“Àá Pàdé ní Párádísè!”
“Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.”—LÚÙKÙ 23:43.
1, 2. Àwọn èrò tó yàtọ̀ wo làwọn èèyàn ní nípa Párádísè?
LẸ́YÌN tí àpéjọ àgbègbè tá a ṣe ní pápá ìṣeré kan nílùú Seoul, lórílẹ̀-èdè Kòríà parí, ńṣe làwọn tó pé jọ bẹ̀rẹ̀ sí í dì mọ́ra, táwọn kan sì ń sunkún bíi pé kí àpéjọ náà má parí. Bí àwọn ará tó wá láti orílẹ̀-èdè míì ti ń dágbére fáwọn ará ní Kòríà, ńṣe làwọn ará Kòríà ń kí wọn ní mẹ́sàn-án mẹ́wàá, tí wọ́n ń juwọ́ sí wọn pé, “Ó dìgbà kan ná, àá pàdé ní Párádísè!” Párádísè wo lo rò pé àwọn ará yẹn ní lọ́kàn?
2 Èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn èèyàn ní nípa Párádísè. Àwọn kan sọ pé àlá lásán lọ̀rọ̀ Párádísè. Àwọn míì gbà pé téèyàn bá ti ní ayọ̀ àti ìbàlẹ̀ ọkàn, inú Párádísè ló wà yẹn. Ẹni tébi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa kú, tó wá jàjà bá ara ẹ̀ níbi àsè tí oúnjẹ ti ya mùrá lè sọ pé òun wà ní Párádísè. Nígbà tí obìnrin arìnrìn-àjò kan rí àfonífojì kan tó kún fún òdòdó, ó yà á lẹ́nu, ó wá sọ pé, “Párádísè gan-an rèé!” Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé Párádísè ni ibẹ̀ yẹn ń jẹ́ títí dòní olónìí? Kí ló máa ń wá sí ẹ lọ́kàn tó o bá gbọ́ Párádísè? Ṣé ìwọ náà ń fojú sọ́nà fún Párádísè?
3. Ìgbà wo ni Bíbélì kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa Párádísè?
3 Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa Párádísè tó wà tẹ́lẹ̀ àtèyí tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. Kódà, inú Jẹ́nẹ́sísì ni Bíbélì ti kọ́kọ́ mẹ́nu kan Párádísè. Bí àpẹẹrẹ, nínú Bíbélì Douay Version tàwọn Kátólíìkì, tí wọ́n túmọ̀ látinú èdè Látìn, Jẹ́nẹ́sísì 2:8 kà pé: “Olúwa Ọlọ́run sì gbin párádísè tó tura látìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀: ibẹ̀ ló sì fi [Ádámù] tó ṣẹ̀dá sí.” (Àwa la kọ ọ́ lọ́nà tó dúdú yàtọ̀.) Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n lò nínú ẹsẹ yẹn ni ọgbà Édẹ́nì. Édẹ́nì túmọ̀ sí “Ìtura,” ó sì dájú pé lóòótọ́ ni ọgbà yẹn tura. Ọgbà náà rẹwà gan-an, oúnjẹ pọ̀ níbẹ̀, àlàáfíà sì wà láàárín èèyàn àtàwọn ẹranko.—Jẹ́n. 1:29-31.
4. Kí nìdí tá a fi lè pe ọgbà Édẹ́nì ní Párádísè?
4 Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí “ọgbà” làwọn Gíríìkì máa ń pè ní pa·raʹdei·sos. Nígbà tí ìwé Cyclopædia tí M’Clintock àti Strong ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa pa·raʹdei·sos, ó sọ pé: “Ọgbà kan tó fẹ̀ dáadáa, tí kò sóhun tó lè pani lára níbẹ̀, tó rẹwà gan-an, tó sì ní àwọn igi ńláńlá tí ọ̀pọ̀ nínú rẹ̀ ń so èso. Àwọn odò tó mọ́ tó sì tutù minimini rọra ń ṣàn gba inú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ìgalà àtàwọn àgùntàn rọra ń jẹko lẹ́bàá odò náà.”—Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 2:15, 16.
