Sapá Láti Túbọ̀ Di Ẹni Tẹ̀mí
“Ẹ máa rìn nípa ẹ̀mí.”—GÁL. 5:16.
1, 2. Kí ni arákùnrin kan wá mọ̀ nípa ara rẹ̀, kí ló sì ṣe?
ỌMỌ ỌDÚN mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] ni Arákùnrin Robert nígbà tó ṣèrìbọmi, àmọ́ kò fọwọ́ pàtàkì mú òtítọ́. Ó sọ pé: “Kì í ṣe pé mo dẹ́ṣẹ̀ kankan, àmọ́ àwọn ohun tí mò ń ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà ò dénú mi, mo kàn ṣáà ń ṣe wọ́n ni. Mo máa ń lọ sípàdé déédéé mo sì máa ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ láwọn oṣù mélòó kan lọ́dún, torí náà ṣe ló dà bíi pé ẹni tẹ̀mí ni mí. Mi ò mọ̀ pé mi ò dàgbà nípa tẹ̀mí rárá.”
2 Ìgbà tí Arákùnrin Robert ṣègbéyàwó ló tó mọ̀ pé òun ò tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Báwo ló ṣe mọ̀? Òun àti ìyàwó rẹ̀ sábà máa ń bi ara wọn láwọn ìbéèrè Bíbélì. Kíá ni ìyàwó rẹ̀ máa ń dáhùn torí pé ẹni tẹ̀mí ni, àmọ́ tó bá di pé kí Robert dáhùn ṣe lara ẹ̀ máa ń wọ̀ ṣìn-ìn torí kì í mohun tó máa sọ. Robert sọ pé: “Ṣe ló dà bíi pé mi ò mọ nǹkan kan. Mo sọ fúnra mi pé, ‘Tí mo bá máa jẹ́ olórí ìdílé tó ń múpò iwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run, àfi kí n wá nǹkan ṣe ní kíá.’ ” Ohun tó sì ṣe nìyẹn. Ó sọ pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo kẹ́kọ̀ọ́, mo kẹ́kọ̀ọ́ títí, mi ò sì jẹ́ kó sú mi. Nígbà tó yá àwọn ohun tí mò ń kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í wọ̀ mí lọ́kàn, ó sì ń yé mi dáadáa. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà.”
3. (a) Kí la rí kọ́ látinú ìrírí Arákùnrin Robert? (b) Àwọn kókó pàtàkì wo la máa jíròrò báyìí?
3 Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la lè rí kọ́ látinú ìrírí Arákùnrin Robert. A lè ní ìmọ̀ Bíbélì ká sì máa lọ sípàdé déédéé, àmọ́ àwọn nǹkan yìí nìkan kò tó láti sọ wá dẹni tẹ̀mí. Ó sì lè jẹ́ pé a ti ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, àmọ́ tá a bá ṣàyẹ̀wò ara wa dáadáa a lè rí i pé àwọn ibì kan ṣì wà tó ti yẹ ká ṣàtúnṣe. (Fílí. 3:16) Ká lè máa dàgbà sí i nípa tẹ̀mí, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè mẹ́ta yìí: (1) Báwo la ṣe lè mọ bá a ṣe dàgbà tó nípa tẹ̀mí? (2) Kí la lè ṣe táá jẹ́ ká túbọ̀ di ẹni tẹ̀mí, ká má sì jó àjórẹ̀yìn? (3) Tá a bá jẹ́ ẹni tẹ̀mí, báwo nìyẹn ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ nígbèésí ayé wa?
BÁ A ṢE LÈ YẸ ARA WA WÒ
4. Àwọn wo lọ̀rọ̀ inú Éfésù 4:23, 24 kàn?
4 Nígbà tá a di ìránṣẹ́ Ọlọ́run, a ṣe àwọn àyípadà kan. Àwọn àyípadà yẹn sì yí ìgbésí ayé wa pa dà pátápátá. Kódà, lẹ́yìn tá a ṣèrìbọmi a ṣì ń ṣe àwọn àyípadà kan. Bíbélì sọ pé ‘kí a di tuntun nínú ipá tí ń mú èrò inú wa ṣiṣẹ́.’ (Éfé. 4:23, 24) Torí pé a kì í ṣe ẹni pípé, a gbọ́dọ̀ máa bá a lọ láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ ní ìgbésí ayé wa. Kódà àwọn tó ti ń sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún gbọ́dọ̀ máa sapá kí wọ́n má bàa jó àjórẹ̀yìn nípa tẹ̀mí.—Fílí. 3:12, 13.
