Sáàmù
Sí olùdarí; kí a yí i sí “Má Ṣe Pa Á Run.” Ti Dáfídì. Míkítámù.*
58 Ṣé ẹ lè sọ nípa òdodo nígbà tó jẹ́ pé ńṣe lẹ dákẹ́?+
Ṣé ẹ lè fi òdodo ṣe ìdájọ́, ẹ̀yin ọmọ èèyàn?+
3 Àwọn ẹni burúkú ti ṣìnà* látìgbà tí wọ́n ti bí wọn;*
Oníwàkiwà ni wọ́n, òpùrọ́ sì ni wọ́n látìgbà tí wọ́n ti bí wọn.
5 Kì í fetí sí ohùn àwọn atujú,
Kò sí bí wọ́n ṣe mọ ọfọ̀ pè tó.
6 Ọlọ́run, gbá eyín wọn yọ kúrò lẹ́nu wọn!
Fọ́ páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ àwọn kìnnìún yìí,* Jèhófà!
7 Kí wọ́n pòórá bí ìgbà tí omi bá gbẹ.
Kí Ó tẹ ọrun rẹ̀, kí ọfà rẹ̀ sì mú kí wọ́n ṣubú.
8 Kí wọ́n dà bí ìgbín tó ń yọ́ dà nù bó ṣe ń lọ;
Bí ọmọ tí obìnrin kan bí ní òkú, tí kò rí oòrùn.
9 Kí àwọn ìkòkò oúnjẹ yín tó mọ iná igi ẹlẹ́gùn-ún lára,
Ọlọ́run yóò gbá ẹ̀ka tútù àti èyí tó ń jó, bí ìgbà tí ìjì bá gbá nǹkan dà nù.+
11 Nígbà náà, aráyé á sọ pé: “Dájúdájú, èrè wà fún olódodo.+
Ní tòótọ́, Ọlọ́run kan wà tó ń ṣe ìdájọ́ ayé.”+