Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ṣé Bíbélì sọ pé kéèyàn máa búra?
Kéèyàn búra túmọ̀ sí kí ẹnì kan “kéde tàbí ṣèlérí níwájú Ọlọ́run pé òun máa ṣe ohun tóun sọ tàbí pé gbogbo ohun tóun bá sọ máa jóòótọ́.” Ó lè fi ẹnu sọ ọ́ tàbí kó kọ ọ́ sílẹ̀.
Àwọn kan lè rò pé kò yẹ kéèyàn máa búra torí Jésù sọ pé: “Má ṣe búra rárá . . . Ẹ ṣáà ti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín, ‘Bẹ́ẹ̀ ni’ jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, kí ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́’ yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́, torí ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà ni ohun tó bá ju èyí lọ ti wá.” (Mát. 5:33-37) Jésù mọ̀ dájú pé Òfin Mósè sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè búra láwọn ipò kan àti pé àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan nígbà àtijọ́ búra. (Jẹ́n. 14:22, 23; Ẹ́kís. 22:10, 11) Jésù tún mọ̀ pé Jèhófà náà búra. (Héb. 6:13-17) Torí náà, Jésù ò sọ pé a ò lè búra rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń kìlọ̀ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n má ṣe máa búra nítorí ohun tí ò tó nǹkan tàbí búra lọ́nà tí kò tọ́. Ó yẹ ká gbà pé tá a bá mú ọ̀rọ̀ wa ṣẹ, ohun tó tọ́ lójú Ọlọ́run la ṣe yẹn. Torí náà, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí bẹ́ẹ̀ ni wa jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni.
Kí lo máa ṣe tí wọ́n bá ní kó o búra? Àkọ́kọ́, rí i dájú pé tó o bá búra, wàá mú ìlérí ẹ ṣẹ. Tí ọ̀rọ̀ kan ò bá dá ẹ lójú, ohun tó dáa jù ni pé kó o má búra rárá. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kìlọ̀ fún wa pé: “Ó sàn kí o má ṣe jẹ́jẹ̀ẹ́ ju pé kí o jẹ́jẹ̀ẹ́, kí o má sì san án.” (Oníw. 5:5) Ìkejì, wo ìlànà Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa ìbúra tó o fẹ́ ṣe, kó o sì wá lo ìlànà náà láti ṣe ìpinnu tí kò ní da ẹ̀rí ọkàn ẹ láàmú. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìlànà Bíbélì tó yẹ kó o ronú lé?
Àwọn ìbúra kan ò lòdì sí ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, níbi ìgbéyàwó àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn tọkọtaya máa ń jẹ́ẹ̀jẹ́. Ìbúra kan ni irú àwọn ẹ̀jẹ́ yìí. Níwájú Ọlọ́run àtàwọn ẹlẹ́rìí, ọkọ àti ìyàwó máa ṣèlérí fún ara wọn pé àwọn máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn, àwọn á máa ṣìkẹ́ ara wọn, àwọn á máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn, àwọn á sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ “níwọ̀n ìgbà tí [àwọn] méjèèjì bá fi jọ wà láàyè.” (Ó lè má jẹ́ bá a ṣe sọ ọ́ níbí yìí ni àwọn tọkọtaya kan ṣe jẹ́ ẹ̀jẹ́ tiwọn, síbẹ̀ ẹ̀jẹ́ ni wọ́n jẹ́ níwájú Ọlọ́run.) Lẹ́yìn náà, wọ́n á di tọkọtaya, àwọn méjèèjì á sì jọ máa gbé títí láé. (Jẹ́n. 2:24; 1 Kọ́r. 7:39) Ẹ̀jẹ́ tí wọ́n jẹ́ yìí dáa, ó bójú mu, ó sì bá ohun tí Ọlọ́run fẹ́ mu.
Àwọn ìbúra kan ta ko ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Kristẹni olóòótọ́ kan ò ní gbà tí wọ́n bá ní kó wá búra pé òun máa jagun láti gbèjà orílẹ̀-èdè òun tàbí tí wọ́n bá ní kó búra pé òun ò ní sin Ọlọ́run mọ́. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó ti rú òfin Ọlọ́run nìyẹn. Bíbélì sọ pé àwa Kristẹni tòótọ́ “kì í ṣe apá kan ayé,” torí náà a kì í lọ́wọ́ sí àwọn àríyànjiyàn àti ogun tó ń lọ nínú ayé.—Jòh. 15:19; Àìsá. 2:4; Jém. 1:27.
