ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 27
Ìsinsìnyí Gan-An Ni Kó O Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Múra Sílẹ̀ fún Inúnibíni
“Gbogbo àwọn tó bá fẹ́ fi ayé wọn sin Ọlọ́run tọkàntọkàn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù ni wọ́n máa ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.”—2 TÍM. 3:12.
ORIN 129 A Ó Máa Fara Dà Á Nìṣó
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí nìdí tó fi yẹ ká múra sílẹ̀ de inúnibíni?
NÍ ALẸ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n máa pa Jésù Olúwa wa, ó sọ nínú àdúrà rẹ̀ pé àwọn èèyàn máa kórìíra àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun. (Jòh. 17:14) Àtìgbà yẹn làwọn tó kórìíra ìjọsìn tòótọ́ ti ń ṣe inúnibíni sáwa ìránṣẹ́ Jèhófà, wọn ò sì jáwọ́ títí di àsìkò wa yìí. (2 Tím. 3:12) Torí náà, bí òpin ayé búburú yìí ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé bẹ́ẹ̀ làwọn ọ̀tá wa á túbọ̀ máa koná mọ́ àtakò tí wọ́n ń ṣe sí wa.—Mát. 24:9.
2-3. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa bẹ̀rù? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Kí la lè ṣe láti múra sílẹ̀ de inúnibíni? Kò ní bọ́gbọ́n mu pé ká máa ronú nípa onírúurú ọ̀nà tí wọ́n lè gbà ṣe inúnibíni sí wa. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀rù á máa bà wá, àá sì máa ṣàníyàn. Àmọ́ kò yẹ ká kú sílẹ̀ de ikú báwọn èèyàn ṣe máa ń sọ. (Òwe 12:25; 17:22) Ìbẹ̀rù wà lára àwọn ohun ìjà tí ‘Èṣù tó jẹ́ ọ̀tá wa’ máa ń lò láti bá wa jà. (1 Pét. 5:8, 9) Torí náà, àwọn nǹkan wo la lè ṣe láti múra sílẹ̀ kó má bàa borí wa?
3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bá a ṣe lè mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára àti ìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí. A tún máa jíròrò àwọn nǹkan tá a lè ṣe ká lè túbọ̀ nígboyà. Lẹ́yìn náà, àá sọ ohun tá a lè ṣe táwọn èèyàn bá kórìíra wa.
BÓ O ṢE LÈ MÚ KÍ ÀJỌṢE RẸ PẸ̀LÚ JÈHÓFÀ TÚBỌ̀ LÁGBÁRA
4. Bó ṣe wà nínú Hébérù 13:5, 6, kí ló yẹ kó dá wa lójú, kí sì nìdí?
4 Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ, kò sì ní fi ẹ́ sílẹ̀ láé. (Ka Hébérù 13:5, 6.) Lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn, Ilé Ìṣọ́ kan sọ pé: “Téèyàn bá mọ Ọlọ́run dáadáa, á gbọ́kàn lé e pátápátá nígbà àdánwò.” Òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yẹn! Ká tó lè fara da àtakò láìbọ́hùn, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ká gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá, ká má sì ṣiyèméjì pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.—Mát. 22:36-38; Jém. 5:11.
5. Kí lá jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ?
5 Máa ka Bíbélì lójoojúmọ́ lọ́nà táá mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. (Jém. 4:8) Bó o ṣe ń kà á, máa ronú nípa àwọn ànímọ́ rere tí Jèhófà ní. Máa kíyè sí bí àwọn ohun tó sọ àtàwọn nǹkan tó ṣe ṣe fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa àti pé ó mọyì wa. (Ẹ́kís. 34:6) Kò rọrùn fún àwọn kan láti gbà pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wọn torí pé kò sẹ́ni tó fìfẹ́ hàn sí wọn rí. Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ tìẹ náà rí, gbìyànjú kó o fi àbá yìí sílò: Lójoojúmọ́, máa ṣàkọsílẹ̀ àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ṣe fún ẹ àti bó ṣe fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ. (Sm. 78:38, 39; Róòmù 8:32) Bó o ṣe ń kíyè sáwọn nǹkan rere tí Jèhófà ń ṣe fún ẹ, tó o sì ń ronú lórí àwọn nǹkan tó ò ń kà nínú Bíbélì, wàá rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ti ṣe fún ẹ. Bó o ṣe túbọ̀ ń mọyì ohun tí Jèhófà ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni àjọṣe tó wà láàárín yín á máa lágbára sí i.—Sm. 116:1, 2.
