ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 2
Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àbúrò Jésù
“Jémíìsì, ẹrú Ọlọ́run àti ti Jésù Kristi Olúwa.” —JÉM. 1:1.
ORIN 88 Mú Mi Mọ Àwọn Ọ̀nà Rẹ
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí lo lè sọ nípa ìdílé tí Jémíìsì ti wá?
INÚ ìdílé tí wọ́n ti ń jọ́sìn Ọlọ́run ni wọ́n ti tọ́ Jémíìsì àbúrò Jésù dàgbà.b Jósẹ́fù àti Màríà ló bí i. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an, wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀ tọkàntọkàn. Jémíìsì tún ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ ní ti pé ẹ̀gbọ́n ẹ̀ ló máa jẹ́ Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. Ẹ wo àǹfààní ńlá tí Jémíìsì ní láti wà nínú ìdílé yẹn!
2. Àwọn nǹkan wo ló mú kí Jémíìsì máa bọ̀wọ̀ fún ẹ̀gbọ́n rẹ̀?
2 Ọ̀pọ̀ nǹkan ló mú kí Jémíìsì máa bọ̀wọ̀ fún ẹ̀gbọ́n rẹ̀. (Mát. 13:55) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù wà lọ́mọ ọdún méjìlá (12), ó mọ Ìwé Mímọ́ gan-an débi pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú kí ẹnu ya àwọn àgbààgbà tọ́ jẹ́ olùkọ́ ní Jerúsálẹ́mù. (Lúùkù 2:46, 47) Ó sì ṣeé ṣe kí Jémíìsì ti bá Jésù ṣiṣẹ́ káfíńtà rí. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á ti mọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ dáadáa. Abájọ tí Arákùnrin Nathan H. Knorr fi máa ń sọ pé: “O máa mọ ẹnì kan dáadáa tó o bá ń bá a ṣiṣẹ́.”c Jémíìsì rí bí ‘ọgbọ́n Jésù ṣe ń pọ̀ sí i, tó ń dàgbà sí i, tó sì ń rí ojúure Ọlọ́run àti èèyàn.’ (Lúùkù 2:52) Torí náà, a lè rò pé ó yẹ kí Jémíìsì wà lára àwọn tó máa kọ́kọ́ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀.
3. Kí ni Jémíìsì ṣe nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀?
3 Nígbà tí Jésù ń ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé, Jémíìsì kò di ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (Jòh. 7:3-5) Ká sòótọ́, Jémíìsì lè wà lára àwọn mọ̀lẹ́bí Jésù tí wọ́n rò pé ‘orí Jésù ti yí.’ (Máàkù 3:21) Kò sì sí ẹ̀rí pé Jémíìsì wà lọ́dọ̀ Màríà ìyá wọn nígbà tí wọ́n pa Jésù lórí òpó igi oró.—Jòh. 19:25-27.
4. Àwọn nǹkan wo la máa kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí?
4 Nígbà tó yá, Jémíìsì nígbàgbọ́ nínú Jésù, ó sì di ọ̀kan lára àwọn alàgbà ìjọ Kristẹni. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa kọ́ ohun méjì lára Jémíìsì: (1) ìdí tó fi yẹ ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti (2) bá a ṣe lè jẹ́ olùkọ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ dáadáa.
JẸ́ ONÍRẸ̀LẸ̀ BÍI TI JÉMÍÌSÌ
5. Kí ni Jémíìsì ṣe nígbà tí Jésù fara hàn án lẹ́yìn tó jíǹde?
5 Ìgbà wo ni Jémíìsì di olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù? Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, “ó fara han Jémíìsì, lẹ́yìn náà, gbogbo àpọ́sítélì.” (1 Kọ́r. 15:7) Lẹ́yìn tí Jésù fara han Jémíìsì, ó di ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Jémíìsì náà wà níbẹ̀ nígbà táwọn àpọ́sítélì fẹ́ gba ẹ̀mí mímọ́ nínú yàrá òkè kan ní Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 1:13, 14) Nígbà tó yá, inú Jémíìsì dùn gan-an pé òun wà lára ìgbìmọ̀ olùdarí nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀. (Ìṣe 15:6, 13-22; Gál. 2:9) Kó tó di ọdún 62 S.K., ẹ̀mí Ọlọ́run darí rẹ̀ láti kọ lẹ́tà sáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. Lẹ́tà yẹn ṣe wá láǹfààní lónìí bóyá ọ̀run la máa gbé tàbí ayé. (Jém. 1:1) Bí Josephus tó jẹ́ òpìtàn nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe sọ, Àlùfáà Àgbà àwọn Júù tó ń jẹ́ Ananáyà Kékeré ló pàṣẹ pé kí wọ́n pa Jémíìsì. Àmọ́, Jémíìsì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà títí tó fi parí iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ láyé.