Àwọn ìbúra kan wà tí ẹ̀rí ọkàn Kristẹni kan lè gbà á láyè láti ṣe. Nígbà míì, tá a bá fẹ́ búra ó lè gba pé ká ronú jinlẹ̀ lórí ìmọ̀ràn tí Jésù gbà wá pé, “ẹ san àwọn ohun ti Késárì pa dà fún Késárì, àmọ́ ẹ fi àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”—Lúùkù 20:25.
Àpẹẹrẹ kan rèé. Ká sọ pé Kristẹni kan fẹ́ gba ìwé ìgbélùú tàbí ìwé ìrìn àjò lọ sórílẹ̀-èdè míì, wọ́n sì sọ fún un pé ó ní láti búra kó tó lè gba àwọn ìwé náà. Tó bá jẹ́ pé irú ìbúra tí wọ́n ń ṣe lórílẹ̀-èdè náà máa jẹ́ kó rú òfin Ọlọ́run, ẹ̀rí ọkàn Kristẹni náà ò ní jẹ́ kó búra torí ohun tó ti kọ́ nínú Bíbélì. Àmọ́ tí ìjọba orílẹ̀-èdè náà bá gbà á láyè láti yí àwọn ọ̀rọ̀ kan nínú ìbúra náà pa dà, ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ lè jẹ́ kó búra.
Tẹ́nì kan bá yí àwọn ọ̀rọ̀ inú ìbúra kan pa dà kí ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ lè gbà á láyè láti búra, ìyẹn ò lòdì sí ìlànà tó wà nínú Róòmù 13:1 tó ní: “Kí gbogbo èèyàn máa tẹrí ba fún àwọn aláṣẹ onípò gíga.” Torí náà, Kristẹni kan lè pinnu pé kò sóhun tó burú nínú kóun búra lórí ohun kan, tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run ti fọwọ́ sí i káwọn Kristẹni máa ṣe é.
Bákan náà, tí wọ́n bá ní kí Kristẹni kan fi ohun kan búra tàbí kó ṣe àmì kan nígbà tó bá ń búra, ó gbọ́dọ̀ ronú lórí ohun tó ti kọ́ nínú Bíbélì kí ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ má bàa dà á láàmú. Nígbà àtijọ́, àwọn ará Róòmù àtàwọn Síkítíánì máa ń fi idà búra, wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ láti fi hàn pé ọlọ́run ogun gba ẹ̀rí àwọn jẹ́. Bákan náà, àwọn Gíríìkì máa ń na ọwọ́ kan sókè nígbà tí wọ́n bá ń búra. Wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ láti fi hàn pé ẹnì kan wà lọ́run tó ń gbọ́ ohun táwọn ń sọ, tó sì ń rí ohun táwọn ń ṣe. Wọ́n sì gbà pé òun ni gbogbo èèyàn máa jíhìn fún.
Ó dájú pé tí wọ́n bá ní kí ìránṣẹ́ Jèhófà kan búra, kò ní fi ẹnu ko àsíá tàbí àwọn nǹkan míì tó jẹ mọ́ ìjọsìn èké, kò sì ní forí balẹ̀ fún wọn. Àmọ́, kí lo máa ṣe tí wọ́n bá sọ fún ẹ nílé ẹjọ́ pé kó o gbé ọwọ́ lé Bíbélì, kó o sì búra pé òótọ́ ni gbogbo ẹ̀rí tó o máa jẹ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o lè ṣe bẹ́ẹ̀ torí Bíbélì sọ nípa àwọn olóòótọ́ èèyàn tí wọ́n lo ohun kan láti fi búra. (Jẹ́n. 24:2, 3, 9; 47:29-31) Tó o bá ń búra, o gbọ́dọ̀ máa rántí pé iwájú Ọlọ́run lo ti ń búra àti pé o máa sọ òótọ́. Torí náà, rí i pé o sọ òótọ́ tí wọ́n bá bi ẹ́ ní ìbéèrè èyíkéyìí.
Tí wọ́n bá ní kó o búra, ó yẹ kó o fi ọ̀rọ̀ náà sádùúrà, kó o sì rí i pé o ò ṣe ohun tó máa da ẹ̀rí ọkàn ẹ láàmú àti pé o ò rú ìlànà Bíbélì torí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà ló ṣe pàtàkì jù lọ. Torí náà kó o tó búra, rí i dájú pé wàá lè mú ìlérí ẹ ṣẹ.—1 Pét. 2:12.