5. Àwọn ìbéèrè wo la lè fi yẹ ara wa wò?
5 Tá a bá fẹ́ tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí ká má sì jó àjórẹ̀yìn, ó yẹ ká ṣàyẹ̀wò ara wa. Yálà ọmọdé ni wá àbí àgbàlagbà, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé àwọn nǹkan tí mò ń ṣe báyìí fi hàn pé mo túbọ̀ ń dẹni tẹ̀mí? Ǹjẹ́ àwọn èèyàn mọ̀ mí sẹ́ni tó ń hùwà bíi Kristi? Ṣé bí mo ṣe ń hùwà nípàdé fi hàn pé ẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí ni mí? Kí làwọn nǹkan tí mo máa ń sọ fi hàn nípa irú nǹkan tí mo nífẹ̀ẹ́ sí? Ṣé mo máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, tí wọ́n bá sì gbà mí nímọ̀ràn, báwo ló ṣe máa ń rí lára mi? Kí ni aṣọ àti ìmúra mi ń sọ nípa irú ẹni tí mo jẹ́ gan-an? Tí mo bá kojú àdánwò, kí ni mo máa ń ṣe? Ṣé òye mi ti kọjá àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, ṣé mo sì ti di géńdé Kristẹni tó ní òye kíkún nípa Jèhófà?’ (Éfé. 4:13) Ìdáhùn wa sáwọn ìbéèrè yìí máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá à ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí àbí a ò ṣe bẹ́ẹ̀.
6. Báwo la ṣe lè mọ bá a ṣe dàgbà tó nípa tẹ̀mí?
6 Tá a bá fẹ́ mọ bá a ṣe dàgbà tó nípa tẹ̀mí, ó lè gba pé káwọn míì ràn wá lọ́wọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ẹni tara kì í gbà pé inú Ọlọ́run kò dùn sáwọn nǹkan tóun ń ṣe. Lọ́wọ́ kejì, ẹni tẹ̀mí máa ń lóye àwọn ìlànà Ọlọ́run, ó sì mọ̀ pé inú Ọlọ́run kì í dùn sáwọn iṣẹ́ ti ara. (1 Kọ́r. 2:14-16; 3:1-3) Àwọn alàgbà máa ń tètè rí àwọn nǹkan tó lè sọ wá dẹni tara torí pé wọ́n ní èrò inú Kristi. Tí wọ́n bá pe àfiyèsí wa sí irú nǹkan bẹ́ẹ̀, ṣé a máa ń gba ìmọ̀ràn wọn, ṣé a sì máa ń fi í sílò? Tá a bá ń gba ìmọ̀ràn wọn, à ń fi hàn pé ó wù wá láti túbọ̀ dẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí.—Oníw. 7:5, 9.
BÁ A ṢE LÈ TÚBỌ̀ DI ẸNI TẸ̀MÍ
7. Ṣé ìmọ̀ Bíbélì nìkan lè sọ wá dẹni tẹ̀mí? Ṣàlàyé.
7 Ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé ìmọ̀ Bíbélì nìkan ò lè sọ wá dẹni tẹ̀mí. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ọba Sólómọ́nì ní ìmọ̀ gan-an nípa Jèhófà, kódà àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó sọ di apá kan Bíbélì. Àmọ́ kí ló gbẹ̀yìn ayé ẹ̀? Ó pàdánù ojúure Ọlọ́run torí pé ó di ẹni tara. (1 Ọba 4:29, 30; 11:4-6) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí la tún nílò yàtọ̀ sí ìmọ̀ Bíbélì? A tún gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. (Kól. 2:6, 7) Àmọ́ báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
8, 9. (a) Kí ló máa jẹ́ ká fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa nípa tẹ̀mí? (b) Kí nìdí tá a fi ń dá kẹ́kọ̀ọ́ tá a sì ń ṣàṣàrò? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
8 Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní nímọ̀ràn pé kí wọ́n “tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú.” (Héb. 6:1) Tó o bá fẹ́ fi ìmọ̀ràn yẹn sílò lónìí, kí làwọn nǹkan tó o máa ṣe? Ọ̀kan lára àwọn nǹkan tó o lè ṣe ni pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ ìwé ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run.’ Tó o bá máa fi kẹ́kọ̀ọ́ ìwé yìí tán, wàá rí bó o ṣe lè máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nígbèésí ayé rẹ. Tó bá sì jẹ́ pé o ti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé yìí tán, wá àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ míì táá jẹ́ kó o fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa nípa tẹ̀mí. (Kól. 1:23) Ohun míì tó yẹ kó o ṣe ni pé kó o máa ronú nípa ohun tó ò ń kọ́, kó o sì máa bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o lè fi wọ́n sílò.
