Gbéṣẹ́ Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ
1 Ojú ọ̀run ṣú dùdù, ìró tí ń bani lẹ́rù ń dún ròkè títí tí ó fi di ariwo tí ń dini létí. Kùrukùru tí ó dà bí èéfín bolẹ̀. Èwo lèyí o? Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ọmọ ogun eéṣú tí wọ́n ń bọ̀ láti pa ilẹ̀ náà run yán-ányán-án mà niì! Ìran yìí tí wòlíì Jóẹ́lì ṣàpèjúwe ní ìmúṣẹ lónìí nínú iṣẹ́ ìwàásù tí àwọn ẹni àmì òróró ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ń ṣe.
2 Ilé Ìṣọ́, May 1, 1998, ojú ìwé 11, ìpínrọ̀ 19, sọ pé: “Ogunlọ́gọ̀ eéṣú Ọlọ́run ti òde òní ti jẹ́rìí kúnnákúnná nínú ‘ìlú ńlá’ Kirisẹ́ńdọ̀mù. (Jóẹ́lì 2:9) . . . Wọ́n ṣì ń borí gbogbo ìdènà, wọ́n ń wọ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ilé, wọ́n ń tọ àwọn ènìyàn lọ ní òpópónà, wọ́n ń bá wọn sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù, wọ́n sì ń kàn sí wọn ní ọ̀nà èyíkéyìí tí ó bá ṣeé ṣe, bí wọ́n ti ń polongo ìhìn iṣẹ́ Jèhófà.” Àǹfààní títóbi lọ́lá ha kọ́ ni ó jẹ́ láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn yìí?
3 Láìdàbí àwọn eéṣú gidi, tí ó jẹ́ pé kí wọ́n ṣáà ti jẹun ni wọ́n mọ̀, àwa gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà ń ṣàníyàn gidigidi ní ti ìwàláàyè àwọn tí a ń wàásù fún. A fẹ́ láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa òtítọ́ ológo tí ó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí a sì sún wọn láti gbégbèésẹ̀ tí yóò ṣamọ̀nà sí ìgbàlà àìnípẹ̀kun fún wọn. (Jòh. 17:3; 1 Tím. 4:16) Nítorí náà, a fẹ́ láti gbéṣẹ́ nínú ọ̀nà tí a ń gbà ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Ọ̀nà ìyówù kí a gbà wàásù, ó yẹ kí a ronú bóyá a ń ṣe é ní ọ̀nà àti ní àkókò tí yóò yọrí sí rere jù lọ. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé “ìrísí ìran ayé yìí ń yí padà,” yóò dára pé kí a ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí a ń lò àti bí a ṣe ń yọ síni láti rí i dájú pé a ń kojú ìpèníjà ti jíjẹ́ ẹni tí ń méso jáde bí ó bá ti ṣeé ṣe tó.—1 Kọ́r. 7:31.
4 Nígbà tí ó jẹ́ pé a ń sakun láti tọ àwọn ènìyàn lọ ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà, iṣẹ́ ilé dé ilé ṣì ni lájorí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. O ha máa ń rí i pé lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn ènìyàn kì í sí nílé nígbà tí o bá kàn sí wọn? Ìyẹn mà ń jáni kulẹ̀ o, níwọ̀n bí ìwọ kò ti lè jẹ́ iṣẹ́ ìhìn rere náà fún wọn! Báwo ni o ṣe lè kojú ìpèníjà yìí?
