Ǹjẹ́ A Lè Mú Kí April 2000 Jẹ́ Oṣù Tí A Tíì Ṣe Dáadáa Jù Lọ?
1 Ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Wednesday, April 19, ló máa jẹ́ àkókò tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn wa. Lọ́jọ́ yẹn, bí oòrùn bá ti wọ̀ jákèjádò ayé, gbogbo ìjọ àti àwùjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé yóò ṣe Ìṣe Ìrántí ikú Kristi. Àkókò yòówù kó bọ́ sí lápá ibi tí a ń gbé, ṣíṣayẹyẹ ìrúbọ Jésù Kristi ni yóò jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ọdún. A fi ọjọ́ Ìṣe Ìrántí hàn gàdàgbà lórí Kàlẹ́ńdà àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ọdún 2000 (2000 Calendar of Jehovah’s Witnesses).
2 Oṣù April látìbẹ̀rẹ̀ dópin ń fún wa ní àgbàyanu àǹfààní láti fi ìmọrírì àtọkànwá hàn fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Jèhófà fi hàn sí wa nípasẹ̀ ìrúbọ Ọmọ rẹ̀. Lọ́nà wo? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa, nítorí èyí ni ohun tí àwa ti ṣèdájọ́, pé ọkùnrin kan kú fún gbogbo ènìyàn; nítorí bẹ́ẹ̀, gbogbo wọ́n ti kú; ó sì kú fún gbogbo wọn kí àwọn tí ó wà láàyè má ṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú fún wọn, tí a sì gbé dìde.” (2 Kọ́r. 5:14, 15) Òótọ́ ni o, lóṣù April, a lè fi hàn pé kì í ṣe ara wa la wà láàyè fún, ṣùgbọ́n a wà láàyè fún ẹni tó kú fún wa, kí a sì mú kí oṣù yìí jẹ́ oṣù tí a tíì ṣe dáadáa jù lọ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ìjọba náà!
3 Forúkọ Sílẹ̀ Láti Ṣe Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ ní Oṣù April: Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ tí ń runi lọ́kàn sókè lélẹ̀ fún wa nígbà tó sọ pé: “Èmi kò ka ọkàn mi sí nǹkan kan tí ó ṣọ̀wọ́n fún mi, bí mo bá sáà ti lè parí ipa ọ̀nà mi àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí mo gbà lọ́wọ́ Jésù Olúwa, láti jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.” (Ìṣe 20:24) Àǹfààní kan náà la ní láti jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Jèhófà Ọlọ́run. Nítorí èyí, a óò fẹ́ láti mú kí oṣù April jẹ́ oṣù tí a tíì ṣe dáadáa jù lọ nínú ìgbòkègbodò aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́!
4 Bí oṣù April 2000 ti ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, ó jẹ́ oṣù tó dáa fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà. Ní March 1997, nígbà tí a ní iye àwọn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tó pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ, àwọn ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlógún, igba ó lé méjìdínlógún [19,218 ] tí wọ́n kópa nínú rẹ̀ dúró fún ìpín mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo akéde. Lọ́dún méjì lẹ́yìn náà, àròpọ̀ iye àwọn akéde tó ròyìn ní April 1999 ti fi ìpín méje nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i. Èyí túmọ̀ sí pé ó ṣeé ṣe gidigidi kí a ní iye àwọn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tó pọ̀ ju iye ti tẹ́lẹ̀ yẹn. Síwájú sí i, a ti dín iye wákàtí tí a ń béèrè kù, èyí sì wá mú kí apá iṣẹ́ ìsìn yìí túbọ̀ ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ìjọ. Ó yẹ kí gbogbo akéde tó ti ṣe batisí ronú tàdúràtàdúrà bóyá òún á lè ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù April.
5 Nípa lílo oṣù April lórí Kàlẹ́ńdà ti ọdún 2000, ṣe ètò tìrẹ nísinsìnyí fún oṣù tí ń bọ̀. Pinnu àwọn ọjọ́ tí wàá lè lọ sóde ẹ̀rí, kí o sì ro gbogbo wákàtí tí o rò pé o lè yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìwàásù lóṣù náà pa pọ̀. Kí ó jẹ́ gbogbo àkókò tí o lè lò láti jẹ́rìí fún àwọn ẹlòmíràn lọ́nà tó jẹ́ bí àṣà àti lọ́nà tí kò jẹ́ bí àṣà. Ǹjẹ́ àròpọ̀ gbogbo wọn sún mọ́ àádọ́ta wákàtí tí a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́? Bí kò bá tó iye wákàtí tó yẹ, ǹjẹ́ o lè ṣe àwọn ìyípadà mìíràn nínú ètò rẹ kí o lè ra àkókò padà láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́? Ohun tí wàá ṣe ni pé kí o ní wákàtí kan àti ogójì ìṣẹ́jú péré lóòjọ́ kí o lè ní àádọ́ta wákàtí lóṣù.
