Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
1. Kí nìdí tó fi dáa ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tí wọ́n bá bi wá ní ìbéèrè?
1 Ọ̀nà tó gbéṣẹ́ tí Jésù gbà fèsì àwọn ìbéèrè àti ìwádìí tí wọ́n wá ṣe lọ́dọ̀ rẹ̀ ṣì ń ya àwọn èèyàn lẹ́nu dòní olónìí. Bí wọ́n bá bi wá ní onírúurú ìbéèrè lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ó máa dáa gan-an tá a bá ń fara wé Jésù nígbà tá a bá ń dáhùn.—1 Pét. 2:21.
2. Kí ló máa jẹ́ ká lè dáhùn ìbéèrè lọ́nà tó gbéṣẹ́?
2 Kọ́kọ́ Tẹ́tí Sílẹ̀: Jésù máa ń ronú nípa ohun tó mú kẹ́ni kan béèrè ìbéèrè. Nígbà míì èyí máa gba pé kéèyàn bi ẹni yẹn ní ìbéèrè tó máa jẹ́ ká mọ ohun tó ní lọ́kàn gan-an. Ó lè jẹ́ torí pé ó ya ẹnì kan lẹ́nu pé o kì í ṣayẹyẹ Kérésìmesì ló ṣe bi ẹ́ pé: “Ǹjẹ́ o gba Jésù gbọ́?” Tó o bá mọ ohun tẹ́ni tó bi ẹ́ ní ìbéèrè ní lọ́kàn gan-an, wàá lè bá a fèrò wérò lọ́nà tó gbéṣẹ́.—Lúùkù 10:25-37.
3. Kí la ní tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí àwọn ìdáhùn tó tẹ́ni lọ́rùn láti inú Ìwé Mímọ́?
3 Gbé Ìdáhùn Rẹ Ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: Ohun tó sábà máa ń dáa jù ni pé kó o lo Bíbélì láti fi dáhùn ìbéèrè tí wọ́n bi ẹ́. (2 Tím. 3:16, 17; Héb. 4:12) Ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó àti “Awọn Akori Ọrọ Bibeli fun Ijiroro” tó wà lẹ́yìn Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti dáhùn ìbéèrè tí wọ́n bá bi wọ́n lọ́nà tó tọ́. Bó bá tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ pé onítọ̀hún ò gba ohun tí Bíbélì sọ gbọ́, o lè fọgbọ́n ṣàlàyé ohun tí Ìwé Mímọ́ fi kọ́ni fún un. Fún ẹni náà níṣìírí láti ronú jinlẹ̀ nípa ọgbọ́n tó ṣeé gbára lé tó wà nínú Bíbélì. Bó o bá fara wé Jésù, ìdáhùn rẹ á dà “bí àwọn èso ápù ti wúrà nínú àwọn ohun gbígbẹ́ tí a fi fàdákà ṣe” ìyẹn ni pé ìdáhùn rẹ á buyì fúnni, á tuni lára, á sì gbéṣẹ́.—Òwe 25:11.
4. Láwọn ipò wo ni kò ti yẹ ká dáhùn gbogbo ìbéèrè tí wọ́n bá bi wá?
4 Ṣé Gbogbo Ìbéèrè La Gbọ́dọ̀ Dáhùn? Bí o kò bá mọ ìdáhùn sí ìbéèrè kan, má ṣe tijú láti sọ pé: “Mi ò mọ ìdáhùn sí ìbéèrè rẹ, àmọ́ mo lè ṣèwádìí lórí rẹ̀, kí n sì pa dà wá fún ẹ lábọ̀ ìwádìí mi.” Bó o ṣe sòótọ́ fún un, tó o sì fi hàn pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ ẹ́ lógún lè mú kẹ́ni tó o wàásù fún náà gbà pé kó o pa dà wá nígbà míì. Bí o bá rí i pé alátakò lẹni tó béèrè ìbéèrè yẹn, tó sì ṣeé ṣe kó fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí jiyàn, fara wé Jésù nípa jíjẹ́ kí ìdáhùn rẹ mọ ní ṣókí. (Lúùkù 20:1-8) Lọ́nà kan náà, bí ẹnì kan tí kò bá nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Bíbélì bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í jiyàn, fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ fòpin sí ìjíròrò náà kó o sì lo àkókò rẹ láti fi wá àwọn tó fẹ́ gbọ́ lóòótọ́.—Mát. 7:6.
5. Àpẹẹrẹ rere wo ni Jésù fi lélẹ̀ nípa bó ṣe yẹ ká máa dáhùn ìbéèrè? (Tún wo àpótí tó wà lójú ìwé yìí.)
5 Jésù mọ̀ pé òun gbọ́dọ̀ gbára lé Jèhófà kóun bàa lè ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé òun lọ́wọ́ láti “jẹ́rìí sí òtítọ́,” èyí tó kan dídáhùn ìbéèrè àwọn tó dìídì fẹ́ mọ òtítọ́. (Jòh. 18:37) Àǹfààní ńlá mà la ní láti fara wé Jésù ká lè fún àwọn tí ‘wọ́n ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun’ ní ìdáhùn tó tọ́!—Ìṣe 13:48.
Àwọn Kókó Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn
◼ Fetí sílẹ̀ dáadáa kó o lè fòye mọ ohun tó ń jẹ ẹni tó béèrè ìbéèrè lọ́kàn.—Lúùkù 8:18.
◼ Gbé ìdáhùn rẹ ka Bíbélì. Àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé ka Bíbélì lè jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè lo Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó gbéṣẹ́.—Héb. 4:12.
◼ Lo ìfòyemọ̀, jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà kó o sì fọ̀wọ̀ hàn. —Kól. 4:6.