MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Ìfẹ́ . . . Kì Í Yọ̀ Lórí Àìṣòdodo”
Àwa Kristẹni tòótọ́ máa ń sapá láti jẹ́ kí ìfẹ́ sún wa ṣe gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìfẹ́ “kì í yọ̀ lórí àìṣòdodo.” (1Kọ 13:4, 6) Torí náà, a máa ń yẹra fún eré ìnàjú tó bá ń gbé ìṣekúṣe àti ìwà ipá lárugẹ. Bákan náà, a kì í yọ̀ tí nǹkan burúkú bá ṣẹlẹ̀ sáwọn míì, títí kan àwọn tó ti ṣe ohun tó dùn wá.—Owe 17:5.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ MÁ GBÀGBÉ OHUN TÍ ÌFẸ́ MÁA Ń ṢE—KÌ Í YỌ̀ LÓRÍ ÀÌṢÒDODO, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Kí ni Dáfídì ṣe nígbà tó gbọ́ pé Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì ti kú?
Irú orin wo ni Dáfídì kọ fún Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì?
Kí nìdí tí Dáfídì ò fi yọ̀ nígbà tó gbọ́ pé Sọ́ọ̀lù kú?