“Èyí Túmọ̀ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun”
1 A gbọ́dọ̀ fi ọwọ́ tí ó nípọn mú ọ̀rọ̀ Jésù tí a kọ sílẹ̀ nínú Jòhánù 17:3. Kò fi ohun tí ó sọ ṣeré rárá—gbígba ìmọ̀ Ọlọ́run àti Kristi sínú túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun! Ṣùgbọ́n, ṣe kìkì níní ìmọ̀ Jèhófà àti ti Jésù nìkan ni yóò mú wa gba èrè ìyè ayérayé? Rárá. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run wọn, ṣùgbọ́n ipa ọ̀nà ìgbésí ayé wọn kò fi ìgbàgbọ́ yẹn hàn. Nítorí èyí, wọ́n pàdánù ojú rere rẹ̀. (Hos. 4:1, 2, 6) Lónìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn lè “ní ìtara fún Ọlọ́run; ṣùgbọ́n kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye.” (Rom. 10:2) Wọ́n ní láti wá mọ Jèhófà, “Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà,” kí wọ́n sì kọ́ bí a ti ń ṣiṣẹ́ sìn ín lọ́nà títọ́. Nítorí èyí, ní November, a óò fi ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun lọni. Ọ̀nà ìyọsíni wo ni ìwọ yóò lò ní gbígbé ìwé Ìmọ̀ kalẹ̀? Àwọn ìdámọ̀ràn díẹ̀ nìyí, tí ó lè ṣàǹfààní fún ọ.
2 Níwọ̀n bí èrò gbígbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé ti jẹ́ ohun tuntun sí ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn, ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ yìí lè ru ìfẹ́ wọn sókè:
◼ “A ń béèrè ìbéèrè kan lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò wa. Bí a bá ké sí ọ láti gbé títí láé nínú ayé kan bí èyí, ìwọ yóò ha tẹ́wọ́ gba ìkésíni náà bí? [Fi àwòrán tí ó wà ní ojú ìwé 4 àti 5 nínú ìwé Ìmọ̀ hàn án. Jẹ́ kí ó fèsì.] O lè gbádùn irú ìgbésí ayé aláyọ̀ yìí, ní tòótọ́. Ṣùgbọ́n, kí ni o rò pé o ní láti ṣe láti jẹ́ kí èyí ní ìmúṣẹ sí ọ lára? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Kíyè sí ìgbésẹ̀ tí a béèrè fún, ní ìbámu pẹ̀lú Jòhánù 17:3. [Kà á.] Ìwé yìí ń ran ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́wọ́ láti jèrè irú ìmọ̀ àkànṣe yìí. O lè gba ẹ̀dà yìí ní ọrẹ ₦80. Nígbà ìbẹ̀wò mi tí yóò tẹ̀ lé e, a lè jíròrò ìdí tí ó fi bọ́gbọ́n mu láti gbà gbọ́ pé a lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun níhìn-ín gan-an lórí ilẹ̀ ayé.”
3 Nígbà tí o bá ṣèpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tí o jíròrò Jòhánù 17:3 pẹ̀lú, o lè tẹ̀ síwájú ní ọ̀nà yìí:
◼ “Nígbà ìbẹ̀wò mi tí ó kọjá, mo ka ọ̀rọ̀ Jésù fífani mọ́ra, tí a rí nínú Jòhánù 17:3 fún ọ, níbi tí ó ti fi dá wa lójú pé, gbígba ìmọ̀ Ọlọ́run àti ti òun sínú túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun. Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà gbọ́ pé, kìkì ọ̀run nìkan ni a ti lè gbádùn ìgbésí ayé sísàn jù. Kí ni èrò rẹ nípa èyí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bí ìwé tí o gbà lọ́wọ́ mi bá wà nítòsí, n óò fẹ́ láti fi àwọn ẹsẹ Bíbélì díẹ̀ hàn ọ́, tí ó fẹ̀rí hàn pé orí ilẹ̀ ayé ni a óò mú Párádísè padà bọ̀ sí. [Jíròrò ìpínrọ̀ 11 sí 16, ní ojú ìwé 9 àti 10, nínú ìwé Ìmọ̀.] Nígbà ìbẹ̀wò mi tí yóò tẹ̀ lé e, èmi yóò fẹ́ láti fi ìdí tí o lè fi gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìlérí wọ̀nyí, tí a rí nínú Bíbélì, hàn ọ́. Kí ó tó di ìgbà yẹn, bóyá o lè ka orí 2 nínú ẹ̀dà ìwé tìrẹ.”
