MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Pọ́ọ̀lù Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Ọlọ́run Ó sì Mọ́kànle”
Nígbà tí àwọn ará tó wà ní ìjọ Róòmù gbọ́ pé Pọ́ọ̀lù ń bọ̀, àwọn arákùnrin kan rìnrìn àjò nǹkan bí ogójì (40) máìlì (64 km) láti lọ pà dé rẹ̀. Báwo ni ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn tí wọ́n ní ṣe rí lára Pọ́ọ̀lù? “Nígbà tí Pọ́ọ̀lù tajú kán rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì mọ́kàn le.” (Iṣe 28:15) Pọ́ọ̀lù ló máa ń fún àwọn ará tó bá lọ bẹ̀ wò ní ìṣírí, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí ẹlẹ́wọ̀n ni, òun gan-an ló wá ń gba ìṣírí.—2Kọ 13:10.
Lónìí, àwọn alábòójútó àyíká máa ń lọ láti ìjọ kan sí ìjọ míì kí wọ́n lè gbé àwọn ará ró. Bíi ti àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run míì, ìgbà míì wà tó máa ń rẹ̀ wọ́n, nǹkan lè tojú sú wọn tàbí kí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì. Nígbà míì tí àwọn alábòójútó àyíká bá wá sí ìjọ yín, kí lo lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ́kàn le, “kí pàṣípààrọ̀ ìṣírí lè wà láàárín yín”?—Ro 1:11, 12.
Lọ sí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá. Inú àwọn alábòójútó àyíká máa ń dùn tí àwọn ará bá ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti kọ́wọ́ ti gbogbo ètò tó wà nílẹ̀ lọ́sẹ̀ pàtàkì yẹn. (1Tẹ 1:2, 3; 2:20) O ò ṣe gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù tí wọ́n bá wá sí ìjọ yín. O tún lè bá alábòójútó àyíká yín àti ìyàwó rẹ̀ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí tàbí ọ̀kan nínú wọn, ẹ lè jọ lọ sọ́dọ̀ ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Inú wọn máa ń dùn tí wọ́n bá ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ará, títí kan àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di akéde tàbí àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní ìrírí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.
Ṣaájò wọn. O lè gbà wọ́n sílé rẹ tàbí kó o pè wọ́n wá jẹun. Èyí máa fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ wọn. Wọn ò retí pé kó o ṣe nǹkan rẹpẹtẹ.—Lk 10:38-42.
Tẹ́tí sí ìmọ̀ràn àti ìtọ́ni, kó o sì tẹ̀ lé e. Alábòójútó àyíká máa ń jẹ́ ká rí àwọn ibi tá a ti lè sunwọ̀n sí i nínú ìjọsìn wa sí Jèhófà, wọ́n sì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́. Nígbà míì, wọ́n tiẹ̀ lè bá wa wí lọ́nà tó le koko. (1Kọ 5:1-5) Inú alábòójútó àyíká máa dùn tá a bá jẹ́ onígbọràn, tá a sì ń tẹrí ba.—Heb 13:17.
Fi ìmọrírì hàn. Jẹ́ kí alábòójútó àyíká àtìyàwó rẹ̀ mọ àǹfààní tó o rí nínú àwọn nǹkan tí wọ́n ń ṣe. O lè lọ sọ fún wọn lójúkojú, o lè kọ̀wé sí wọn tàbí kó o fún wọn ní ìwé pélébé tí wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.—Kol 3:15.