9 Ẹ máa fi sọ́kàn pé ìdí tá a fi ń dá kẹ́kọ̀ọ́ tá a sì ń ṣàṣàrò ni pé a fẹ́ múnú Jèhófà dùn, a sì fẹ́ pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́. (Sm. 40:8; 119:97) Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ ká sapá láti yẹra fáwọn nǹkan tó lè mú ká jó rẹ̀yìn nípa tẹ̀mí.—Títù 2:11, 12.
10. Kí làwọn ọ̀dọ́ lè ṣe kí wọ́n lè dẹni tẹ̀mí?
10 Tó bá jẹ́ ọ̀dọ́ ni ẹ́, ṣé o ti mọ nǹkan tó o fẹ́ fayé ẹ ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà? Ohun kan wà tí arákùnrin kan tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì máa ń ṣe tó bá lọ sáwọn àpéjọ àyíká. Ó sábà máa ń bá àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi sọ̀rọ̀ kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀, ọ̀pọ̀ wọn ló sì máa ń jẹ́ ọ̀dọ́. Arákùnrin yẹn máa ń bi wọ́n pé kí làwọn àfojúsùn wọn nínú ìjọsìn Jèhófà. Ọ̀pọ̀ ni ìdáhùn wọn máa ń fi hàn pé wọ́n ti mọ ohun tí wọ́n fẹ́ fayé wọn ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà, àwọn kan lè fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alákòókò kíkún tàbí kí wọ́n fẹ́ lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀. Àmọ́, àwọn kan wà tí wọn ò tíì mọ ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe rárá. Ṣe ló dà bíi pé àwọn ọ̀dọ́ yẹn ò tíì mọ̀ pé ó yẹ káwọn láwọn àfojúsùn tẹ̀mí. Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, bi ara rẹ pé: ‘Ṣé torí àwọn òbí mi ni mo ṣe ń lọ́wọ́ sáwọn nǹkan tẹ̀mí, àbí ó tọkàn mi wá? Ṣé mò ń sapá láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà?’ Kì í ṣe àwọn ọ̀dọ́ nìkan ló yẹ kí wọ́n ní àfojúsùn tẹ̀mí, ó kan àwọn àgbàlagbà náà. Tá a bá láwọn àfojúsùn tẹ̀mí, gbogbo wa máa fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa, àá sì dúró sán-ún nípa tẹ̀mí.—Oníw. 12:1, 13.
11. (a) Tá a bá fẹ́ tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, kí la gbọ́dọ̀ ṣe? (b) Àpẹẹrẹ inú Bíbélì wo la lè fara wé?
11 Tá a bá ti mọ àwọn ibi tó ti yẹ ká ṣàtúnṣe, ó yẹ ká tètè ṣe bẹ́ẹ̀ ká lè tẹ̀ síwájú. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká dẹni tẹ̀mí, tá ò bá dẹni tẹ̀mí, ìyè àìnípẹ̀kun lè bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́. (Róòmù 8:6-8) Kò dìgbà tá a bá di ẹni pípé ká tó lè dẹni tẹ̀mí. Jèhófà lè fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ láti tẹ̀ síwájú. Síbẹ̀, àwa náà ní láti sapá. Nígbà tí Arákùnrin John Barr, tó wà lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí nígbà kan ń sọ̀rọ̀ nípa Lúùkù 13:24, ó sọ pé, “Ọ̀pọ̀ ni kò lè gba ọ̀nà tóóró yẹn wọlé nítorí pé wọn ò sapá tó láti di alágbára.” Ó yẹ ká dà bíi Jékọ́bù tó bá áńgẹ́lì wọ̀yá ìjà tí kò sì juwọ́ sílẹ̀ títí tó fi rí ìbùkún gbà. (Jẹ́n. 32:26-28) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń gbádùn mọ́ni, kò yẹ ká máa kà á bí ìwé ìtàn àròsọ tá a fi ń dá ara wa lára yá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká máa wá àwọn ìṣúra tẹ̀mí tó máa ràn wá lọ́wọ́.
