Kí Ni Ogun Amágẹ́dọ́nì?
Ohun tí Bíbélì sọ
Ogun Amágẹ́dọ́nì ni ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run tí yóò fòpin sí ìṣàkóso èèyàn. Títí di báyìí, àwọn ìjọba èèyàn àti àwọn tó ń tì wọ́n lẹ́yìn ń ta ko Ọlọ́run ní ti pé wọn ò fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀. (Sáàmù 2:2) Ogun Amágẹ́dọ́nì ló máa fòpin sí ìṣàkóso èèyàn.—Dáníẹ́lì 2:44.
Ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni ọ̀rọ̀ náà “Amágẹ́dọ́nì” fara hàn nínú Bíbélì, inú ìwé Ìṣípayá 16:16 ló sì ti fara hàn. Àsọtẹ́lẹ̀ kan nínú ìwé Ìfihàn tàbí Ìṣípayá fi hàn pé “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá” ni a ò kó jọ pọ̀ sí “ibi tí a ń pè ní Ha-Mágẹ́dọ́nì lédè Hébérù,” “sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.”—Ìṣípayá 16:14.
Àwọn wo ni yóò ja ogun Amágẹ́dọ́nì? Jésù máa lo àwọn ọmọ ogun ọ̀run láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá Ọlọ́run. (Ìṣípayá 19:11-16, 19-21) Àwọn ọ̀tá yìí làwọn tí kò bọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ Jèhófà.—Ìsíkíẹ́lì 39:7.
Ṣé Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ni ogun Amágẹ́dọ́nì yóò ti jà ni? Rárá o. Kì í ṣe apá ibì kan ni ogun Amágẹ́dọ́nì ti máa jà bí kò ṣe gbogbo ilẹ̀ ayé pátá.—Jeremáyà 25:32-34; Ìsíkíẹ́lì 39:17-20.
Amágẹ́dọ́nì tá a tún máa ń pè ní “Ha-Mágẹ́dọ́nì” (Hébérù Har Meghiddohnʹ), túmọ̀ sí “Òkè Ńlá Mẹ́gídò.” Ìlú Mẹ́gídò wà ní ìpínlẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́. Ìtàn jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ogun àjàmọ̀gá làwọn èèyàn ti jà ní tòsí ibẹ̀ tó fi mọ́ àwọn ogun kan tí Bíbélì mẹ́nu bà pàápàá. (Àwọn Onídàájọ́ 5:19, 20; 2 Àwọn Ọba 9:27; 23:29) Àmọ́, a ò lè sọ pé ibì kan tó wà ní tòsí Mẹ́gídò ni Amágẹ́dọ́nì. Kò sí òkè ńlá kankan níbẹ̀ àti pé Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Rírẹlẹ̀ Jésíréélì to tún sún mọ́ ọn ò lè gba èrò tó pọ̀ tó ti àwọn tó fẹ́ bá Ọlọ́run jagun. Kàkà bẹ́ẹ̀, Amágẹ́dọ́nì ni ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ jákèjádò ayé, tí gbogbo orílẹ̀ èdè á kóra jọ pọ̀ lòdì sí ìṣàkóso Jèhófà.
Báwo ni nǹkan ṣe máa rí nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ bí Jèhófà ṣe máa lo agbára rẹ̀ síbẹ̀ a mọ̀ pé ó lè lo àwọn nǹkan bíi yìnyín, ìmìtìtì ilẹ̀, àgbáàràgbá òjò, iná àti imí ọjọ́, mànàmáná àti àjàkálẹ̀ àrùn. (Jóòbù 38:22, 23; Ìsíkíẹ́lì 38:19, 22; Hábákúkù 3:10, 11; Sekaráyà 14:12) Àwọn kan lára àwọn ọ̀tá Ọlọ́run yìí à tún kọjú ìjà sí ara wọn látàrí ìdàrúdàpọ̀ tó máa wáyé láàárín wọ́n, lẹ́yìn ìgbà náà ni wọ́n á wá rí i pé Ọlọ́run ló ń bá àwọn jà.—Ìsíkíẹ́lì 38:21, 23; Sekaráyà 14:13.
Ṣé àmì òpin ayé ni ogun Amágẹ́dọ́nì? Níwọ̀n bí ayé ti jẹ́ ibi tí àwa èèyàn á máa gbé títí láé, torí náà kì í ṣe ogun Amágẹ́dọ́nì ló máa pa ayé yìí run. (Sáàmù 37:29; 96:10; Oníwàásù 1:4) Dípò kí ogun Amágẹ́dọ́nì pa ẹ̀dá èèyàn run, ńṣe ló máa gba ẹ̀mí là, torí pé “ogunlọ́gọ̀ ńlá” àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run yóò yè.—Ìṣípayá 7:9, 14; Sáàmù 37:34.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì máa ń sọ̀rọ̀ nípa ilẹ̀ ayé, nígbà míì tí Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ nípa “ayé”, ńṣe ló ń tọ́ka sí àwùjọ èèyàn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (1 Jòhánù 2:15-17) Torí náà, Amágẹ́dọ́nì ló máa ṣe okùnfà “òpin ayé.”—Mátíù 24:3, Ìròhìn Ayọ̀.
Ìgbà wo ni ogun Amágẹ́dọ́nì máa bẹ̀rẹ̀? Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ìpọ́njú ńlá tó máa dópin nígbà Ogun Amágẹ́dọ́nì, ó sọ pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹnì kankan tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba nìkan.” (Mátíù 24:21, 36) Àmọ́ ṣá o, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Amágẹ́dọ́nì á wáyé nígbà wíwàníhìn-ín Jésù tó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1914.—Mátíù 24:37-39.