Ìpè Tí Ń runi Sókè Dún Jáde Ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè!—Ẹ Fi Ìdùnnú-Ayọ̀ Yin Jehofa Láti Ọjọ́ dé Ọjọ́!
1 Aposteli Paulu béèrè pé: “Bí kàkàkí bá mú ìpè kan tí kò dún ketekete jáde, ta ni yoo gbaradì fún ìjà ogun?” (1 Kor. 14:8) Ìpè tí ó dún jáde ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn” ha ròkè ketekete bí? Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣe bẹ́ẹ̀. ‘Ẹ yin Jehofa tìdùnnútìdùnnú lójoojúmọ́’ ni ìhìn iṣẹ́ tí ń runi sókè náà! Ìpè yìí ha ru ọkàn rẹ sókè sí iṣẹ́ bí? Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ náà kún fún àwọn ìdí pàtàkì tí ó fi yẹ kí á máa yin Ọba ayérayé, Jehofa, déédéé.—Orin Da. 35:27, 28.
2 Àwọn ọ̀run gígadabú ń polongo ògo Jehofa “láti ọjọ́ dé ọjọ́.” (Orin Da. 19:1-3) Bí àwọn ẹ̀dá aláìlèsọ̀rọ̀, aláìlẹ́mìí bá ń fi ìyìn fún Jehofa déédéé, kò ha yẹ kí á sún àwa ẹ̀dá ènìyàn olóye láti gbé ohùn wa sókè láti yìn ín nígbà gbogbo fún àwọn ànímọ́ àti àṣeyọrí rẹ̀ tí kò láfiwé bí? Ta ni ó tún yẹ fún ìyìn onídùnnú-ayọ̀ wa ju atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa lọ?—Orin Da. 145:3, 7.
3 Láti Ọjọ́ dé Ọjọ́: Onípsalmu tí a mí sí kọ̀wé pé: “Ẹ máa fi ìgbàlà rẹ̀ hàn láti ọjọ́ dé ọjọ́. Nítorí tí Olúwa tóbi, ó sì ní ìyìn púpọ̀púpọ̀.” (Orin Da. 96:2, 4) Àwọn aṣáájú ọ̀nà nìkan ṣoṣo ha ni èyí kàn bí? Bẹ́ẹ̀ kọ́! Èyí ha túmọ̀ sí pé gbogbo wá ní láti sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa Jehofa nígbàkigbà àti níbikíbi tí a bá ti lè ṣe é, àní ní àwọn ọjọ́ tí a kò lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé pàápàá bí? Bẹ́ẹ̀ ni! Àìní láti yin Jehofa lójoojúmọ́, kí a sì sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa ìpèsè rẹ̀ fún ìgbàlà jẹ́ kánjúkánjú. Àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ mọ̀ pé Jehofa ní Ọba Ayérayé àti pé Òún tí fi ìṣàkóso ayé lé Ọmọkùnrin Rẹ̀ tí a ṣe lógo, Jesu Kristi, lọ́wọ́. Ìfẹ́ fún Jehofa àti fún àwọn ènìyàn yóò mú kí á máa bá a lọ ní sísọ nípa ìhìn iṣẹ́ yìí àti nípa ìpèsè rẹ̀ fún ìgbàlà, níbikíbi tí a bá ti lè rí àwọn ènìyàn.—Orin Da. 71:15.
4 Ní gbogbo ọjọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, Jesu Kristi fi àpẹẹrẹ dídára jù lọ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́tìkọ̀ olùyin Jehofa. Ó sọ pé: “Mo yìn ọ́ ní gbangba, Baba, Oluwa ọ̀run ati ilẹ̀-ayé.” (Matt. 11:25) Ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Jesu yin Jehofa ní gbangba, níbikíbi tí ó bá wà. Níbikíbi tí àwọn èrò bá sì péjọ sí—yálà ní sinagọgu, ní tẹ́ḿpìlì ní Jerusalemu, lórí òkè, tàbí ní etíkun—ó yin Jehofa. Bí a bá tẹ̀ lé ipasẹ̀ Jesu pẹ́kípẹ́kí nípa bíbá ìgbòkègbodò ojoojúmọ́, tí ó ṣe déédéé nìṣó, nínú gbígbé Jehofa ga ní gbangba, a óò rí àbájáde aláyọ̀, tí ń dùn mọ́ni nínú.
5 Dídáhùn Ìpè Náà: Ìwọ yóò ha dáhùn ìpè náà láti yin Jehofa ní gbangba lójoojúmọ́ bí? Rántí pé, ọjọ́ orí kò dí ọ lọ́wọ́. Orin Dafidi 148:12 ké sí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin, wúndíá, arúgbó, àti ọmọdé láti yin Jehofa. Ẹ̀yin èwe, ẹ óò ha yin Jehofa láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ yín àti olùkọ́ láàárín ọdún ilé ẹ̀kọ́ yìí bí? Ẹ̀yin àgbà, àwọn tí ẹ ń bá ṣiṣẹ́ ní ibi iṣẹ́ yín ha ń gbọ́ nípa Jehofa àti àwọn ète rẹ̀, nígbà tí àkókò yíyẹ bá ṣí sílẹ̀ láti jùmọ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀ bí? Ó yẹ kí gbogbo wá sọ sísọ̀rọ̀ nípa Jehofa dí apá kan ìgbésí ayé wa gẹ́gẹ́ bí mímí èémí àti jíjẹ oúnjẹ ti jẹ́. Kódà bí àwọn ènìyàn tí ń dágunlá kò bá fetí sí ohun tí a ń sọ, Ẹnì kan wà tí ń ṣe bẹ́ẹ̀, òun yóò sì san ẹ̀san fún wa.—Mal. 3:16.
6 Bí òpin ètò nǹkan tí ń sún mọ́lé, ìpè náà ń jáde lọ sí òpin ilẹ̀ ayé pé: “Ẹ yin Jah, ẹ̀yin ènìyàn!” (Orin Da. 106:1, NW) Ǹjẹ́ kí igbe ìyìn wa túbọ̀ máa ròkè sí i bí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti ń kọjá, kí gbogbo ènìyàn lè mọ̀ pé Ẹnì kan ṣoṣo tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jehofa, ní Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ayé.—Orin Da. 83:18.