6 Nísinsìnyí tó jẹ́ pé a ti dín wákàtí tí a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé kù pẹ̀lú, ǹjẹ́ o ń ronú nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún? April á jẹ́ oṣù tó dáa láti bẹ̀rẹ̀! Bí kò bá dá ẹ lójú bóyá wàá lè máa ní àádọ́rin wákàtí tí a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé, o ò ṣe ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù April, kí o sì ní i lọ́kàn láti ní àádọ́rin wákàtí? Bí o bá ti rí i pé o lè ṣe é, á túbọ̀ ṣeé ṣe fún ẹ láti forúkọ sílẹ̀ kí o sì dara pọ̀ mọ́ òtú àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé bó bá ti ṣeé ṣe kó yá tó.—Wo ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 113 àti 114.
7 Máa Kópa Lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ Gẹ́gẹ́ Bí Akéde Ìhìn Rere: Ojúlówó ìfẹ́ táa ní sí Ọlọ́run àti aládùúgbò ló ń sún gbogbo wa, àtakéde, àtaṣáájú ọ̀nà láti ṣe gbogbo ohun tí a bá lè ṣe tọkàntọkàn nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà bí àyíká ipò ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bá ti rí. (Lúùkù 10:27) Nípa báyìí, a ń fi hàn pé “àwa ń ṣiṣẹ́ kára, . . . a sì ń tiraka, nítorí tí a ti gbé ìrètí wa lé Ọlọ́run alààyè, ẹni tí ó jẹ́ Olùgbàlà gbogbo onírúurú ènìyàn, ní pàtàkì ti àwọn olùṣòtítọ́.” (1 Tím. 4:10) Ìdí nìyẹn tí a fi gbọ́dọ̀ retí pé kí gbogbo wa kópa nínú iṣẹ́ ìsìn ní April, ká kópa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú iṣẹ́ Ìjọba náà.
8 Kí a má ṣe gbàgbé ìṣíléti Jésù pé: “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” Bí Jésù ṣe sọ ọ̀rọ̀ yìí tán, ó pe àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá jọ, ó sì rán wọn jáde láti wàásù. (Mát. 9:37, 38; 10:1, 5, 7) Ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, lẹ́yìn tí Jésù ti fi iṣẹ́ ìwàásù kọ́ àwọn méjìlá náà dáadáa, ó “yan àwọn àádọ́rin mìíràn sọ́tọ̀, ó sì rán wọn jáde,” ó sì fún wọn nítọ̀ọ́ni kan náà pé: “Ìkórè pọ̀, ní tòótọ́ . . . Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè kí ó rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” (Lúùkù 10:1, 2) Ìwé Ìṣe nínú Bíbélì ròyìn bí Jèhófà ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn. Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, iye àwọn ọmọ ẹ̀yìn ti pọ̀, wọ́n sì tó ọgọ́fà. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn di ẹgbẹ̀rún mẹ́ta, àfi fẹ̀rẹ̀, wọ́n tún di ẹgbẹ̀rún márùn-ún. (Ìṣe 1:15; 2:41; 4:4) Lẹ́yìn ìyẹn, “iye àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì ń di púpọ̀ sí i ṣáá.” (Ìṣe 6:7) Bákan náà, lóde òní, a gbọ́dọ̀ máa bẹ Ọ̀gá náà fún àwọn oníwàásù Ìjọba náà púpọ̀ sí i! Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àdúrà wa, kí akéde kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ ṣe ètò tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lóṣooṣù.
9 Jọ̀wọ́ wo oṣù April dáadáa lórí Kàlẹ́ńdà ti ọdún 2000. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọjọ́ méjì àkọ́kọ́ lóṣù náà jẹ́ Saturday àti Sunday, ṣé o lè wéwèé láti kópa nínú iṣẹ́ ìsìn ní òpin ọ̀sẹ̀ yẹn, kí o tètè bẹ̀rẹ̀ lóṣù yẹn? Ṣé o lè bá àwùjọ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ rẹ kọ́wọ́ ti gbogbo “Ọjọ́ Ìwé Ìròyìn” lóṣù yẹn? Ǹjẹ́ o lè lo wákàtí kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní gbogbo ọjọọjọ́ Sunday? Ǹjẹ́ o lè ṣètò láti kópa nínú ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́? Má sì ṣe gbàgbé láti lo gbogbo àǹfààní tí o bá ní láti jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà níbi iṣẹ́, ní ilé ẹ̀kọ́, tàbí nígbà tí o bá ń lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ mìíràn. Sàmì sí àwọn ọjọ́ tí wàá lè lo àkókò díẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, kí o sì lo kàlẹ́ńdà náà láti ṣètò àkókò iṣẹ́ ìsìn rẹ lóṣù April.