6. Bó ṣe wà nínú Sáàmù 94:17-19, báwo ni àdúrà ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?
6 Máa gbàdúrà déédéé. Fojú inú wo ọmọkùnrin kan tí bàbá ẹ̀ gbé mọ́ra. Ọkàn ọmọ náà balẹ̀ débi pé gbogbo ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀ ló sọ fún bàbá rẹ̀, ó sọ àwọn nǹkan dáadáa tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn àtèyí tó kù díẹ̀ káàtó. Ìwọ náà lè gbádùn irú àjọṣe tímọ́tímọ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà Baba rẹ ọ̀run tó o bá ń gbàdúrà àtọkànwá sí i lójoojúmọ́. (Ka Sáàmù 94:17-19.) Bó o ṣe ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nínú àdúrà, máa “tú ọkàn rẹ jáde bí omi,” kó o sì jẹ́ kó mọ gbogbo ohun tó ń kó ẹ lọ́kàn sókè àtohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù. (Ìdárò 2:19) Kí ni Jèhófà máa ṣe fún ẹ? Wàá ní ohun tí Bíbélì pè ní “àlàáfíà Ọlọ́run tó kọjá gbogbo òye.” (Fílí. 4:6, 7) Bó o ṣe túbọ̀ ń gbàdúrà lọ́nà yìí, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà.—Róòmù 8:38, 39.
7. Kí nìdí tó fi yẹ kó dá ẹ lójú pé Ìjọba Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí Ọlọ́run ṣẹ?
7 Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ìjọba Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí Ọlọ́run ṣẹ. (Nọ́ń. 23:19) Tó o bá ń ṣiyèméjì pé bóyá làwọn ìlérí yẹn máa ṣẹ, wẹ́rẹ́ ni Sátánì àtàwọn ìsọ̀ǹgbè rẹ̀ máa rí ẹ mú. (Òwe 24:10; Héb. 2:15) Kí lo lè ṣe táá jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé àwọn ìlérí Ọlọ́run máa ṣẹ? Àbá kan rèé: Walẹ̀ jìn nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kó o lè mọ àwọn ohun tí Jèhófà máa ṣe nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ àti ìdí tó fi yẹ kó dá ẹ lójú pé á mú àwọn ìlérí náà ṣẹ. Báwo nìyẹn ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́? Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arákùnrin Stanley Jones tó lo ọdún méje lẹ́wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀.b Kí ló jẹ́ kó lè fara dà á láìbọ́hùn? Ó sọ pé: “Ìgbàgbọ́ mi lágbára gan-an torí mo mọ ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ àtohun tó máa ṣe, mi ò sì ṣiyèméjì nípa ẹ̀ rárá. Ìyẹn ni ò jẹ́ kí n bọ́hùn.” Tó bá dá ẹ lójú pé àwọn ìlérí Ọlọ́run máa ṣẹ láìsí tàbí ṣùgbọ́n, wàá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, kò sì sóhun tó máa dẹ́rù bà ẹ́ débi tí wàá fi bọ́hùn.—Òwe 3:25, 26.
8. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa pésẹ̀ sípàdé? Ṣàlàyé.
8 Máa lọ sípàdé déédéé. Àwọn ìpàdé wa máa ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ọwọ́ tá a bá fi mú ìpàdé máa fi hàn bóyá àá lè fara da inúnibíni lọ́jọ́ iwájú. (Héb. 10:24, 25) Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Tí àwọn nǹkan kéékèèké bá ń dí wa lọ́wọ́ àtimáa lọ sípàdé báyìí, kí ló máa ṣẹlẹ̀ tó bá di pé ká fẹ̀mí ara wa wewu ká lè wà pẹ̀lú àwọn ará wa lásìkò tí nǹkan bá ṣòro gan-an? Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, tá a bá pinnu pé a ò ní jẹ́ kí ohunkóhun dí wa lọ́wọ́ àtimáa pésẹ̀ sípàdé, ó dájú pé kò sóhun táwọn alátakò lè ṣe lọ́jọ́ iwájú táá mú ká pa ìpàdé tì. Àkókò yìí gan-an ló yẹ ká túbọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìpàdé wa. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ohun yòówù káwọn alátakò ṣe, kódà kí ìjọba fòfin de iṣẹ́ wa, a ò ní dẹwọ́ àtimáa ṣègbọràn sí Ọlọ́run dípò èèyàn.—Ìṣe 5:29.
