Ṣé Ọlọ́run Mọ Bí Nǹkan Ṣe Máa Ń Rí Lára Wa?
OHUN TÁ A RÍ KỌ́ LÁRA ÌṢẸ̀DÁ
Tá a bá fẹ́ mọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹlòmíì, ó gba pé ká fojú inú wo bó ṣe máa rí tó bá jẹ́ pé àwa ni nǹkan yẹn ṣẹlẹ̀ sí. Rick Hanson tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìlera ọpọlọ sọ pé, “gbogbo wa pátá ni Ọlọ́run dá lọ́nà tá a fi lè fi ọ̀rọ̀ ẹlòmíì ro ara wa wò.”
RÒ Ó WÒ NÁ: Nínú gbogbo nǹkan tí Olọ́run dá sáyé, kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwa èèyàn nìkan la lè fojú inú wo bí nǹkan ṣe rí lára ẹlòmíì? Bíbélì sọ pé Ọlọ́run dá àwa èèyàn ní àwòrán ara rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Ọlọ́run dá àwa èèyàn ní àwòrán ara rẹ̀ níti pé a lè fìwà jọ ọ́, ká sì ní àwọn ìwà àtàtà tó ní. Torí náà, tí ìfẹ́ bá mú ká fi ọ̀rọ̀ ẹnì kan ro ara wa wò tá a sì ràn án lọ́wọ́, ńṣe la fìwà jọ Ẹlẹ́dàá wa aláàánú, Jèhófà Ọlọ́run.—Òwe 14:31.
BÍBÉLÌ KỌ́ WA PÉ ỌLỌ́RUN MỌ BÍ NǸKAN ṢE RÍ LÁRA WA
Ọlọ́run mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára àwa èèyàn, kò sì fẹ́ ká máa jìyà rárá. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àwọn ará Íjíbítì kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ lẹ́rú tí wọ́n sì hùwà ìkà tó burú jáì sí wọn, tí wọ́n tún jìyà fún ogójì [40] ọdún nínú aginjù, Bíbélì sọ pé: “Nínú gbogbo wàhálà wọn, ó jẹ́ wàhálà fún un.” (Aísáyà 63:9) Kíyè sí i pé kì í wulẹ̀ ṣe pé Ọlọ́run mọ̀ pé wọ́n ń jìyà nìkan ni, ó tún mọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn. Ó tiẹ̀ sọ pé: “Mo mọ ìrora tí wọ́n ń jẹ ní àmọ̀dunjú.” (Ẹ́kísódù 3:7) Ọlọ́run tún sọ pé: “Ẹni tí ó bá fọwọ́ kàn yín ń fọwọ́ kan ẹyinjú mi.” (Sekaráyà 2:8) Táwọn èèyàn bá ṣe ohun tí kò dáa sí wa, ó máa ń dun Ọlọ́run bó ṣe ń dùn wá.
Tá a bá ti ro ara wa pin, tá a sì rò pé Ọlọ́run ò mọ bí nǹkan ṣe rí lára wa, a gbọ́dọ̀ máa rántí ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ tí Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.” (1 Jòhánù 3:19, 20) Olọ́run mọ̀ wá ju bá a ṣe mọ ara wa lọ. Gbogbo nǹkan tó ń ṣe wá pátá ni Jèhófà mọ̀, ó sì mọ èrò wa àti bí nǹkan ṣe ń rí lára wa.
A lè bẹ Olọ́run pé kó tù wá nínú, kó fún wa lọ́gbọ́n, kó sì tì wá lẹ́yìn, torí ó máa ń ran àwọn tó wà nínú ìdààmú lọ́wọ́
Bíbélì fi dá wa lójú pé
“Ìwọ yóò pè, Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò sì dáhùn; ìwọ yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́, òun yóò sì wí pé, ‘Èmi rèé!’ ”—AÍSÁYÀ 58:9.
“ ‘Nítorí èmi fúnra mi mọ àwọn èrò tí mo ń rò nípa yín ní àmọ̀dunjú,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘àwọn èrò àlàáfíà, kì í ṣe ti ìyọnu àjálù, láti fún yín ní ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan. Dájúdájú, ẹ ó sì pè mí, ẹ ó sì wá gbàdúrà sí mi, èmi yóò sì fetí sí yín.’ ”—JEREMÁYÀ 29:11, 12.
“Fi omijé mi sínú ìgò awọ rẹ. Wọn kò ha sí nínú ìwé rẹ?”—SÁÀMÙ 56:8.
ỌLỌ́RUN Ń KÍYÈ SÍ WA, Ọ̀RỌ̀ WA YÉ E, Ó SÌ MÁA Ń DÙN ÚN TÁ A BÁ Ń JÌYÀ
Ṣé a lè fara da ìṣòro tá a bá mọ̀ pé Ọlọ́run mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára wa? Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Maria:
“Ìgbà tí ọmọkùnrin mi kú lẹ́yìn tí àrùn jẹjẹrẹ ti bá a fínra fún ọdún méjì gbáko ni mo mọ̀ pé ayé yìí le, ìyà sì pọ̀. Ìbànújẹ́ dorí mi kodò, mo sì ń bínú sí Jèhófà pé ó ń wo ọmọ mi níran títí tó fi kú!
“Ọdún mẹ́fà lẹ́yìn náà, ó ṣì ń ṣe mí bíi pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ mi. Mo sọ ohun tó wà lọ́kàn mi fún ọ̀rẹ́ mi àtàtà kan nínú ìjọ, ó sì tẹ́tí sí mi. Lẹ́yìn tó ti fara balẹ̀ tẹ́tí sí mi fún wákàtí mélòó kan tí kò sì dá ọ̀rọ̀ mọ́ mi lẹ́nu, ó ka ẹsẹ Bíbélì kan tó wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, ìyẹn 1 Jòhánù 3:19, 20, tó sọ pé: ‘Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.’ Ó wá sọ pé tá a bá wà nínú ìdààmú, ọ̀rọ̀ wa yé Jèhófà.
“Àmọ́, inú ṣì ń bí mi! Lẹ́yìn náà, mo ka Sáàmù 94:19, tó sọ pé: ‘Nígbà tí ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè di púpọ̀ nínú mi, ìtùnú tìrẹ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣìkẹ́ ọkàn mi.’ Ńṣe ló dà bíi pé torí tèmi ni wọ́n ṣe kọ ẹsẹ Bíbélì yẹn! Nígbà tó yá, ara máa ń tù mí láti sọ àwọn nǹkan tó ń dà mí láàmú fún Jèhófà, torí mo mọ̀ pé ó ń gbọ́ mi, ọ̀rọ̀ mi sì yé e.”
Ṣé ìwọ náà rí i pé ó ń tuni nínú láti mọ̀ pé ọ̀rọ̀ wa yé Ọlọ́run àti pé ó máa ń dùn ún tí ìyà bá ń jẹ wá? Àmọ́, kí nìdí tí ìyà fi pọ̀ tó báyìí? Ṣé Ọlọ́run ń fìyà ẹ̀ṣẹ̀ wa jẹ wá ni? Ṣe Ọlọ́run máa mú gbogbo ìyà kúrò? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó kàn.