóye ohun tí Bíbélì sọ, ṣe ni wọ́n máa ń pa ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì tì. Àmọ́ o, ẹ̀mí wọn lè lọ sí i tí wọ́n bá gbìyànjú láti kọ́ àwọn míì lóhun tí Bíbélì sọ.
11. Báwo ló ṣe di pé àwọn àlùfáà nìkan ló lè ka Bíbélì?
11 Nígbà tó yá, àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ sọ èdè Gíríìkì àti Látìn mọ́, torí náà wọn ò lè ka Bíbélì. Yàtọ̀ síyẹn, ṣọ́ọ̀ṣì ò gbà kí wọ́n túmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí èdè táwọn èèyàn ń sọ. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àwọn àlùfáà àtàwọn ọ̀mọ̀wé nìkan ló lè ka Bíbélì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé púrúǹtù làwọn kan lára àwọn àlùfáà náà. Bí ṣọ́ọ̀ṣì bá sì gbọ́ pé ẹnì kan ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, onítọ̀hún wọ gàù nìyẹn, wọ́n á sì fimú rẹ̀ dánrin. Torí náà, àwọn ẹni àmì òróró ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń dá ọgbọ́n kí wọ́n lè jọ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà yẹn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Ọ̀rọ̀ àwọn ẹni àmì òróró tí Bíbélì pè ní “ẹgbẹ́ àlùfáà aládé” wá dà bíi tàwọn Júù tó wà nígbèkùn Bábílónì nígbà yẹn lọ́hùn-ún, kò ṣeé ṣe fún wọn láti jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó wà létòletò. Ó mà ṣé o, àwọn èèyàn Ọlọ́run bọ́ sínú akóló Bábílónì Ńlá!
ÌMỌ́LẸ̀ BẸ̀RẸ̀ SÍ Í DÉ
12, 13. Ohun méjì wo ló jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn èèyàn ń wọ́nà àtijáde nínú akóló Bábílónì Ńlá? Ṣàlàyé.
12 Ṣó ṣì máa ṣeé ṣe fáwọn Kristẹni tòótọ́ láti máa jọ́sìn Ọlọ́run bí wọ́n ṣe fẹ́, tí inú Ọlọ́run á sì dùn sí wọn? Ó dájú pé ó máa ṣeé ṣe! Nígbà tó yá, ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í dé, òkùnkùn sì ń para dà. Ohun méjì ló sì jẹ́ kíyẹn ṣeé ṣe. Àkọ́kọ́ lára rẹ̀ ni ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tí àwọn lẹ́tà rẹ̀ ṣeé tún tò tí wọ́n ṣe ní nǹkan bí ọdún 1450. Kó tó di pé wọ́n ṣe ẹ̀rọ ìtẹ̀wé, ńṣe làwọn kan ń fi ọwọ́ ṣe àdàkọ Bíbélì bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn. Ìdí nìyẹn tí iye Bíbélì tó wà nígbà yẹn ò fi tó nǹkan, èyí tó sì wà wọ́n gan-an. Wọ́n tiẹ̀ sọ pé kí adàwékọ kan tó jáfáfá tó lè ṣe àdàkọ odindi Bíbélì kan ṣoṣo, ó máa gbà á lóṣù mẹ́wàá! Yàtọ̀ síyẹn, owó kékeré kọ́ ni wọ́n ń ra awọ tí wọ́n máa ń lò nígbà yẹn. Kò dà bíi tòde òní tó jẹ́ pé ọ̀jáfáfá atẹ̀wé lè fi ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tó ń lo bébà tẹ ìwé tó ní ojú ìwé ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [1,300] lọ́jọ́ kan péré!
13 Ohun kejì tó jẹ́ kó ṣeé ṣe ni àwọn ọkùnrin mélòó kan tó fi ìgboyà túmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí èdè táwọn èèyàn ń sọ láàárín ọdún 1501 sí 1540. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn atúmọ̀ èdè yẹn mọ̀ pé ẹ̀mí àwọn lè lọ sí i, síbẹ̀ wọ́n ń báṣẹ́ náà lọ. Nígbà táwọn aṣáájú ìsìn mọ̀, ṣe ni wọ́n gbaná jẹ. Kí nìdí? Wọ́n gbà pé táwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá fi lè máa ka Bíbélì lédè wọn, tọwọ́ àwọn bọ́ nìyẹn! Àmọ́ ẹ̀pa ò bóró mọ́, Bíbélì dé ọwọ́ àwọn èèyàn, wọ́n sì ń kà á dáadáa. Bí wọ́n ṣe ń kà á, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń béèrè pé: ‘Ibo ni pọ́gátórì wà nínú Bíbélì? Ṣé Bíbélì ló ní kéèyàn máa sanwó fún àlùfáà kéèyàn tó sìnkú? Ṣé inú Bíbélì náà ni wọ́n ti rí póòpù àtàwọn kádínà?’ Àrífín gbáà làwọn aṣáájú ìsìn ka gbogbo ìyẹn sí. Wọ́n ní ta ni ń jẹun tájá ń jùrù! Bó ṣe di pé wọ́n tutọ́ sókè nìyẹn tí wọ́n sì fojú gbà á. Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ̀sùn kan àwọn èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin pé wọ́n ń sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run torí pé wọn ò gba ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì gbọ́ mọ́. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, inú ẹ̀kọ́ ayé táwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí bí Aristotle àti Plato fi ń kọ́ni kí wọ́n tó bí Jésù Kristi lọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ èké yẹn ti wá. Tí ṣọ́ọ̀ṣì bá dájọ́ ikú fẹ́ni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn, ìjọba á mú onítọ̀hún wọ́n á sì pa á. Ìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọn ò fẹ́ káwọn èèyàn máa ka Bíbélì, wọn ò sì fẹ́ kí wọ́n máa ṣe ọ̀fíntótó ṣọ́ọ̀ṣì mọ́. Wọ́n ṣàṣeyọrí déwọ̀n àyè kan. Síbẹ̀, àwọn onígboyà kan wà tí wọn ò jẹ́ kí Bábílónì Ńlá kó jìnnìjìnnì bo àwọn. Wọ́n ti tọ́ adùn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wò, wọn ò sì fẹ́ kẹ́nì kan dí wọn lọ́wọ́ àtimáa jadùn ẹ̀ nìṣó! Níbi tọ́rọ̀ dé yìí, ó ṣe kedere pé àwọn èèyàn ń wọ́nà àtijáde kúrò nínú akóló ìsìn èké.