9. Tó o bá há àwọn ẹsẹ Bíbélì kan sórí, báwo nìyẹn ṣe lè jẹ́ kó o múra sílẹ̀ fún inúnibíni?
9 Há àwọn ẹsẹ Bíbélì tó o fẹ́ràn jù sórí. (Mát. 13:52) O lè má rántí gbogbo ẹ̀, àmọ́ Jèhófà lè fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ kó o lè rántí àwọn ẹsẹ Bíbélì náà lásìkò tó o nílò rẹ̀. (Jòh. 14:26) Arákùnrin kan tí wọ́n fi sínú àhámọ́ ní East Germany sọ pé: “Inú mi dùn gan-an pé nígbà yẹn, mo ti mọ ohun tó lé ní ọgọ́rùn-rún méjì ẹsẹ Ìwé Mímọ́ sórí! Ìyẹn jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti ṣàṣàrò lórí onírúurú ẹ̀kọ́ Bíbélì láwọn ọjọ́ tí mo fi dá wà yẹn.” Àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn jẹ́ kí arákùnrin náà túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, kó sì fara da inúnibíni náà láìbọ́hùn.
10. Kí nìdí tó fi yẹ ká há àwọn orin wa sórí?
10 Há àwọn orin ìyìn sórí, kó o sì máa kọ wọ́n déédéé. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Sílà wà lẹ́wọ̀n nílùú Fílípì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ àwọn orin ìyìn tí wọ́n mọ̀ lórí. (Ìṣe 16:25) Bákan náà, ìgbà kan wà tí ìjọba kó àwọn ará wa ní Soviet Union lọ sígbèkùn ní Siberia. Kí ló mú kí wọ́n lè fara dà á? Arábìnrin Mariya Fedun sọ ohun tí wọ́n ṣe, ó ní: “A kọ gbogbo orin tá a mọ̀, ìyẹn àwọn orin tó wà nínú ìwé orin wa.” Ó sọ pé àwọn orin yẹn fún àwọn níṣìírí gan-an, ó sì jẹ́ káwọn túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ṣé orí tìẹ náà máa ń wú tó o bá ń kọ àwọn orin ìyìn tó o fẹ́ràn jù? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, há àwọn orin náà sórí nísinsìnyí!—Wo àpótí náà “Jẹ́ Kí N Ní Ìgboyà.”
BÁ A ṢE LÈ TÚBỌ̀ NÍGBOYÀ
11-12. (a) Bó ṣe wà nínú 1 Sámúẹ́lì 17:37, 45-47, kí ló mú kí Dáfídì nígboyà? (b) Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la kọ́ látinú àpẹẹrẹ Dáfídì?
11 Kó o tó lè kojú inúnibíni láìbọ́hùn, o nílò ìgboyà. Tí ẹ̀rù bá ń bà ẹ́, kí lo lè ṣe? Kì í ṣe béèyàn ṣe tóbi tó, bó ṣe lágbára tó tàbí ẹ̀bùn àbínibí tó ní lá mú kó nígboyà. Rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Dáfídì kojú Gòláyátì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì ò ga tó Gòláyátì, kò lágbára, kódà kò ní idà lọ́wọ́. Síbẹ̀, ó nígboyà, ó sì kojú fìrìgbọ̀n náà láìbẹ̀rù.
12 Kí ló mú kí Dáfídì nígboyà? Ó dá a lójú pé Jèhófà wà pẹ̀lú òun. (Ka 1 Sámúẹ́lì 17:37, 45-47.) Dáfídì ò ronú nípa bí Gòláyátì ṣe tóbi ju òun lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ronú nípa bí Gòláyátì ṣe kéré ní ìfiwéra pẹ̀lú Jèhófà. Kí la rí kọ́ látinú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí? A máa nígboyà tó bá dá wa lójú pé Jèhófà wà pẹ̀lú wa àti pé àwọn alátakò wa ò ju bíńtín lọ ní ìfiwéra pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run Alágbára ńlá. (2 Kíró. 20:15; Sm. 16:8) Kí la lè ṣe ká lè túbọ̀ nígboyà nísinsìnyí kí inúnibíni tó dé?