5 Má Ṣe Rin Kinkin, sì Fòye Báni Lò: Ní Ísírẹ́lì ti ọ̀rúndún kìíní, alẹ́ ni àwọn apẹja máa ń pẹja. Èé ṣe tí ó fi jẹ́ alẹ́? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí kì í ṣe àkókò tí ó rọrùn fún wọn jù lọ, ó jẹ́ àkókò tí ó dára jù lọ láti rí ọ̀pọ̀ ẹja pa. Àkókò tí ń méso jáde jù lọ ni. Nígbà tí Ilé-Ìṣọ́nà, June 15, 1992 ń ṣàlàyé nípa àṣà yìí, ó wí pé: “Awa pẹlu gbọdọ mọ ipinlẹ wa daradara ki a baa lè lọ pẹja, gẹgẹ bi a ti ṣe lè sọ ọ́, nigba ti ọpọ julọ eniyan wà ni ile ti wọn sì fẹ́ gbọ́.” Fífarabalẹ̀ kíyè sí ọ̀nà tí àwọn ènìyàn gbà ń ṣe nǹkan ti fi hàn pé ní ọ̀pọ̀ ibi tí kì í ṣe ìlú ńlá àti ní ọ̀pọ̀ ibi tí àwọn ènìyàn ń gbé, àwọn ènìyàn kì í sí nílé nígbà tí a bá kàn sí wọn ní àwọn àkókò kan. Ó ṣeé ṣe kí gbogbo wọn ti lọ sí ọjà, wọ́n ti lè lọ sí oko wọn, tàbí kí wọ́n ti gba ibòmíràn lọ. Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ọ̀ràn rí ní àgbègbè rẹ, o ha lè yí àkókò tí o ń kàn síni padà sí ọwọ́ ọ̀sán tàbí sí ìrọ̀lẹ́ pàápàá? Èyí jẹ́ ọ̀nà dídára kan láti mú kí gbígbéṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa sunwọ̀n sí i, kí a sì fi ìgbatẹnirò hàn fún àwọn aládùúgbò wa, èyí tí ó jẹ́ ẹ̀rí ìfẹ́ Kristẹni tòótọ́.—Mát. 7:12.
6 Ní Fílípì 4:5, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán wa létí pé kí a ‘jẹ́ kí ìfòyebánilò wa di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.’ Ní ìbámu pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà tí a mí sí yìí, a fẹ́ jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì àti afòyebánilò ní àwọn ọ̀nà tí a ń gbà fi ìtara àti ìyáramọ́ni ṣe iṣẹ́ ìwàásù tí a yàn fún wa. A kò fẹ́ láti ‘fà sẹ́yìn kúrò nínú kíkọ́ni ní gbangba àti láti ilé dé ilé,’ ṣùgbọ́n a fẹ́ láti rí i dájú pé a ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé wa ní àwọn àkókò tí ó fi òye hàn tí ó sì ń méso jáde. (Ìṣe 20:20) Bí àwọn apẹja wọ̀nyẹn ní Ísírẹ́lì ọ̀rúndún kìíní, a ń ṣàníyàn nípa ‘pípẹja’ ní àwọn àkókò tí a lè méso jáde, kì í ṣe ní àwọn àkókò tí a rí i pé ó rọrùn jù lọ fún wa.
7 Àwọn ìyípadà wo ni a lè ṣe? Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá ni a máa ń ṣe ní agogo mẹ́jọ àbọ̀ tàbí agogo mẹ́sàn-án òwúrọ̀ ọjọ́ Saturday àti ọjọ́ Sunday, lẹ́yìn èyí tí àwùjọ yóò lọ lọ́gán sẹ́nu iṣẹ́ ilé dé ilé ní ìpínlẹ̀ wọn. Ṣùgbọ́n, àwọn ẹgbẹ́ alàgbà kan ti ṣètò fún àwùjọ láti lọ sẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní ọwọ́ ìyálẹ̀ta tàbí ní ọwọ́ ọ̀sán bí wọ́n bá rí i pé púpọ̀ jù lọ àwọn ènìyàn ti jáde nílé tí wọn kì yóò sì sí nílé títí di ọ̀sán tàbí ìrọ̀lẹ́. Àwọn ìjọ mìíràn ti fi àkókò tí wọ́n máa ń ṣe ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá sí ọwọ́ ìyálẹ̀ta—ní agogo mẹ́wàá tàbí mọ́kànlá òwúrọ̀ tàbí agogo méjìlá ọ̀sán. Lẹ́yìn ìyẹn, àwùjọ náà yóò wá lọ tààràtà sẹ́nu iṣẹ́ ilé dé ilé, wọn yóò sì wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn títí di ọwọ́ ọ̀sán gangan. Ní àwọn ìpínlẹ̀ kan, ọ̀sán tàbí ìrọ̀lẹ́, ní nǹkan bí agogo mẹrin, dípò òwúrọ̀, lè jẹ́ àkókò tí ó dára jù lọ láti pàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá. Irú àwọn ìyípadà bẹ́ẹ̀ lè fi kún míméso jáde lọ́nà púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ilé dé ilé.