5, 6. Báwo ni aráyé ṣe pàdánù Párádísè, àwọn ìbéèrè wo sì nìyẹn lè mú ká béèrè?
5 Irú Párádísè yẹn ni Ọlọ́run fi Ádámù àti Éfà sí, àmọ́ wọn ò pẹ́ níbẹ̀. Kí nìdí? Wọ́n ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, wọ́n sì pàdánù ojú rere rẹ̀. Bí wọ́n ṣe pàdánù Párádísè nìyẹn, tí wọ́n sì tún fi du àtọmọdọ́mọ wọn. (Jẹ́n. 3:23, 24) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí èèyàn kankan nínú ọgbà náà, ó jọ pé ọgbà náà wà títí dìgbà Ìkún Omi ọjọ́ Nóà.
6 Àwọn kan lè béèrè pé, ‘Ṣé á ṣeé ṣe fún ẹnikẹ́ni láti gbé inú Párádísè?’ Kí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ? Tó o bá ń retí àtigbé nínú Párádísè pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ, kí lá jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé á ṣeé ṣe? Ṣé o lè ṣàlàyé ìdí tó fi dá ẹ lójú pé ayé yìí ṣì máa di Párádísè?
ÀWỌN OHUN TÓ JẸ́ KÁ MỌ̀ PÉ AYÉ YÌÍ MÁA DI PÁRÁDÍSÈ
7, 8. (a) Ìlérí wo ni Ọlọ́run ṣe fún Ábúráhámù? (b) Ibo ni Ábúráhámù fọkàn sí pé a ti máa gbádùn ìbùkún tí Ọlọ́run ṣèlérí?
7 Inú ìwé tí Ọlọ́run mí sí la ti lè rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yẹn, ó ṣe tán, òun ni Ẹlẹ́dàá tó ṣètò Párádísè àkọ́kọ́. Nígbà tí Ọlọ́run ń bá Ábúráhámù tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó sọ fún un pé òun máa sọ àtọmọdọ́mọ rẹ̀ di púpọ̀ bí “àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà ní etíkun.” Jèhófà tún ṣèlérí fún un pé: ‘Nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn nítorí òtítọ́ náà pé ìwọ ti fetí sí ohùn mi.’ (Jẹ́n. 22:17, 18) Ìlérí yìí kan náà ló tún ṣe fún ọmọ Ábúráhámù àti ọmọ ọmọ rẹ̀.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 26:4; 28:14.
8 Kò síbì kankan nínú Bíbélì tí Ábúráhámù ti ronú pé ọ̀run làwa èèyàn ti máa gbádùn Párádísè. Torí náà, nígbà tí Ọlọ́run sọ pé “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé” máa gba ìbùkún, kò sí àní-àní pé orí ilẹ̀ ayé ni Ábúráhámù máa fọkàn sí. Torí pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló ṣèlérí náà, ó dájú pé ìgbà ọ̀tun máa dé fún “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé.” Ṣé àwọn míì wà nínú Bíbélì tó gbà pé orí ilẹ̀ ayé ni Párádísè máa wà?
9, 10. Àwọn ìlérí míì wo ló mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé ayé yìí máa di Párádísè?
9 Dáfídì tóun náà jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù sọ pé lọ́jọ́ iwájú, kò ní sí “àwọn aṣebi” àti “àwọn tí ń ṣe àìṣòdodo” mọ́. Lédè míì, àwọn “ẹni burúkú ò ní sí mọ́.” (Sm. 37:1, 2, 10) Dípò bẹ́ẹ̀, “àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” Ọlọ́run tún mú kí Dáfídì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sm. 37:11, 29; 2 Sám. 23:2) Báwo làwọn ìlérí yìí ṣe rí lára àwọn tó fẹ́ ṣèfẹ́ Ọlọ́run? Àwọn ìlérí yẹn jẹ́ kó túbọ̀ dá wọn lójú pé táwọn olódodo nìkan bá ń gbé láyé, ayé máa pa dà di Párádísè bíi ti ọgbà Édẹ́nì.
