Ǹjẹ́ O Lè Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́?
1 Jèhófà máa ń wá bó ṣe máa ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin lọ́wọ́ nígbà gbogbo. (2 Kíró. 16:9; Aísá. 41:10, 13) Aísáyà fi Jèhófà wé olùṣọ́ àgùntàn tó ń bójú tó àwọn àgùntàn rẹ̀. Ó kọ̀wé pé: “Apá rẹ̀ ni yóò fi kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn jọpọ̀; oókan àyà rẹ̀ sì ni yóò gbé wọn sí. Àwọn tí ń fọ́mọ lọ́mú ni yóò máa rọra dà.” (Aísá. 40:11) Wo àwọn ọ̀nà díẹ̀ tí a fi lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà ní ti bó ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.
2 Máa Ran Àwọn Ẹni Tuntun Lọ́wọ́: Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣèrànwọ́ ni pé ká fa àwọn ẹni tuntun mọ́ra kí wọ́n lè rí àwọn ọ̀rẹ́ tí yóò gbé wọn ró. (Òwe 13:20) Arákùnrin kan sọ bí àwọn ará ṣe ran òun lọ́wọ́ nígbà tí òun ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wá sí ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí, ó ní: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìdílé kan tàbí òmíràn máa ń sọ pé kí n wá bá àwọn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé pa pọ̀. Bí mo ṣe ń tẹ̀ síwájú, àwọn tọkọtaya aṣáájú ọ̀nà kan tí wọn kò tíì dàgbà púpọ̀ sábà máa ń sọ fún mi pé kí n bá àwọn jáde òde ẹ̀rí láti àárọ̀ ṣúlẹ̀. A sì máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí gan-an.” Ó fi kún un pé: “Kí n tó di Kristẹni, alaalẹ́ Friday àti Sátidé ni mo máa ń wá ibi eré ìnàjú kan lọ. Àmọ́ ní báyìí, ìfararora mi pẹ̀lú àwọn ará ti dípò gbogbo ìyẹn.” Ìfẹ́ tí ìjọ fi hàn sí arákùnrin yìí ló jẹ́ kó di ẹni tó ta gbòǹgbò, tó sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́. Nísinsìnyí, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì.—Kól. 2:6, 7.
3 Ẹ Jẹ́ Ká Máa Gbé Ara Wa Ró: Nígbà táwọn ará wa bá níṣòro, a lè fúnra wa ronú ọ̀nà tá a lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́. Ǹjẹ́ o lè ṣètò pé kí ìwọ àti akéde kan tó ní àìlera jọ ṣe ìjẹ́rìí orí tẹlifóònù tàbí kó o sọ pé kó bá ọ lọ síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tàbí kó o tiẹ̀ mú akẹ́kọ̀ọ́ rẹ wá sílé akéde náà kẹ́ ẹ wá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀? Ǹjẹ́ o lè ran òbí kan tó ní àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ lọ́wọ́ nígbà tẹ́ ẹ bá wà lóde ẹ̀rí? Ǹjẹ́ àwọn kan wà tí wọ́n jẹ́ onítìjú èèyàn tó o lè ràn lọ́wọ́ nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò tàbí tí ẹ̀ ń kópa nínú ẹ̀ka iṣẹ́ òjíṣẹ́ mìíràn?—Róòmù 14:19.
4 Bí a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà ní ti bó ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, a óò máa fún ara wa lókun, a óò jẹ́ kí ìfẹ́ gbilẹ̀, kí ìjọ sì wà ní ìṣọ̀kan, a óò sì máa tipa bẹ́ẹ̀ yin Baba wa ọ̀run lógo.—Éfé. 4:16.