A Ha Ń Wà Lójúfò—Ní Yíyẹra fún Ìpínyà Ọkàn Bí?
1 Jesu kìlọ̀ pé: “Ẹ máa wà lójúfò, . . . kí ẹ lè kẹ́sẹjárí ní yíyèbọ́” nínú àwọn àjálù tí ó dájú pé yóò wáyé. (Luku 21:36) A ń gbé ní àkókò eléwu jù lọ nínú ìtàn ènìyàn. Ìjàm̀bá ń dúró de àwọn tí ń tòògbé nípa tẹ̀mí. Èyí gbé ewu kan dìde fún olúkúlùkù wa. Jesu mẹ́nu kan jíjẹ, mímu, àti àníyàn ìgbésí ayé ojoojúmọ́. Èé ṣe? Nítorí pé àwọn ohun wọ̀nyí pàápàá lè gbà wá lọ́kàn, wọ́n lè pín ọkàn wa níyà, kí wọ́n sì mú wa tòògbé nípa tẹ̀mí.
2 Àwọn Ìpínyà Ọkàn Tí Ó Wọ́pọ̀: Àwọn kan ti kó wọnú eré ìnàjú tí ó pàpọ̀jù tàbí tí ó gbé ìbéèrè dìde, ní dídi ẹni tí wíwo tẹlifíṣọ̀n ti di bárakú fún. Dájúdájú, wíwá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́ kò túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ yẹra fún gbogbo eré ìnàjú. Nígbà tí a bá lo ọgbọ́n, tí a sì ṣe é ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, eré ìnàjú lè ṣàǹfààní. (Fi wé 1 Timoteu 4:8.) Ṣùgbọ́n, ó ń pín ọkàn níyà nígbà tí ó bá di ohun bàbàrà nínú ìgbésí ayé wa, ní jíjẹ wá lákòókò, owó, tàbí ìpín wa nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà.
3 Ìfẹ́ fún àwọn ohun ti ara tí kò pọn dandan jẹ́ ohun mìíràn tí ń fa ìpínyà ọkàn tí ń múni tòògbé nípa tẹ̀mí. Èyí ń béèrè pé kí ènìyàn lo àkókò púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, ó sì ń fún ìlépa tẹ̀mí pa. Àwọn kan ti sọ àwọn góńgó tẹ̀mí nù, nípa dídi ẹni tí kíkó àwọn ohun ti ara jọ, láti baà lè gbádùn ìgbésí ayé yọ̀tọ̀mì, gbà lọ́kàn pátápátá. Nígbà tí a nílò “ohun ìgbẹ́mìíró ati ìbora,” a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún mímú ìfẹ́ owó dàgbà, èyí tí ó lè múni ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́. (1 Tim. 6:8-10) Nípa kíkùnà láti pa ojú wa mọ́ sórí àwọn ire Ìjọba, a lè jọ̀gọ̀ nù ní bíbójú tó àwọn àìní tẹ̀mí ìdílé wa, kí a sì kùnà láti ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.—1 Tim. 5:8; 2 Tim. 4:5.
4 Síbẹ̀, àwọn mìíràn ń fàyè gba ‘ọkàn-àyà wọn láti di èyí tí a dẹrùpa pẹlu awọn àníyàn ìgbésí-ayé’ débi pé wọ́n sùn lọ fọnfọn nípa tẹ̀mí. (Luku 21:34) Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a máa ń ṣàníyàn nítorí àwọn ìṣòro ìlera tàbí àwọn ipò másùnmáwo nínú ìdílé. Ṣùgbọ́n, a kò gbọdọ̀ yọ̀ọ̀da fún irú àwọn àníyàn ara ẹni bẹ́ẹ̀ láti dín ìwàlójúfò wa sí òpin ètò nǹkan ìsinsìnyí tí ń yára sún mọ́lé kù.—Marku 13:33.
5 Kò sí ohun tí yóò dùn mọ́ Eṣu nínú bíi pé kí ó ṣàṣeyọrí ní fífi wá sínú ipò lílálàá ọ̀sán gangan, ní lílépa àlá asán kan nínú ayé. A ní láti jìjàkadì láti wà lójúfò nípa tẹ̀mí. A mọ̀ pé ‘ọjọ́ Jehofa ń bọ̀ bí olè,’ ó sì ṣe pàtàkì pé kí a “wà lójúfò kí a sì pa agbára ìmòye wa mọ́.” (1 Tessa. 5:2, 6) Bí a bá kíyè sí i pé a ń tòògbé, ó ṣe kánjúkánjú pé kí a “bọ́ awọn iṣẹ́ tí ó jẹ́ ti òkùnkùn kúrò.”—Romu 13:11-13.
6 Àwọn Àrànṣe Láti Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Wà Lójúfò: Kí ni irú àwọn àrànṣe bẹ́ẹ̀? Àdúrà ṣe kókó. A ní láti máa gbàdúrà láìdabọ̀. (1 Tessa. 5:17) Sísún mọ́ ìjọ Kristian pẹ́kípẹ́kí yóò ‘ru wa lọ́kàn sókè sí ìfẹ́ ati sí awọn iṣẹ́ àtàtà.’ (Heb. 10:24) Yíyẹ ara wa wò déédéé, láìlábòsí, lè ṣèrànwọ́ láti mú wa wà lójúfò sí àwọn àìní wa láti ṣẹ́pá àwọn àìlera wa. (2 Kor. 13:5) Àṣà ìdákẹ́kọ̀ọ́ tí ó jíire yóò mú kí a máa “fi awọn ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ bọ́” wa nìṣó. (1 Tim. 4:6) Bí a bá jẹ́ aláápọn, a lè ní ìdánilójú pé yóò ṣeé ṣe fún wa láti yẹra fún ìpínyà ọkàn, kí a ‘wà lójúfò, kí a sì dúró gbọn-in-gbọn-in ninu ìgbàgbọ́.’—1 Kor. 16:13.