4 Ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí o lè fẹ́ láti lò pẹ̀lú àwọn ènìyàn onísìn nìyí:
◼ “A ń bá àwọn aládùúgbò wa sọ̀rọ̀ lórí ìdí tí ọ̀pọ̀ onírúurú ìsìn fi wà láyé lónìí. Ẹ̀yà ìsìn tí ó wà kárí ayé lé ní 10,000. Síbẹ̀, ọ̀kan ṣoṣo ni Bíbélì. Ní èrò tìrẹ, kí ni ìdí tí ìdàrúdàpọ̀ yìí ní ti ìsìn fi wáyé? [Jẹ́ kí ó fèsì. Ṣí ìwé Ìmọ̀ sí orí 5, kí o sì ka ìpínrọ̀ 1.] Ìwọ yóò rí ìdáhùn tí ń tẹ́ni lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, nípa kíka orí yìí. Èmi yóò láyọ̀ láti fi ìwé náà sílẹ̀ fún ọ, fún ọrẹ ₦80, bí o bá bìkítà láti yẹ̀ ẹ́ wò.” Bí ó bá gbà á, ṣe ètò tí ó ṣe gúnmọ́ láti padà wá, kí o sì sọ pé: “Nígbà ti mo bá padà wá, bóyá a lè jíròrò lórí bóyá gbogbo ìsìn wulẹ̀ jẹ́ onírúurú ọ̀nà tí ń sinni lọ sí ibì kan náà ni.”
5 Nígbà tí o bá padà lọ láti tẹ̀ síwájú nínú ìjíròrò nípa ìdí tí ìsìn fi pọ̀ jáǹtìrẹrẹ, o lè sọ èyí:
◼ “Nígbà tí mo bá ọ sọ̀rọ̀ kẹ́yìn, mo gbé ìbéèrè náà dìde pé, bóyá àwọn ìsìn wulẹ̀ jẹ́ onírúurú ọ̀nà tí ń sinni lọ sí ibì kan náà ni. Kí ni èrò rẹ nípa èyí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Èmi yóò fẹ́ láti fi ohun tí Jésù sọ lórí ọ̀ràn yìí hàn ọ́, nínú ìwé tí mo fi sílẹ̀ fún ọ. [Ṣí ìwé Ìmọ̀ sí orí 5, kí o sì ka ìpínrọ̀ 6 àti 7, títí kan Mátíù 7:21-23.] O lè ṣe kàyéfì nípa ìdí tí ó fi ṣe pàtàkì láti mọ ohun tí ìfẹ́ inú Ọlọ́run jẹ́ gan-an. Ìwọ yóò rí i pé àwọn ìpínrọ̀ tí ó tẹ̀ lé e kún fún ìtọ́ni. Jọ̀wọ́, ka àwọn ìpínrọ̀ tí ó ṣẹ́ kù nínú orí yìí. Nígbà tí mo bá tún padà wá, inú mi yóò dùn láti fi ìníyelórí níní ìmọ̀ pípéye nípa Bíbélì hàn ọ́.”
6 Ọ̀nà ìyọsíni ṣíṣe tààràtà sábà máa ń yọrí sí rere nínú bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ kan tí a dábàá nìyí, tí ó fara hàn ní ojú ìwé 12, ìwé “Reasoning”:
◼ “Mo ń ṣe ìkésíni láti fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ lọ̀ ọ́. Bí o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, n óò fẹ́ láti lo ìṣẹ́jú díẹ̀ péré, láti ṣàṣefihàn bí àwọn ènìyàn ní orílẹ̀-èdè bíi 200, ṣe ń jíròrò Bíbélì nínú ilé wọn, gẹ́gẹ́ bí àwùjọ ìdílé. A lè lo èyíkéyìí nínú àwọn àkòrí wọ̀nyí láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò wa. [Fi kókó ẹ̀kọ́ inú ìwé, tí ó wà nínú ìwé Ìmọ̀ hàn án.] Èwo ni ó fà ọ́ lọ́kàn mọ́ra jù lọ?” Ní sùúrù fún un láti yan ọ̀kan. Ṣí i sí orí tí ó yàn, kí o sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ní ìpínrọ̀ àkọ́kọ́.
7 Ọ̀nà ìyọsíni ṣíṣe tààràtà míràn nìyí, tí ó ti yọrí sí rere, tí o lè gbìyànjú rẹ̀ wò fún bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́:
◼ “Mo máa ń kọ́ àwọn ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láìgba kọ́bọ̀, àyè sì wà fún mi láti fi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn kún un. Àrànṣe fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí ni a máa ń lò. [Fi ìwé Ìmọ̀ hàn án.] Kìkì oṣù mélòó kan ni ìkẹ́kọ̀ọ́ náà máa ń gbà, ó sì ń pèsè ìdáhùn sí irú àwọn ìbéèrè bí: Èé ṣe tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà? Èé ṣe tí a fi ń darúgbó tí a sì ń kú? Kí ní ń ṣẹ lẹ̀ sí àwọn olólùfẹ́ wa tí wọ́n ti kú? Àti báwo ni a ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run pẹ́kípẹ́kí?” Lẹ́yìn náà, béèrè pé, “Ṣe mo lè fi bí a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà hàn ọ́?” Bí kò bá gbà láti kẹ́kọ̀ọ́, fi ìwé Ìmọ̀ lọ̀ ọ́, ni iye tí a ń fi síta.
8 Ẹ wo bí ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run àti Kristi ti jẹ́ ìṣura oníyebíye tó fún àwọn tí ó ní in! Gbígbà á sínú túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun nínú ipò pípé pérépéré ní tòótọ́. Ẹ jẹ́ kí a lo gbogbo àǹfààní tí a ní ní November láti ṣàjọpín ìmọ̀ tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.