13. Báwo la ṣe lè nígboyà? Ṣàlàyé.
13 A lè túbọ̀ nígboyà nísinsìnyí tá a bá ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Iṣẹ́ ìwàásù máa ń jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká má sì bẹ̀rù èèyàn. (Òwe 29:25) Bó ṣe jẹ́ pé àá túbọ̀ lágbára tá a bá ń ṣe eré ìmárale, bẹ́ẹ̀ náà làá túbọ̀ nígboyà tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé, níbi térò pọ̀ sí, lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà àti níbi táwọn èèyàn ti ń tajà. Tá a bá ń fìgboyà wàásù nísinsìnyí, ẹ̀rù ò ní bà wá láti wàásù nígbà tí wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ wa.—1 Tẹs. 2:1, 2.
14-15. Kí la rí kọ́ lára Nancy Yuen àti Valentina Garnovskaya?
14 A lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn arábìnrin méjì tí wọ́n lo ìgboyà nígbà tí wọ́n ṣe inúnibíni sí wọn. Bí àpẹẹrẹ, Arábìnrin Nancy Yuen ò ga ju ẹsẹ̀ bàtà márùn-ún lọ (1.5 m), síbẹ̀ kì í bẹ̀rù.c Nígbà táwọn alátakò halẹ̀ mọ́ ọn pé kò gbọ́dọ̀ wàásù mọ́, ó kọ̀ jálẹ̀, ó sì ń wàásù nìṣó. Torí náà, wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n fún nǹkan bí ogún (20) ọdún lọ́gbà ẹ̀wọ̀n àwọn Kọ́múníìsì ní orílẹ̀-èdè Ṣáínà. Àwọn ọlọ́pàá tó fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò sọ pé “òun ló lágídí jù” lórílẹ̀-èdè wọn.
15 Bákan náà, ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ju Arábìnrin Valentina Garnovskaya sẹ́wọ̀n ní Soviet Union, ó sì lo ọdún mọ́kànlélógún (21) lẹ́wọ̀n.d Kí nìdí? Ìdí ni pé arábìnrin yìí ò dẹ́kun àtimáa wàásù débi táwọn ọlọ́pàá fi pè é ní “ọ̀daràn tó burú gan-an.” Kí ló mú káwọn arábìnrin méjì yìí nígboyà tó bẹ́ẹ̀? Ó dá wọn lójú pé Jèhófà wà pẹ̀lú wọn.
16. Kí ló máa jẹ́ ká nígboyà?
16 Bá a ṣe sọ, kì í ṣe agbára wa tàbí ẹ̀bùn àbínibí tá a ní ló ń jẹ́ ká nígboyà. Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ gbà pé Jèhófà wà pẹ̀lú wa àti pé òun ló ń jà fún wa. (Diu. 1:29, 30; Sek. 4:6) Ohun tó máa jẹ́ ká nígboyà nìyẹn.
OHUN TÁ A LÈ ṢE TÁWỌN ÈÈYÀN BÁ KÓRÌÍRA WA
17-18. Ìkìlọ̀ wo ni Jésù fún wa nínú Jòhánù 15:18-21? Ṣàlàyé.
17 Inú wa máa ń dùn táwọn míì bá bọ̀wọ̀ fún wa, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ wa. Àmọ́ kì í ṣe báwọn èèyàn ṣe gba tiwa tó ló ń pinnu bá a ṣe níyì tó. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni yín nígbàkigbà tí àwọn èèyàn bá kórìíra yín àti nígbàkigbà tí wọ́n bá ta yín nù, tí wọ́n pẹ̀gàn yín, tí wọ́n sì fẹ̀sùn kàn yín pé ẹni burúkú ni yín nítorí Ọmọ èèyàn.” (Lúùkù 6:22) Kí nìdí tí Jésù fi sọ bẹ́ẹ̀?
18 Jésù ò sọ pé inú àwa Kristẹni máa ń dùn táwọn èèyàn bá kórìíra wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń kìlọ̀ fún wa. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé ayé máa kórìíra wa torí pé a kì í ṣe apá kan ayé. Yàtọ̀ síyẹn, à ń wàásù ìhìn rere kan náà tí Jésù wàásù, ìlànà tó sì fi kọ́ni là ń tẹ̀ lé. (Ka Jòhánù 15:18-21.) A fẹ́ múnú Jèhófà dùn, táwọn èèyàn bá wá tìtorí ìyẹn kórìíra wa, wàhálà tiwọn nìyẹn.