8 Jẹ́ Afòyemọ̀ àti Amẹ̀tọ́mẹ̀yẹ: Bí a ti ń tọ àwọn ènìyàn lọ láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà, a máa ń bá ọ̀pọ̀ ìhùwàpadà sí ìhìn iṣẹ́ wa pàdé. Àwọn onílé kan máa ń tẹ́wọ́ gbà wá, àwọn mìíràn kì í fi ọkàn-ìfẹ́ hàn tò bẹ́ẹ̀, àwọn díẹ̀ kan sì lè máa jiyàn tàbí kí wọ́n jẹ́ aríjàgbá. Ní ti àwọn tí a mẹ́nu kàn kẹ́yìn, ní ojú ìwé 7 nínú ìwé Reasoning From the Scriptures, a rán wa létí pé kì í ṣe pé a ń wọ́nà láti “‘borí nínú àríyànjiyàn’ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí kò bọ̀wọ̀ fún òtítọ́.” Bí onílé bá gbaná jẹ, ó dára jù lọ pé kí a kúrò níbẹ̀. A kò gbọ́dọ̀ tako àwọn ènìyàn nípa rírinkinkin pé kí wọ́n bá wa sọ̀rọ̀ tàbí kí wọ́n tẹ́wọ́ gba ojú ìwòye wa. A kì í fagídí mú àwọn ènìyàn gbọ́ ìhìn iṣẹ́ wa. Ìyẹn kì yóò fi òye hàn, ó sì lè fa ìṣòro fún Àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn àti fún iṣẹ́ náà lódindi.
9 Kí a tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ kan, ó bọ́gbọ́n mu pé kí a ṣàyẹ̀wò káàdì ìpínlẹ̀ kí a lè mọ àwọn àdírẹ́sì ilé tí àwọn tí ó ń gbé ibẹ̀ ti sọ pé kí a má ṣe wọ̀. Bí irú àwọn àdírẹ́sì bẹ́ẹ̀ bá wà, kí a sọ fún akéde kọ̀ọ̀kan nípa ilé tí kò gbọ́dọ̀ wọ̀. Ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ fúnra rẹ̀ pinnu láti kàn sí àwọn ilé wọ̀nyí láìjẹ́ pé alábòójútó iṣẹ́ ìsìn bá sọ bẹ́ẹ̀.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 1994, Àpótí Ìbéèrè.
10 A lè mú kí gbígbéṣẹ́ wa pọ̀ sí i nípa jíjẹ́ afòyemọ̀ nígbà tí a bá ń ṣiṣẹ́ láti ilé dé ilé. Kíyè sí àwọn nǹkan bí o bá ti ń sún mọ́ ilé kan. Ṣé wọ́n ti gbogbo ilẹ̀kùn àti fèrèsé? Ǹjẹ́ kò dà bíi pé o kò gbọ́ ìró kankan? Èyí lè fi hàn pé onílé náà jẹ́ ẹni tí àkókò iṣẹ́ rẹ̀ máa ń yí padà, ó sì ń sùn lọ́wọ́. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé bí a bá padà wá, a óò lè jíròrò pẹ̀lú onílé lọ́nà tí ó túbọ̀ ń méso jáde. Bóyá yóò dára jù lọ láti fo ilé yìí fún àkókò yẹn ná, kí a kọ nọ́ńbà ilé náà sílẹ̀. A lè bẹ ilé náà wò lẹ́ẹ̀kan sí i kí a to kúrò ní ìpínlẹ̀ náà tàbí kí a kọ àkọsílẹ̀ pé a óò tún ṣèbẹ̀wò lẹ́yìn àkókò díẹ̀ sí i.
