‘Ẹ Fi Ara Yín Hàn Ní Ẹni Tí Ó Kún fún Ọpẹ́’
1 Ọ̀pọ̀ jù lọ lára wa ni a kọ́ ní ìgbà kékeré láti sọ pé “ẹ jọ̀wọ́” àti “ẹ ṣeun” nígbà tí ẹnì kan bá fi ìwà ọ̀làwọ́ tàbí inú rere hàn sí wa. Pọ́ọ̀lù ṣí wa létí láti máa fìgbà gbogbo ‘fi ara wa hàn ní ẹni tí ó kún fún ọpẹ́,’ a sì gbọ́dọ̀ kún fún ìmoore sí Jèhófà ní pàtàkì. (Kól. 3:15, 16) Ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe lè fọpẹ́ fún Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa? Àwọn ìdí pàtàkì wo ni a sì ní láti kún fún ọpẹ́ sí Ọlọ́run?
2 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, nítorí ó ń fún wa ní ìjagunmólú nípasẹ̀ Olúwa wa Jésù Kristi!” (1 Kọ́r. 15:57) Ní àkókò Ìṣe Ìrántí lọ́dọọdún, a ń rán wa létí ìfẹ́ aláìláàlà tí Ọlọ́run àti Kristi fi hàn ní pípèsè ìràpadà tí ó fún wa ní ìrètí ìyè ayérayé. (Jòh. 3:16) Níwọ̀n bí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo wa ni ó ti pàdánù àwọn tí a nífẹ̀ẹ́ nínú ikú, ẹ wo bí a ti kún fún ọpẹ́ tó fún ìlérí Jésù nípa àjíǹde! Ọkàn àyà wa kún àkúnwọ́sílẹ̀ fún ìmoore nígbà tí a bá ronú nípa ìfojúsọ́nà líla òpin ètò ìgbékalẹ̀ búburú yìí já láìtilẹ̀ kú rárá. (Jòh. 11:25, 26) Ẹnu wa kò gba ọpẹ́ fún gbogbo àgbàyanu ìbùkún tí a óò ṣì gbádùn láti ọ̀dọ̀ Jèhófà nínú Párádísè ilẹ̀ ayé tí ń bọ̀. (Ìṣí. 21:4) Ìdí tí ó sàn jù wo ni ẹnì kan lè ní láti ‘fi ara rẹ̀ hàn ní ẹni tí ó kún fún ọpẹ́’ sí Ọlọ́run?
3 Bí A Ṣe Lè Fọpẹ́ fún Ọlọ́run: Ó máa ń fìgbà gbogbo bá a mu wẹ́kú láti fọpẹ́ wa hàn nínú àdúrà wa sí Jèhófà fún oore rẹ̀. (Orin Dá. 136:1-3) A tún ń sún wa láti fi ọpẹ́ wa hàn fún un ní àwọn ọ̀nà dídára mìíràn. Fún àpẹẹrẹ, ó dájú pé a óò wà níbẹ̀ ní ọjọ́ Sunday, March 23, fún Ìṣe Ìrántí ikú Kristi. Láti ṣèrànwọ́ nínú pípèsè fún àwọn àìní ohun ti ara ti ìjọ àdúgbò àti ti iṣẹ́ kárí ayé, a ń ‘fi ohun ìní wa bọlá fún Olúwa’ tayọ̀tayọ̀. (Òwe 3:9) A ń ṣètìlẹyìn kíkún fún àwọn alàgbà, a sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn, ní títipa báyìí fi ìmoore wa hàn fún Jèhófà fún ìrànwọ́ tí ó ń pèsè nípasẹ̀ wọn. (1 Tẹs. 5:12, 13) Lójoojúmọ́, a ń tiraka láti pa ìwà títọ́ tí ń fògo fún orúkọ Ọlọ́run mọ́. (1 Pét. 2:12) Inú Jèhófà dùn sí gbogbo ẹ̀rí ìmoore wa wọ̀nyí.—1 Tẹs. 5:18.
4 Ìfọpẹ́hàn Wa Tí Ó Dára Jù Lọ: Nínípìn-ín tọkàntọkàn nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba, bíbọlá fún orúkọ Jèhófà, fífi ìmoore hàn nínú àdúrà, àti fífi ìdúróṣinṣin gbèjà òtítọ́ wà lára àwọn ìfọpẹ́hàn àtọkànwá tí ó dára jù lọ tí a lè ṣe fún Ẹlẹ́dàá wa fún ohun gbogbo tí ó ti ṣe nítorí wa. Inú Jèhófà ń dùn láti rí wa tí a ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ sí i ní ṣíṣètìlẹyìn fún ìfẹ́ inú rẹ̀ “pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là.” (1 Tím. 2:3, 4) Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ akéde tí wọ́n lè ṣètò fún un fi ń dáhùn sí ìpè náà tí ó fara hàn nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti February láti forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú oṣù March, April, àti May. Lílo àfikún ìsapá nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ jẹ́ ọ̀nà dáradára kan láti ‘fi ara wa hàn ní ẹni tí ó kún fún ọpẹ́’ sí Ọlọ́run. Ìwọ yóò ha lè dara pọ̀ mọ́ òtú àwọn aṣáájú ọ̀nà ní April bí? May ńkọ́?
5 A ti fún wa ní ìrètí dídájú ti wíwàláàyè títí láé. Nígbà tí ó bá ní ìmúṣẹ, a óò túbọ̀ ní ìdí púpọ̀ síwájú sí i lójoojúmọ́ láti máa bá a nìṣó ní fífi ọpẹ́ onídùnnú fún Jèhófà.—Orin Dá. 79:13.