Jẹ́ Kí Ojú Rẹ Mú Ọ̀nà Kan
1. Kí ni níní ojú tó mú ọ̀nà kan túmọ̀ sí, kí nìdí tí èyí sì fi ṣe pàtàkì?
1 Nínú Ìwàásù Orí Òkè, Jésù sọ bí fífi ojú tẹ̀mí wo nǹkan ṣe lè nípa tó jinlẹ̀ lórí ìgbésí ayé ẹni. Ó sọ pé: “Nígbà náà, bí ojú rẹ bá mú ọ̀nà kan, gbogbo ara rẹ yóò mọ́lẹ̀ yòò; ṣùgbọ́n bí ojú rẹ bá burú, gbogbo ara rẹ yóò ṣókùnkùn.” (Mát. 6:22, 23) Bí ojú èèyàn bá mú ọ̀nà kan, ẹni náà yóò pọkàn pọ̀ sórí ohun kan ṣoṣo, ìyẹn ni ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, dípò jíjẹ́ kí àníyàn tí kò pọn dandan lórí àwọn ohun ti ara pín ọkàn òun níyà. (Mát. 6:19-21, 24-33) Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ kí ojú wa lè mú ọ̀nà kan?
2. Èrò wo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú láti ní nípa àwọn ohun ti ara?
2 Níní Ìtẹ́lọ́rùn: Ìwé Mímọ́ sọ pé gbígbọ́ bùkátà agboolé wa jẹ́ ara ojúṣe àwa Kristẹni. (1 Tím. 5:8) Àmọ́, èyí ò wá túmọ̀ sí pé ká máa fi tọ̀sán tòru lé àwọn ohun tó dára jù lọ àtàwọn ohun tó lòde táráyé ń lé. (Òwe 27:20; 30:8, 9) Kàkà bẹ́ẹ̀, Ìwé Mímọ́ gbà wá níyànjú pé tá a bá ti ní “ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ” kí èyí tẹ́ wa lọ́rùn, torí pé ìwọ̀nyí làwọn ohun kòṣeémánìí nígbèésí ayé. (1 Tím. 6:8; Héb. 13:5, 6) Tá a bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, á jẹ́ kí ojú wa mú ọ̀nà kan.
3. Báwo la ṣe lè yẹra fún àwọn ohun ìdíwọ́?
3 Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká yẹra fún títọrùn bọ gbèsè tí kò pọn dandan tàbí fífi àwọn ohun ìní tàbí ìgbòkègbodò tó ń gba ọ̀pọ̀ àkókò tó sì ń tánni lókun dí ara wa lọ́wọ́. (1 Tím. 6:9, 10) Báwo la ṣe lè yẹra fún èyí? Bó o bá ń ronú nípa ohun kan tó o fẹ́ ṣe, gbàdúrà àtọkànwá nípa ohun náà, kó o sì fi òótọ́ inú wò ó bóyá ó lè ṣèdíwọ́ fún àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí. Pinnu pé àwọn nǹkan tẹ̀mí ni wàá máa fi ṣáájú nígbèésí ayé rẹ.—Fílí. 1:10; 4:6, 7.
4. Kí nìdí tó fi yẹ ká mú àwọn ohun tí kò pọn dandan kúrò?
4 Má Fi Ohun Tí Kò Pọn Dandan Dí Ara Rẹ Lọ́wọ́: Ohun mìíràn tá a lè ṣe kí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì má bàa fa ìpínyà ọkàn fún wa ni pé ká má fi ohun tí kò pọn dandan dí ara wa lọ́wọ́. Arákùnrin kan tó rí i pé ìwọ̀nba ohun ìní díẹ̀ ti tó ìdílé òun lò láìsí pé wọ́n ń kó ohun ti ara jọ rẹpẹtẹ sọ pé: “Ní báyìí, mò ń ráyè ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan sí i nínú ìjọ láti fi sin àwọn arákùnrin mi. Ó dá mi lójú pé Jèhófà máa ń bù kún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bí wọ́n bá fi ìjọsìn tòótọ́ ṣáájú ìgbádùn ti ara wọn.” Ǹjẹ́ ìwọ náà lè mú àwọn ohun tí kò pọn dandan kúrò kó o lè rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà?
5. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa sapá lójú méjèèjì láti jẹ́ kí ojú wa mú ọ̀nà kan?
5 A ní láti máa sapá lójú méjèèjì ká bàa lè gbógun ti Sátánì, ayé onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì rẹ̀ àti àìpé tiwa fúnra wa. Dípò ká jẹ́ kí ojú wa máa wòhín-wọ̀hún, ẹ jẹ́ ká pọkàn pọ̀ sórí ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run àti sórí ìrètí iyebíye tá a ní, ìyẹn ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun.—Òwe 4:25; 2 Kọ́r. 4:18.