11 Àwọn ipò mìíràn tún lè wáyé tí a ti lè má mọ̀ọ́mọ̀ jí ẹnì kan lójú oorun tàbí kí a dí i lọ́wọ́. Ó tilẹ̀ lè dà bí pé ó kanra tàbí pé inú bí i. Báwo ni ó ṣe yẹ kí a hùwà padà? Òwe 17:27 gbani nímọ̀ràn pé: “Ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ . . . tutù ní ẹ̀mí.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ní bẹ̀bẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, dájúdájú a lè sọ bí a ṣe káàánú tó pé a ṣèbẹ̀wò ní àkókò tí kò bọ́ sí i. A lè fi ọ̀wọ̀ béèrè bí àkókò mìíràn yóò bá rọgbọ kí a sì sọ pé a óò padà wá. Fífi ohùn pẹ̀lẹ́ ṣàlàyé àníyàn tí a ní fún un lè ṣèrànwọ́ láti pẹ̀tù sí ẹni náà nínú. (Òwe 15:1) Bí onílé kan bá sọ fún wa pé iṣẹ́ alẹ́ ni òun máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà, a lè fi àkọsílẹ̀ kan sínú káàdì ìpínlẹ̀ kí a bàa lè ṣe ìkésíni ní ọjọ́ iwájú ní àkókò yíyẹ.
12 Ìfòyemọ̀ tún ṣe pàtàkì bí a ṣe ń sakun láti ṣe ìpínlẹ̀ wa kúnnákúnná. Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ ènìyàn kì í ti í sí nílé nígbà tí a bá kọ́kọ́ ṣe ìkésíni, ó yẹ kí a ṣe àfikún ìsapá láti kàn sí wọn láti ṣàjọpín ìhìn iṣẹ́ ìgbàlà pẹ̀lú wọn. (Róòmù 10:13) Ìròyìn fi hàn pé nígbà mìíràn àwọn akéde máa ń ṣe ìkésíni sí ilé kan náà lọ́pọ̀ ìgbà lọ́jọ́ kan láti gbìyànjú láti bá àwọn ènìyàn nílé. Àwọn aládùúgbò ń kíyè sí èyí. A lè tẹ èrò tí kò dára mọ́ wọn lọ́kàn pé ‘gbogbo ìgbà’ ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ‘ṣe ìkésíni’ sí àdúgbò wọn. Báwo ni a ṣe lè dènà èyí?
13 Lo ìfòyemọ̀. Nígbà tí a bá ń padà ṣe ìkésíni sí ọ̀dọ̀ ẹni tí kò sí nílé, ṣé àmì wà pé ẹnì kan ti wà nílé báyìí? Bí ìwé bá yọ jáde nínú àpótí ìfìwéránṣẹ́, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ẹni náà kò tí ì sí nílé síbẹ̀, pípadà ṣe ìkésíni síbẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí kì yóò méso jáde. Lẹ́yìn ìgbìyànjú díẹ̀ tí a ṣe ní àkókò tí ó yàtọ̀ lóòjọ́, irú bí ní ìrọ̀lẹ́, bí kò bá ṣeé ṣe láti bá ẹni náà nílé, a lè fọgbọ́n fi ìwé àṣàrò kúkúrú tàbí ìwé ìléwọ́ sí ẹnu ọ̀nà, pàápàá bí ó bá jẹ́ ìpínlẹ̀ tí a máa ń ṣe déédéé. Ó lè jẹ́ pé a lè kàn sí ẹni náà ní ìgbà mìíràn tí a bá ṣe ìpínlẹ̀ náà.
