Saturday, November 23
Gbogbo wọn tẹra mọ́ àdúrà pẹ̀lú èrò tó ṣọ̀kan.—Ìṣe 1:14.
Ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń jẹ́ ká lè máa ṣiṣẹ́ ìwàásù. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Sátánì ń gbógun tì wá kó lè dá iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe dúró. (Ìfi. 12:17) Tá a bá fojú èèyàn wò ó, a ò lè borí Sátánì. Àmọ́ bá a ṣe ń wàásù nìṣó, ṣe là ń ṣẹ́gun Sátánì! (Ìfi. 12:9-11) Lọ́nà wo? Tá a bá ń wàásù, ṣe là ń fi hàn pé ẹ̀rù Sátánì ò bà wá bó ṣe ń halẹ̀ mọ́ wa. Gbogbo ìgbà tá a bá ń wàásù, ṣe là ń ṣẹ́gun Sátánì. Torí náà, a lè sọ pé ohun tó ń ràn wá lọ́wọ́ ni ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run àti bá a ṣe mọ̀ pé inú Jèhófà ń dùn sí wa. (Mát. 5:10-12; 1 Pét. 4:14) Ó dá wa lójú pé ẹ̀mí Ọlọ́run máa ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro èyíkéyìí tá a bá bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (2 Kọ́r. 4:7-9) Torí náà, kí la lè ṣe kí Ọlọ́run lè máa fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀? Gbogbo ìgbà ló yẹ ká máa bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀, kó sì dá wa lójú pé ó máa gbọ́ àdúrà wa. w22.11 5 ¶10-11
Sunday, November 24
Ẹ̀yin ará, à ń rọ̀ yín pé kí ẹ máa kìlọ̀ fún àwọn tó ń ṣe ségesège, ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn tó sorí kọ́, ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ẹ máa mú sùúrù fún gbogbo èèyàn.—1 Tẹs. 5:14.
A máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú wọn. Táwọn èèyàn bá ṣẹ̀ wá, a máa ń dárí jì wọ́n bíi ti Jèhófà. Tí Jèhófà bá lè yọ̀ǹda Ọmọ ẹ̀ kó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, ṣé kò wá yẹ káwa náà dárí ji àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tí wọ́n bá ṣẹ̀ wá? A ò ní fẹ́ dà bí ẹrú burúkú tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú ọ̀kan lára àkàwé rẹ̀. Lẹ́yìn tí ọ̀gá rẹ̀ fagi lé gbèsè ńlá tó jẹ, ẹrú yẹn kọ̀ láti dárí ji ẹrú míì tó jẹ ẹ́ ní gbèsè tí ò tó nǹkan. (Mát. 18:23-35) Torí náà, tí èdèkòyédè bá wà láàárín ìwọ àti ẹnì kan nínú ìjọ, ṣé o lè kọ́kọ́ lọ yanjú ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ẹni yẹn, kí àlàáfíà lè wà kó o tó wá sí Ìrántí Ikú Kristi? (Mát. 5:23, 24) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn máa fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù gan-an. w23.01 29 ¶8-9
Monday, November 25
Ẹni tó ń ṣojúure sí aláìní, Jèhófà ló ń yá ní nǹkan.—Òwe 19:17.
Ọ̀nà kan tó o lè gbà mọ ohun táwọn ará fẹ́ ni pé kó o fọgbọ́n bi wọ́n láwọn ìbéèrè táá jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́. (Òwe 20:5) O lè bi wọ́n pé ṣé ẹ ní oúnjẹ, oògùn àtàwọn nǹkan míì tẹ́ ẹ nílò? Ṣé wọn ò máa dín àwọn òṣìṣẹ́ kù níbi iṣẹ́ yín, ṣé ẹ ṣì ń rówó ilé san? O tún lè bi wọ́n pé ṣé wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ kí wọ́n lè rí nǹkan tí ìjọba ṣètò fáwọn aráàlú gbà? Ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé ká máa fún ara wa níṣìírí, ká sì máa ran ara wa lọ́wọ́. (Gál. 6:10) Kódà tó bá jẹ́ ọ̀rọ̀ ìtùnú díẹ̀ la sọ fún ẹnì kan tó ń ṣàìsàn, ó lè mú kára ẹ̀ yá gágá. Ọmọ kékeré kan lè fi káàdì tàbí àwòrán tó yà ránṣẹ́ sí arákùnrin kan láti fún un níṣìírí. Ọ̀dọ́ kan lè lọ bá arábìnrin kan jíṣẹ́ tàbí kó lọ bá a ra nǹkan lọ́jà. Àbí ṣé a lè se oúnjẹ fún ẹnì kan tí ara ẹ̀ ò yá? Àwọn ará kan ti fi lẹ́tà ìdúpẹ́ ránṣẹ́ sáwọn alàgbà tí wọ́n ṣiṣẹ́ kára lákòókò àjàkálẹ̀ àrùn. Ẹ ò rí i pé ó máa dáa gan-an tá a bá ń ‘fún ara wa níṣìírí, tí a sì ń gbé ara wa ró!’—1 Tẹs. 5:11. w22.12 22 ¶2; 23 ¶5-6