10 Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kẹ̀yìn sí Jèhófà, wọn ò sì jọ́sìn rẹ̀ mọ́. Torí náà, Jèhófà gba àwọn ará Bábílónì láyè láti ṣẹ́gun wọn, wọ́n run ilẹ̀ wọn, wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ wọn lẹ́rú. (2 Kíró. 36:15-21; Jer. 4:22-27) Síbẹ̀, àwọn wòlíì Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé lẹ́yìn àádọ́rin (70) ọdún, àwọn èèyàn náà máa pa dà sí ilẹ̀ wọn. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ní ìmúṣẹ, wọ́n sì tún kan àwa náà lónìí. Bá a ṣe ń jíròrò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn, ẹ kíyè sóhun tó fi hàn pé ayé yìí ṣì máa di Párádísè.
11. Báwo lọ̀rọ̀ inú Aísáyà 11:6-9 ṣe nímùúṣẹ, àmọ́ ìbéèrè wo la lè béèrè?
11 Ka Aísáyà 11:6-9. Ọlọ́run ṣèlérí nípasẹ̀ wòlíì Aísáyà pé lẹ́yìn táwọn èèyàn Jèhófà bá pa dà sí ilẹ̀ wọn, kò ní sóhun táá pọ́n wọn lójú mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò ní máa bẹ̀rù àwọn ẹranko ẹhànnà àtàwọn èèyànkéèyàn. Tọmọdétàgbà ni ọkàn wọn máa balẹ̀. Ǹjẹ́ ìlérí yẹn ò rán wa létí bí nǹkan ṣe rí nínú ọgbà Édẹ́nì? (Aísá. 51:3) Àmọ́ ẹ kíyè sí i pé àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sọ pé gbogbo ilẹ̀ ayé ló máa kún fún “ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun” kì í ṣe orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nìkan. Ìgbà wo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí máa ṣẹ?
12. (a) Àwọn ìbùkún wo làwọn tó dé láti ìgbèkùn Bábílónì gbádùn? (b) Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé Aísáyà 35:5-10 ṣì máa nímùúṣẹ lọ́jọ́ iwájú?
12 Ka Aísáyà 35:5-10. Aísáyà tún tẹnu mọ́ ọn pé àwọn ẹranko ẹhànnà àtàwọn èèyànkéèyàn kò ní da àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ti ìgbèkùn dé láàmú. Bákan náà, ilẹ̀ wọn máa so èso wọ̀ǹtìwọnti, torí pé àwọn igi á máa rómi tó pọ̀ fà mu bó ṣe rí nínú ọgbà Édẹ́nì. (Jẹ́n. 2:10-14; Jer. 31:12) Àmọ́, ṣé ìyẹn nìkan ni ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn? Rárá o. Kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn tó ti ìgbèkùn dé rí ìwòsàn gbà lọ́nà ìyanu. Bí àpẹẹrẹ, kò sí ẹ̀rí pé ojú àwọn afọ́jú là. Torí náà, ó ṣe kedere pé lọ́jọ́ iwájú Ọlọ́run ṣì máa wo àwọn èèyàn sàn bó ṣe wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn.