6. Báwo ni Jémíìsì ṣe yàtọ̀ sáwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà ayé rẹ̀?
6 Jémíìsì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tí Jémíìsì ṣe nípa Jésù àti ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ṣe. Nígbà tí Jémíìsì rí ẹ̀rí tó dájú pé Jésù ni Ọmọ Ọlọ́run, ìrẹ̀lẹ̀ tó ní mú kó gbà pé òótọ́ ni. Àmọ́ àwọn àlùfáà àgbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù ò gbà bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n mọ̀ pé Jésù ló jí Lásárù dìde, àmọ́ wọn ò gbà. Kàkà kí wọ́n gbà pé Jèhófà ló rán Jésù, ńṣe ni wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa Jésù àti Lásárù. (Jòh. 11:53; 12:9-11) Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jésù jíǹde, wọn ò fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ó jíǹde lóòótọ́. (Mát. 28:11-15) Ìgbéraga àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn ni ò jẹ́ kí wọ́n gbà pé Jésù ni Mèsáyà.
7. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa gbéra ga?
7 Ohun tá a rí kọ́: Má ṣe gbéra ga, àmọ́ jẹ́ kí Jèhófà kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́. Bí àrùn ṣe máa ń ṣèpalára fún ọkàn tí kì í jẹ́ kó ṣiṣẹ́ dáadáa, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbéraga kì í jẹ́ ká ṣègbọràn sí Jèhófà. Àwọn Farisí jẹ́ kí ọkàn wọn le débi pé wọn ò gba ẹ̀rí tó dájú tí ẹ̀mí mímọ́ fi hàn wọ́n pé Jésù ni Ọmọ Ọlọ́run. (Jòh. 12:37-40) Ohun tí wọ́n ṣe yẹn léwu gan-an torí kò ní jẹ́ kí wọ́n níyè àìnípẹ̀kun. (Mát. 23:13, 33) Ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa tọ́ wa sọ́nà nínú ìwà wa àti èrò wa, kí wọ́n sì jẹ́ ká máa ṣe ìpinnu tó dáa. (Jém. 3:17) Nítorí pé Jémíìsì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó jẹ́ kí Jèhófà kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́. Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tó ní ló sì mú kó di olùkọ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ dáadáa.
JẸ́ OLÙKỌ́ TÓ MỌ̀Ọ̀YÀN KỌ́ BÍI TI JÉMÍÌSÌ
8. Kí ló máa jẹ́ ká mọ̀ọ̀yàn kọ́ dáadáa?
8 Jémíìsì ò kàwé rẹpẹtẹ. Ó dájú pé ojú táwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà yẹn fi wo àpọ́sítélì Pétérù àti Jòhánù náà ni wọ́n fi wo Jémíìsì torí wọ́n gbà pé “wọn ò kàwé àti pé wọ́n jẹ́ gbáàtúù.” (Ìṣe 4:13) Àmọ́ Jémíìsì kọ́ bó ṣe lè di olùkọ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ dáadáa. Ìwé Bíbélì tí Jémíìsì kọ ló jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀. Bíi ti Jémíìsì, àwa náà lè má kàwé rẹpẹtẹ, àmọ́ ẹ̀mí Jèhófà àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ látọ̀dọ̀ ètò ẹ̀ máa ràn wá lọ́wọ́ láti di olùkọ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ dáadáa. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Jémíìsì yẹ̀ wò nípa bó ṣe jẹ́ olùkọ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́, ká sì wo ohun tá a lè rí kọ́ lára ẹ̀.