10 Oṣù April yóò fún gbogbo àwọn tó tóótun, tí àwọn alàgbà sì ti fọwọ́ sí, láǹfààní láti bẹ̀rẹ̀ sí sìn gẹ́gẹ́ bí akéde tí kò tíì ṣe batisí. Bí o bá ń bá ẹnì kan ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣé ẹni yẹn ti tẹ̀ síwájú débi tó fi lè lọ bá alábòójútó olùṣalága, kó sì sọ fún un pé òún fẹ́ di akéde ìhìn rere? Bí o bá ní àwọn ọmọ tí kò tíì ṣe batisí, ǹjẹ́ o ti bá àwọn alàgbà jíròrò ìtẹ̀síwájú wọn nípa tẹ̀mí? Ǹjẹ́ kì í ṣe ìgbà tó dáa kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kéde nìyí?—Wo Iwe Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 97 sí 100.
11 Nígbà tí a bá ń sapá láti mú kí April 2000 jẹ́ oṣù tí a tíì ṣe dáadáa jù lọ, ó yẹ kí gbogbo wa kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, kí a sì ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wa níparí oṣù. (Fi wé Máàkù 6:30.) Kí a fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di akéde tí kò tíì ṣe batisí, tí wọ́n ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún ìgbà àkọ́kọ́ níṣìírí pé kí wọ́n ròyìn iṣẹ́ wọn lásìkò. Nípa ṣíṣe ipa tiwa, a lè mú kí ìròyìn April pọ̀ dáadáa, a sì lè fi kún igbe ìyìn ńlá tí a óò fi yin Jèhófà nípasẹ̀ iṣẹ́ ìjẹ́rìí wa.
12 Mú Àwọn Ẹlòmíràn Wá sí Ìṣe Ìrántí: Ǹjẹ́ inú wa ò ní dùn tí iye àwọn tí yóò wá sí Ìṣe Ìrántí ikú Kristi ní ọdún 2000 yìí bá pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ? Bẹ́ẹ̀ ni o! Á túmọ̀ sí pé ju ti ìgbàkígbà rí lọ, àwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ pé jọ láti fi ìmọrírì tí wọ́n ní hàn fún ìfẹ́ títóbi jù lọ tí Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi fi hàn nítorí wa! (Jòh. 3:16; 15:13) Ṣe gbogbo ètò tó bá yẹ kó má bàa sí ohunkóhun tí yóò dí ìwọ àti ìdílé rẹ lọ́wọ́ láti wá sí Ìṣe Ìrántí.
13 Ìsinsìnyí tún ni àkókò láti bẹ̀rẹ̀ sí ké sí àwọn ẹlòmíràn láti wá sí Ìṣe Ìrántí. Kọ orúkọ gbogbo àwọn tí o fẹ́ kó wá. Fi orúkọ gbogbo àwọn tí o ti bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rí, àwọn tí o ṣì ń bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́, àti gbogbo ìpadàbẹ̀wò rẹ kún un. Fi orúkọ àwọn ojúlùmọ̀ rẹ níbi iṣẹ́, ní ilé ẹ̀kọ́, àti ládùúgbò kún un, títí kan orúkọ àwọn oníbàárà rẹ. Má ṣe gbàgbé láti fi àwọn mìí tí o mọ̀ àti àwọn ìbátan rẹ kún un. Lẹ́yìn tí o bá ti kọ gbogbo orúkọ náà, bẹ̀rẹ̀ sí fi tọkàntọkàn ké sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn fúnra rẹ. Jẹ́ kí wọ́n mọ ibi tí ẹ óò ti ṣe Ìṣe Ìrántí àti ìgbà tí ẹ óò ṣe é. Bí April 19 bá ti ń sún mọ́lé, fúnra rẹ rán gbogbo àwọn tí o kọ orúkọ wọn sílẹ̀ létí. Sọ pé wàá wá pè wọ́n kí ẹ lè jọ lọ sí Ìṣe Ìrántí ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn.
14 Ní ìbámu pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà tí Society ti pèsè tẹ́lẹ̀, ẹgbẹ́ àwọn alàgbà yóò sapá lákànṣe láti fún gbogbo àwọn akéde aláìṣiṣẹ́mọ́ tó wà ní ìpínlẹ̀ wọn níṣìírí láti wá sí Ìṣe Ìrántí. (Mát. 18:12-14) Kí àwọn alàgbà ṣàtúnyẹ̀wò lẹ́tà tí Society kọ ní February 2, 1999. Kí akọ̀wé ìjọ kọ orúkọ gbogbo akéde aláìṣiṣẹ́mọ́, kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn sì yan àwọn alàgbà láti bẹ̀ wọ́n wò kí wọ́n sì ké sí wọn wá sí Ìṣe Ìrántí. Ó ṣeé ṣe pé bí a bá ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn tí ń fúnni níṣìírí sí ọ̀dọ̀ àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ wọ̀nyí, bó bá ti ṣeé ṣe kó yá tó, a lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lẹ́ẹ̀kan sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, àní lóṣù April pàápàá. Bí a bá ké sí wọ́n láti kópa nínú iṣẹ́ ìsìn pápá pẹ̀lú akéde kan tó dáńgájíá, èyí yóò gbé wọn ró.