13, 14. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà 65:21-23 ṣe nímùúṣẹ nígbà táwọn Júù ti ìgbèkùn dé? Apá wo nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà ni kò tíì nímùúṣẹ? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
13 Ka Aísáyà 65:21-23. Kì í ṣe inú ilé tó tuni lára làwọn Júù yẹn pa dà sí, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò bá ilẹ̀ tó kún fún ọgbà àjàrà tàbí àwọn igi tó ń so èso wọ̀ǹtìwọnti. Àmọ́ nǹkan yí pa dà torí pé Ọlọ́run bù kún wọn. Ẹ wo bí inú wọn ṣe dùn tó nígbà tí wọ́n kọ́lé tí wọ́n sì gbénú wọn! Bákan náà, wọ́n gbin onírúurú igi, wọ́n sì jẹ èso wọn.
14 Ẹ kíyè sí kókó pàtàkì kan nínú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn. Ṣé ìgbà kan ń bọ̀ tí ọjọ́ wa máa gùn “bí ọjọ́ igi”? Àwọn igi kan máa ń lo ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún láyé, àmọ́ kí ẹ̀mí àwa èèyàn tó lè gùn tóyẹn, ìlera wa gbọ́dọ̀ jí pépé. Tí nǹkan bá yí pa dà, tí ayé sì rí bí Aísáyà ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ó dájú pé ayé máa dùn, á sì di Párádísè. Ìgbà yẹn ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí á tó nímùúṣẹ ní kíkún.
15. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìbùkún tí Aísáyà sọ pé a máa gbádùn?
15 Ronú nípa báwọn ìlérí tá a jíròrò tán yìí ṣe mú kó dá wa lójú pé ayé máa di Párádísè lọ́jọ́ iwájú. Kò ní sí ẹranko tàbí èèyàn táá máa hùwà ẹhànnà. Ojú afọ́jú á là, adití á gbọ́ràn, àwọn arọ á sì máa rìn. Àwọn èèyàn á kọ́lé tí wọ́n á máa gbé, wọ́n á sì gbádùn àwọn igi eléso tí wọ́n bá gbìn. Ẹ̀mí wọn á gùn ju ti igi lọ. Ó ṣe kedere pé ìbùkún ọjọ́ iwájú làwọn ìlérí yìí ń tọ́ka sí. Síbẹ̀, àwọn kan lè sọ pé àsọdùn wà nínú ọ̀rọ̀ yìí, pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ọjọ́ iwájú. Kí ni wàá sọ fún àwọn tó bá sọ bẹ́ẹ̀? Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé láìsí tàbí-ṣùgbọ́n ayé yìí máa di Párádísè? Ọ̀rọ̀ tí Jésù Kristi sọ ló mú kó túbọ̀ dá wa lójú.
ÌWỌ YÓÒ WÀ NÍ PÁRÁDÍSÈ!
16, 17. Ìgbà wo ni Jésù sọ̀rọ̀ nípa Párádísè?
16 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ò ṣẹ̀, wọ́n dájọ́ ikú fún un, wọ́n sì kàn án mọ́gi. Wọ́n kan àwọn ọ̀daràn Júù méjì sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ méjèèjì. Kí wọ́n tó kú, ọ̀kan nínú wọn gbà pé ọba ni Jésù, ó wá bẹ Jésù pé: “Jésù, rántí mi nígbà tí o bá dé inú Ìjọba rẹ.” (Lúùkù 23:39-42) Ìdáhùn tí Jésù fún un nínú Lúùkù 23:43 kan ọjọ́ iwájú wa. Ọ̀nà táwọn ọ̀mọ̀wé kan gbà tú ìdáhùn Jésù ni pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ, lónìí ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó lo ọ̀rọ̀ náà “lónìí”? Èrò táwọn èèyàn ní nípa rẹ̀ yàtọ̀ síra.
17 Láti mú kí ọ̀rọ̀ yéni, wọ́n sábà máa ń lo àmì ìdánudúró nínú ọ̀pọ̀ èdè tí wọ́n fi ń kọ̀wé lóde òní, àmọ́ ní èdè Gíríìkì tí wọ́n fi kọ Bíbélì, kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀. Ìyẹn wá mú kéèyàn béèrè pé: Ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé, “Mo sọ fún ọ, lónìí ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè”? Àbí ohun tó ń sọ ni pé, “Mo sọ fún ọ lónìí, ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè”? Ohun táwọn atúmọ̀ èdè bá rò ló máa pinnu ibi tí wọ́n máa fi àmì ìdánudúró sí, téèyàn bá sì wo àwọn Bíbélì òde òní, á rí ìtumọ̀ méjèèjì.