12, 13. (a) Kí ló máa jẹ́ ká fi ohun tó wà nínú Róòmù 15:5 sílò? (b) Báwo ni àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pétérù ṣe lè ràn wá lọ́wọ́, báwo la ṣe lè fi ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò? (d) Kí lo lè ṣe kó o lè dẹni tẹ̀mí? (Wo àpótí náà “Àwọn Nǹkan Táá Mú Kó O Túbọ̀ Dẹni Tẹ̀mí.”)
12 Bá a ṣe ń sapá láti dẹni tẹ̀mí, ẹ̀mí mímọ́ máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè yí èrò inú wa pa dà. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú bíi ti Kristi. (Róòmù 15:5) Yàtọ̀ síyẹn, á tún ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, ká sì ní àwọn ànímọ́ táá múnú Ọlọ́run dùn. (Gál. 5:16, 22, 23) Tó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan tara tàbí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lọkàn rẹ sábà máa ń fà sí, má jẹ́ kó sú ẹ. Máa bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, Jèhófà á yí èrò inú rẹ pa dà débi pé àwọn nǹkan tó tọ́ láá máa wà lọ́kàn rẹ. (Lúùkù 11:13) Ẹ rántí àpọ́sítélì Pétérù. Àwọn ìgbà kan wà tí kò ṣe ohun tó yẹ kí ẹni tẹ̀mí ṣe. (Mát. 16:22, 23; Lúùkù 22:34, 54-62; Gál. 2:11-14) Àmọ́ kò jẹ́ kó sú òun. Jèhófà ràn án lọ́wọ́ débi pé nígbà tó yá, òun náà bẹ̀rẹ̀ sí í ronú bíi ti Kristi. Ohun tó yẹ káwa náà ṣe nìyẹn.
13 Nígbà tó yá, Pétérù sọ àwọn ànímọ́ kan tó yẹ ká sapá láti ní. (Ka 2 Pétérù 1:5-8.) Bá a ṣe ń sapá gidigidi láti ní àwọn ànímọ́ bí ìkóra-ẹni-níjàánu, ìfaradà àti ìfẹ́ni ará, ṣe làá túbọ̀ máa dẹni tẹ̀mí. Ó yẹ ká máa bi ara wa lójoojúmọ́ pé, ‘Kí ni mo lè ṣe lónìí yìí táá mú kí n túbọ̀ dẹni tẹ̀mí?’
BÁ A ṢE LÈ MÁA FI ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ SÍLÒ LÓJOOJÚMỌ́
14. Tá a bá jẹ́ ẹni tẹ̀mí, báwo nìyẹn ṣe máa nípa lórí ìgbésí ayé wa?
14 Tá a bá ní èrò inú Kristi, ó máa hàn nínú ọ̀rọ̀ wa, ìṣe wa níbi iṣẹ́ tàbí níléèwé, àti nínú àwọn ìpinnu tá à ń ṣe lójoojúmọ́. Àwọn ìpinnu tá à ń ṣe máa fi hàn bóyá à ń sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Tá a bá jẹ́ ẹni tẹ̀mí, a ò ní jẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Tá a bá ń hùwà bíi Kristi, a máa borí ìdẹwò èyíkéyìí tó bá yọjú. Tá a bá fẹ́ ṣèpinnu, á dáa ká bi ara wa pé: ‘Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló máa ràn mí lọ́wọ́ kí n lè ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu? Ká ní Jésù ló fẹ́ ṣe ìpinnu tí mo fẹ́ ṣe yìí, kí ló máa ṣe? Tí mo bá ṣe ohun tí mo fẹ́ ṣe yìí, ṣé inú Jèhófà máa dùn sí mi?’ Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan táá jẹ́ ká máa ronú bí Kristi ṣe ń ronú. Nínú àpẹẹrẹ kọ̀ọ̀kan, a máa rí ìlànà Ìwé Mímọ́ kan táá jẹ́ ká ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu.
15, 16. Tó o bá ń ronú bíi ti Kristi, báwo nìyẹn ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ (a) láti pinnu ẹni tó o máa fẹ́? (b) láti yan àwọn tó o máa bá kẹ́gbẹ́?
15 Tó o bá fẹ́ pinnu ẹni tó o máa fẹ́. Ìlànà tó wà nínú 2 Kọ́ríńtì 6:14, 15 ló yẹ kó o fi sọ́kàn. (Kà á.) Pọ́ọ̀lù jẹ́ kó ṣe kedere pé ẹni tẹ̀mí kò lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ẹni tara. Báwo lo ṣe lè fi ìlànà yìí sílò tó o bá fẹ́ yan ẹni tó o máa fẹ́?