19. Báwo la ṣe lè fara wé àwọn àpọ́sítélì?
19 Má ṣe jẹ́ kí ohun táwọn èèyàn ń sọ tàbí tí wọ́n ń ṣe mú kójú tì ẹ́ láti sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́. (Míkà 4:5) A lè borí ìbẹ̀rù èèyàn tá a bá ronú nípa ohun táwọn àpọ́sítélì ṣe ní Jerúsálẹ́mù lẹ́yìn táwọn alátakò pa Jésù. Wọ́n mọ̀ pé àwọn aṣáájú ìsìn Júù kórìíra àwọn. (Ìṣe 5:17, 18, 27, 28) Láìfi ìyẹn pè, ojoojúmọ́ ni wọ́n ń lọ sí tẹ́ńpìlì àtàwọn ibi térò pọ̀ sí, wọ́n ń wàásù, wọ́n sì ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ọmọlẹ́yìn Jésù làwọn. (Ìṣe 5:42) Wọn ò jẹ́ kẹ́rù bà wọ́n débi tí wọ́n á fi dáwọ́ iṣẹ́ náà dúró. Àwa náà lè borí ìbẹ̀rù èèyàn tá a bá ń wàásù, tá a sì ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, yálà ní ibiṣẹ́, níléèwé tàbí ládùúgbò wa.—Ìṣe 4:29; Róòmù 1:16.
20. Kí nìdí tínú àwọn àpọ́sítélì fi ń dùn?
20 Kí nìdí tí inú àwọn àpọ́sítélì fi ń dùn? Inú wọn ń dùn torí wọ́n mọ ìdí táwọn èèyàn fi kórìíra wọn, wọ́n sì ń yọ̀ nítorí a ti kà wọ́n yẹ láti jìyà nítorí orúkọ Jésù. (Lúùkù 6:23; Ìṣe 5:41) Nígbà tó yá, àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Tí ẹ bá tiẹ̀ jìyà nítorí òdodo, inú yín máa dùn.” (1 Pét. 2:19-21; 3:14) Tá a bá ń fi sọ́kàn pé torí à ń ṣe ohun tó tọ́ làwọn èèyàn fi kórìíra wa, a ò ní fi Jèhófà sílẹ̀ láé.
Á DÁA KÓ O MÚRA SÍLẸ̀ NÍSINSÌNYÍ
21-22. (a) Kí lo pinnu láti ṣe kó o lè múra sílẹ̀ fún inúnibíni? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
21 Ìgbàkigbà ni inúnibíni lè bẹ̀rẹ̀, a ò sì mọ̀gbà tí ìjọba máa fòfin de iṣẹ́ wa. Síbẹ̀, a mọ̀ pé a lè múra sílẹ̀ nísinsìnyí tá a bá mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára, tá a túbọ̀ nígboyà, tá a sì mọ ohun tó yẹ ká ṣe táwọn èèyàn bá kórìíra wa. Tá a bá múra sílẹ̀ nísinsìnyí, àá lè dúró gbọin-in nígbà tí àtakò bá dé lọ́jọ́ iwájú.
22 Tí ìjọba bá fòfin de iṣẹ́ wa ńkọ́? Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò àwọn ìlànà tó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa sin Jèhófà nìṣó tí wọ́n bá tiẹ̀ fòfin de iṣẹ́ wa.
ORIN 118 “Fún Wa Ní Ìgbàgbọ́ Sí I”
a Kò sẹ́ni tó fẹ́ káwọn èèyàn kórìíra òun. Àmọ́ bó pẹ́ bó yá gbogbo wa pátá la máa kojú inúnibíni. Torí náà, àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí bá a ṣe lè múra sílẹ̀ ká sì fìgboyà kojú àtakò.
b Wo Ile-Iṣọ Na, April 1, 1967, ojú ìwé 118 sí 127.
c Wo Ile-Iṣọ Naa, January 15, 1980, ojú ìwé 4 sí 7. Tún wo fídíò náà Orúkọ Jèhófà Máa Di Mímọ̀ lórí JW Broadcasting® ìyẹn Tẹlifíṣọ̀n JW. Wo abẹ́ ÌFỌ̀RỌ̀WÁNILẸ́NUWÒ ÀTI ÌRÍRÍ.
d Wo Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ọdún 2008 lédè Gẹ̀ẹ́sì, ojú ìwé 191 àti 192.
e ÀWÒRÁN: Nígbà ìjọsìn ìdílé, àwọn òbí kan lo àwọn káàdì tí wọ́n kọ̀rọ̀ sí káwọn ọmọ wọn lè há àwọn ẹsẹ Bíbélì kan sórí.
f ÀWÒRÁN: Ìdílé kan ń kọ àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run nínú mọ́tò bí wọ́n ṣe ń lọ sípàdé.