Fi Hàn Nísinsìnyí Pé Ìjọba Ọlọ́run Lo Fara Mọ́!
Ká sọ pé ìjì líle kan ń jà, ó sì ń bọ̀ níbi tó o wà, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba wá ń kéde pé: “Ẹ JÁDE, Ẹ WÁ IBÌ KAN FORÍ PA MỌ́ SÍ!” Kí lo máa ṣe? Ó dájú pé o máa wá ibi ààbò kan forí pa mọ́ sí.
Bákan náà lónìí, gbogbo wa là ń gbé ní àkókò tí ìjì ńlá kan máa tó jà, èyí tí Jésù pè ní “ìpọ́njú ńlá.” (Mátíù 24:21) Kò sóhun tá a lè ṣe láti dá ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀ yẹn dúró. Àmọ́, a lè ṣe ohun kan láti dáàbò bo ara wa. Kí la lè ṣe?
Jésù Kristi sọ nínú Ìwàásù Lórí Òkè pé: “Torí náà, ẹ máa wá Ìjọba [Ọlọ́run] àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́.” (Mátíù 6:33) Báwo la ṣe lè ṣe é?
Máa wá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́. Èyí túmọ̀ sí pé Ìjọba Ọlọ́run ló yẹ kó ṣe pàtàkì sí wa ju ohunkóhun mìíràn. (Mátíù 6:25, 32, 33) Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn èèyàn ò lágbára láti yanjú ìṣòro aráyé. Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú ìṣòro aráyé.
Máa wá òdodo rẹ̀. Ó yẹ ká máa sapá láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, ká sì máa fi àwọn ìlànà òdodo rẹ̀ sílò. Kí nìdí? Ìdí ni pé tá a bá kàn ń ṣe ohun tá a rò pé ó tọ́ lójú ara wa, ìgbẹ̀yìn ẹ̀ ò ní dáa rárá. (Òwe 16:25) Àmọ́, tá a bá ń fi àwọn ìlànà Ọlọ́run sílò láyé wa, yàtọ̀ sí pé a máa múnú Ọlọ́run dùn, ayé wa á tún dáa.—Àìsáyà 48:17, 18.
Máa wá Ìjọba Ọlọ́run àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́. Jésù kìlọ̀ pé àwọn kan lè yà bàrá kúrò lọ́nà òtítọ́ torí pé wọ́n fẹ́ di olówó rẹpẹtẹ, èrò irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni pé ìyẹn ló máa fi àwọn lọ́kàn balẹ̀. Àwọn míì sì lè jẹ́ kí àníyàn ìgbésí ayé bò wọ́n mọ́lẹ̀ débi pé wọn ò ní ráyè wá Ìjọba Ọlọ́run mọ́.—Mátíù 6:19-21, 25-32.
Àmọ́, Jésù ṣèlérí pé àwọn tó ń wá Ìjọba Ọlọ́run máa ní ohun tí wọ́n nílò ní báyìí, wọ́n á sì gbádùn ìbùkún títí láé lọ́jọ́ iwájú.—Mátíù 6:33.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ń wá Ìjọba Ọlọ́run àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, ìrora àti ìyà ṣì ń han àwọn èèyàn léèmọ̀ nígbà ayé wọn. Àmọ́, wọ́n rí ààbò. Lọ́nà wo?
Torí pé wọ́n ń fi àwọn ìlànà òdodo Ọlọ́run sílò láyé wọn, wọn ò kó sínú irú ìṣòro táwọn tí kò tẹ̀ lé ohun tí Ọlọ́run sọ máa ń kó sí. Torí pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó lágbára pé Ìjọba Ọlọ́run máa dé, ìyẹn jẹ́ kí wọ́n lè fara da àwọn ìṣòro tó lékenkà. Ọlọ́run wá fún wọn ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá” kí wọ́n lè fara da àwọn ìṣòro tí wọ́n kojú.—2 Kọ́ríńtì 4:7-9.
ṢÉ WÀÁ MÁA WÁ ÌJỌBA NÁÀ LÁKỌ̀Ọ́KỌ́?
Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù pé kí wọ́n máa wá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́. Wọ́n wàásù ìhìn rere Ìjọba náà débi gbogbo láyé ìgbà yẹn. (Kólósè 1:23) Ṣé àwọn kan ń ṣe ohun kan náà lónìí?
Bẹ́ẹ̀ ni! Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé ìgbà díẹ̀ ló kù tí Ìjọba Ọlọ́run máa pa gbogbo ìjọba àti ètò búburú ayé yìí run. Torí náà, wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti tẹ̀ lé àṣẹ Jésù tó sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.”—Mátíù 24:14.
Kí lo máa ṣe tí wọ́n bá wàásù ìhìn rere fún ẹ? A rọ̀ ẹ́ pé kó o fara wé àwọn kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tí wọ́n ń gbé ní Bèróà ní ìlú Makedóníà. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wàásù ìhìn rere fún wọn, “wọ́n gba ọ̀rọ̀ náà tọkàntọkàn.” Lẹ́yìn náà, wọ́n “ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ kínníkínní” láti mọ̀ bóyá àwọn nǹkan tí wọ́n gbọ́ rí bẹ́ẹ̀, wọ́n sì ṣiṣẹ́ lórí ohun tí wọ́n gbọ́.—Ìṣe 17:11, 12.
Ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀. Tó o bá ń wa Ìjọba Ọlọ́run àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, wàá rí ààbò ní báyìí, wàá sì gbádùn àlàáfíà àti ààbò títí láé lọ́jọ́ iwájú.