9. Kí lo lè sọ nípa ọ̀nà tí Jémíìsì gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́?
9 Jémíìsì ò lo ọ̀rọ̀ kàbìtìkàbìtì, kò sì ṣe àlàyé tó lọ́jú pọ̀. Torí náà, àwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ mohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, wọ́n sì mọ bí wọ́n ṣe máa ṣe é. Bí àpẹẹrẹ, wo ọ̀nà tó rọrùn tí Jémíìsì gbà kọ́ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n fara dà á táwọn èèyàn bá hùwà ìkà sí wọn, kí wọ́n má sì di àwọn èèyàn sínú. Ó sọ pé: “A ka àwọn tó ní ìfaradà sí aláyọ̀. Ẹ ti gbọ́ nípa ìfaradà Jóòbù, ẹ sì ti rí ibi tí Jèhófà jẹ́ kó yọrí sí, pé Jèhófà ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, ó sì jẹ́ aláàánú.” (Jém. 5:11) Ṣé ẹ rí i pé inú Ìwé Mímọ́ ni Jémíìsì ti fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ. Ó lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti jẹ́ kí àwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ rí i pé tí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́ bíi ti Jóòbù, Jèhófà máa fún wọn lérè. Jémíìsì fi ẹ̀kọ́ yẹn kọ́ wọn, ó sì lo àwọn ọ̀rọ̀ tó rọrùn àti àlàyé tí kò lọ́jú pọ̀. Torí náà, ó fi yé wọn pé Jèhófà ló ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ kì í ṣe òun.
10. Ọ̀nà wo la lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jémíìsì nígbà tá a bá ń kọ́ni?
10 Ohun tá a rí kọ́: Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ yéni dáadáa, kó o sì kọ́ni látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, kì í ṣe bí ìmọ̀ wa ṣe tó la fẹ́ fi hàn, àmọ́ a fẹ́ kí wọ́n mọ bí ìmọ̀ Jèhófà ṣe pọ̀ tó àti bó ṣe ń fìfẹ́ hàn sí wọn. (Róòmù 11:33) Á rọrùn fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀ tó bá jẹ́ pé Ìwé Mímọ́ la fi ń kọ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, táwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá fẹ́ ṣèpinnu, a ò ní ṣèpinnu fún wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ronú lórí àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì àti ohun tí Jèhófà máa fẹ́ kí wọ́n ṣe. Ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n ṣe ohun táá múnú Jèhófà dùn, kì í ṣe inú tiwa.
11. Àwọn ìṣòro wo làwọn Kristẹni kan ní nígbà ayé Jémíìsì, ìmọ̀ràn wo ló sì fún wọn? (Jémíìsì 5:13-15)
11 Jémíìsì máa ń sọ òótọ́ ọ̀rọ̀. Ó hàn gbangba nínú lẹ́tà tí Jémíìsì kọ pé ó mọ ìṣòro táwọn ará ní, ó sì fún wọn nímọ̀ràn tó dáa nípa bí wọ́n ṣe máa borí ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Kristẹni kan kì í tètè lo ìmọ̀ràn tí wọ́n bá fún wọn. (Jém. 1:22) Àwọn míì ń ṣojúure sáwọn kan torí pé wọ́n jẹ́ olówó. (Jém. 2:1-3) Àwọn kan tún wà tí wọn ò lè kápá ahọ́n wọn. (Jém. 3:8-10) Àwọn Kristẹni yẹn ní ọ̀pọ̀ ìṣòro, àmọ́ Jémíìsì gbà pé wọ́n ṣì lè yí pa dà. Ó gbà wọ́n nímọ̀ràn lọ́nà tó tura, àmọ́ ó sòótọ́ ọ̀rọ̀ fún wọn. Ó sì gba àwọn tí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà kò gún régé níyànjú láti wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ àwọn alàgbà.—Ka Jémíìsì 5:13-15.
12. Kí nìdí tó fi yẹ ká ní èrò rere tá a bá ń ran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́?
12 Ohun tá a rí kọ́: Máa sọ òótọ́ ọ̀rọ̀, àmọ́ má fojú burúkú wo àwọn èèyàn. Ó lè nira fún ọ̀pọ̀ àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ láti lo ìmọ̀ràn inú Bíbélì. (Jém. 4:1-4) Ó lè gba àkókò kí wọ́n tó jáwọ́ nínú ìwà burúkú, kí wọ́n sì fìwà jọ Kristi. Bíi ti Jémíìsì, ó yẹ ká fìgboyà sọ ibi tó yẹ kí wọ́n ti ṣàtúnṣe. Ó sì tún yẹ ká máa ní èrò rere, ká fọkàn tán Jèhófà pé á fa àwọn onírẹ̀lẹ̀ wá sọ́dọ̀ ara ẹ̀, á sì fún wọn ní agbára láti yí ìgbésí ayé wọn pa dà.—Jém. 4:10.