16 Àwọn tó ò ń bá kẹ́gbẹ́. Ẹ ronú nípa ìlànà tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 15:33. (Kà á.) Ẹni tẹ̀mí kò ní máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó lè ba àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Àwọn ìbéèrè kan wà táá jẹ́ kó o rí bó o ṣe lè fi ìlànà yìí sílò. Bí àpẹẹrẹ, báwo ni ìlànà yìí ṣe kan àwọn tí mò ń bá kẹ́gbẹ́ lórí ìkànnì àjọlò? Tí ẹni tó ò mọ̀ rí bá ní kẹ́ ẹ jọ máa gbá géèmù lórí ìkànnì, kí lo máa ṣe?
17-19. Tó o bá jẹ́ ẹni tẹ̀mí, báwo nìyẹn ṣe máa mú kó o (a) yẹra fáwọn ohun tí kò ní jẹ́ kó o ṣe púpọ̀ sí i nínú ìjọsìn Ọlọ́run? (b) ní àwọn àfojúsùn tó yẹ? (d) yanjú èdèkòyédè?
17 Àwọn nǹkan tí kò ní jẹ́ kó o tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Ìkìlọ̀ pàtàkì kan wà nínú ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú Hébérù 6:1. (Kà á.) Kí làwọn “òkú iṣẹ́” tó yẹ ká yẹra fún? Òkú iṣẹ́ ni ohunkóhun tí kò bá ti jẹ́ kéèyàn ṣe púpọ̀ sí i nínú ìjọsìn Ọlọ́run tàbí tí kò jẹ́ kéèyàn dẹni tẹ̀mí. Ìlànà yìí máa jẹ́ ká rí ìdáhùn sí ọ̀pọ̀ ìbéèrè tó lè jẹyọ. Bí àpẹẹrẹ, bi ara rẹ pé: ‘Ṣé nǹkan tí mo fẹ́ ṣe yìí wà lára àwọn iṣẹ́ ti ara tí Bíbélì mẹ́nu kàn? Ṣó yẹ kí n lọ́wọ́ sí òwò táyé ń pariwo rẹ̀ yìí? Kí nìdí tí kò fi yẹ kí n dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ atúnlùúṣe?’
18 Àwọn àfojúsùn tẹ̀mí. Àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Ìwàásù Lórí Òkè jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ ká fi ṣe àfojúsùn wa. (Mát. 6:33) Àwọn àfojúsùn tẹ̀mí lẹni tẹ̀mí máa ń lé, ó sì máa ń wá bó ṣe máa ṣe púpọ̀ sí i nínú ìjọsìn Jèhófà. Tá a bá ń fi ìlànà yìí sọ́kàn, á jẹ́ ká lè dáhùn àwọn ìbéèrè bíi: ‘Ṣé kí n lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga? Ṣé kí n gba iṣẹ́ tí wọ́n fún mi yìí?’
19 Èdèkòyédè. Báwo ni ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará ní Róòmù ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ní èdèkòyédè pẹ̀lú ẹnì kan? (Róòmù 12:18) Torí pé ọmọlẹ́yìn Kristi ni wá, a máa ń sapá láti “jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.” Tí èdèkòyédè bá ṣẹlẹ̀, kí ni mo máa ń ṣe? Ṣé kì í gbọ́ kì í gbà ni mí àbí ẹni tó máa ń “wá àlàáfíà” làwọn èèyàn mọ̀ mí sí?—Ják. 3:18.
20. Ṣó wù ẹ́ kó o túbọ̀ di ẹni tẹ̀mí? Kí nìdí?
20 Àwọn àpẹẹrẹ yìí ti jẹ́ ká rí i pé tá a bá ń ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì, àá máa ṣe àwọn ìpinnu tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Èyí á sì fi hàn pé a jẹ́ ẹni tẹ̀mí. Tá a bá jẹ́ ẹni tẹ̀mí, a máa ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn. Arákùnrin Robert tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, mo di ọkọ àti bàbá tó túbọ̀ ń ṣe ojúṣe rẹ̀ bó ṣe yẹ. Mo ní ìtẹ́lọ́rùn, mo sì ń láyọ̀.” Táwa náà bá ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, tá a sì ń ṣe púpọ̀ sí i nínú ìjọsìn Ọlọ́run, àwa náà máa rí ìbùkún gbà. Ìgbésí ayé wa máa ládùn, á lóyin nísinsìnyí, àá sì ní “ìyè tòótọ́” lọ́jọ́ iwájú.—1 Tím. 6:19.