18, 19. Kí ló jẹ́ ká lóye ohun tí Jésù ní lọ́kàn?
18 Àmọ́, ẹ má gbàgbé pé kí Jésù tó kú ló ti sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ọmọ ènìyàn yóò wà ní àárín ilẹ̀ ayé fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta.” Ó tún sọ pé: “Ọmọ ènìyàn ni a ti yàn tẹ́lẹ̀ pé a ó fi lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́, wọn yóò sì pa á, a ó sì gbé e dìde ní ọjọ́ kẹta.” (Mát. 12:40; 16:21; 17:22, 23; Máàkù 10:34) Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé bọ́rọ̀ ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn. (Ìṣe 10:39, 40) Torí náà, Jésù ò lọ sí Párádísè kankan lọ́jọ́ tí òun àti ọ̀daràn yẹn kú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Bíbélì sọ ni pé Jésù wà nínú “Hédíìsì [tàbí Isà Òkú]” fún ọjọ́ mélòó kan títí dìgbà tí Ọlọ́run jí i dìde.—Ìṣe 2:31, 32.a
19 Ẹ kíyè sí i pé gbólóhùn náà, “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí” ni Jésù fi bẹ̀rẹ̀ ìlérí tó ṣe fún ọ̀daràn náà. Kódà nígbà tí Mósè wà láyé, àwọn èèyàn máa ń lo gbólóhùn yìí gan-an. Bí àpẹẹrẹ, Mósè sọ pé: “Kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sì wà ní ọkàn-àyà rẹ.”—Diu. 6:6; 7:11; 8:1, 19; 30:15.
20. Ẹ̀rí wo ló tún jẹ́ ká mọ̀ pé èrò tó tọ́ la ní nípa ohun tí Jésù sọ?
20 Ọkùnrin kan tó wá láti Middle East tó sì jẹ́ atúmọ̀ Bíbélì sọ nípa ìdáhùn Jésù pé: “Ọ̀rọ̀ pàtàkì tó wà nínú ohun tí Jésù sọ ni ‘lónìí,’ torí náà ohun tó yẹ kó jẹ́ ni, ‘Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.’ Ọjọ́ yẹn ni Jésù ṣèlérí náà, ó sì máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú. Báwọn èèyàn tó wà lágbègbè yẹn ṣe máa ń sọ̀rọ̀ nìyẹn, ohun tó sì ní lọ́kàn ni pé ìlérí tó ṣe ní ọjọ́ yẹn máa ṣẹ láìkùnà.” Bákan náà, bí wọ́n ṣe tú ọ̀rọ̀ Jésù yẹn nínú Bíbélì èdè Syriac tí wọ́n ṣe ní ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún ni pé: “Àmín, mo sọ fún ọ lónìí, pẹ̀lú mi ni ìwọ yóò wà nínú Ọgbà Édẹ́nì.” Ṣe ló yẹ kí ìlérí tí Jésù ṣe yìí fi gbogbo wa lọ́kàn balẹ̀ gan-an.