15 Ẹ Fún Àwọn Ará Níṣìírí Láti Ṣètìlẹ́yìn Dáadáa Lóṣù April! Láti lè mú kí April 2000 jẹ́ oṣù tí a tíì ṣe dáadáa jù lọ, ó ń béèrè ìfọwọ́sowọ́pọ̀ gidigidi láàárín àwọn alàgbà, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, àti àwọn olórí ìdílé. Àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ sapá gidigidi láti ṣètò gbogbo nǹkan dáadáa, kí wọ́n sì mú ipò iwájú. (Héb. 13:7) A gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ètò tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ fún ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá ní àwọn ọjọ́ àárín ọ̀sẹ̀ àti ní àwọn òpin ọ̀sẹ̀. A tún lè ṣètò fún àwọn ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá mìíràn lọ́wọ́ ọ̀sán àti lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́. Kí a lẹ ìwé gbogbo ètò tí a bá ṣe fún oṣù April mọ́ ojú pátákó ìsọfúnni. Kí a yan ẹni tí yóò bójú tó ìpàdé kọ̀ọ̀kan tí a ṣètò fún iṣẹ́ ìsìn. Kí a ṣètò ìpínlẹ̀ tí ó pọ̀ tó, kó lè jẹ́ pé gbogbo àwọn tó bá wá fún iṣẹ́ ìsìn á ríbi ṣiṣẹ́.
16 Ní oṣù April, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la ó fi lọni. Kí a lè bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn nínú ilé wọn, a ní láti fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọ gbogbo àwọn tó bá fìfẹ́ hàn. Nítorí náà, kí a rí i pé ìwé ìròyìn àti ìwé pẹlẹbẹ tó pọ̀ wà lọ́wọ́.
17 Ní ìparí oṣù, kí gbogbo Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ àti àwọn olùrànlọ́wọ́ wọn fún gbogbo àwọn tó wà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ wọn níṣìírí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn wọn sílẹ̀ ní gbàrà tí oṣù bá parí. Ó tilẹ̀ lè ṣeé ṣe kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ ní Sunday, April 30. Lẹ́yìn náà, bí akọ̀wé bá ti kó ìròyìn jọ, tó sì wá kíyè sí i pé àwọn akéde kan ò tíì fi tiwọn sílẹ̀, ó lè fi pẹ̀lẹ́tù rán wọn létí pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ kó tó di May 6, nígbà tí òún á fi ìròyìn ìjọ ránṣẹ́ sí Society. Ó lè sọ pé kí àwọn Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ran òun lọ́wọ́ láti bá akéde kọ̀ọ̀kan sọ̀rọ̀.
18 Ìgbà Ìṣe Ìrántí ni àkókò tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ọdún fún àwọn èèyàn Ọlọ́run. Gbogbo wa ló yẹ ká kún fún iṣẹ́ pẹrẹwu nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà lákòókò yẹn. Bẹ́ẹ̀ ló máa rí bí gbogbo wa bá ṣiṣẹ́ bí a ti lè ṣe tó gẹ́gẹ́ bí akéde ìhìn rere, bí àwọn tó lè forúkọ sílẹ̀ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ bá ṣe bẹ́ẹ̀, bí gbogbo wa bá sì sapá gidigidi láti mú àwọn ẹlòmíràn wá sí Ìṣe Ìrántí ikú Kristi. Ẹ jẹ́ kí a máa fi taratara gbàdúrà fún ìbùkún jìngbìnnì látọ̀dọ̀ Jèhófà bí a ṣe ń sakun láti mú kí April 2000 jẹ́ oṣù tí a tíì ṣe dáadáa jù lọ, kí gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ fún ìyìn àti ògo Ọlọ́run!—Héb. 13:15.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]
Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́
Iye Tó Ju ti Ìgbàkígbà Rí Lọ Tí A Ní: 19,218
(March 1997)
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
Àròpọ̀ Akéde
Iye Tó Ju ti Ìgbàkígbà Rí Lọ Tí A Ní: 226,539
(September 1999)
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
Àwọn Tó Wá sí Ìṣe Ìrántí
Iye Tó Ju ti Ìgbàkígbà Rí Lọ Tí A Ní: 598,717
(1997)