14 A gbọ́dọ̀ yẹra fún ìjíròrò gígùn lẹ́nu ọ̀nà nígbà tí òjò bá ń rọ̀. Bí a bá ké sí ọ wọlé, ṣọ́ra kí o má ṣe dọ̀tí ilẹ̀. Lo ìfòyemọ̀ nígbà tí ajá tí ń gbó bá pa kuuru mọ́ ọ. Bí o bá ń ṣiṣẹ́ nínú ilé fúláàtì, rọra máa sọ̀rọ̀ kí o sì yẹra fún pípariwo lọ́nà tí yóò di àwọn tí ń gbé ibẹ̀ lọ́wọ́ tí yóò sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o ti dé.
15 Wà Létòlétò Kí O sì Buyì Fúnni: Pẹ̀lú ìṣètò rere, a lè dènà mímú kí àwùjọ ńlá, tí gbogbo ènìyàn lè rí kóra jọ ní ìpínlẹ̀ wa. Ẹ̀rù lè ba àwọn onílé kan nígbà tí àwùjọ ńlá ti àwọn akéde bá dé síwájú ilé wọn. A kò fẹ́ kí àwọn ènìyàn ní èrò pé ṣe ni a “ń ya lu” àwọn àgbègbè tí ènìyàn ń gbé. Ibi ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá ni ó dára jù lọ láti ṣètò fún ṣíṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ wa. Àwùjọ kéréje ti àwọn akéde, irú bí ìdílé, kì í sábà dáyà fo onílé, kò sì fi bẹ́ẹ̀ béèrè fún títún ètò ṣe bí a ti ń ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ náà.
16 Ìwàlétòlétò ń béèrè pé kí àwọn òbí ṣàkóso àwọn ọmọ wọn dáadáa nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ kan. Àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ hùwà dáadáa nígbà tí wọ́n bá ń bá àwọn òbí wọn lọ sẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. A kò gbọ́dọ̀ yọ̀ǹda kí àwọn èwe máa ṣeré kiri tàbí kí wọ́n máa rìn gbéregbère kiri, kí wọ́n sì máa pe àfiyèsí àwọn onílé àti àwọn tí ó ń kọjá lọ sí ara wọn lọ́nà tí kò tọ́.
17 A ń béèrè ìwàdéédéé pẹ̀lú nínú ọ̀ràn jíjẹ ìpápánu àti oúnjẹ ọ̀sán. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíṣíwọ́ láti jẹ ìpápánu jẹ́ ìpinnu ẹnì kọ̀ọ̀kan, ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ Ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 104, ìpínrọ̀ 1, sọ pé: “Akoko iṣẹ-isin [pápá] rẹ gbọdọ bẹrẹ nigba tí o bẹrẹ iṣẹ ijẹrii ki ó sì pari nigba tí o bá pari ikesini rẹ tí ó kẹhin patapata laarin akoko ijẹrii kọọkan. Akoko tí a lò fun itura tabi ounjẹ laarin igba tí a fi nṣe iṣẹ-isin [pápá] ni a kò gbọdọ kà kún un. Awọn aṣaaju-ọna oluranlọwọ, déédéé ati akanṣe, mọ́ awọn [míṣọ́nnárì], ní iye wakati tí a beere lọwọ wọn lati kájú. Awọn akede ijọ bakan naa ni a rọ̀ lati fi ire Ijọba naa si ipò kìn-ín-ní ki wọn sì lo ara wọn dé gongo ninu iṣẹ-ojiṣẹ lati ṣe aṣeyọri gbogbo ohun tí wọn bá lè ṣe nínú [pápá] ní ibamu pẹlu ayika-ipò olukuluku wọn. Gbogbo awọn iranṣẹ Jehofah tí wọn ti ṣe iyasimimọ́ ni wọn nilati sakun gidigidi lati jẹ olufọkansin ninu iṣẹ-ojiṣẹ naa. (Col. 3:23)”
18 Ọ̀pọ̀ ti rí àbájáde rere nípa títọ àwọn ènìyàn lọ níbikíbi tí wọ́n bá ti lè rí wọn—ní òpópónà, ní ibùdókọ̀, àti ní àwọn ibòmíràn tí àwọn ènìyàn máa ń wà. Níhìn-ín pẹ̀lú, a fẹ́ láti jẹ́rìí lọ́nà rere nípa jíjẹ́ afòyebánilò pẹ̀lú kì í ṣe nípa ọ̀rọ̀ wa nìkan. Kí àwọn akéde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan rí i dájú pé wọn kò kọjá ààlà ìpínlẹ̀ wọn kí wọ́n má bàa ya bo àwọn tí ń fẹsẹ̀ rìn lọ ní àwọn àgbègbè iṣẹ́ ajé tàbí àwọn tí a gbà síṣẹ́ níbi iṣẹ́ òwò, irú bí ilé epo. Láti rí i dájú pé a ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ní ọ̀nà tí ó wà létòlétò tí ó sì ń buyì fúnni, a óò ṣe kìkì ìpínlẹ̀ tí a yàn fún wa àyàfi bí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ ti ìjọ mìíràn bá ti ṣe ètò pàtó fún ìyẹn, pé kí a ṣèrànwọ́ díẹ̀ fún wọn.—Fi wé 2 Kọ́ríńtì 10:13-15.