21. Kí ni kò ṣẹlẹ̀ sí ọ̀daràn yẹn, kí sì nìdí?
21 Ó dájú pé ọ̀daràn yẹn ò mọ̀ pé Jésù ti bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olóòótọ́ dá májẹ̀mú pé wọ́n máa jọba pẹ̀lú òun ní ọ̀run. (Lúùkù 22:29) Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀daràn náà ò tíì ṣèrìbọmi. (Jòh. 3:3-6, 12) Torí náà, kò sí àní-àní pé Párádísè orí ilẹ̀ ayé ni Jésù ṣèlérí fún un. Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa ìran kan níbi tó ti rí ọkùnrin kan tí a ‘gbà lọ sínú párádísè.’ (2 Kọ́r. 12:1-4) Ìrètí tí ọ̀daràn yẹn ní yàtọ̀ sí ìrètí tí Pọ́ọ̀lù àtàwọn àpọ́sítélì olóòótọ́ yòókù ní torí pé Ọlọ́run yàn wọ́n láti bá Jésù jọba ní ọ̀run. Síbẹ̀ nínú ìran yẹn, Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí “párádísè” kan tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú.b Ṣé ayé yìí ni Párádísè náà máa wà? Ṣé ìwọ náà á sì wà níbẹ̀?
KÍ LÒ Ń FOJÚ SỌ́NÀ FÚN?
22, 23. Kí lò ń fojú sọ́nà fún?
22 Ká rántí pé Dáfídì sọ tẹ́lẹ̀ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí ‘àwọn olódodo máa ni ilẹ̀ ayé.’ (Sm. 37:29; 2 Pét. 3:13) Dáfídì ń tọ́ka sí ọjọ́ iwájú kan tí ìlànà Ọlọ́run á máa darí àwọn èèyàn tó ń gbé láyé. Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà 65:22 sọ pé: “Bí ọjọ́ igi ni ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí.” Èyí túmọ̀ sí pé àwọn èèyàn á gbé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún láyé. Ṣéyẹn sì máa ṣeé ṣe? Bẹ́ẹ̀ ni, torí pé Ìṣípayá 21:1-4 sọ pé Ọlọ́run máa yí àfiyèsí rẹ̀ sọ́mọ aráyé, á sì bù kún wọn. Kódà, ọ̀kan lára àwọn ìlérí náà ni pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó máa wà nínú ayé tuntun ò ní kú mọ́ láé.
23 Ọ̀rọ̀ yìí ti wá ṣe kedere. Ádámù àti Éfà pàdánù Párádísè nínú ọgbà Édẹ́nì, àmọ́ ìrètí ṣì wà. Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa bù kún aráyé lọ́jọ́ iwájú. Lábẹ́ ìmísí, Dáfídì sọ pé àwọn ọlọ́kàn tútù àtàwọn olódodo ló máa jogún ayé, wọ́n á sì gbé inú rẹ̀ títí láé. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Aísáyà fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé a ṣì máa gbádùn ara wa gan-an lọ́jọ́ iwájú. Ìgbà wo làwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀? Á ṣẹlẹ̀ nígbà tí ìlérí tí Jésù ṣe fún ọ̀daràn yẹn bá ṣẹ. Ìwọ náà lè wà nínú Párádísè yẹn. Nígbà yẹn, ọ̀rọ̀ ìdágbére táwọn tó lọ sí àpéjọ àgbègbè Kòríà sọ fún ara wọn á wá ṣẹ, pé: “Àá pàdé ní Párádísè!”
a Ọ̀jọ̀gbọ́n C. Marvin Pate sọ pé: “Àwọn ọ̀mọ̀wé Bíbélì kan gbà pé nígbà tí Jésù lo ọ̀rọ̀ náà, ‘lónìí,’ ohun tó ń sọ ni pé láàárín wákàtí mẹ́rìnlélógún (24) ọjọ́ yẹn, òun máa kú, òun á sì lọ sí Párádísè.” Ọ̀jọ̀gbọ́n yìí wá fi kún un pé, “Ìṣòro ibẹ̀ ni pé àlàyé yìí ta ko àwọn ẹsẹ Bíbélì míì. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé Jésù wà nínú Isà Òkú lẹ́yìn tó kú àti pé ẹ̀yìn-ọ̀-rẹyìn ló wá lọ sọ́run.”—Mát. 12:40; Ìṣe 2:31; Róòmù 10:7.
b Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.