13. Bó ṣe wà nínú Jémíìsì 3:2 àti àlàyé ìsàlẹ̀, kí ni Jémíìsì kò ṣe?
13 Jémíìsì kò ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Jémíìsì kò rò pé ìdílé tí òun ti wá tàbí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tóun ní mú kóun di èèyàn pàtàkì tàbí kó dọ̀gá lórí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin inú ìjọ. Ó pe àwọn tí wọ́n jọ ń sin Ọlọ́run ní “ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n.” (Jém. 1:16, 19; 2:5) Kò jẹ́ káwọn èèyàn máa rò pé ẹni pípé lòun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi hàn pé òun náà lè ṣàṣìṣe, ó ní: “Gbogbo wa ni a máa ń ṣàṣìṣe lọ́pọ̀ ìgbà.”—Ka Jémíìsì 3:2 àti àlàyé ìsàlẹ̀.
14. Kí nìdí tó fi yẹ ká gbà pé a lè ṣàṣìṣe?
14 Ohun tá a rí kọ́: Ká máa rántí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni gbogbo wa. A ò gbọ́dọ̀ máa rò pé lọ́nà kan, a sàn ju àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Tá a bá jẹ́ kí àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rò pé a ò lè ṣàṣìṣe, wọ́n lè rò pé àwọn ò ní lè ṣègbọràn sí Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀, ìrẹ̀wẹ̀sì á sì bá wọn. Àmọ́ tá a bá fòótọ́ inú sọ fún wọn pé kò rọrùn fáwa náà láti máa tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, tá a sì ṣàlàyé fún wọn bí Jèhófà ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro wa, ìyẹn á ràn wọ́n lọ́wọ́, wọ́n á sì rí i pé àwọn náà lè sin Jèhófà.
15. Kí lo lè sọ nípa àwọn àpèjúwe tí Jémíìsì lò? (Jémíìsì 3:2-6, 10-12)
15 Jémíìsì lo àwọn àpèjúwe tó wọni lọ́kàn. Ó dájú pé ẹ̀mí mímọ́ ló ran Jémíìsì lọ́wọ́, àmọ́ ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó mú kí Jémíìsì mọ bá a ṣe ń fi àpèjúwe kọ́ni ni pé, ó ti kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ lára bí Jésù ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ṣe ń lo àpèjúwe. Àwọn àpèjúwe tí Jémíìsì lò nínú lẹ́tà rẹ̀ rọrùn, àwọn ẹ̀kọ́ inú ẹ̀ sì yéni dáadáa.—Ka Jémíìsì 3:2-6, 10-12.
16. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lo àwọn àpèjúwe tó yéni dáadáa?
16 Ohun tá a rí kọ́: Lo àwọn àpèjúwe tó yéni dáadáa. Tó o bá lo àpèjúwe tó bá ọ̀rọ̀ rẹ mu, ó máa gbé ẹ̀kọ́ inú ọ̀rọ̀ ẹ yọ, á sì jẹ́ kó yéni dáadáa. Àpèjúwe náà á jẹ́ káwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ máa rántí àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tí wọ́n rí kọ́ nínú Bíbélì. Ọ̀gá ni Jésù tó bá dọ̀rọ̀ ká lo àpèjúwe tó yéni dáadáa, àbúrò rẹ̀ Jémíìsì sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀kan lára àpèjúwe tí Jémíìsì lò àti ìdí tó fi yéni dáadáa.
17. Kí nìdí tí àpèjúwe tó wà nínú Jémíìsì 1:22-25 fi wọni lọ́kàn gan-an?
17 Ka Jémíìsì 1:22-25. Jémíìsì lo dígí nínú àpèjúwe rẹ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan ló sì mú kí àpèjúwe náà wọni lọ́kàn. Ó fi kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan pé ká tó lè jàǹfààní látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a ò kàn ní kà á lásán, a gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ lórí ohun tá a kà. Jémíìsì lo àpèjúwe ẹnì kan tó ń wo dígí, ó sì yé àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ dáadáa. Ẹ̀kọ́ wo ló fi kọ́ wa? Ẹ̀kọ́ náà ni pé ìwà òmùgọ̀ ni kí ẹnì kan wo ara ẹ̀ nínú dígí, kó wá rí àbùkù kan tó yẹ kó ṣàtúnṣe ẹ̀, àmọ́ tí kò ṣe bẹ́ẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ ìwà òmùgọ̀ tá a bá ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì rí ohun kan nínú ìwà wa tó yẹ ká yí pa dà, àmọ́ tá ò ṣe bẹ́ẹ̀.
