Tètè Sọ Ohun Tóo Ní Í Sọ!
1 Àwọn èèyàn kan lóde ìwòyí ò ní sùúrù mọ́ o. Wọ́n fẹ́ mọ ẹni táa jẹ́ àti ohun táa bá wá. Nígbà tí wọ́n bá rí i pé ọ̀rọ̀ Bíbélì la wá bá wọn sọ, wọ́n lè máà fẹ́ gbọ́. Bíbélì kíkà àti jíjíròrò nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí kò jẹ ọ̀pọ̀ èèyàn lógún. Báwo la ṣe lè fi yé irú àwọn onílé bẹ́ẹ̀ pé ó yẹ kí wọ́n fún wa ní ìṣẹ́jú díẹ̀ láti fi bá wọn jíròrò kókó kan látinú Bíbélì?
2 Ohun Tó Gbéṣẹ́ Jù Lọ: Kókó pàtàkì ni láti jẹ́ kí onílé mọ̀ pé Bíbélì pèsè àwọn ọ̀nà àbájáde tó múná dóko kúrò nínú àwọn ìṣòro tí ó ń bá yí, kí o sì sọ ìyẹn ní ṣókí. Àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tó gbéṣẹ́ jù lọ máa ń dá lé ìbéèrè pàtó, tí yóò mú kí onílé ro àròjinlẹ̀, lẹ́yìn èyí, a óò wá ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó dáhùn ìbéèrè náà. O lè gbádùn lílò lára àwọn ìdámọ̀ràn tó tẹ̀ lé e yìí. Wọ́n jẹ́ fún ríràn wà lọ́wọ́ láti tètè sọ ohun táa ní í sọ, wọ́n sì tún ń ru ìfẹ́ onílé sókè.
3 Ní ìpínlẹ̀ táwọn èèyàn ti máa ń sọ pé àwọn ò fẹ́ gbọ́, bi wọ́n ní ìbéèrè kan tó kàn wọ́n gbọ̀ngbọ̀n:
◼ “Báa ti fẹ́ wọ ẹgbẹ̀rún ọdún tuntun, ṣé ìrètí ń bẹ àbí ò ń ṣiyèméjì? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń dani lọ́kàn rú táa ń rí lónìí àti ìyọrísí wọn.” Ka 2 Tímótì 3:1, 2, 5 àti Òwe 2:21, 22.
◼ “Àníyàn pọ̀ gan-an lórílẹ̀-èdè yìí nípa ọ̀ràn ìlera. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Ọlọ́run ṣèlérí láti yanjú àwọn ìṣòro tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ìlera pátápátá?” Ka Ìṣípayá 21:3, 4.
◼ “Báwo lo rò pé yóò ti ṣe àdúgbò wa láǹfààní tó, bí olúkúlùkù tí ń gbé níhìn-ín bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò?” Ka Mátíù 22:37-39.
4 Níwọ̀n bí iṣẹ́ wa ti jẹ́ láti máa wàásù nípa ìhìn rere Ìjọba náà, ní gbogbo ìgbà tó bá ṣeé ṣe ló yẹ ká máa pe àfiyèsí sóhun tí Ìjọba náà yóò gbé ṣe. O lè sọ pé:
◼ “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Bíbélì, tí í ṣe ìwé tó ti pẹ́ jù lọ lágbàáyé, sọ tẹ́lẹ̀ pé ìjọba kan ṣoṣo ni yóò wà fún gbogbo ayé?” Ka Dáníẹ́lì 2:44.
◼ “Kí lo rò pé ipò àwọn nǹkan yóò ti rí, bó bá ṣe pé Jésù Kristi ló ń ṣàkóso ayé?” Ka Sáàmù 72:7, 8.
5 Ní ìpínlẹ̀ táwọn èèyàn ti lẹ́mìí ẹ̀sìn, o lè lo ọ̀kan lára ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí:
◼ “Ọ̀pọ̀ èèyàn là ń hùwà ẹ̀tanú sí torí pé wọ́n jẹ́ obìnrin tàbí ọkùnrin, torí ẹ̀sìn wọn, torí ẹ̀yà tí wọ́n jẹ́, tàbí torí àwọ̀ wọn. Ojú wo lo rò pé Ọlọ́run fi ń wo irú ìwà ẹ̀tanú bẹ́ẹ̀?” Ka Ìṣe 10:34, 35.
◼ “A mọ̀ pé Jésù Kristi ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu lọ́jọ́ rẹ̀. Bó bá ṣeé ṣe fún ẹ láti bẹ̀ ẹ́ pé kí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu kan sí i, èwo ni wàá ní kí ó ṣe?” Ka Sáàmù 72:12-14, 16.
6 Bí onílé bá lọ́ tìkọ̀ kó tó ṣílẹ̀kùn, o lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò báyìí:
◼ “Àwọn ìṣòro táa ń gbọ́ ṣáá lóde òní ti sú ọ̀pọ̀ èèyàn. Ojútùú ló kù tí wọ́n ń fẹ́ gbọ́ báyìí. Ó dájú pé ohun tí ìwọ náà fẹ́ gbọ́ nìyẹn. Àmọ́, ibo la ti lè rí ojútùú gidi sáwọn ìṣòro wa?” Jẹ́ kó fèsì. Ka 2 Tímótì 3:16, 17.
7 O Ò Ṣe Lò Ó Wò? Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé, ìbéèrè tó rọrùn, tó ṣe ṣókí nìkan la nílò láti fi ru ìfẹ́ onílé sókè. Obìnrin kan tí kì í gbọ́rọ̀ wa tẹ́lẹ̀ ké sáwọn arábìnrin méjì wọlé lẹ́yìn tí ọ̀kan lára wọn bi í pé: “Ǹjẹ́ o tiẹ̀ mọ Ìjọba tí o ń gbàdúrà fún nínú Àdúrà Olúwa?” Ìbéèrè yẹn ru ìfẹ́ obìnrin náà sókè, ó sì tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó mà ti di ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ṣèyàsímímọ́ báyìí!
8 Tóo bá ń bá onílé sọ̀rọ̀, máa fòtítọ́ inú sọ̀rọ̀. Máa sọ̀rọ̀ látọkànwá. Kò sí ni, àwọn èèyàn yóò dáhùn padà lọ́nà rere tí wọ́n bá rí i dájú pé lóòótọ́ lọkàn wa fà sí wọn.—Ìṣe 2:46, 47.
9 Ìpèníjà ni iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ lónìí. Àwọn onílé kan máa ń fura sí àlejò. Kòókòó jàn-án jàn-án kò jẹ́ káwọn ẹlòmí-ìn ráyè gbọ́ tiwa. Síbẹ̀, ó dá wa lójú gbangba pé ọ̀pọ̀ ẹni yíyẹ ṣì wà tó yẹ láti wá kàn. (Mat. 10:11) Ó jọ pé ìsapá wa láti wá wọn rí yóò túbọ̀ kẹ́sẹ járí báa bá ń gbé ọ̀rọ̀ wa kalẹ̀ ní ṣókí, táa sì ń tètè sọ ohun táa ní í sọ!