19 Àwọn ìjọ kan tí wọ́n ní ọ̀pọ̀ àgbègbè tí a ti lè ṣe ìjẹ́rìí ìtagbangba ti ṣètò àwọn àgbègbè wọ̀nyí sí ìpínlẹ̀-ìpínlẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọn óò wá fún akéde kọ̀ọ̀kan tàbí àwùjọ ní káàdì ìpínlẹ̀ kan. Èyí ń mú kí ó rọrùn láti lè túbọ̀ kárí àgbègbè kan lọ́nà gbígbéṣẹ́, ó sì ń dènà kí akéde púpọ̀ jù máa ṣe àgbègbè kan náà lẹ́ẹ̀kan náà, ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí ó wà ní 1 Kọ́ríńtì 14:40 pé: “Kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.”
20 Ìrísí wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ máa gbayì nígbà gbogbo kí ó sì jẹ́ ti àwọn òjíṣẹ́ tí a ń fi orúkọ Jèhófà pè. Bákan náà ni ó ṣe gbọ́dọ̀ rí ní ti ohun èlò wa. Àpò tí ó ti gbó àti Bíbélì tí ó ti kájọ ní eteetí tàbí tí ó ti dọ̀tí kò buyí kún iṣẹ́ Ìjọba náà. A máa ń sọ pé “ìrínisí ni ìsọnilọ́jọ̀,” ìwọṣọ àti ìmúra wa “a máa sọ ẹni tí a jẹ́ àti ohun tí a jẹ́ àti ẹgbẹ́ àwọn ẹni tí a jẹ́ láwùjọ fún àwọn tí ń bẹ ní àyíká wa.” Nítorí náà, ìrísí wa kò gbọ́dọ̀ rí wúruwùru, kò gbọ́dọ̀ dọ̀tí, bẹ́ẹ̀ ni kò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ ti aláṣehàn tàbí aláṣerégèé, ṣùgbọ́n kí ó máa fi ìgbà gbogbo “yẹ ìhìn rere.”—Fílí. 1:27; fi wé 1 Tímótì 2:9, 10.
21 Ní 1 Kọ́ríńtì 9:26, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Bí mo ti ń sáré kì í ṣe láìní ìdánilójú; bí mo ti ń darí àwọn ẹ̀ṣẹ́ mi jẹ́ láti má ṣe máa gbá afẹ́fẹ́.” Ní àfarawé Pọ́ọ̀lù, a pinnu láti máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí ó gbéṣẹ́ tí ó sì ń méso jáde. Bí a ti ń fi ìtara nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí gẹ́gẹ́ bí apá kan “ọmọ ogun eéṣú” ti Jèhófà lónìí, kí a máa lo ìfòyebánilò àti ìfòyemọ̀ Kristẹni bí a ṣe ń mú ìhìn iṣẹ́ ìgbàlà lọ fún gbogbo ènìyàn ní ìpínlẹ̀ wa.