18. Tá a bá fẹ́ lo àpèjúwe, nǹkan mẹ́ta wo ló yẹ ká ṣe?
18 Tá a bá fẹ́ lo àpèjúwe, ó yẹ ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jémíìsì ká sì ṣe nǹkan mẹ́ta yìí: (1) Rí i dájú pé àpèjúwe ẹ bá nǹkan tó ò ń sọ mu. (2) Lo àpèjúwe táá yé àwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ. (3) Jẹ́ kí àpèjúwe ẹ gbé ẹ̀kọ́ tó wà nínú ọ̀rọ̀ ẹ yọ. Tó bá ṣòro fún ẹ láti rí àpèjúwe tó bá ọ̀rọ̀ ẹ mu, lọ wo Watch Tower Publications Index. Wo ìsọ̀rí náà “Illustrations,” wàá rí ọ̀pọ̀ àpèjúwe tó o lè lò. Àmọ́ rántí pé, àpèjúwe dà bí gbohùngbohùn ni, ṣe ló máa ń jẹ́ kí ẹ̀kọ́ tá a fẹ́ fi kọ́ àwọn èèyàn túbọ̀ yé wọn. Torí náà, àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ ẹ nìkan ni kó o máa lo àpèjúwe fún, kì í ṣe gbogbo ohun tó o bá sọ. Síbẹ̀, ká má gbàgbé ìdí pàtàkì tá a fi fẹ́ kí ọ̀nà tá à ń gbà kọ́ni túbọ̀ dáa sí i. Ìdí náà ni pé a fẹ́ ran ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ lọ́wọ́ láti wá di ara ìdílé aláyọ̀ tó ń sin Jèhófà, kì í ṣe láti máa wá ògo ti ara wa.
19. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa?
19 Ẹni pípé ni ẹ̀gbọ́n Jémíìsì, wọ́n sì jọ dàgbà ni. Àwa ò nírú àǹfààní yẹn, àmọ́ a láǹfààní láti máa sin Jèhófà pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tá a jọ jẹ́ Kristẹni. Àá fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn tá a bá ń wà pẹ̀lú wọn, tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn, tá a jọ ń wàásù, tá a sì jọ ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. Tá a bá ń sa gbogbo ipá wa láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jémíìsì nínú bá a ṣe ń ronú, nínú ìwà wa àti ọ̀nà tá à ń gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn á fi hàn pé à ń yin Jèhófà lógo, a sì ń ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ láti wá sọ́dọ̀ Baba wa ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wa.
ORIN 114 Ẹ Máa Ní Sùúrù
a Inú ilé kan náà ni Jémíìsì àti Jésù dàgbà sí, ìyẹn ló jẹ́ kí Jémíìsì mọ Jésù Ọmọ Ọlọ́run dáadáa ju ọ̀pọ̀ èèyàn lọ nígbà yẹn. Àbúrò Jésù ni Jémíìsì, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ń ṣàbójútó nínú ìjọ Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára ẹ̀ àti bó ṣe kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́.
b Kí àpilẹ̀kọ yìí lè yé wa dáadáa, a máa pe Jémíìsì ní àbúrò Jésù. Ìyá kan náà ló bí òun àti Jésù. Ẹ̀rí sì fi hàn pé òun ló kọ ìwé Bíbélì tá à ń pè ní Jémíìsì.
c Arákùnrin Nathan H. Knorr wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Ó parí iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ láyé lọ́dún 1977.
d ÀWÒRÁN: Jémíìsì lo àpèjúwe iná láti fi ṣàlàyé ewu tó wà nínú kéèyàn lo ahọ́n nílòkulò. Àpèjúwe náà sì yé àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ dáadáa torí wọ́n mọ ohun tí iná lè ṣe.