14. (a) Kí làwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì ṣe ní nǹkan bí ọdún 1870? (b) Kí làwọn ohun tí Arákùnrin Russell ṣe kó tó lóye òtítọ́?
14 Ọ̀pọ̀ àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì sá lọ sáwọn orílẹ̀-èdè táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ò ti lẹ́nu ọ̀rọ̀. Ìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n fẹ́ máa ka Bíbélì, kí wọ́n sì jọ máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, wọn ò fẹ́ kó jẹ́ pé àwọn àlùfáà láá máa sọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe. Amẹ́ríkà wà lára àwọn orílẹ̀-èdè táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ò ti lẹ́nu ọ̀rọ̀. Ibẹ̀ sì ni Arákùnrin Charles Taze Russell ń gbé. Ní nǹkan bí ọdún 1870, òun àtàwọn míì máa ń kóra jọ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Níbẹ̀rẹ̀, ohun tí Arákùnrin Russell ní lọ́kàn ni bó ṣe máa mọ èyí tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lára àwọn ìsìn tó wà nígbà yẹn. Torí náà, ó fara balẹ̀ gbé ẹ̀kọ́ onírúurú ṣọ́ọ̀ṣì yẹ̀ wò, títí kan àwọn tí kì í ṣe Kristẹni, ó sì wò ó bóyá ẹ̀kọ́ wọn bá ohun tó wà nínú Bíbélì mu. Kò pẹ́ tó fi mọ̀ pé kò séyìí tó rọ̀ mọ́ Bíbélì délẹ̀délẹ̀. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì mélòó kan, ó ronú pé wọ́n á tẹ́wọ́ gba òtítọ́ tóun àtàwọn yòókù rẹ̀ ṣàwárí nínú Bíbélì, wọ́n á sì máa fi kọ́ ìjọ wọn. Etí ikún làwọn àlùfáà yẹn kọ sí gbogbo àlàyé tó ṣe. Ó wá di pé káwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn Russell àtàwọn yòókù rẹ̀ ṣèpinnu, ìpinnu náà sì ni pé àwọn ò ní ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn ìsìn tó ń fi ẹ̀kọ́ èké kọ́ni.—Ka 2 Kọ́ríńtì 6:14.
15. (a) Ìgbà wo làwọn Kristẹni tòótọ́ lọ sígbèkùn Bábílónì Ńlá? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
15 Níbi tá a bọ́rọ̀ dé yìí, ó ṣe kedere pé lẹ́yìn tí àpọ́sítélì tó gbẹ̀yìn kú làwọn Kristẹni tòótọ́ lọ sígbèkùn Bábílónì. Àmọ́, àwọn ìbéèrè kan wà tá a ṣì máa dáhùn: Ẹ̀rí míì wo ló fi hàn pé ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú ọdún 1914 àwọn ẹni àmì òróró ti ń já ara wọn gbà lọ́wọ́ Bábílónì Ńlá, tí wọn ò sì sí lábẹ́ ìsìnrú rẹ̀ mọ́? Ṣé òótọ́ ni pé inú Jèhófà ò dùn sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ torí pé wọ́n dẹwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù lásìkò Ogun Àgbáyé Kìíní? Ṣé òótọ́ sì ni pé àwọn ará wa kan lọ́wọ́ sí ogun nígbà yẹn tí Jèhófà sì tìtorí rẹ̀ bínú sí wọn? Paríparí rẹ̀, tó bá jẹ́ pé ẹ̀yìn ikú àwọn àpọ́sítélì làwọn Kristẹni tòótọ́ lọ sígbèkùn Bábílónì, ìgbà wo ni wọ́n jáde? Kò sí àní-àní pé àwọn ìbéèrè yìí bọ́gbọ́n mu, a sì máa dáhùn wọn nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.